Windows

  Àkópọ̀ Òjíṣẹ́ Èdè Windows 7

  Yi Ede Pada:
  Àkópọ̀ Òjíṣẹ́ Èdè Windows 7 (LIP) máa pèsè òjíṣẹ́ aṣàmúlò tí a tí sọ àwọn àgbègbpe tí à ǹlò júlọ nínú Windows 7 di ìbílẹ̀.
  • Note:There are multiple files available for this download.Once you click on the "Download" button, you will be prompted to select the files you need.
   Ẹya:

   1.0

   Orukọ Faili:

   LIP_yo-NG-32bit.mlc

   LIP_yo-NG-64bit.mlc

   Ọjọ Igbejade:

   23/2/1432

   Iwọn Faili:

   2.6 MB

   4.1 MB

    Àkópọ̀ Òjíṣẹ́ Èdè Windows (LIP) máa pèsè ẹ̀yà Windows tí a máa ńlò jùlọ tí a ti túmọ̀. Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe ìfiṣípò LIP, àyòkà inú onímọ̀, àwọn àpòtí ìjíròrò, àwọn mẹ́nù, àti àwọn àkọlé Ìrànlọ́wọ́ àti Àtìlẹ̀yìn máa farahàn ní èdè LIP. Àyọkà tí a kò bá túmọ̀ máa wà ní ìpilẹ̀ èdè Windows 7. Fún àpẹẹrẹ, tí o bá ra ẹ̀yà Windows 7 Spanish tí o ṣe ìfiṣípò Catalan LIP, àwọn àyọkà kan máa sì wà ní Spanish. O le ṣe ìfiṣípò jú Windows LIP kan lórí ìpìlẹ̀ èdè kansoso. O le ṣe ìfiṣípò àwọn LIP lórí gbogbo ẹ̀yà Windows 7.
  • Awọn Ohun Elo Isẹ-sişe ti a Gbarukuti:

   Windows 7

    • Windows 7 Microsoft
    • Ìfiṣípò ìpìlẹ̀ èdè Windows 7 tí a bèèrè fún: Gẹ̀ẹ́sì
    • 4.63 Mb ààyè tó sófo fún àgbàsílẹ̀
    • 15 Mb ààyè tó sófo fún àgbékalẹ̀

   • ÌKÌLỌ̀: Tí o bá ní Ìpàrokò BitLocker nípò ìmúṣiṣẹ́, jọ̀wọ́ dáwọ́ rẹ̀ dúró kí o tó máa ṣe ìfiṣípò LIP. Ṣí Control Panel, yan System and Security, lẹ́yìn èyí BitLocker Drive Encryption. Tẹ Suspend Protection.

    Nítorípé àgbàsílẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó wà fún àwọn ẹ̀yà LIP Windows 7 oníbíìtì 32 àti oníbíìti 64, kí o tó bẹ̀rẹ̀ àgbàsílẹ̀, o níláti mọ irú ẹ̀yà Windows 7 tí o ṣe ìfiṣípò rẹ̀: Èyí ni bí o ṣe máa mọ irú ẹ̀yà Windows 7 tí o ṣe ìfiṣípò rẹ̀:

    Tẹ bọ́tìnnì Start lẹ́yìn èyí kí o ṣe ìtẹ-ọ̀tún lórí kọ̀ǹpútà kí o wá yan Properties. Èléyìí yóò gbé àwọn ìwífún tó ṣe kókó nípa kọ̀ǹpútà rẹ jáde.
    Wo abala Ẹ̀rọ fún irú Ẹ̀rọ. Eléyìí yóò sọ bí Ìlànà-ètò ìmú ṣiṣẹ́ Windows 7 bá jẹ́ oníbíìtì 32 tàbí oníbíìtì 64.

    Láti ṣe ìfisípò ẹ̀yà 32-biìtì, o le ṣe ọ̀kan nínú ìwọ̀nyìí:

    1. Tẹ bọ́tìnnì Download, lẹ́hìn náà tẹ Open láti ṣe ìfisípò LIP náà


    2. tàbí

    3. Tẹ bọ́tìnnì Download
     • Tẹ Saveláti ṣẹ̀dá fáìlì náà sí orí kọ̀ǹpútà rẹ,
     • Ṣàwárí ibi tí fàìlì tí a ti ṣe àgbàsílẹ̀ rẹ̀ wà kí ó tẹ̀ẹ́ lẹ́ẹ̀mejì láti ṣe ìfisípò LIP náà

    Láti ṣe ìfisípò ẹ̀yà 64-biìtì, O gbọ́dọ̀ ṣe ìfisípò ẹ̀yàn kejì tí a ṣàlàyé lókè yìí.

  Awọn Gbaa Lati Ayelujara to Gbajumọ

  Loading your results, please wait...

  Awọn ìmúdójúìwọ̀n PC ọ̀fẹ́

  • Awọn ìmúdójúìwọ̀n aṣàtúnṣe sí àbò
  • Awọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú
  • Awọn àkójọpọ̀ iṣẹ́
  • Awọn awakọ̀ ẹ̀yà àfojúrí