Office

  Microsoft® Office Language Interface Pack 2013 – Yorùbá

  Yi Ede Pada:
  Microsoft Office Language Interface Pack 2013 - Yorùbá ń pèsè Atọ́kùn Asàmúlò ìtúmọ̀ èdè kan fún ọ̀pọ̀ àwọn ìfilọ́lẹ̀ Microsoft Office 2013.
  • Note:There are multiple files available for this download.Once you click on the "Download" button, you will be prompted to select the files you need.
   Ẹya:

   2013

   Orukọ Faili:

   languageinterfacepack-x86-yo-NG.exe

   languageinterfacepack-x64-yo-NG.exe

   Ọjọ Igbejade:

   15/4/1434

   Iwọn Faili:

   12.8 MB

   12.9 MB

    Microsoft Office Language Interface Pack 2013 - Yorùbá ń pèsè Atọ́kùn Asàmúlò tí ìtúmọ̀ èdè fún àwọn ìfilọ́lẹ̀ wọ̀nyí Microsoft Office 2013:

   • Microsoft Excel® 2013

   • Microsoft OneNote® 2013

   • Microsoft Outlook® 2013

   • Microsoft PowerPoint® 2013

   • Microsoft Word® 2013


   • Nípa lílo Microsoft Office Language Interface Pack 2013 - Yorùbá, àwọn asàmúlò le sisé nínú àwọn ojúlówó ẹ̀yà àgbékalẹ̀ tí a tìlẹ́yìn ti àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office kí wọ́n si wo àwọn àsẹ àti àwọn ẹ̀yàn fún àwọn ìfilọ́lẹ̀ náà ní - Yorùbá.

    Ní àkókò àgbékalẹ̀ Microsoft Office Language Interface Pack 2013, àwọn fáìlì tí ń gba àwọn asàmúlò láàyè láti yí èdè atọ́kùn asàmúlò padà ni a sẹ̀dà sí èbúté àwo gbagidi. Lẹ́yìn àgbékalẹ̀, Microsoft Office Language Interface Pack 2013 - Yorùbá àwọn àgbára àti àwọn ẹ̀yàn tójọra wà láti àárín àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office 2013 àti ìfilọ́lẹ̀ Microsoft Office 2013 Language Settings.
  • Awọn Ohun Elo Isẹ-sişe ti a Gbarukuti:

   Windows 7, Windows 8

     Microsoft Windows 7 - 32 tàbí 64 biti OS
     Microsoft Windows 8 - 32 tàbí 64 biti OS
     Àkíyèsí: Jọ̀wọ́ sàrídájú láti sàgbékalẹ̀ Àwọn Àkópọ̀ Isẹ́ tuntun fún Ìlànà-ètò Ìmú Sisẹ́ rẹ láti sàrídájú àtìlẹ́yìn dáradára fún èdè rẹ.

    Ẹ̀yà Àìrídìmú Ẹ̀yà kankan ti ìkópọ̀ Office 2013 tàbí ìdádúró tó ní Microsoft Excel, Microsoft OneNote, Microsoft Outlook, Microsoft PowerPoint tàbí Microsoft Word tàbí ni yóò sàtìlẹ́yìn fún Microsoft Office Language Interface Pack 2013 - Yorùbá. Àkíyèsí: Jọ̀wọ́ Sàrídájú láti sàgbékalẹ̀ Microsoft Office Service Packs tuntun fún àwọn ohun ìgbéjáde Microsoft Office rẹ. Èyí yóò sàrídájú ìrírí asàmúlò tó dára.

    Kọ̀ǹpútà àti Odo Ìsirò Kọ̀ǹpútà Odo ìsirò kọ̀ǹpútà 1 GHz pẹ̀lú àtìlẹ́yìn SSE2 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ; 2 GB RAM tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ

    Ààyè àwo Ní àfikún sí ààyè àwo gbagidi èyí tí àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office 2013 tí a sàgbékalẹ̀ lò,
   • 3 GB ti ààyè àwo gbagidi tó wà.

   • Gbogbo àwọn àmúyẹ ẹ̀rọ míràn jẹ́ ọ̀kanáà bí àwọn tí àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office 2013 ń lò pẹ̀lú Microsoft Office Language Interface Pack 2013 - Yorùbá.


   • Windows Language Interface Pack A gbà ọ́ níyànjú láti sàgbékalẹ̀ Windows 7 tàbí Windows 8 Language Interface Packs tuntun fún àtìlẹ́yìn èdè tó dára fún Ìlànà-ètò Isẹ́ Síse àti àwọn ìfilọ́lẹ̀ ẹ̀yà àìrídìmú.

    Ìtànsán Asàfihàn àti Ètò DPI Ọ̀pọ̀ àwọn ìrísí-lẹ́tà ni a ti sẹ̀dá láti kà dáradára ní ìtànsán 1366 x 768. Tí o bá ní ìsòro láti ka ìrísí-lẹ́tà èdè rẹ jọ̀wọ́ sàfikún ètò àfihàn rẹ sí ìtànsán yìí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí o bá sepàtàkì. Jọ̀wọ́ sàkíyèsí: a gbà ọ́ níyànjú kí o lo àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office 2013 ní ètò DPI àkùnàyà Windows - 96 DPI. Lílo ètò DPI 120 le sokùnfà ìrírí asàmúlò Office tí kò dára tó ní ọ̀pọ̀ àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office kan nípa síse àfikún ìwọ̀n ìsọ̀rọ̀gbèsì Office.

    Àwọn Ẹ̀yàn Èdè àti Agbègbè Ní àfikún a gbà ọ́ níyànjú pé gbogbo Àwọn Ẹ̀yàn Èdè àti Agbègbè nínú Pánẹ̀lì Ìdarí ni a sètò sí èdè ti Microsoft Office Language Interface Pack 2013 - Yorùbá.

   • Láti sàgbékalẹ̀ ìgbàsílẹ̀ yìí:
    1. Sègbàsílẹ̀ fáìlì LanguageInterfacePack.exe nípa títẹ bọ́tìnnì Gbàsílẹ̀ náà (lókè) kí o si sàfipamọ́ fáìlì náà sí awo gbagidi rẹ.
    2. Tẹ àtòjọ-ètò fáìlì LanguageInterfacePack.exe lẹ́ẹ̀mejì lórí awo gbagidi rẹ láti bẹ̀rẹ̀ àtòjo-ètò Ìsètò náà.
    3. Tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni náà lórí ìbòjú láti parí ìsàgbékalẹ̀ náà.
    4. Kété tí o sàgbékalẹ̀ fáìlì kàmí fún Microsoft Office 2013 Language Interface Pack rẹ ni a le rí ní C:\Program Files\Common Files\microsoft shared\OFFICE15\1130\LIPread.htm.
    5. Síse àfikún Office 2010 pẹ̀lú Office 2010 Language Interface Pack tàbí ẹ̀yà ìsájú sí Office 2013 pẹ̀lú Office 2013 Language Interface Pack ni kò sàtìlẹ́yìn fún. Tí o bá fẹ́ láti sàfikún àgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ rẹ ti Office 2010 sí Office 2013 pẹ̀lú Office 2013 Language Interface Pack o gbọ́dọ̀:
     • Sàyọkúrò Office 2010 Language Interface Pack.
     • Mú ìsètò Office 2013 sisẹ́ kí o sì yan ẹ̀yàn àfikún.
     • Nígbàtí ìsètò Office 2013 bá parí, sàgbékalẹ̀ kí o si sàtúntò Office 2013 Language Interface Pack.    Mímú àgbéjáde Office rẹ sisẹ́:
    Tí o bá ní ìsòro ní kíka gbogbo Kóòdù Ìsàgbékalẹ̀ lórí ìsọ̀rọ̀gbèsì "Microsoft Office Activation Wizard", tàbí gbogbo kóòdù ìsàgbékalẹ̀ kò farahàn dáradára nígbàtí o ń lo Microsoft Office Language Interface Pack 2013 rẹ, jọ̀wọ́ pa àmọ̀ràn rẹ́ kí o si yí sí àgbéjáde èdè ìpìlẹ̀ rẹ láti mú àgbéjáde Microsoft Office rẹ sisẹ́.

    Àwọn ìtọ́ni fún lílò:
    Láti yí Atọ́kùn Asàmúlò rẹ sí èdè ti Microsoft Office Language Interface Pack 2013 – Yorùbá, tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí:

    1. Músisẹ́ Microsoft Office 2013 Language Preferences láti Bẹ̀rẹ̀\Gbogbo Àtòjọ-ètò\Microsoft Office\Microsoft Office Tools mẹ́nù.
    2. Lábẹ́ Yan Àfihàn àti Àwọn Èdè Ìrànlọ́wọ́, lábẹ́ Sàfihàn Èdè yan èdè tó nílò kí o sì tẹ̀ lórí Sètò bíi Àkùnàyàn bọ́tìnnì.
    3. Lábẹ́ Yan Àwọn Èdè Àtúnse, yan èdè tó nílò kí o sì tẹ̀ lórí Sètò bíi Àkùnàyàn bọ́tìnnì.
    4. Tẹ Ó DÁA bọ́tìnnì.


    Àwọn ètò èdè tí o ti yan yóò bẹ̀rẹ̀ isẹ́ nígbà míràn tí o bá bẹ̀rẹ̀ àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office rẹ.
    Àkíyèsí: Ìrànlọ́wọ́ ni a kò le yí sí èdè Microsoft Office Language Interface Pack 2013 – Yorùbá. Ìrànlọ́wọ́ yóò máa wà ní èdè ti ojúlówó àgbékalẹ̀.
    Máa sètò sàfihàn ìrànlọ́wọ́ rẹ nínú àtòkọ ìfàsílẹ̀ sí èdè ìpìlẹ̀.

    Láti yọ ìgbàsílẹ̀ yìí kúrò:
   • Jáde kúró nínú gbogbo àtòjọ-ètò Microsoft Office.
   • Tẹ àtòjọ-ètò fáìlì Àwọn Àtòjọ-ètò àti Àfidámọ̀ lẹ́ẹ̀mejì nínú Windows Pánẹ̀lì Ìdarí.
   • Nínú ẹ̀yàn Sàyọkúrò tàbí Sàyípadà Àtòjọ-ètò kan tẹ Microsoft Office Language Interface Pack 2013 – Yorùbá nínú àpótí Àwọn àtòjọ-ètò tí a sàgbékalẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn náà, yan Ẹ̀yàn Sàyọkúrò.
   • Tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni lórí ìbòjú náà.

  Awọn Gbaa Lati Ayelujara to Gbajumọ

  Loading your results, please wait...

  Awọn ìmúdójúìwọ̀n PC ọ̀fẹ́

  • Awọn ìmúdójúìwọ̀n aṣàtúnṣe sí àbò
  • Awọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú
  • Awọn àkójọpọ̀ iṣẹ́
  • Awọn awakọ̀ ẹ̀yà àfojúrí