Office

  Microsoft Office Language Interface Pack 2007 – Yorùbá

  Yi Ede Pada:
  Microsoft Office Language Interface Pack 2007 – Yorùbá náà ń pèsè atọ́kùn aṣàmúlò Yorùbá fún ọ̀pọ̀ àwọn ètò Microsoft Office 2007.
  • Note:There are multiple files available for this download.Once you click on the "Download" button, you will be prompted to select the files you need.
   Ẹya:

   1

   Orukọ Faili:

   LanguageInterfacePack.exe

   LIP_Help.chm

   Ọjọ Igbejade:

   10/5/1431

   Iwọn Faili:

   14.5 MB

   231 KB

    Microsoft Office Language Interface Pack 2007 – Yorùbá náà ń pèsè atọ́kùn aṣàmúlò Yorùbá fún:
    • Microsoft Office Excel 2007

    • Microsoft Office Outlook 2007

    • Microsoft Office PowerPoint 2007

    • Microsoft Office Word 2007
  • Awọn Ohun Elo Isẹ-sişe ti a Gbarukuti:

   Windows Vista Service Pack 2

    • Ẹ̀yà àìrídìmú tí o níílò: Ìṣẹ̀dà èdè gẹ̀ẹ́sì èyíkèyí nínú àkópọ̀ ti Microsoft Office 2007 ń ní Excel, Outlook, Powerpoint tàbí Word.
    • Ààyè àwo-àká-ọ̀rọ̀ tí o níílò:Ní àfikún sí ààyè àwo-àká-ọ̀rọ̀ ti àwọn ètò Office 2007 tóti wà nílẹ̀ ń lò, o níílò ààyè 20mb.
   • Láti ṣàgbékalẹ̀ ìgbàsílẹ̀ yìí:
    1. Ṣègbàsílẹ̀ LanguageInterfacePack.exe fáìlì náà nípa títẹ bọ́tìnìṢègbàsílẹ̀ (lókè) kí o sì fi fáìlì náà pamọ́ sórí àwo-àká-ọ̀rọ̀ rẹ.
    2. Ṣíratẹ-lẹ́ẹ̀mejì LanguageInterfacePack.exe fáìlì ètò náà lórì àwo-àká-ọ̀rọ̀ rẹ láti bẹ̀rẹ̀ Àgbékalẹ̀ ètò náà.
    3. Tẹ̀lé àwọn àlàyé tó wà lójú aṣàfihàn rẹ láti parí ètò náà.
    4. Tí o bá ti ṣe tán, fáìlì kàmí fún Microsoft Office 2007 Language Interface Pack yíóò ti wà ní C:\Àwọn Fáìlì Ètò\Àwọn Fáìlì Tówọ́pọ̀\pínpínmicrosoft\OFFICE12\LCID\LIPread.htm
    5. Ṣíṣàfikún Office 2003 pẹ̀lú Office 2003 Language Interface Pack sí Office 2007 pẹ̀lú Office 2007 Language Interface Pack kò ṣeé ṣe. Tí o bá fẹ́ ṣàfikún Office 2003 tówà nílẹ̀ di Office 2007 pẹ̀lú Office 2007 Language Interface Pack o gbọ́dọ̀:
     • Ṣàyọkúrò Office 2003 Language Interface Pack
     • Ṣí àgbékalẹ̀ Office 2007 kí o sì yan ẹ̀yàn àfikún.
     • Nígbàtí àgbékalẹ̀ Office 2007 bá parí, ṣàgbékalẹ̀ kí o sì ṣàtòpọ̀ Office 2007 Language Interface Pack

     • Ìmúṣiṣẹ́ ẹ̀yà Office rẹ:
     • Aìíbàámọ̀, bí o bá ń ní ìṣòrò láti ka gbogbo ẹnà tí ó wà lórí atọ́kùn "Microsoft Office Activation Wizard", tàbí tí gbogbo ẹnà ìṣàgbékalẹ̀ náà kò ba hàn dáradára ní ìgbà tí o bá ń lo Microsoft® Office Language Interface Pack 2007, jọ̀wọ́ ṣàparẹ́ atọ́kùn alàgàta kí o sì lọ lo èyà èdè gẹ̀ẹ́sì rẹ láti ṣàmúṣiṣẹ́ ẹ̀yà Microsoft Office rẹ.


    Àlàyé fún lílò:

    Láti yí Atọ́kùn Aṣàmúlò rẹ sí èdè ti Microsoft Office Language Interface Pack 2007 – Yorùbá, tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí:

    1. Ṣí Àwọn Àgbékalẹ̀ Èdè Microsoft Office 2007 láti mẹ́nùBẹ̀rẹ̀\Gbogbo àwọn Ètò\Microsoft Office\Àwọn Irinṣẹ́ Microsoft Office náà.
    2. Yan táàbùṢàfihàn Èdèlẹ́yìn náà, nínú Ṣàfihàn àwọn mẹ́nù Microsoft Office àti àwọn àpótí ìjíròrò nínú: àtòjọ àsẹ́yọ, yan èdè tí o fẹ́ kì ò máa hàn. Èdè tí o yàn yìí ni yíóò máa hàn látì ìsìnyí lọ.
    3. Nínú táàbù Ṣàfihàn Èdè o lè ṣètò kí àfihàn Office bá àfihàn Windows rẹ mu. A ó kọ èdè tí Windows ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ fún ọ. Tí o bá fẹ́ kí àfihàn Office bá àfihàn Windows rẹ mu, yan Ṣètò kí èdè àfihàn Microsoft Office bá èdè àfihàn Windows munínú àpótí ẹ̀yàn. Ẹ̀yàn yìí fagilé ẹ̀yàn tí o ṣe nínú Ṣàfihàn àwọn ètò iṣẹ́ àti àwọn àpótí ìjíròrò Microsoft Office àkọsílẹ̀.
    4. Nínú táàbù ìṣàtúnṣe àwọn Èdè yan èdè tí o nílò nínú Àwọn Èdè Ìṣàtúnṣe tí ó wànílẹ̀ kí o sì tẹṢàmúmọ́.. Èdè tí o yàn yìí yíóò bọ́ sí àkọsílẹ̀ lára Àwọn Èdè tí alè lò.
    5. Nínú táàbù Èdè Ìṣàtúṣe yan èdè tí o fẹ́ kí ó jẹ́ ààyò Èdè Ìṣàtúṣe látiinú àtòkọ Ààyò Èdè Ìṣàtúṣenáà.
    6. Tẹ̀bọ́tìnì Bẹ́ẹ̀ni.

    Èdè tí o ti yàn yíò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìgbà tí o bá tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí Office.
    Àkíyèsí:" A kò le yí ìrànwọ́ sí èdè Microsoft Office Language Interface Pack 2007 – Yorùbá. Ìrànwọ́ yíò máa wà ní èdè tí o fi kọ́kọ́ ṣàgbékalẹ . "
    Máa ṣàgbékalẹ̀ àfihàn ìrànwọ́ lórí àtòjọ asẹ́yọ sí èdè ìpìlẹ̀.

    Láti yọ ìgbàsílẹ̀ yìí kúrò:
     Tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí lórí Windows XP Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀sí ti Ilé tàbí Òṣìṣẹ́:
    1. Jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ètò tí ò ń lò lọ́wọ́.
    2. Ṣíra-tẹ àwòrán-aṣàmì Ṣàfikún tàbí Yọ àwọn Ètò kúrò ní Pánẹ̀lì Ìdarí Windows lẹ́ẹ̀mejì.
    3. TẹMicrosoft Office Language Interface Pack 2007 nínú àpótí Àwọn ètò tí a fisíi lọ́wọ́lọ́wọ́ lẹ́yìn náà, tẹ bọ́tìnì Yọkúrò.
    4. Tẹ̀lé àwọn ìwífún lóríi dígí kọ̀mpútà náà.

     Tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí lóríi Windows Vista:
    1. Jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ètò tí ò ń lò lọ́wọ́.
    2. Tẹ-lẹ́ẹ̀mejì àwòrán aṣàmì Àwọn Àbùdá àti Ètò ní Pánẹ̀lì Ìdarí Windows náà.
    3. Nínú ẹ̀yàn Ṣàìfisí tàbí Ṣàyípadà Ètò kan tẹ, Microsoft Office Language Interface Pack 2007 – Yorùbá nínú àpótí Àwọn ètò tí a fisíi lọ́wọ́lọ́wọ́ lẹ́yìn náà, yan ẹ̀yàn Ṣàìfisí.
    4. Tẹ̀lé àwọn ìwífún lóríi dígí kọ̀mpútà náà.

  Awọn Gbaa Lati Ayelujara to Gbajumọ

  Loading your results, please wait...

  Awọn ìmúdójúìwọ̀n PC ọ̀fẹ́

  • Awọn ìmúdójúìwọ̀n aṣàtúnṣe sí àbò
  • Awọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú
  • Awọn àkójọpọ̀ iṣẹ́
  • Awọn awakọ̀ ẹ̀yà àfojúrí