Ọjọ́ àtẹ̀jáde:
Ọjọ́ ìmúṣẹ: Ọjọ́ 30 Oṣù kẹẹ̀jọ, 2019
Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft
Ohun ìkọ̀kọ̀ RẹOhun ìkọ̀kọ̀ Rẹ1_YourPrivacy
Ní ṣókí

1. Ìpamọ́ Rẹ Ìpamọ́ rẹ ṣe pàtàkì sí wa. Jọ̀wọ́ ka Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ Microsoft ("Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀") bí ó ti ṣe àlàyé irú àwọn détà tí à ngbà láti ọ̀dọ̀ rẹ àti láti inú àwọn ẹ̀rọ rẹ ("Détà"), bí a ṣe nlo Détà rẹ, àti àtìlẹ́yìn òfin tí a ní láti wọlé sí Détà rẹ. Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ tún ṣàlàyé bí Microsoft ti ń lo àkóónú rẹ, èyí tííṣe ìbánisọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn; àwọn ìfiṣọwọ́ tí o firánṣẹ́ sí Microsoft nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè náà; àti àwọn fáìlì, fọ́tò, àkọsílẹ̀, ohun àfetígbọ́, iṣẹ́ onídíjítà, ìgbàsílẹ̀ àti fídíò tí o fiṣọwọ́, tí o fipamọ́, tí o fisórí afẹ́fẹ́ tàbí ṣàpínlò nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè ("Àkóónú Rẹ"). Níbití ìṣètò bá dá lórí ìgbaniláàyè, àti títí dé ibi tí òfin gbà wá làáyé dé, nípa fífaramọ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, o gbà sí àkójọ̀ Microsoft, ìlò àti àfihàn Àkóónú Rẹ àti Détà bí a ti ṣàlàyé nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà. Ní ọ̀nà míràn, a ó pèsè àkíyèsí míràn a ó sì bèrè fún ìyọ̀nda rẹ bí a ti tọ́kasí nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà.

Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àkóónú RẹÀkóónú Rẹ2_yourContent
Ní ṣókí

2. Àkóónú Rẹ. Púpọ̀ nínú àwọn Iṣẹ́ wa gbà ọ́ láàyè láti fi Àkóónú Rẹ pamọ́, láti ṣàjọpín rẹ̀, tàbí láti gba ohun àmúlò láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwa kìí sọ pé àwa ni a ni Àkóónú Rẹ. Àkóónú Rẹ yóò má a jẹ́ Àkóónú Rẹ, ìwọ sì ni ó ni ojúṣe fún un.

 • a. Nígbàtí o bá ṣàpínlò Àkóónú Rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, ó yé ọ pé wọ́n lè, káàkiri àgbáyé, lò, ṣàfipamọ́, ṣàkọsílẹ̀, ṣàtúndá, tàn káàkiri, ta ní àtagbà, ṣàpínlò, tàbí kí wọn ṣàfihàn (àti lórí HealthVault, ṣèparẹ́) Àkóónú Rẹ láì sanwó fún ọ. Bí o kò bá fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ní irú agbára yìí, máṣe lo Iṣẹ́ náà láti ṣàjọpín Àkóónú Rẹ. O ṣèdúró, o sì fọwọ́sọ̀yà pé, níwọ̀n ìgbàtí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí yóò fi wà, ìwọ ní (ìwọ yóò sì ní) gbogbo ẹ̀tọ́ tó ṣe pàtàkì fún Àkóónú Rẹ tí a fiṣọwọ́, tí a fipamọ, tàbí tí a ṣàpínlò lórí tàbí nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè náà, àti pé àkójọpọ̀, ìlò, àti ìmúdání Àkóónú Rẹ kì yóò tàpá sí èyíkéyìí òfin tàbí ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn. Microsoft kìí ṣe oníhun, kò ṣàkóso, ṣàyẹ̀wò, sanwó fún, fọwọ́ sí tàbí gba ojúṣe yòówù fún Àkóónú Rẹ, a kò sì lè múu dáhùn fún Àkóónú Rẹ tàbí ohun àmúlò tí àwọn ẹlòmíràn gbé lọ sí ayélujára, tí wọ́n fipamọ́ tàbí ṣàjọpín nípasẹ̀ Iṣẹ́ náà.
 • b. Títí dé ibití ó yẹ láti pèsè àwọn Iṣẹ́ náà fún ọ àti àwọn ẹlòmíràn, láti dáàbòbò ọ́ àti àwọn Iṣẹ́ náà, àtí láti mú ìlọsíwájú bá àwọn ọjà àti iṣẹ́ Microsoft, o fún Microsoft ní ìwé-ẹ̀rí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ káàkiri àgbáyé, láì sí sísan owó oníhun, láti lo Àkóónú Rẹ, fún àpẹẹrẹ, láti ṣe ẹ̀dà Àkóónú Rẹ tó wà lórí àwọn Iṣẹ́ náà, láti dìímú, gbée kiri, tún-un-tò, fihàn àti pín i kiri nípasẹ̀ àwọn irin-iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀. Bí o bá ṣe àgbéjáde Àkóónú Rẹ ní àwọn abala Iṣẹ́ náà níbití òun ti wà káàkiri ayélujára láìsí ìhámọ́, Àkóónú Rẹ lè hàn nínú àwọn àfihàn tàbí ohun àmúlò tí a fi gbé Iṣẹ́ náà lárugẹ. Lára àwọn Iṣẹ́ náà ní àtìlẹyìn fún ìpolówó ọjà. Àwọn ìdarí fún bí Microsoft ṣe nfi ìpolówó ṣe ti ara ẹni wà lórí ojú-ìwé Ààbò & ìkọ̀kọ̀ ti àyè ayélujára ìṣàkóso àkọọ́lẹ̀ Microsoft. A kìí lo àwọn ohun tí o bá sọ sínú ímeèlì rẹ, iwiregbe, ìpè fidio tàbí méèlì ohùn, tàbí àwọn àkọsílẹ̀ rẹ, fọ́tò, tàbí àwọn fáìlì ara ẹni láti fi kọjú ìpolówó ọjà sí ọ. A ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn ìlànà ìpolówó ọjà wa nínú Gbólóhùn Ìpamọ́.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Òfin ÌhùwàsíÒfin Ìhùwàsí3_codeOfConduct
Ní ṣókí

3. Òfin Ìṣesí.

 • a. Nípa fífaramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ìwọ ngbà pé, nígbàtí o bá nlo àwọn Iṣẹ́ náà, ìwọ yóò tẹ̀lé àwọn òfin wọ̀nyí:
  • i. Máṣe ṣe ohun tí kò bá òfin mu.
  • ii. Máṣe lọ́wọ́ nínú ìṣesí yòówù tó nlo àwọn ọmọdé ní ọ̀nà àìtọ́, tó npa wọ́n lára, tàbí tó nhalẹ̀ láti pa wọ́n lára.
  • iii. Máṣe fi àkọránṣẹ́ àìbèrèfún ránṣẹ́. Àkọránṣẹ́ àìbèrèfún jẹ́ ímeèlì púpọ̀, àfihàn, ìbéèrè fún kíkànsíni, SMS (àwọn àkọránṣẹ́), tàbí àkọránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí a kò fẹ́ tàbí tí a kò bèèrè fún.
  • iv. Máṣe ṣàfihàn ní gbangba tàbí lo Àwọn Ìpèsè náà láti ṣàpínlò àkóónú tàbí àwọn ohun èlò mìíràn tí kò tọ̀nà tàbí ohun ìní (tó kan fún àpẹrẹ, ìhòhò, bíbá ẹranko lópọ̀, àwòrán oníhòhò, èdè àìdára, àwòrán ìwà ipá, tàbí iṣẹ́ ọ̀daràn) tàbí Àkóónú Rẹ tàbí ohun ìní tí kò faramọ́ àwọn òfin abẹ́lé tàbí àwọn ìlànà.
  • v. Máṣe kópa nínú iṣẹ́-ṣíṣe tó jẹ́ gbéwiri, irọ́ tàbí láti ṣi ènìyàn lọ́nà (fún àpẹrẹ, bíbèrè owó lábẹ́ orúkọ ẹlòmíràn, kíkóbá ẹlòmíràn, ìṣàtúnṣe Àwọn Ìpèsè láti fikún kíka ìṣeré, tàbí tó kan àwọn ipele, ìgbéléwọ̀n, tàbí àwọn ìdáásí) tàbí ìbánilórúkọ jẹ́ tàbí ìtakoni.
  • vi. Máṣe wá ọ̀nà láti yí ìhámọ́ yòówù nípa wíwọlé sí tàbí wíwà Iṣẹ́ náà po.
  • vii. Máṣe lọ́wọ́ nínú ìṣesí yòówù tó lè pa ìwọ, Iṣẹ́ náà tàbí àwọn ẹlòmíràn lára (fún àpẹẹrẹ, gbígbè àwọn ohun búburú tí nba ẹ̀rọ jẹ́ kiri, ìyọnilẹ́nu, ṣíṣàfihàn àkóónú apániláyà tàbí àkóónú ìwà ipá àṣejù, sísọ ọ̀rọ̀ ìkórira, tàbí ṣíṣe alágbàwí fún ìwà jàgídí-jàgan sí àwọn ẹlòmíràn.
  • viii. Máṣe tàpá sí ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn (fún àpẹẹrẹ, ṣíṣàjọpín orin tó ní ẹ̀tọ́ ọjà-títà tàbí àwọn ohun àmúlò mìíràn tó ní ẹ̀tọ́ ọjà-títà láì gba àṣẹ, àtúntà tàbí pípín àwọn àwòrán-ayé àti àwòrán Bing káàkiri).
  • ix. Máṣe lọ́wọ́ nínú ohun àmúṣe tó tàpá sí ohun ìkọ̀kọ̀ tàbí àwọn ẹ̀tọ́ ààbò détà àwọn ẹlòmíràn.
  • x. Máṣe ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rú àwọn òfin wọ̀nyí.
 • b. Gbígbòfinró. Tí o bá rúfin àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, a le, ní èrò ti wa, dẹ́kun pípèsè Àwọn Ìpèsè fún ọ tàbí a le mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin. A tún le dènà ìfijíṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ (bíi í-meèlì, àpínlò fáìlì tàbí ìfiránṣẹ́ kíá) sí tàbí láti Àwọn Ìpèsè ní ìgbìyànjú láti fipámú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, tàbí a le ṣèmúkúrò tàbí kọ̀ láti ṣàgbéjáde Àkóónú Rẹ fún èrèdí kankan. Nígbàtí a bá nṣe ìwádìí ìtàpá sí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò Àkóónú Rẹ láti lè yanjú ọ̀ràn náà, ìwọ sì fún wa ní àṣẹ báyìí fún irú àtúnyẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwa kò lè ṣàkóso gbogbo Iṣẹ́ náà, a kò sí gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀.
 • c. Bí ó ṣe kan Àwọn Iṣẹ́ Xbox. Ṣíra tẹ here fún àlàyé síwájú síi nípa bí Òfin Ìhùwàsí yìí ti kan Xbox Live, Xbox Game Pass, Games for Windows Live àti àwọn ìṣeré Xbox Game Studios, ìṣàfilọ́lẹ̀, àwọn iṣẹ́ àti àkóónú èyítí Microsoft pèsè. Ìrúfin Òfin Ìhùwàsí náà nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè Xbox (tí a sọ àsọyé nípa rẹ ní abala 13(a)(i)) le yọrísí ìdádúró tàbí ìyọkúrò nínú ìkópa nínú Àwọn Ìpèsè Xbox, pẹ̀lú ìpàdánù àwọn ìwé àṣẹ àkóónú, àkókò Jíjẹ́ Omọ-ẹgbẹ́ Xbox Gold, àwọn ìyókù àkọọ́lẹ̀ Microsoft tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ náà.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Lílo Àwọn Iṣẹ́ àti Àtìlẹ́yìnLílo Àwọn Iṣẹ́ àti Àtìlẹ́yìn4_usingTheServicesSupport
Ní ṣókí

4. Lílo Àwọn Ìpèsè àti Àtìlẹ́yìn.

 • a. Àkọọ́lẹ̀ Microsoft. Ìwọ yóò nílò àkọọ́lẹ̀ Microsoft láti wọlé sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn Iṣẹ náà. Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ a má a jẹ́ kí o buwọ́lù wọlé sí àwọn ọjà, àyè ayélujára àti àwọn iṣẹ́ ti Microsoft àti àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ Microsoft npèsè.
  • i. Ṣíṣẹ̀dá Àkọọ́lẹ̀. O le ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan nípa fíforúkọ sílẹ̀ lóníforíkorí. O gbà láti máṣe lo èyíkéyìí àlàyé tó jẹ́ irọ́, àìpéye tàbí tó ṣi ni lọ́nà nígbàtí o bá ń forúkọ sílẹ̀ fún àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ. Nígbà mìíràn, ẹlòmíràn, bíi olùpèsè iṣẹ́ Ayélujára rẹ, lè pín àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan fún ọ. Bí o bá gba àkọọ́lẹ̀ Microsoft láti ọwọ́ ẹlòmíràn, ẹlòmíràn náà lè ní àwọn àfikún ẹ̀tọ́ kan lórí àkọọ́lẹ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí agbára láti wọlé sí àti láti pa àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ rẹ́. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹwò àwọn àfikún àdéhùn yòówù tí ẹlòmíràn náà pèsè fún ọ, nítorí tí Microsoft kò ní ojúṣe kankan nípa àwọn àfikún àdéhùn wọ̀nyí. Bí o bá ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft lórúkọ ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí òwò tàbí agbanisíṣẹ́ rẹ, ìwọ jẹ́ aṣojú pé o ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti mú àwọn Adéhùn wọnyí pọn dandan fún ẹni náà. O kò le fi àwọn àlàyé àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ ṣọwọ́ sí aṣàmúlò tàbí ilé-iṣẹ́ míràn. Láti dáàbòbo àkọọ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí àwọn àlàyé àti ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé àkọọ́lẹ̀ rẹ jẹ́ ohun àṣírí. Wàá dáhùn fún gbogbo iṣẹ́-ṣíṣe tó bá wáyé lábẹ́ àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ.
  • ii. Ìmúlò Àkọọ́lẹ̀. O gbọ́dọ̀ má a lo àkọọ́lẹ̀ Microsoft láti jẹ́ kí ó lè má a ṣiṣẹ́. Èyí túmọ̀ sí wípé o gbọ́dọ̀ buwọ́lù láti wọlé ó kéré jù ẹ̀kan láàrín ọdún méjì láti tọ́jú Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, àti Àwọn iṣẹ́ tó jọra, ìṣiṣẹ́, àyàfi tí a bá pèsè ìgbà pípẹ́ nínú ofin iṣẹ́-ṣíṣe Àkọọ́lẹ̀ Microsoft ní https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=2086738 tàbí nínú ìfúnni fún abala tí a sanwó fún nínú Àwọn iṣẹ́ náà. Bí o kò bá buwọ́lù wọlé ní àsìkò yìí, àwa yóò ríi bí ẹni pé àkọọ́lẹ̀ Microsoft kò ṣiṣẹ́ mọ́, a ó sì múu dópin fún ọ. Jọ̀wọ́ wo abala 4(a)(iv)(2) fún àtúnbọ̀tán àkọọ́lẹ̀ Microsoft tí a mú dópin. O gbọ́dọ̀ buwọ́lù wọlé sí àpótí àgbàwọlé Outlook.com rẹ àti OneDrive rẹ (lọ́tọ̀ọ̀tọ̀), ó kéré, ní ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọdún kan, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò mú àpótí àgbàwọlé Outlook.com rẹ àti OneDrive rẹ dópin fún ọ. O gbọ́dọ̀ wọlé sí Àwọn pèsè Xbox ní, ó kéré, ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọdún marun, láti lè mú kí gamertag tó níí ṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ má a ṣiṣẹ́. Tí a bá fura ní ọ̀nà tó mọú ọgbọ́n wá wípé Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ wà lábẹ́ ewu lílò nípa ẹlòmíràn ní ọ̀nà gbéwiri (fún àpẹrẹ, nítorí ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ Àkọọ́lẹ̀ kan), Microsoft le dá Àkọọ́lẹ̀ rẹ dúró fún ìgbà díẹ̀ títí wàá fi le gba olóhun rẹ̀ padà. Bí a bá wo irú ìpàdánù ààbò tí èyí jẹ́, a lè nílò láti mú kí wíwọlé sí lára àwọn Àkóónú Rẹ tàbí sí gbogbo rẹ̀ má lè ṣeé ṣe mọ́. Bí o bá nní ìṣòro láti wọlé sí àkọọ́lẹ̀ Microsoft, jọ̀wọ́ kàn sí àyè ayélujára yìí. https://go.microsoft.com/fwlink/?LinkId=238656.
  • iii. Àwọn Ọmọdé àti Àkọọ́lẹ̀. Nípa lílo àwọn Iṣẹ́ náà, o jẹ́rìí pé o ti dé ọjọ́-orí ¨àgbàlagbਠtàbí ¨ojúṣe lábẹ́ òfin¨ níbití ìwọ ngbé tàbí o ní ìfọwọ́sí òbí tàbí alágbàtọ́ lábẹ́ òfin tó wà lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Tí o kò bá mọ̀ bóyá o ti dé ọjọ́-orí ẹnití a lè pè ní àgbàlagbà tàbí "ṣíṣe ojúṣe ẹni lábẹ́ òfin" níbití o ń gbé, tàbí abala yìí kò yé ọ, jọ̀wọ́ bèrè lọ́wọ́ òbí tàbí alágbàtọ́ rẹ fún ìrànwọ́ àti ìyọ̀nda kí o tó ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan. Tí o bá jẹ́ òbí tàbí alágbàtọ́ ọmọdé kan tó ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft, ìwọ àti ọmọ rẹ gbà, ẹ sì faramọ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ẹ̀yin sì ni ó ni ojúṣe fún gbogbo ìlò àkọọ́lẹ̀ tàbí Àwọn Ìpèsè Microsoft, pẹ̀lú àwọn ìrajà, yàlá àkọọ́lẹ̀ ọmọdé náà ti wà ní ṣíṣí báyìí tàbí ìwọ yóò ṣẹ̀dá rẹ̀ tóbáyá.
  • iv. Mímú Àkọọ́lẹ̀ Rẹ Dé Òpin.
   • 1. O le fagilé Àwọn Ìpèsè kan pàtó tàbí mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin nígbà kugbà àti fún èyíkéyìí èrèdí. Láti mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin, jọ̀wọ́ kàn sí https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=618278. Bí o bá ní kí a mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin, a ó fi sí ipò ìdádúró fún ìgbà díẹ̀ fún ọjọ́ 60, bóyá o lè yí ọkàn rẹ padà. Lẹ́yìn ọjọ́ 60, a ó mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin. Jọ̀wọ́ wo abala 4(a)(iv)(2) nísàlẹ̀ fún àlàyé lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nígbàtí a bá mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin. Bíbuwọ́lù wọlé padà lákòókò ọjọ́ 60 náà yóò mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ má a ṣiṣẹ́ padà.
   • 2. Tí a bá mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin (yálà nípasẹ̀ ìwọ tàbí àwa), àwọn ǹkan díẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀. Ní àkọkọ, ẹ̀tọ́ rẹ láti lo àkọọ́lẹ̀ Microsoft fún wíwọlé sí àwọn Ìpèsè náà yóò dópin lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ìkejì, a ó pa Détà tàbí Àkóónú rẹ tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ rẹ́ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ kí a fi ìpinya sáàárín ìwọ àti àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ (àyàfi tí òfin bá ní kí a tọ́jú rẹ̀, kí a dáa padà, tàbí kí a fifún ọ tàbí ẹlòmíràn tí ìwọ yàn). O gbọ́dọ̀ ní ètò àfẹ̀hìntì nígbà gbogbo nítorí tí Microsoft kì yóò lè mú Àkóónú Rẹ tàbí Détà padà lọ́gán tí a bá tí múu dópin. Ìkẹẹ̀ta, o le pàdánù ìráyèsí àgbéjáde tí o ti rà/gbà. Ìkẹẹ̀rin, a le dènà ṣíṣẹ̀dá Àkọọ́lẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ èyí tó níṣe pẹ̀lú àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì tí o pèsè.
 • b. Àwọn Àkọọ́lẹ̀ Ilé-iṣẹ́ tàbí ti Ilé-ẹ̀kọ́. O lè buwọlù wọlé sí àwọn iṣẹ́ Microsoft kan pẹ̀lú àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì ilé-iṣẹ́ tàbí ti ilé-ẹ̀kọ́. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o gbà wípé olóhun agbègbè ìkápá náà tó níṣe pẹ̀lú àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ ni a le sọfún nípa wíwà nílẹ̀ ti Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ àti àwọn ìṣalábàápín tí ṣepọ̀ mọ́ọ, darí kí o sì ṣàkóso Àkọọ́lẹ̀ rẹ, kí o sì ráyèsí àti láti ṣiṣẹ́ lórí Dátà rẹ, pẹ̀lú àwọn àkóónú ti ìbánisọ̀rọ̀ àti fáìlì rẹ, àti wípé Microsoft le wífún olóhun ti agbègbè ìkápá náà tí Àkọọ́lẹ̀ náà tàbí ti Dátà bá gbọ̀jẹ̀gẹ́. O tún gbà pé ìlò rẹ ti àwọn ìpèsè Microsoft le wà lábẹ́ àwọn àdéhùn tí Microsoft ní pẹ̀lú rẹ tàbí ilé-iṣẹ́ rẹ àti pé Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí ni a le má ṣàmúlò. Tí o bá ti ní àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan tẹ́lẹ̀ tí o sì ń lo iṣẹ́ kan tó yàtọ̀ tàbí àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì ti ilé-ìwé láti ráyèsí Àwọn Ìpèsè tó wà lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, a le tà ọ́ lólonbó láti ṣàfikún àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ láti le tẹ̀síwájú ìráyèsí irú Àwọn Ìpèsè náà.
 • c. Àfikún Irinṣẹ́/Àwọn Ètò Détà. Láti lo ọ̀pọ̀ lára àwọn Iṣẹ́ náà, o nílò àsopọ̀ ayélujára àti/tàbí ètò détà/ẹ̀rọ aláàgbéká. O tún lè nílò àwọn àfikún ẹ̀rọ, bíi àgbékarí, kámẹ́rà tàbí gbohùngbohùn. Ìwọ ni ó ni ojúṣe fún pípèsè gbogbo ìsopọ̀, ètò, àti irinṣẹ́ tí a nílò fún lílo Àwọn Ìpèsè náà, àti láti san owó tí (àwọn) olùpèsè àwọn ìsopọ̀, ètò àti irinṣẹ́ rẹ yóò bèèrè fún. Àwọn owó náà jẹ́ àfikún sí iye owó yòówù tí o bá san fún wa fún àwọn Iṣẹ́ náà, àwa kì yóò sì dá irú owó bẹ́ẹ̀ padà fún ọ. Ṣàyẹ̀wò pẹ̀lú (àwọn) olùpèsè rẹ láti mọ̀ bóyá irú àwọn owó bẹ́ẹ̀ wà tó kàn ọ.
 • d. Àwọn Ìwífúnni Iṣẹ́. Nígbàtí a bá ní ohun kan láti sọ fún ọ nípa Ìpèsè kan tí o lò, a ó fi àwọn ìwífúnni Ìpèsè ránṣẹ́ sí ọ. Tí o bá ti fún wa ní àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì tàbí nọ́mbà fóònù rẹ èyí tó ṣepọ̀ mọ́ Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, lẹ́yìn náà a le fi àwọn ìfitónilétí Iṣẹ́ ránṣẹ́ sí ọ nípasẹ̀ í-meèlì tàbí SMS (ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́), pẹ̀lú láti jẹ́rìísí ìdánimọ̀ rẹ kí a tó ṣàkọsílẹ̀ nọ́mbà fóònù alágbèéká rẹ kí o sì jẹ́rìísí àwọn ìrajà rẹ. A tún le fi àwọn ìwífúnni Ìpèsè ránṣẹ́ sí ọ nípa ọ̀nà míràn (fún àpẹrẹ nípa àwọn ìfiránṣẹ́ inú-àgbéjáde). Iye owó détà tàbí ti àkọránṣẹ́ lè wà fún sísan bí o bá ngba àwọn ìwífúnni nípasẹ̀ SMS.
 • e. Àtìlẹ́yìn. Àtìlẹ́yìn oníbàárà fún Àwọn Iṣẹ́ kan wà nílẹ̀ ní support.microsoft.com. Àwọn Ìpèsè kan lè má a fúnni ní àfikún tàbí àtìlẹ́yìn oníbàárà ọ̀tọ̀, èyí tó dá lórí àwọn àdéhùn tó wà ní www.microsoft.com/support-service-agreement, àfi bí a bá sọ ohun mìíràn tó yàtọ̀ sí èyí. Ó ṣeé ṣe kí àtìlẹ́yìn má wà fún àwọn ẹ̀yà àfidámọ̀ tàbí Ìpèsè àkọ́wò tàbi beta. Iṣẹ́ náà lè má wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn iṣẹ́ tí àwọn ẹlòmíràn npèsè, ìwọ sì ni ó ni ojúṣe láti mọ àwọn ohun tó yẹ fún bíbáramu.
 • f. Mímú Ìpèsè rẹ Dópin. Tí a bá fagilé àwọn Ìpèsè rẹ (yálà nípasẹ̀ ìwọ tàbí àwa), Ní àkọkọ, ẹ̀tọ́ rẹ láti wọlé sí àwọn Ìpèsè náà yóò dópin lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìgbaniláàyè rẹ fún ẹ̀yà àìrídìmú tó níí ṣe pẹ̀lú Ìpèsè náà yóò dópin. Ìkejì, a ó pa Détà tàbí Àkóónú rẹ tó níṣe pẹ̀lú Ìpèsè rẹ rẹ́ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ kí a fi ìpinya sáàárín ìwọ àti àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ (àyàfi tí òfin bá ní kí a tọ́jú rẹ̀, kí a dáa padà, tàbí kí a fifún ọ tàbí ẹlòmíràn tí ìwọ yàn). Nítorí èyí, ó ṣeé ṣe kí ìwọ má lè wọlé sí àwọn Ìpèsè náà yòówù mọ́ (tàbí Àkóónú Rẹ tí o fipamọ́ sórí àwọn Ìpèsè wọ̀nyí). O gbọ́dọ̀ ní ètò àbọ̀ábá láti ìgbà dé ìgbà. Ìkẹẹ̀ta, o le pàdánù ìráyèsí àgbéjáde tí o ti rà/gbà. Bí o bá ti fagilé àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, tí o kò sì ní Microsoft mìíràn láti gbà wọlé sí àwọn Ìpèsè náà, a lè fagilé àwọn Ìpèsè rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Lílo Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ ẸlòmíranLílo Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹlòmíran5_usingThird-PartyAppsAndServices
Ní ṣókí

5. Lílo Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta. Àwọn Ìpèsè náà le gbà ọ́ láàyè láti ráyèsí tàbí gba àwọn àgbéjáde, àwọn ìpèsè, ojúlé wẹ́ẹ̀bù, ìtọ́kasí, àkóónú, ohun ìní, ìṣeré, ọgbọ́n-inú, àkójọpọ̀, bọ́ọ̀tì tàbí àwọn ìfilọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹta (àwọn ilé-iṣẹ́ tàbí àwọn ènìyàn tí kìíṣe Microsoft) ("Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta"). Ọ̀pọ̀ àwọn Iṣẹ́ wa tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wá, bèrè sí, tàbí bá Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn ṣepọ̀ tàbí gbà ọ́ láàyè láti ṣàpínlò Àkóónú tàbí Dátà rẹ, ó sì yé ọ wípé nípa lílo Àwọn iṣẹ́ wa o ń darí wọn láti le jẹ́ kí Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn wà nílẹ̀ fún ọ. Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta náà lè ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà ìpamọ́ kan fún ọ, tàbí kí wọ́n ní kí o faramọ́ àwọn àfikún àdéhùn kí o tó le ṣàgbékalẹ̀ tàbí lo Ìpèsè tàbí Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta náà. Ìṣàfilọ́lẹ̀àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn le fún ọ ni òfin ìpamọ́ tàbí bèrè lọ́wọ́ rẹ láti gba àwọn àwíyé wọn kí o tó le ṣàgbékalẹ̀ tàbí lo Ìṣàfilọ́lẹ̀ tàbí Iṣẹ́ Ẹlòmíràn. Wo abala 13(b) fún àfikún àwíyé fún àwọn ìbéèrè tí a gbà nípasẹ̀ àwọn Ìsọ̀ kan tí a ni tàbi èyítí Microsoft ń darí tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ (pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò pín sí, Office Store, Microsoft Store lórí Xbox àti Microsoft Store lórí Windows O gbọ́dọ̀ ṣàtúnwò àwọn òfin ìpamọ́ àti àwíyé ẹlomíràn kí o tó gbà, lo, bèrè, tàbí so Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ pọ̀ mọ́ Ìṣafilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn. Èyíkéyìí àwíyé ẹlòmíràn kò ṣàtúnṣe Àwọn àwíyé wọ̀nyí. Microsoft kò fún ọ ní ìwé-ẹ̀rí fún ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ yòówù gẹ́gẹ́ bí ara àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ àwọn Ẹlòmíràn yòówù. O gbà láti gbé gbogbo ewu àti ojúṣe tó lè wáyé nípasẹ̀ ìmúlò rẹ fún àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ àwọn Ẹlòmíràn wọ̀nyí, àti pé Microsoft kò ní ojúṣe fún ọ̀ràn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ ìmúlò rẹ fún wọn. Microsoft kò ní ojúṣe yòówù, òun kì yóò sì ní láti dá ìwọ tàbí àwọn ẹlòmíràn lóhùn nípa àlàyé tàbí àwọn ìpèsè Ìfilọ́lẹ̀ àtí Ìpèsè Ẹnikẹta.

Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Wíwà Iṣẹ́Wíwà Iṣẹ́6_serviceAvailability
Ní ṣókí

6. Wíwà Iṣẹ́.

 • a. Àwọn Iṣẹ́ náà, àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ àwọn Ẹlòmíràn, tàbí àwọn ohun àmúlò tàbí ọjà tí a fifúnni nípasẹ̀ àwọn Iṣẹ́ náà lè máṣe wà láti ìgbà dé ìgbà, a lè lo ìdíwọ̀n ní pípèsè wọn, wọn sì lè yàtọ láti agbègbè sí agbègbè tàbí ẹ̀rọ sí ẹ̀rọ. Bí o bá yí ipò tó níí ṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ padà, o lè nílò láti ṣe àtúnrà àwọn ohun àmúlò àti ohun èlò kan tó ti wà fún ọ tẹ́lẹ̀ rí, àti tí o sanwó fún ní ibití o wà tẹ́lẹ̀. O gbà láti máṣe wọlé sí tàbí lo ohun àmúlò tàbí àwọn Iṣẹ́ tí kò bá òfin mu tàbí tí kò sí ìwé-àṣẹ fún lílò wọn ní orílẹ̀-èdè tí o tí nwọlé sí tàbí lo irú ohun àmúlò tàbi àwọn Iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, tàbí láti fi ipò tàbí ààmì ìdánimọ̀ rẹ pamọ́ tàbí kí o parọ́ nípa rẹ̀, láti lè wọlé sí tàbí lo irú ohun àmúlò tàbí àwọn Iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.
 • b. Àwa ngbìyànjú láti mú kí Iṣẹ́ náà má a lọ nígbà gbogbo; ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn iṣẹ́ orí ayélujára a má a ní ìdádúró ẹ̀ẹ̀kọ̀kan, Microsoft kò sì ní ohunkóhun láti dáhùn fún ìdádúró tàbí àdánù yòówù tí o lè rí nípasẹ̀ èyí. Bí ìdádúró bá wáyé, o lè má lè mú Àkóónú tàbí Détà Rẹ tí o fipamọ́ padà mọ́. A gbà ọ́ níyànjú pé kí o má a ṣe àbọ̀ábá Àkóónú àti Détà tí o fipamọ́ sórí Àwọn Ìpèsè tàbí ibi ìpamọ́ náà láti ìgbà dé ìgbà nípa lílo Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Ìmúdójúìwọ̀n sí Àwọn Iṣẹ́ tàbí Ẹ̀yà Àìrídìmú, àti Àwọn Àyípadà sí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyíÀwọn Ìmúdójúìwọ̀n sí Àwọn Iṣẹ́ tàbí Ẹ̀yà Àìrídìmú, àti Àwọn Àyípadà sí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí7_updatesToTheServicesOrSoftwareAndChangesToTheseTerms
Ní ṣókí

7. Àwọn Ìmúdójúìwọ̀n sí Àwọn Iṣẹ́ tàbí Ẹ̀yà Àìrídìmú, àti Àwọn Àyípadà sí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí.

 • a. Àwa lè yí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí padà nígbà yòówù, àwa yóò sì sọ fún ọ nígbàtí a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Lílò àwọn Iṣẹ́ náà lẹ́yìn tí àwọn àyípadà náà bá ti bẹ̀rẹ̀ túmọ̀ sí pé o faramọ́ àwọn àdéhùn titun náà. Tí o kò bá faramọ́ àwọn àdéhùn titun náà, o gbọ́dọ̀ dẹ́kun lílo Àwọn Ìpèsè náà, mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin àti, tí o bá jẹ́ òbí tàbí alágbàtọ́, ran ọmọdé rẹ lọ́wọ́ láti mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ̀ dópin.
 • b. Nígbà mìíràn ìwọ yóò nílò àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú láti lè tẹ̀síwájú ní lílo àwọn Iṣẹ́ náà. A lè ṣàyẹ̀wò oríṣi ẹ̀yà àìrídìmú àti ti àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú tí o gbé wálẹ̀ láti ayélujára tàbí ti àwọn àyípadà sí ìṣètò ẹ̀rọ rẹ, láìfọwọ́yí. A tún lè ní kí o mú ẹ̀yà àìrídìmú dójú ìwọ̀n láti lè tẹ̀síwájú ní lílo àwọn Iṣẹ́ náà. Irú àwọn ìmúdójúìwọ̀n bẹ́ẹ̀ wà lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àfi bí àwọn àdéhùn mìíràn bá bá àwọn ìmúdójúìwọ̀n náà wá, nígbà náà, tí àwọn àdéhun mìíràn náà yóò ní ipa. Kìíṣe dandan fún Microsoft láti mú kí àfikún yòówù wà, kò sì sí ìdánilójú pé àwa yóò ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀yà ìlànà-ètò náà, èyítí o rà ẹ̀yà àìrídìmú, àwọn ìfilọ́lẹ̀, àkóónú tàbí àwọn àgbéjáde mìíràn náà fún, tàbí tí o gbà ìgbaniláàyè fún. Irú àwọn ìmúdójúìwọ̀n bẹ́ẹ̀ lè má wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí iṣẹ́ tí àwọn ẹlòmíràn npèsè. O lè gba fífaramọ́ rẹ fún àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú lọ́jọ́ iwájú padà nígbà yòówù nípa yíyọ ẹ̀yà àìrídìmú náà kúrò lórí ẹ̀rọ.
 • c. Ní àfikún, àwọn àsìkò kan lè wà tí a nílò láti mú àwọn àfidámọ̀ inú àwọn Iṣẹ́ náà kan kúrò tàbí kí a yí wọn padà, tàbí kí a dẹ́kun pípèsè Iṣẹ́ kan tàbí wíwọlé sí àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ àwọn Ẹlòmíràn. Àfi títí dé ibití òfin tó yẹ bèèrè dé, àwa kò ní ojúṣe kankan láti pèsè àtún-gbéwálẹ̀ tàbí rírọ́pò ohun àmúlò yòówù, àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà (tí a sọ àsọyé nípa rẹ̀ ní abala 13(b)(v)), tàbí àwọn ohun èlò tí o rà tẹ́lẹ̀ rí. A lè ṣe àgbéjáde àwọn Ìpèsè náà tàbí àwọn àfidámọ̀ wọn nínú ẹ̀yà àkọ́wò tàbí beta, èyítí ó le má ṣiṣẹ́ dáradára tàbí ní ọ̀nà kan náà ti ẹ̀yà tí a gbéjáde kẹ́yìn yóò fi ṣiṣẹ́.
 • d. Kí ìwọ báa lè ṣàmúlò ohun èlò tí a dáàbòbò pẹ̀lú ìṣàkóso àwọn ẹ̀tọ́ díjítà (DRM), bíi àwọn orin kan, ìṣeré, fíìmù, ìwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yà àìrídìmú DRM lè kàn sí apèsè ẹ̀tọ́ oníforíkorí tìkálárarẹ̀, kí o gba ẹ̀dà fáìlì̀ àwọn àfikún DRM sílẹ̀, kí ó sì ṣàgbékalẹ̀ wọn.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Ìwé-àṣẹ Ẹ̀yà ÀìrídìmúÌwé-àṣẹ Ẹ̀yà Àìrídìmú8_softwareLicense
Ní ṣókí

8. Ìwé-Àṣẹ Ẹ̀yà Àìrídìmú. Àfi bí ó bá wá pẹ̀lú àdéhùn ìwé-àṣẹ Microsoft ọ̀tọ̀ (fún àpẹẹrẹ, bí o bá nlo ohun èlò Microsoft tó jẹ́ ara Windows, nígbà náà, àwọn Àdéhùn Ìwé-àṣẹ Ẹ̀yà àìrídìmú Microsoft fún Ètò Ìpìlẹ Kọmputa Windows ni ó ndarí irú ẹ̀yà àìrídìmú bẹ́ẹ̀), ẹ̀yà àìrídìmú yòówù tí àwa bá pèsè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ara àwọn Iṣẹ́ náà wà lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ kan tí a gbà nípasẹ̀ Àwọn Ìsọ̀ tí Microsoft ni tàbí darí tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ (pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò pin sí Office Store, Microsoft Store lórí Windows àti Microsoft Store lórí Xbox wà lábẹ́ abala 13(b)(i) nísàlẹ̀.

 • a. Bí o bá tẹ̀lé àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, a fún ọ ní ẹ̀tọ́ láti lò àti láti fi ẹ̀dà ẹ̀yà àìrídìmú náà kanṣoṣo sórí ẹ̀rọ fún ẹ̀rọ kọ̀ọ̀kan káàkiri àgbáyé fún ìmúlò ẹnìkanṣoṣo nígbà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ara ìmúlò rẹ fún Iṣẹ́ náà. Fún àwọn ohun èlò kan, irú ẹ̀yà àìrídìmú bẹ́ẹ̀ ni a lè kọ́kọ́ ṣàgbékalẹ̀ fún ìlò àdáni, àìfiṣòwò rẹ ti Àwọn Ìpèsè náà. Ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àyè ayélujára tó jẹ́ ara Iṣẹ́ náà lè ní kóòdù ẹlòmíràn nínú. Àwọn ìtọ́sọ́nà tàbí kóòdù àwọn ẹlòmíràn, èyítí ó ní àsopọ̀ pẹ̀lú tàbí tí a tọ́ka sí láti inú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àyé ayélujára náà, ni a fún ọ ní ìwé-àṣẹ fún láti ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn tó ni irú kóòdù bẹ́ẹ̀, kìí ṣe láti ọwọ́ Microsoft. Àwọn àkíyèsi, bí ó bá wà, fún kóòdù àwọn ẹlòmíràn náà ní a fi sínú rẹ fún àlàyé nìkan.
 • b. A fún ọ ní ìwé-àṣẹ fún ẹ̀yà àìrídìmú náà ni, a kò tàá, Microsoft sì ni ó ni gbogbo ẹ̀tọ́ sí àwọn ẹ̀yà àìrídìmú náà, èyítí Microsoft kò fifún ni tààrà lábẹ́ àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ náà, yálà nípasẹ̀ èrò tí a mú jáde nínú ohun tí a kò fẹnusọ, nípasẹ̀ àìlè yí èrò tí a fẹ́ kí ohun tí a kò fẹnusọ mú jáde padà, tàbí lọ́nà mìíràn. Ìwé-àṣẹ yìí kò fún ọ ní ẹ̀tọ́ yòówù lati, o kò sì gbọdọ̀:
  • i. yípo tàbí rékọjá àwọn ìlànà ìdáàbòbò nípasẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ tó wà nínú tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn Iṣẹ́ náà;
  • ii. túká, tú palẹ̀, yọ kóòdù rẹ̀ kúrò, wọlé sínú rẹ̀ lọ́nà àìtọ́, jíi wò, lòó lọ́nà àìtọ́, tàbí tún iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tò nínú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí abala mìíràn lára àwọn Iṣẹ́ náà tó wà nínú tàbí tó ṣeé wọlé sí nípasẹ̀ àwọn Iṣẹ́ náà, àfi àti títí dé ibití òfin ẹ̀tọ́ ọjà-títà bá gba ni láàyè ní ṣiṣẹ bẹ́ẹ̀ dé;
  • iii. ya àwọn àkóónú inú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn Iṣẹ́ náà sọ́tọ̀ fún ìmúlò lórí àwọn oríṣiríṣi ẹ̀rọ;
  • iv. ṣe àgbéjáde, dàkọ, yá ni fún èrèdí owó, fifún ni fún ìgbà díẹ̀, tà, gbée lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, gbée wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn, pín kiri, tàbí jẹ́ kí ẹlòmíràn lo ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn Iṣẹ́ náà, àfi bí Microsoft bá fún ọ ní àṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀;
  • v. fi ẹ̀yà àìrídìmú náà, ìwé-ẹrí ẹ̀yà àìrídìmú náà yòówù, tàbí ẹ̀tọ́ yòówù láti wọlé sí tàbí láti lo àwọn Iṣẹ́ náà fún ẹlòmíràn;
  • vi. lo àwọn Ìṣẹ́ náà lọ́nàkọnà tí a kò fún ni ní àṣẹ láti lòó, èyí tó lè dí ìmúlò ẹlòmíràn lọ́wọ́ tàbí kí o wọlé sí iṣẹ́ yòówù, détà, àkọọ́lẹ̀, tàbí nẹ́tíwọọ̀kì, lọ́nàkọnà;
  • vii. mú ìráyèsí Àwọn Iṣẹ́ ṣiṣẹ́ tàbí ṣàtúnṣe èyíkéyìí ohun èlò tí Microsoft fún láṣẹ (fún àpẹrẹ., Xbox One, Xbox 360, Microsoft Surface, abbl.) nípasẹ̀ àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ ẹlòmíràn tí a kò fún láṣẹ.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Àwíyé ÌsanwóÀwọn Àwíyé Ìsanwó9_paymentTerms
Ní ṣókí

9. Àwọn Àdéhùn Ìsanwó. Bí o bá ra Iṣẹ́ kan, nígbà náà, àwọn àdéhùn owó sísan wọ̀nyí kan ọjà rírà rẹ, ìwọ sì faramọ́ wọn.

 • a. Owó sísan. Bí owó kan bá wà tó níí ṣe pẹ̀lú abala àwọn Iṣẹ́ náà kan; o gbà láti san owó náà pẹ̀lú irú owó tí a filélẹ̀. Iye owó tí a kọ sílẹ̀ fún àwọn Iṣẹ́ náà kò kan gbogbo àwọn owó ìlú tó yẹ fún sísan àti ìyàtọ̀ tó wà nínú pàṣípààrọ̀ owó, àfi bí a bá sọ ohun tó yàtọ̀ sí èyí. Àwọn owó-ìlú tó yẹ wà lára gbogbo iye owó tí a nsan fún àwọn ọjà Skype tí à nsanwó fún, àfi bí a bá kọ ohun mìíràn nípa èyí. Ìwọ nìkan ni ó ni ojúṣe fún sísan irú àwọn owó ìlú bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn owó mìíràn. Skype ń ṣírò owó-orí bí ó ti dá lórí àdírẹ́ẹ̀sì ibi tí o ń gbé tó níṣe pẹ̀lú àlàyé ìdíyelé rẹ. Ojúṣe rẹ ni láti ṣàrídájú pé àdírẹ́ẹ̀sì yìí kójú òṣùwọ̀n ó sì péye. Àyàfi fún àwọn àgbéjáde Skype, owó-orí ni a ń ṣírò bí ó ti dá lórí ibi tí o wà ní àkókò tí a ṣàkọsílẹ̀ àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ àyàfi tí òfin abẹ́lé bá ní kí a ṣírò ní ọ̀nà míràn. A lè dá àwọn Iṣẹ́ náà dúró tàbí kí a fagilé wọn bí a kò bá gba owó tó yẹ fún sísan lẹkunrẹrẹ àti lakoko láti ọ̀dọ̀ rẹ. Ìdádúró tàbí ìfagilé Iṣẹ́ náà nítorí àìsan lè fa pípàdánù ànfàní àti wọlé sí àti láti lo àkọọ́lẹ̀ rẹ àti àkóónú inú rẹ̀. Sísopọ̀ mọ́ Íntánẹ́ẹ̀tì nípasẹ̀ alásopọ̀ àdáni tàbí tí ilé-iṣẹ́ míràn tó bo ibi tí o wà mọ́lẹ̀ le ṣokùnfà kí àwọn ìdíyelé yàtọ̀ sí àwọn tó farahàn fún ibi tí o wà gangan. Àwọn ìbánidòwòpọ̀ kan lè nílò ìṣàyípadà owó ilẹ̀ òkèèrè tàbí kí wọ́n nílò iṣẹ́ ṣíṣe síwájú síi ní orílẹ̀-èdè mìíràn, èyí sì dá lórí ipò ibití ìwọ wà. Ilé ìfowópamọ́ rẹ lè bèèrè fún àfikún owó fún àwọn iṣẹ́ náà bí o bá lo káàdì dẹ́bíìtì tàbí kírẹ́díìtì. Jọ̀wọ́ kàn sí ilé ìfowópamọ́ rẹ fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.
 • b. Àkọọ́lẹ̀ Ìdíyelé Rẹ. Làti san owó fún Iṣẹ́ kan, àwa yóò ní kí o pèsè ìlànà owó sísan kan nígbàtí ìwọ nforúkọsílẹ fún Iṣẹ́ náà. Fún gbogbo Iṣẹ́ yàtọ̀ sí Skype, o le ráyèsí kí o sì yí àlàyé ìdíyelé rẹ padà àti ìlànà ìsanwó lórí Ojúlé wẹ́ẹ̀bù ìṣàkóso àkọọ́lẹ̀ Microsoft àti fún ẹ̀yà àìrídìmú Skype àti àwọn àgbéjáde nípa wíwọlé sínú ààyè ìwọlé àkọọ́lẹ̀rẹ ní https://skype.com/go/myaccount. Ní àfikún, o gbà láti gba Microsoft láàyè láti lo àlàyé àkọọ́lẹ̀ yòówù tí a mú dójú ìwọ̀n, tó níí ṣe pẹ̀lú ìlànà owó sísan tí o yàn àti tí ilé-ìfowópamọ́ rẹ tàbí nẹtiwọki owó sísan tó kàn bá pèsè. O gbà láti tètè mú àkọọ́lẹ̀ rẹ àti àwọn àlàyé rẹ mìíràn dójú ìwọ̀n, èyí sì kan àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ àti àlàyé nípa ìlànà owó-sísan rẹ, kí a bá a lè parí iṣẹ́ lórí ìbánidòwòpọ̀ rẹ, kí a sì kàn sí ọ bí ó ti yẹ nípa ìbánidòwòpọ̀ rẹ. Àwọn àyípadà tí a bá ṣe sí àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ kì yóò kan iye owó tí a ó fi rànṣẹ sí àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ, kí a tó lè ṣiṣẹ lórí àwọn àyípada rẹ sí àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ.
 • c. Ìdíyelé. Nípa pípèsè ìlànà ìsanwó fún Microsoft, o (i) ṣojú pé o ní àṣẹ láti lo ìlànà ìsanwó náà tí o pèsè àti pé èyíkéyìí àlàyé ìsanwó tí o pèsè jẹ́ òtítọ́ àti pé ó péye; (ii) fún Microsoft ní àṣẹ láti díyelé ọ fún Àwọn Ìpèsè tàbí àkóónú tó wà nílẹ̀ nípa lílo ìlànà ìsanwó rẹ; àti (iii) fún Microsoft ní àṣẹ láti díyelé ọ fún èyíkéyìí ẹ̀yà tí a sanwó fún lára Àwọn Ìpèsè náà tí o yàn láti forúkọ sílẹ̀ fún tàbí lò ní ìwọ̀n ìgbà tí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà lójú iṣẹ́. Àwa lè díyelé ọ (a) ṣáájú ohun tí o fẹ́ rà; (b) ní àkókò ọjà-rírà; (c) lọ́gán lẹ́yìn ọjà-rírà; (d) láti ìgbà dé ìgbà fún àwọn Iṣẹ́ tí a nṣe aláàbápín fún. Bákan náà a tún lè díyelé ọ tó iye owó tí o ti fọwọ́ sí, àwa yóò sì sọ fún ọ ṣáájú iye owó yòówù tí èyí jẹ́ fún àwọn Iṣẹ́ tí ò nṣe aláàbápín fún. Àwa lè díyelé ọ nígbà kan náà fún iye àkókò ìdíleyé ìṣáájú tó ju ọ̀kan lọ fún àwọn owó tí a kò tètè ṣiṣẹ lé lórí.
 • d. Owó Sísan Láti Ìgbà Dé Ìgbà. Nígbàtí o bá ra Àwọn Ìpèsè náà lórí ìṣalábàápín (fún àpẹrẹ, oṣoṣù, ní gbogbo oṣù 3 tàbí ọdọdún), o gbà pé o ń fọwọ́sí ìsanwó àsantúnsan, àti pé a ó sanwó fún Microsoft nípasẹ̀ ìlànà náà àti ìgbà àsantúnsan tí o ti faramọ́, títí a ó fi mú ìṣalábàápín fún Ìpèsè náà dópin nípasẹ̀ rẹ tàbí nípasẹ̀ Microsoft. O gbọ́dọ̀ fagilé Àwọn Iṣẹ́ rẹ ṣáájú déètì ìdíyelé tókàn láti dẹ́kun sísanwó láti tẹ̀síwájú Àwọn Iṣẹ́ rẹ. A ó pèsè àwọn ìtọ́ni fún ọ lórí bí o ti le fagilé Àwọn Iṣẹ́ rẹ. Nípa fífi ọwọ́ sí ìsanwó àṣantúnsan, o ń fún Microsoft ní àṣẹ láti ṣiṣẹ́ lórí ìsanwó náà yálà bíi ìsanwó gbèsè tàbí ìfowó ránṣẹ́, tàbí sọ̀wédowó orí ẹ̀rọ láti ibi àkọọ́lẹ̀ rẹ tí o yàn (fún Automated Clearing House tàbí ìsanwó tójọra), tàbí bí ìdíyelé sí àkọọ́lẹ̀ rẹ tí o yàn (fún káàdì ìsanwó tàbí ìsanwó tójọra) (lápapọ̀, "Àwọn Ìsanwó Orí-ẹ̀rọ"). Owó ìṣalábàápín ni a máa ń yọ ṣáájú ìgbà ìṣalábàápín tí o bèrè. Tí a bá dá èyíkéyìí owó padà ní àìsan tàbí ti èyíkéyìí káàdì ìsanwó ìdúnàádúrà tójọra bá padà tàbí di sísẹ́, Microsoft tàbí àwọn olùpèsè iṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ láti gba èyíkéyìí wúnrẹ̀n tí a dá padà, ìkọ̀sílẹ̀ tàbí àìtó owó sísan kí a sì ṣiṣẹ́ lórí irú ìsanwó bẹ́ẹ̀ bíi Ìsanwó Orí-ẹ̀rọ.
 • e. Àwọn Àṣìṣe àti Gbólóhùn Orí Ayélujára. Fún gbogbo Iṣẹ́ yàtọ̀ sí Skype, Microsoft yóò pèsè gbólóhùn ìdíyelé orí ayélujára fún ọ lórí Ojúlé wẹ́ẹ̀bù ìṣàkóso àkọọ́lẹ̀ Microsoft, níbití o ti le wò kí o sì tẹ gbólóhùn rẹ jáde. Fún Skype, o le ráyèsí ohun àkọsílẹ̀ rẹ lóníforíkorí nípa wíwọlé sínú àkọọ́lẹ̀ rẹ ní www.skype.com. Èyí nìkan ní àlàyé owó tí àwa npèsè. Bí a bá ṣe àṣìṣe lórí ìdíyelé rẹ, o gbọdọ sọ fún wa láàárín ọjọ́ 90 lẹ́yìn tí aṣìṣe náà kọ́kọ́ hàn lórí ìdíyelé rẹ. Àwa yóò sì ṣe ìwádìí lọ́gàn nípa ìdíyelé náà. Bí o kò bá sọ fún wa láàárín àkókò náà, o yọ wá kúrò nínú gbogbo ojúṣe àti ẹ̀sùn àdánù tó lè wáyé nípasẹ̀ àṣìṣe náà, àwa kì yóò sì ní láti ṣe àtúnṣe sí àṣìṣe náà tàbí kí a san àsanpadà, àfi bí òfin bá ní kí a ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Microsoft bá ti rí àṣìṣe ìdíyelé kan, àwa yóò ṣàtúnṣe sí àṣìṣe náà láàárín ọjọ́ 90. Ìlànà yìí kò kan ẹ̀tọ́ yòówù lábẹ́ òfin tó lè ní ipa.
 • f. Òfin Owó Àsanpadà. Àfi bí òfin tàbí ìpèsè Iṣẹ́ kan pàtó bá sọ ohun mìíràn, gbogbo ọjà-rírà ohun àṣeparí, kò sì sí àsanpadà. Bí o bá gbàgbọ́ pé Microsoft ti ṣe àṣìṣe ní dídíyelé ọ, o gbọ́dọ̀ kàn sí wa láàárín ọjọ́ 90 tí ìdíyelé náà wáyé. A kì yóò san àsanpadà kankan fún ìdíyelé tó bá ti ju ọjọ́ 90 lọ, àfi bí òfin bá ní kí a ṣe bẹ́ẹ̀. Àwa ní gbogbo ẹ̀tọ́ láti san àsanpadà tàbí gbèsè nípasẹ̀ làákàyè wa nìkan. Bí a bá san àsanpadà tàbí gbèsè, àwa kò sí lábẹ́ ojúṣe kankan láti san irú àsanpadà bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Ìlànà àsanpadà yìí kò kan ẹ̀tọ́ yòówù lábẹ́ òfin tó lè ní ipa. Fún àlàyé síwájú síi nípa àsanpadà, jọ̀wọ́ kàn sí àkọlé ìrànlọ́wọ́ wa. Bí o bá ngbé ní Taiwanu, jọ̀wọ́ ṣàkíyèsi pé, ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Ìdáàbòbò Aṣàmúlò Ìkẹyìn ti Taiwanu àti ti àwọn ìlànà tó yẹ, ọjà-rírà tó níí ṣe pẹ̀lú àkóónú díjítàlì, èyí tí a pèsè nípasẹ̀ ohun àìrídìmú àti/tàbí àwọn iṣẹ́ orí ayélujára, jẹ́ àṣekẹ́yìn, kò sì sí àsanpadà bí a bá pèsè irú àkóónú tàbí iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lórí ayélujára. O kò ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè fún àkókò ìsinmi yòówù tàbí àsanpadà yòówù.
 • g. Fífagilé Àwọn Iṣẹ́ náà. O lè fagilé Iṣẹ́ kan nígbà yòówù, pẹ̀lú tàbí láìsí ìdí. Fífagilé Àwọn Iṣẹ́ tí a sanwó fún dẹ́kun ìdíyelé ọjọ́ wájú láti tẹ̀síwájú Iṣẹ́ náà. Para cancelar un Servicio y solicitar un reembolso, si tiene derecho a uno, visite el sitio web de administración de cuentas de Microsoft. Para Skype, complete el Formulario de Desistimiento con la información que se suministra aquí. O gbọ́dọ̀ padà sí ìfilọ̀ tó ṣàlàyé Àwọn Ìpèsè náà, nítorí (i) o lè má gba owó àsanpadà ní àkókò ìfagilé; (ii) ó lè jẹ́ ojúṣe rẹ láti san owó ìdíyelé ìfagilé; (iii) ó lè jẹ́ ojúṣe rẹ láti san gbogbo ìdíyelé tí a ṣe sínú àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ fún Àwọn Ìpèsè náà ṣáájú ọjọ́ ìfagilé; àti (iv) o lè pàdánù ìráyèsí àti ìlò àkọọ́lẹ̀ rẹ nígbàtí o bá fagilé Àwọn ìpèsè náà; tàbí tí o bá ń gbé ní ilú Taiwan, (v) o lè gba owó àsanpadà tó bá iye owó tí o san fún Ìpèsè kan tí a kò lò dọ́gba, a ó sì ṣírò èyí ní àkókò ìfagilé. Àwa yóò ṣètò Détà rẹ bí a ti ṣàlàyé lókè yìí ní abala 4. Bí o bá fagilée, wíwọlé rẹ sínú Iṣẹ́ náà yóò parí ní òpin àkókò Iṣẹ́ rẹ tó nlọ lọ́wọ́ tàbí, bí a bá má a ndíyelé àkọọ́lẹ̀ rẹ láti ìgbà dé ìgbà, ní òpin àkókò tí o ṣe ìfagilé náà.
 • h. Àwọn Ìfúnni Ìgbà Ìdánwò. Tí o bá ń kópa ninú èyíkéyìí ìfúnni ìgbà ìdánwò,a le sọ fún ọ kí o fagilé (àwọn) Iṣẹ́ ìdánwò láàrín àkókò tí a sọ fún ọ nígbàtí o gba ìfúnni náà láti le dènà dídíyelé láti tẹ̀síwájú (àwọn) Iṣẹ́ náà lópin ìgbà ìdánwò náà.
 • i. Àwọn Ìfúnni Ìpolówó Ọjà. Láti ìgbà dé ìgbà, Microsoft lè pèsè àwọn Iṣẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ fún àkókò ìdánwò. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti díyelé ọ fún irú Àwọn Ìpèsè bẹ́ẹ̀ (ní iye owó déédé) tí Microsoft bá pinnu (nínú èrò rẹ̀) pé o ń ṣe àṣìlò àwọn àdéhùn ìfilọ̀ náà.
 • j. Àwọn Àyípadà Iye-owó. A le yí owó àwọn Ìpèsè náà padà ní ìgbàkúgbà àti pé tí o bá ní ìrajà àsantúnsa, a ó sọ fún ọ nípasẹ̀ í-meèlì, tàbí ọ̀nà míràn tó mọ́gbọ́nwá, ó kéré jù ọjọ́ 15 kí iye owó náà tó yípadà. Bí o kò bá faramọ́ àyípadà iye owó náà, o gbọ́dọ̀ fagilé Iṣẹ́ náà tabí kí o dẹ́kun àti lòó kí àyípadà iye owó náà tó bẹ̀rẹ̀. Bí àkókò àti iye owó àìṣeéyípadà bá wà fún ìpèsè Iṣẹ́ rẹ, iye owó náà ní yóò má a ní ipa fún àkókò àìṣeéyípadà náà.
 • k. Ìsanwó fún Ọ. Bí a bá jẹ ọ ní owó kan, o gbà láti pèsè àlàyé yòówù tí a nílò láti fún ọ ní owó náà lásìkò àti lẹkunrẹrẹ. Ìwọ ni ó ni ojúṣe fún owó ìlú yòówù àti àwọn owó tó lè wà fún sísan nípasẹ̀ owó sísan fún ọ yìí. O tún gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àwọn àgbékalẹ̀ yòówù tí a fi sórí ẹ̀tọ́ rẹ sí owó gbígbà yòówù. Bí o bá gba owó kan nípasẹ̀ àṣìṣe, a lè yíipadà tàbí kí á bèèrè fún ìdápadà owó náà. O gbà láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa nínú ìgbìyànjú wa láti ṣe èyí. A tún lè dín iye owó sísan fún ọ kù láì sọ láti lè ṣàtúnṣe sí àsanlé yòówù tó ti wáyé tẹ́lẹ̀.
 • l. Àwọn Káàdì Ẹ̀bùn. Ìràpadà àti ìmúlò àwọn káàdì ẹ̀bùn (yàtọ̀ sí àwọn káàdì ẹ̀bùn Skype) ni a ndarí nípasẹ̀ Àwọn Àdéhùn àti Ìlànà Káàdì Ẹ̀bùn Microsoft. Àlàyé nípa àwọn káàdì ẹ̀bùn Skype wà ní Ojú-ìwé Ìrànlọ́wọ́ Skype.
 • m. Ìlànà Ìsanwó Àkọọ́lẹ̀ Ilé-ìfowópamọ́. O le ṣàkọsílẹ̀ àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ tó yẹ pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ láti lòó gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ìsanwó rẹ. Àwọn àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ tó yẹ pẹ̀lú àwọn àkọọ́lẹ̀ tí a dìmú ní ilé ìṣúná owó tó lágbára láti gba àwọn ìwọlé gbèsè tààrà (fún àpẹrẹ, àwọn ilé iṣẹ́ ìṣúná owó tó wà ní Ilú Amẹrika tó sì faramọ́ automated clearing house ("ACH") àwọn ìwọlé, ilé iṣẹ́ ìṣúná owó tó wà ní Yuropu tó faramọ́ Single Euro Payments Area ("SEPA") tàbí "iDEAL" ní Netherlands). Àwọn Àdéhùn tí o faramọ́ nígbàtí o ń ṣàfikún àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìsanwó nínú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ (fún àpẹrẹ, ṣíṣe "dandan" tó bá jẹ́ SEPA) tún ṣàmúlò. O ṣojú o sì fọwọ́sọ̀yà pé àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ tí o ṣàkọsílẹ̀ wà ní orúkọ rẹ tàbí a gbà ọ́ láàyè láti forúkọ sílẹ̀ kí o sì lo àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ yìí bíi ìlànà ìsanwó. Nípa ìforúkọsílẹ̀ tàbí yíyan àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ìsanwó rẹ, o fún Microsoft ní àṣẹ (tàbí àṣojú rẹ̀) láti bẹ̀rẹ̀ gbèsè kan tàbí ọ̀pọ̀ fún àpapọ̀ iye owó ọjà tí o rà tàbí ìdíyelé ìṣalábàápín rẹ (gẹ́gẹ́ bíi àdéhùn ìpèsè ìṣalábàápín rẹ) láti inú àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ (àti, tó bá ṣe pàtàkì, bẹ̀rẹ̀ kírẹ́dìtì kan tàbí ọ̀pọ̀ sínú àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ láti yanjú àwọn àṣìṣe, fúnni ní owó àsanpadà tàbí èrèdí tó jọra), àti pé o fún ilé iṣẹ́ ìṣúná tó ní àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ lọ́wọ́ ní àṣẹ láti yọ bíi gbèse tàbí gba irú kírẹ́dìtì náà. O lóye pé ìfúnláṣẹ yìí yóò wà lójú iṣẹ́ àti ìṣe títí wàá fi yọ àlayé àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ kúrò nínú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ. Kàn sí àtìlẹ́yìn oníbàárà bí a ti kọọ́ sílẹ̀ lókè ní abala 4(e) ní kíákíá tí o bá gbà pé a díyelé ọ ní àṣìṣe. Àwọn òfin tí a ń ṣàmúlò ní orílẹ̀-èdè rẹ tún le ṣòdíwọ̀n fún gbèsè rẹ fún èyíkéyìí ìwà gbéwiri, àwọn ìdúnàádúrà àìgbàṣẹ tàbí àṣìṣe láti inú akọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ. Nípa ìforúkọsílẹ̀ tàbí yíyan àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ kan gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ìsanwó rẹ, o gbà pé o ti kà, ó sì yé ọ o sì faramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àjọ Tí Ń Ṣàdéhùn, Ẹ̀yàn Òfin, Àti Agbègbè Tí A Ti Ń Parí Aáwọ̀Àjọ Tí Ń Ṣàdéhùn, Ẹ̀yàn Òfin, àti Àti Ibití A Ti Parí Aáwọ̀10_11_contractingEntityChoiceOfLaw
Ní ṣókí

10. Àjọ Tí Ń Ṣàdéhùn, Ẹ̀yàn Òfin, Àti Agbègbè Tí A Ti Ń Parí Aáwọ̀. Fún ìlò rẹ ti Àwọn Iṣẹ́ olórúkọ Skype ti ọ̀fẹ́ àti oníbàárà tí ń sanwó, tí o bá ń gbé lóde Europe , Middle East àti Africa, o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú, gbogbo ìtọ́kasí "Microsoft" nínú Àwọn Àwíyé wọ̀nyí túmọ̀ sí,, Skype Communications S.à.r.l, 23 – 29 Rives de Clausen, L-2165 Luxembourg. Fún Àwọn Iṣẹ́ olórúkọ Skype ti ọ̀fẹ́ tàbí oníbàárà tí ń sanwó, tí o bá ń gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, òfin Luxembourg ń darí ìtúmọ̀ ti Àwọn Àwíyé àti ìbèrè fún dídalẹ̀ kọ̀ọ̀kan, láì fi ti àwọn ìlànà òfin aáwọ̀ ṣe. Òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè ibiti iwọ ngbé ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan gbígba ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ìpínlẹ̀ fún ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, òfin fífiga-gbága ti kò tọ́, ati nínú òfin ti ndarí ìwà àìtọ́. Tí o bá ń gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, ìwọ àti àwa gbà sí agbègbè àti ibi àwọn ilé-ẹjọ́ ti Luxembourg fún gbogbo aáwọ̀ tó le jáde láti tàbí tó jọmọ́ onibàárà ti Àwọn Iṣẹ́ olórúkọ ti Skype. Fún gbogbo Iṣẹ́ míràn, àjọ tí o ń ti ipasẹ̀ wọn ṣàdéhùn, òfin tí ń darí, àti ibi láti yanjú àwọn aáwọ̀ farahàn nísàlẹ̀:

 • a. Canada. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Canada, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Àwọn òfin ìpínlẹ̀ ibití ìwọ ngbé (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, ibití olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà) ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, àti gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ mìíràn (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́) láì ka awọn òfin miiran tó rọ̀ mọ́ èyí, ti wọ́n si le yàtọ̀ síi kún. Ìwọ àti àwa faramọ́, láìsí àyípadà ọkàn, pé sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Ontario ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Iṣẹ́.
 • b. Àríwá tàbí Gúsù America lóde United States tàbí Canada. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Àríwá tàbí Gúsù America lóde United States tàbí Canada, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Àwọn òfin ìpínlẹ̀ Washington ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka àṣàyàn òfin tó rọ̀ mọ́ èyí kún. Òfin orílẹ̀-èdè ibiti à ndarí Àwọn Iṣẹ́ rẹ sí ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́.
 • c. Middle East, Africa tàbí Europe. Tí o bá ń gbé ní (tàbí, tí ìṣòwò kan, olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Middle East, Africa tàbí ní Europe lóde European Union (EU) àti European Free Trade Association (EFTA), tí o sì ń lo abala ọ̀fẹ́ ti Àwọn Iṣẹ́ náà (bíi Bing àti MSN), o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A., àyàfi tí o bá ń lo abala ọ̀fẹ́ ti Skype, o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Ireland Operations Limited, One Microsoft Place, South County Business Park, Leopardstown, Dublin 18, Ireland. Tí o bá sanwó láti lo abala kan ti Àwọn Iṣẹ́, o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Ireland Operations Limited, One Microsoft Place, South County Business Park, Leopardstown, Dublin 18, Ireland. Fún Àwọn Iṣẹ́ ọ̀fẹ́ tàbí tí a nsanwó fún, òfin Ireland ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àti àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka awọn òfin miiran tó rọ̀ mọ́ èyí, ti wọ́n sì lè yàtọ̀ síi kún. Òfin orílẹ̀-èdè ibiti à ndarí Àwọn Iṣẹ́ rẹ sí ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́. Ìwọ àti àwa faramọ́, láìsí àyípadà ọkàn, pé sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Ireland ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Iṣẹ́.
 • d. Asia tàbí Gúsù Pacific, àfi bí a bá dárúkọ orílẹ̀-èdè rẹ ní pàtó nísàlẹ̀ yìí. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Asia (yàtọ̀ sí China, Japan, Republic of Korea, tàbí Taiwan) tàbí Gúsù Pacific, tí o sì nlo ẹ̀yà ọ̀fẹ́ Àwọn Ìpèsè náà (gẹ́gẹ́ bíi Bing àti MSN), ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Bí o bá nsanwó láti lo ẹ̀yà Iṣẹ́ náà kan, tàbí ìwọ nlo iṣẹ́ Outlook.com ọ̀fẹ́ ní Singapore tàbí Hong Kong, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Regional Sales Corp., ilé-iṣẹ́ tí a dásílẹ̀ lábẹ́ àwọn òfin Ìpínlẹ̀ Nevada, U.S.A., pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ní Singapore àti Hong Kong, àti olú ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ní 438B Alexandra Road, #04-09/12, Block B, Alexandra Technopark, Singapore, 119968; tó bá jẹ pé, bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Australia, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Pty Ltd, 1 Epping Road, North Ryde, NSW 2113, Australia, bí o bá sì ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) New Zealand, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft New Zealand Limited, Level 5, 22 Viaduct Harbour Avenue, PO Box 8070 Symonds Street, Auckland, 1150 New Zealand. Fún Àwọn Iṣẹ́ ọ̀fẹ́ àti èyítí a nsanwó fún, òfin Ìpínlẹ̀ Washington ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn àti àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn òfin miiran kún. Òfin orílẹ̀-èdè ibiti à ndarí Àwọn Iṣẹ́ rẹ sí ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́. Àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tàbí àwọn Iṣẹ́ náà yàtọ̀ sí Skype, títí kan ìbéèrè yòówù tó níí ṣe pẹ̀lú wíwà wọn, wíwúlò, tàbí píparí iṣẹ́, ni a ó mẹ́nubà, tí a ó sì yanjú nípasẹ̀ ìlàjà ní Singapore ní ìbámu pẹ̀lú Àwọn Òfin Ìlàjà ti Singapore International Arbitration Center (SIAC), awọn òfin èyí tí a kà kún pé a kọ sínú gbólóhùn kúkúrú yìí. Àjọ àwọn adájọ́ náà yóò ní onílàjà kan nínú, èyí tí Ààrẹ SIAC yóò yàn. Èdè tí a ó lò fún ìlàjà náà yóò jẹ́ Gẹ̀ẹ́sì. Ìpinnu onílàjà náà yóò jẹ́ ìdájọ́ ìkẹyìn, èyí tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé, a ki yóò si lè jiyàn rẹ̀, a sì lè lòó gẹ́gẹ́ bíi ìlànà fún ìdájọ́ ní orilẹ̀-èdè yòówù.
 • e. Japan. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Japan, tí o sì nlo ẹ̀yà ọ̀fẹ́ Àwọn Iṣẹ́ náà (gẹ́gẹ́ bíi Bing àti MSN), ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Bí o bá nsawó láti lo ẹ̀yà Iṣẹ náà kan, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Japan Co., Ltd (MSKK), Shinagawa Grand Central Tower, 2-16-3 Konan Minato-ku, Tokyo 108-0075. Fún Àwọn Iṣẹ́ ọ̀fẹ́ tàbí tí a nsanwó fún, òfin Japan ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àti àwọn ẹjọ́ yòówù tó lè wáyé láti inú wọn tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú wọn tàbi Àwọn Iṣẹ́ náà. Ìwọ àti àwa faramọ́, láìsí àyípadà ọkàn, pé ojúlówó sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Tokyo District ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Iṣẹ́.
 • f. Republic of Korea. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Republic of Korea, tí o sì nlo ẹ̀yà ọ̀fẹ́ Àwọn Iṣẹ́ náà (gẹ́gẹ́ bíi Bing àti MSN), ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Bí o bá nsawó láti lo ẹ̀yà Iṣẹ náà kan, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Korea, Inc., 11th Floor, Tower A, K-Twin Tower, Jongro 1 gil 50, Jongro-gu, Seoul, Republic of Korea, 110-150. Fún Àwọn Iṣẹ́ ọ̀fẹ́ tàbí tí a nsanwó fún, òfin Republic of Korea ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àti àwọn ẹjọ́ yòówù tó lè wáyé láti inú wọn tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú wọn tàbi Àwọn Iṣẹ́ náà. Ìwọ àti àwa faramọ́, láìsí àyípadà ọkàn, pé ojúlówó sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Seoul Central District ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Iṣẹ́.
 • g. Taiwan. Tí o bá ń gbé ní (tàbí, tí ìṣòwò kan, olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Taiwan, tí o sì ń lo abala ọ̀fẹ́ ti Àwọn Iṣẹ́ náà (bíi Bing àti MSN), o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Tí o bá sanwó láti lo abala kan ti Àwọn Iṣẹ́, o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Taiwan Corp., 18F, No. 68, Sec. 5, Zhongxiao E. Rd., Xinyi District, Taipei 11065, Taiwan. Fún Àwọn Iṣẹ́ ọ̀fẹ́ àti ìsanwó, àwọn òfin Taiwan ń darí Àwọn Àwíyé wọ̀nyí àti èyíkéyìí ọ̀ràn tó le jẹyọ láti tàbí tó jọmọ́ wọn tàbí Àwọn Iṣẹ́. Fún àlàyé síwájú síi nípa Microsoft Taiwan Corp., jọ̀wọ́ wo àyè ayélujára tí a pèsè láti ọwọ́ Ministry of Economic Affairs R.O.C.. Ìwọ àti àwa yan, láìsí àyípadà ọkàn, Ilé-ẹjọ́ Taipei District gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹjọ́ àkọ́kọ́ tó ní ẹ̀tọ́ láti dá ẹjọ́ lórí àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Iṣẹ́, títí dé ibití òfin Taiwan gba ni láàyè dé.

Oníbàárà ìkẹyìn agbègbè rẹ lè nílò àwọn òfin agbègbè láti darí tàbí láti fún ọ ní ẹ̀tọ́ láti yanjú àríyànjiyàn ní ibòmíràn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àṣàyàn òfin àti ìpèsè ibòmíràn ní apá 10 yóò ní ipa dé ibití àwọn òfin agbègbè rẹ bá gba ni láàyè dé.

Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Ìfọwọ́sọ̀yàÌfọwọ́sọ̀yà12_Warranties
Ní ṣókí

11. Àwọn àtìlẹ́yìn ọjà.

 • a. MICROSOFT, ÀTI ÀWỌN ALÁÀBÁṢIṢẸ́PỌ̀ WA, ALÁÀTÚNTÀ, OLÙPÍN ỌJÀ, ÀTI ÀWỌN ALÁGBÀTÀ, KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN ỌJÀ KANKAN, TÍ A FẸNUSỌ TÀBÍ TÍ A KÒ SỌ PÀTÓ, ÀFẸ̀HÌNTÌ TÀBÍ MÁJẸ̀MÚ NÍPA ÌMÚLÒ RẸ FÚN IṢẸ́ NÁÀ. Ó YÉ Ọ PÉ ÌMÚLÒ IṢẸ́ NÁÀ JẸ́ EWU TÌRẸ, ÀTI PÉ A PÈSÈ IṢẸ́ NÁÀ LÓRÍ ÌPÌLẸ̀ ¨BÍ Ó ṢE Rͨ ¨PẸ̀LÚ GBOGBO ÀṢÌṢE¨ ÀTI ¨BÍ Ó ṢE WÀ.¨ MICROSOFT KÒ ṢE ÌDÁNILÓJÚ KANKAN NÍPA ṢÍṢIṢẸ́ DÁRADÁRA ÀTI LÁSÌKÒ ÀWỌN ÌPÈSÈ NÁÀ. O LÈ NÍ ÀWỌN Ẹ̀TỌ́ KAN LÁBẸ́ ÀWỌN ÒFIN AGBÈGBÈ RẸ. KÒ SÍ OHUNKÓHUN NÍNÚ ÀWỌN ÀDÉHÙN WỌ̀NYÍ TÍ A GBÈRÒ PÉ KÍ Ó NÍ IPA LÓRÍ ÀWỌN Ẹ̀TỌ́ WỌ̀NYÍ, BÍ Ó BÁ KÀN WỌ́N. O GBÀ PÉ ÀWỌN Ẹ̀RỌ KỌMPUTA ÀTI TI ÌBÁRAẸNISỌ̀RỌ̀ KÒ WÀ LÁÌSÍ ÀṢÌṢE ÀTI PÉ ÀWỌN ÀKÓKÒ ÀÌṢEDÉÉDÉ KAN A MÁ A WÁYÉ LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN. ÀWA KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN PÉ IṢẸ́ NÁÀ YÓÒ JẸ́ ÈYÍ TÍ KÒ NÍ ÌDÁDÚRÓ KANKAN, TÍ YÓÒ LỌ GEERE LASIKO, PẸ̀LÚ ÀÀBÒ, LÁÌNÍ ÀṢÌṢE TÀBÍ PÉ KÌ YÓÒ SÍ ÀDÁNÙ ÀKÓÓNÚ, BẸ́Ẹ̀ SÌ NI A KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN FÚN ÀSOPỌ̀ SÍ TÀBÍ ÌFIRÁNṢẸ́ LÁTI ÀWỌN NẸTIWỌKI KỌMPUTA.
 • b. TÍTÍ DÉ IBITÍ ÒFIN AGBÈGBÈ RẸ FI ÀÀYÈ GBA NI DÉ, ÀWA MÚ ÀTÌLẸ́YÌN YÒÓWÙ TÍ A KÒ DÁRÚKỌ KÚRÒ, ÈYÍ TÍ Ó KAN WÍWÚLÒ LÓRÍṢIRÍṢI Ọ̀NÀ, DÍDÁRA NÍ Ọ̀NÀ TÓ TẸ́NILỌ́RÙN, YÍYẸ FÚN ÈRÈDÍ KAN PÀTÓ, AKITIYAN BÍI ÒṢÌṢẸ́, ÀTI ÀÌTAPÁ SÍ ÀDÉHÙN.
 • c. Fún àwọn aṣàmúlò tí ngbé ní Australia: Àwọn ọjà àti iṣẹ́ wa ń wá pẹ̀lú ìfọwọ́sọ̀yà tí a kò le yọkúrò lábẹ́ Òfin Oníbàá Ilẹ̀ Australian. Fún ìkùnnà gbógì pẹ̀lú iṣẹ́ náa, o ní ẹ̀tọ́:
  • láti fagilé àdéhùn iṣẹ́ rẹ pẹ̀lú wa; àti
  • sí ìdáwópadà fún abala tí o kò lò, tàbí sí owó gbà má bínú fún ẹ̀dínwó rẹ̀.

  O tún ní ẹ̀tọ́ láti yàn tàbí ìrọ́pò fún àwọn ìkùnnà gbógì pẹ̀lú àwọn ọjà. Tí ìkùnnà kan sí ọjà tàbí iṣẹ́ kò bá tó ìkùnnà gbógì, o ní ẹ̀tọ́ sí àtúnṣe ìkùnnà náà láàrín àkókò díẹ̀. Tí a kò bá ṣe èyí o ní ẹ̀tọ́ sí owó àsanpadà fún ọjà náà kí o sì fagilé àdéhùn náà fún iṣẹ́ náà kí o sì gba owó àsanpadà fún abala tí o kò lò. O tún ní ẹ̀tọ́ fún owó gbà má bínú fún èyíkéyìí ìdíbàjẹ́ tàbí àdánù tí a le rí nítorí ìkùnnà kan nínú ọjà tàbí iṣẹ́.

 • d. Fún àwọn aṣàmúlò ìkẹyìn tí ngbé ní New Zealand, o lè ní àwọn ẹ̀tọ́ kan lábẹ́ àwọn Òfin Àtìlẹ́yìn Ọjà Aṣàmúlò Ìkẹyìn New Zealand, kò sì sí ohunkóhun nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tí a gbèrò láti ní ipa lórí àwọn ẹ̀tọ́ náà.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Ìdíwọ̀n OjúṣeÌdíwọ̀n Ojúṣe13_limitationOfLiability
Ní ṣókí

12. Ìdíwọ̀n Ojúṣe.

 • a. Tí o bá ní ìdí kankan láti gba àsanpadà (èyítí ó kan ìtàpá sí òfin Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí), títí dé ibi tí òfin tó yẹ gbani láàyè dé, o gbà pé àtúnṣe rẹ, láìsí ohun mìíràn, ni láti gbà àsanpadà tààrà, èyítí iye owó rẹ tó iye owó Ìpèsè rẹ fún oṣù náà nínú èyítí àdánù tàbí ìtàpà sí òfin náà wáyé (tàbí iye tó tó USD$10.00 bí àwọn Ìpèsè náà bá jẹ́ ọ̀fẹ́), láti ọ̀dọ̀ Microsoft tàbí aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ yòówù, aláàtúntà, olùpín kiri, àwọn olùpèsè Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta, àti àwọn alágbàtà.
 • b. Títí dé ibití òfin tí ó yẹ gba ni láàyè dé, ìwọ kó lè gba ohunkóhun padà fún (i) àwọn àdánù tàbí ìbàjẹ́ tó ti ìdí ohun kan jáde; (ii) àdánù ojúlówó èrè tàbí ti èrè tí à nretí (yálà tààrà tàbí tí kò lọ tààrà); (iii) àdánù ojúlówó owó tó nwọlé tàbí ti èyítí à nretí (yálà tààrà tàbí tí kò lọ tààrà); (iv) àdánù iṣẹ́ aláàdèhùn tàbí ti òwò tàbí àwọn àdánù tàbi ìbàjẹ́ mìíràn tó wáyé nípasẹ̀ lílò rẹ Iṣẹ́ náà ní ọ̀nà tí kìí ṣe ti ara ẹni; (v) àwọn àdánù tàbí ìbàjẹ́ pàtàkì, tí kò lọ tààrà, tó ti ìpasẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé tàbí tó wáyé nípasẹ̀ ìfìyàjẹni; àti (vi) títí dé ibití òfin fi ààyè gba ni dé, àwọn àdánù tàbí ìbàjẹ́ tó rékọjá àwọn akọsílẹ̀ tó wà ní apá 12(a) lókè yìí. Àwọn ìdíwọ̀n àti ìyọkúrò wọ̀nyí yóò ní ipa bí àtúnṣe yìí kò bá san àsanpadà lẹkunrẹrẹ fún ọ fún àdánù yòówù tàbí bí ó bá kùnà láti ṣe ohun pàtàkì tí a gbèrò rẹ̀ fún tàbí bí a bá mọ̀ tàbí tó yẹ kí a mọ̀ nípa ṣíṣeéṣe àwọn àdánù náà. Títí dé òpin ibití òfin fi ààyè gba ni dé, àwọn ìdíwọ̀n àti ìyọkúrò wọ̀nyí ní ipa lórí ohunkóhun yòówù tàbí gbígbà padà yòówù tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, àwọn Iṣẹ́ náà, tàbí ẹ̀yà àìrídìmú tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Iṣẹ́ náà.
 • c. Microsoft kò ní ojúṣe kankan tàbí ní ohun kankan láti dáhùn fún kíkùnà láti ṣiṣẹ́ tàbí ìdádúró ní ṣíṣe iṣẹ́ tó jẹ́ ojúṣe rẹ̀ lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí títí kan ibi tó jẹ́ pé ìkùnà tàbí ìdádúró náà wáyé nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó rékọjá agbára Microsoft (gẹ́gẹ́ bíi àríyànjiyàn àwọn òṣìṣẹ́, àwọn àmúwá Ọlọrun, ogun tàbí ìwà àwọn adánilóró. ìbàjẹ́ tí a fi ṣe ìkà fún ni, ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ tàbí ìfèsì sí òfin tí ó yẹ tàbí sí àṣẹ ìjọba). Microsoft yóò gbìyànjú láti dín ipa èyíkéèyí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kù, àti láti ṣe àwọn ojúṣe tí èyí kò kàn.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtóÀwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtó14_service-SpecificTerms
Ní ṣókí

13. Àwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtó. Àwọn àdéhùn tó wà ṣáájú àti lẹ́yìn apá 13 kan gbogbo àwọn Iṣẹ́ lápapọ̀. Apá yìí ní àwọn àdéhùn tó kan àwọn iṣẹ́ kan pàtó nínú, àwọn èyí tó jẹ́ àfikún sí àwọn àdéhùn gbogbogbò. Àwọn àdéhùn tó níí ṣe pẹlú ìpèsè kan pàtó wọ̀nyí ni a ó lò bí aáwọ̀ yòówù bá jẹyọ pẹ̀lú àwọn àdéhùn gbogbogbò.

Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Xbox Live àti Xbox Game Studios Games àti Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀Xbox Live àti Xbox Game Studios Games àti Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀14a_XboxLive
Ní ṣókí
 • a. Xbox Live àti Xbox Game Studios Games àti Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀.
  • i. Ìmúlò Ara ẹni Tí Kìí Ṣe fún Òwò. Xbox Live, Games fún Windows Live àti Xbox Game Studios games, àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀, iṣẹ́ àti àkóónú tí Microsoft pèsè (lápapọ̀ "Xbox Services") wà fún àdálò nìkan kìíṣe fún ìṣòwò.
  • ii. Àwọn Ìpèsè Xbox. Nígbàtí o bá forúkọ sílẹ̀ sí Xbox Live àti/tàbí gba Xbox Services, àlàyé nípa ìṣeré rẹ, àwọn ìṣiṣẹ́ àti ìlò àwọn eré àti Xbox Services ni a o tọpinpin tí a ó sì ṣàpínlò pẹ̀lú àwọn olùkọ-kóòdù eré míràn fún Microsoft àti àwọn olùkọ-kóòdù eré míràn le ṣiṣẹ́ lórí àwọn eré wọn láti le ṣàgbéjáde Xbox Services. Bí o bá yàn láti so àkọọ́lẹ̀ awọn Iṣẹ́ Xbox Microsoft rẹ pọ̀ mọ́ àkọọ́lẹ̀ rẹ lórí iṣẹ́ tí kìí ṣe ti Microsoft (fún àpẹẹrẹ, olùgbéjáde eré Àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ Àwọn Ẹlòmíràn tí kìí ṣe ti Microsoft), o faramọ́ ọ pé: (a) Microsoft lè ṣe àjọpín àlàyé àkọọ́lẹ̀ níwọnba (èyítí ó kan, láìní àhámọ́ gamertag, gamerscore, iye máàkì eré, ìtàn eré, àti àkójọ àwọn ọ̀rẹ́), pẹ̀lú ẹlòmíràn tí kìí ṣe Microsoft náà gẹ́gẹ́ bí a ti kọọ́ sínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ Microsoft, àti (b) bí ètò ìkọ̀kọ̀ Xbox rẹ bá gba ni láàyè, ẹlomíràn tí kìí ṣe Microsoft náà lé ní ànfàní láti wọlé sí Àkóónú rẹ bákan náà láti inú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lórí eré nígbàtí o bá buwọ́lù wọlé sí àkọọ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú ẹnití kìí ṣe Microsoft náà. Bákan náà, bí ètò ìkọ̀kọ̀ Xbox rẹ bá gba ni láàyè, Microsoft lè ṣe àtẹ̀jáde orúkọ rẹ, gamertag, gamerpic, motto, avatar, gameclips àti àwọn eré rẹ tí o ti ṣe, nínú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn tí o gbà láàyè.
  • iii. Àkóónú Rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ara mímú ìlọsíwájú bá àwùjọ aṣàmúlò Àwọn Ìpèsè Xbox, ìwọ fún Microsoft, àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, àti àwọn tí nfúni ní ìgbaniláàyè lórúkọ rẹ̀, ní ẹ̀tọ́ ọ̀fẹ káríayé, láti lò, ṣàtúnṣe sí, ṣàtúndá, pín kiri, tàn káàkiri, ṣàpínlò, àti láti ṣàfihàn Àkóónú Rẹ tàbí orúkọ rẹ, gamertag, motto, tàbí avatar tí o fihàn fún àwọn Ìpèsè Xbox yòówù.
  • iv. Àwọn Olùṣàkóso Eré. Àwọn eré kan lè má a lo àwọn olùṣàkóso àti olùgbàlejò eré. Àwọn olùṣàkóso àti olùgbàlejò eré kìí ṣe agbẹnusọ Microsoft tí a fún ní àṣẹ. Èròngbà wọn kò kúkú ṣe àfihàn èròngbà ti Microsoft.
  • v. Àwọn ọmọde lórí Xbox. Bí o bá jẹ́ ọmọdé tó nlo Xbox Live, àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ rẹ lè ní ìṣàkóso lórí ọ̀pọ̀ lára abala àkọọ́lẹ̀ rẹ, wọ́n sì lè má a gba ìjábọ̀ nípa ìmúlò Xbox Live rẹ.
  • vi. Owó Eré tàbí Àwọn Ọjà Àìsílótìítọ́. Lára àwọn Iṣẹ́ náà lè jẹ́ owó eré àìsílótìítọ́ (bíi wúrà, owó-idẹ tàbí máàkì) tí a lè rà láti ọwọ́ Microsoft nípa lílo ohun èlò owó gangan bí o bá ti dé ọjọ́-orí ¨àgbàlagbਠníbití ìwọ ngbé. Lára àwọn Iṣẹ́ náà tún lè jẹ́ àwọn nkan tàbí ọjà àìsílótìítọ́ oní-nọ́mbà tí a lè rà láti ọwọ́ Microsoft nípa lílo ohun èlò owó gangan tàbí nípa lílo owó eré. A lè má lè fi owó eré àti ọjà àìsílótìítọ́ náà gba ohun èlò owó gangan, ọjà tàbí àwọn nkan mìíràn tó ní owó lórí padà láti ọwọ́ Microsoft tàbí ẹlòmíràn yòówù. Yàtọ sí ìwé-àṣẹ tó ní àhámọ́, ti ara ẹni, tó ṣeé fagilé, tí kò ṣeé fifún ẹlòmíràn, tí kò sì ṣeé fún ẹlòmíràn láṣẹ láti lò, tí a fifún ni láti lè lo owó eré àti àwọn ọjà àìsílótìítọ́ nínú àwọn Iṣẹ́ náà nìkan, ìwọ kò ní ẹ̀tọ́ kankan sí irú owó eré tàbí ọjà àìsílótìítọ́ bẹ́ẹ̀ tó nhàn lórí tàbí tó wá láti inú àwọn Iṣẹ́ náà, tàbí àwọn ohun mìíràn tó lè níí ṣe pẹ̀lú ìmúlò àwọn Iṣẹ́ náà tàbí tí a fipamọ́ sínú àwọn Iṣẹ́ náà. Microsoft lè ṣàkóso, ṣàyípadà àti/tàbí mú owó eré àti/tàbí ọjà àìsílótìítọ́ náà kúrò nígbà yòówù, bí òun bá ṣe rò pé ó tọ́ nínú làákàyè tirẹ̀ nìkan.
  • vii. Awọn Ìmúdójúìwọ̀n Ẹ̀yà àìrídìmú. Fún ẹ̀rọ yòówù tó lè ní àsopọ̀ pẹ̀lú àwọn Iṣẹ́ Xbox, àwa lè ṣàyẹ̀wò oríṣi ẹ̀yà àìrídìmú àtẹ ìṣàkóso Xbox rẹ tàbí ẹ̀yà àìrídìmú ohun èlò Xbox rẹ láìfọwọ́yí, kí a sì gbé àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn àyípadà àtúntò ẹ̀rọ àtẹ ìṣàkóso Xbox tàbí ti ohun èlò Xbox rẹ wálẹ̀, èyítí ó kan àwọn èyí tó má a ndènà rẹ ní wíwọlé sí àwọn Iṣẹ́ Xbox náà, ní lílo àwọn eré Xbox tàbí àwọn ohun èlò Xbox tí kò ní àṣẹ, tàbí ní lílo àwọn ẹ̀rọ àsopọ̀ mọ́ ẹ̀yà àfojúrí tí a kò fún ni láṣẹ láti lò pẹ̀lú àtẹ ìṣàkóso Xbox.
  • viii. Píparí Iṣẹ́ Gamertag. O gbọ́dọ̀ buwọ́lù wọlé sí àwọn Iṣẹ́ Xbox ní, ó kéré, ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọdún marun, bí bẹ́ẹ̀kọ́, o lè pàdánù wíwọlé sí gamertag tó níí ṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ rẹ, gamertag náà sì lè di ohun tó wà fún lílò àwọn ẹlòmíràn.
  • ix. Arena. Arena jẹ́ Ìpèsè Xbox kan nípasẹ̀ èyítí Microsoft tàbí ẹnikẹta le fún ọ ní agbára láti kópa nínú tàbí ṣẹ̀dá ìdíje eré fídíò, nígbà míràn fún ẹ̀bùn kan ("Ìdíje"). Ìlò Arena rẹ wà lábẹ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, wọ́n sì lè mú ọ nílò láti faramọ́ àwọn àfikún àdéhùn Ìdíje, àwọn àgbékalẹ̀ àti àwọn òfin tí olùṣètò Ìdíje náà bèèrè fún ní àkókò ìforúkọsílẹ̀ ("Àwọn Àdéhùn Ìdíje"). Àwọn ofin àmúyẹ ni a le ṣàmúlò, ó sì le yàtọ̀ nípasẹ̀ àdúgbò. Àwọn ìdíje kò ní ipa níbití a kò tí gbà wọ́n láàyè tàbí níbití wọ́n bá ti ní ìhámọ́ lábẹ́ òfin. Ìrúfin àwọn Àwíyé wọ̀nyí (pẹ̀lú Òfin Ìhùwàsí) tàbí Àwọn Àdéhùn Ìdíje le yọrísí jíjófintàbí ìyọkúrò nínú Ìdíje náà. Tí o bá ṣẹ̀dá Ìdíje kan, o le má nílò Àwọn Òfin Ìdíje tí Microsoft (nínú èrò rẹ̀ nìkan) rò pé kò ṣe déédé pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti fagilé èyíkéyìí Ìdíje nígbàkugbà.
  • x. Ẹ̀yà Àìrídìmú Ìrẹ́jẹ àti Ìkọlù. Fún èyíkéyìí ohun èlò tó le sopọ̀ mọ́ Àwọn Ìpèsè Xbox, a le ṣàyẹ̀wò ohun èlò rẹ láìròtẹ́lẹ̀ fún ẹ̀yà àfojúrí tàbí ẹ̀yà àrídìmú tí a kò gbà láàyè, tó sì ń gba ìrẹ́jẹ tàbí àyípadà tí kò tọ́ láàyè, ní ìtàpà sí òfin Àfẹnukò Ìhùwàsí tàbí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, kí a sì gba ẹ̀dà fáìlì̀ àwọn àfikún ẹ̀yà àìrídìmú ìfilọ́lẹ̀ àti ti àyípadà àtòpọ Xbox sílẹ̀, èyí sì kan àwọn tí yóò dènà rẹ láti ráyèsí Àwọn Ìpèsè Xbox pẹ̀lú, tàbí tí kì yóò jẹ́ kí o lè lo ẹ̀yà àfojúrí tàbí ẹ̀yà àrídìmú tí ń gba ìrẹ́jẹ tàbí àyípadà tí kò tọ́ láàyè.
  • xi. Mixer.
   • 1. Àwọn Àwíyé Mixer. Tí o bá n lo Mixer Service, ìlò rẹ wà lábẹ́ Àwọn Àwíyé Mixer tó wà ní https://mixer.com/about/tos ní àfikún sí Àwọn Àwíyé wọ̀nyí. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí ni a ó ṣàmúlò nígbàtí rògbòdìyàn bá wà.
   • 2. Àkóónú Rẹ lórí Mixer. "Àkóónú Rẹ lórí Mixer" túmọ̀ sí pé gbogbo àkóónú tí ìwọ̀, tàbí ẹlòmíràn ní orúkọ rẹ, ṣẹ̀dá lórí Ìpèsè Mixer, pẹ̀lú ṣùgbọ́n kò dópin sí àwọn ìgbàsílẹ̀ tààrà tàbí tí a kásílẹ̀ (àti èyíkéyìí àkóónú, bíi àkóónú àwòrán olóhùn, tí wọ́n ní); àwọn orúkọ ìṣòwò, àmì òwò, àwọn àmì ìpèsè, àwọn orúkọ ọrọ̀ ajé, àmì ìdánimọ̀ ilé-iṣẹ́, tàbí ibi orísun; àwọn ìdáásí rẹ, àwòrán èrò inú, àti iṣẹ́-ṣíṣe nínú àwọn ìkànnì Mixer (pẹ̀lú àkóónú tí a fi bọ́ọ̀tì gbéjáde); àti gbogbo mẹtadata tójọra. Ẹnikẹ́ni, pẹ̀lú Microsoft àti àwọn aṣàmúlò, le rí, lò, gbàlejò, ṣàṣetúnṣe, ṣàtúnṣe, pín, gbéjáde, tí a ṣe ní gbangba àti àfihàn onídíjítà, túmọ̀, ṣàmúlò, àti láti fi Àkóónú Rẹ lórí Mixer ṣiṣẹ́, ní ọ̀nà kọnà, ọ̀nà ìgúnrégé, mídíà, tàbí àwọn ìkànnì tí a mọ̀ báyìí tàbí tí a ṣe tóbáyá.
   • 3. Òfin Ìhùwàsí Tó Wà fún Mixer. Ṣíra tẹ ibí fún àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa bí Òfin Ìhùwàsí Microsoft ti kan Mixer.
   • 4. Lílo Ìpèsè Mixer.
    • a. Ọjọ́-orí Tó Kéré Jù. Nípa lílo Ìpèsè Mixer náà, o ṣojú pé o jẹ́ ọmọ ọdún 13 ó kéré jù àti pé, tí o bá kéré sí ọjọ́-ori ọ̀pọ̀ ènìyàn níbití o ń gbé, ìlò rẹ ni a ń darí nípasẹ̀ òbí tàbí alágbàtọ́ kan tó bá òfin mu.
    • b. Ìlò Àìlórúkọ àti Lílórúkọ. O le lo Mixer ní àìlórúkọ tí o bá fẹ́ wo àkóónú nìkan. Ṣùgbọ́n, ìtàkùrọ̀sọ, ìtẹ̀lé ìkànnì, ìgbàsílẹ̀, àti àwọn ìbánisọ̀rọ̀ míràn tó nílò kí o buwọ́lù láti wọlé sínú àkọọ́lẹ̀ kan, ní ọ̀nàkọnà tí Mixer Service ti ń lo àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ tó wà nílẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀kọ́, o ní láti ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ kan, wọlé, a ó sìí daá mọ̀ sí àwọn aṣàmúlò míràn nípasẹ̀ orúkọ Mixer rẹ.
    • c. Àwọn Àkọọ́lẹ̀ Mixer àti Àwọn Àkọọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn. Mixer ń fún ọ ní agbára láti wọlé nípa lílo àkọọ́lẹ̀ Mixer tàbí àkọọ́lẹ̀ ẹlòmíràn (Twitter tàbí Discord). Tí o bá lo èyíkéyìí àkọọ́lẹ̀ wọ̀nyí láti fi wọlé, o gbọ́dọ̀ da àkọọ́lẹ̀ náa pọ̀ mọ́ àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ.
    • d. Ìlò Àkọọ́lẹ̀. Tí o bá lo àkọọ́lẹ̀ Mixer, o gbọ́dọ̀ lòó láti le jẹ́ kí ó máa ṣiṣẹ́. Wọlé sínú Mixer Service ó kéré jù ẹ̀ẹ̀kan láàrín ọdún márùún láti le jẹ́ kí ìnagijẹ Mixer rẹ wà pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ.
   • 5. Àwọn Ìwífúnni Ìpèsè. Nígbàtí nkan tí a ní láti sọ fún ọ bá wà nípa Ìpèsè Mixer, a ó fi àwọn ìwífúnni Ìpèsè ránṣẹ́ sí í-meèlì tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Mixer rẹ àti/tàbí àkọọ́lẹ̀ Microsoft.
   • 6. Àtìlẹ́yìn. Àtìlẹ́yìn oníbàárà fún Ìpèsè Mixer wà nílẹ̀ ní mixer.com/contact.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Ìsọ̀Ìsọ̀14b_Store
Ní ṣókí
 • b. Ibi ìpamọ́. "Ìsọ̀" túmọ̀ sí Iṣẹ́ kan tí ń gbà ọ́ láàyè láti ṣàwákiri, gbàsílẹ̀, rajà, kí o sì díwọ̀n àti àtúnyẹ̀wò àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀ náa "ìṣàfilọ́lẹ̀" pẹ̀lú ìṣeré) àti àkóónú díjítà míràn. Àwọn Àwíyé wọ̀nyí kan ìlò àwọn Ìsọ̀ kan èyítí Microsoft ni tàbí darí tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ (pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò pin sí, Office Store, Microsoft Store lórí Windows àti Microsoft Store lórí Xbox). “Office Store” túmọ̀ sí ìsọ̀ kan fún àwọn àgbéjáde àti ìṣàfilọ́lẹ̀ fún Office, Office 365, SharePoint, Exchange, Access àti Project (2013 ẹ̀yà tàbí titun), tàbí èyíkéyìí ìrírí míràn tó lórúkọ Office Store. “Microsoft Store on Windows” túmọ̀ sí Ìsọ̀ kan, tí Microsoft ni tó sì ń darí tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀, fún àwọn ohun èlò Windows bíi fóònù, PC àti tabulẹti, tàbí èyíkéyìí ìrírí míràn tó lórúkọ Microsoft Store tó sì wà lórí àwọn ohun èlò Windows bíi fóònù, PC, tàbí tabulẹti. “Microsoft Store on Xbox” túmọ̀ sí Ìsọ̀ kan tí Microsoft ni tó sì ń darí tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ fún Xbox One àti Xbox 360 consoles, tàbí èyíkéyìí ìrírí míràn tó lórúkọ Microsoft Store tó sì wà nílẹ̀ lórí Xbox console.
  • i. Àwọn Àdéhùn Ìwé-àṣẹ. Àwa yóò ṣe ìdánimọ̀ olùgbéjáde ohun èlò kọ̀ọ̀kan tó wà ní Ibi ìpamọ́ tó yẹ. Àyàfi tí a bá pèsè àwọn àwíyé ìwé-àṣẹ míràn pẹ̀lú ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, Àwọn Àwíyé Ìwé-Àṣẹ Ìṣàfilọ́lẹ̀ Gbèdéke ("SALT") ní òpin Àwọn Àwíyé wọ̀nyí jẹ́ àdéhùn láàrín ìwọ àti olùtẹ̀jáde ìṣàfilọ́lẹ̀ tí ń ṣètò àwíyé ìwé-àṣẹ tó kan ìṣàfilọ́lẹ̀ kan tí o gbàsílẹ̀ nípasẹ̀ èyíkéyìí Ìsọ̀ tí Microsoft ní tàbí darí tàbí ti àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ (àyàfi Office Store). Láti mú u yé ni síwájú síi, Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kan ìlò, àti àwọn ìpèsè tí, Àwọn Ìpèsè Microsoft nfifún ni. Apá 5 àwọn Àdéhùn wọ̀nyí náà ní ipa lórí àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn yòówù tí a rà nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ kan. Àwọn ohun èlò tí o gbé wálẹ̀ nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ Office ni a kò darí nípasẹ̀ SALT náà, àwọn sì ní ìwé-àṣẹ ọ̀tọ̀ tó kàn wọ́n.
  • ii. Àwọn Ìmúdójúìwọ̀n. Microsoft yóò ṣàyẹ̀wò láìfọwọ́yí fún àwọn ìmúdójúìwọ̀n, yóò sì gbé wọn wálẹ̀ sórí àwọn ohun èlò rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò buwọ́lù wọlé sí Ibi ìpamọ́ náà. O lè yí àwọn ètò Ibi ìpamọ́ tàbí ẹ̀rọ rẹ padà bí o kò bá fẹ́ má a gba àwọn ìmúdójúìwọ̀n láìfọwọ́yí sórí àwọn ohun èlò Ibi ìpamọ́. Ṣùgbọn, àwọn ohun èlò Ibi ìpamọ́ Office kan tó wà lórí ayélujára pátápátá tàbí fún ìgbà díẹ̀ ni a lè mú dójú ìwọ̀n nígbà yòówù nípasẹ̀ olùgbéjáde ohun èlò náà, wọ́n sì lè má nílò àṣẹ rẹ láti mú wọn dójú ìwọ̀n.
  • iii. Ṣíṣe ìdíwọ̀n dídára àti Ṣíṣàtúnyẹ̀wò. Tí o bá díwọ̀n tàbí ṣàtúnyẹ̀wò ìfilọ́lẹ̀ kan tàbí Ọjà Onídíjítà míràn nínú Ibi ìpamọ́ náà, o le gba í-meèlì láti Microsoft tó ní àkóónú láti olùgbéjáde ìfilọ́lẹ̀ náà tàbí Ọjà Onídíjítà. Èyíkéyìí irú í-meèlì náà ń wá láti ọ̀dọ̀ Microsoft; a kò ṣàpínlò àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ pẹ̀lú àwọn olùgbéjáde àwọn ìfilọ́lẹ̀ náà tàbí Àwọn Ọjà Onídíjítà tí o gbà nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́.
  • iv. ìkìlọ̀ Ààbò. Láti yàgò fún ìpalára, ìnira tàbí dídá ojú ẹni lágaara, ọ gbọ́dọ̀ ní ìsinmi láti ìgbà dé ìgbà kúrò lẹ́nu lílò àwọn eré tàbí ohun èlò mìíràn, pàápàá bí o bá nní ìrora tàbí bí ó bá nrẹ̀ ọ́, àwọn èyítí ó nwáyé nípasẹ̀ ìmúlò. Bí o bá ní ìrírí ìnira yòówù, ṣíwọ́ nínú eré. Ìnira lè jẹ́, kí èébì má a gbé ni, àìlera ìrìn-àjò, òòyì, àìmọ ibi tí ènìyàn wà, orí-fifọ́, àárẹ̀, dídá ojú ẹni lágaara, tàbí ẹyin ojú aláìlómijé. Lílò àwọn ohun èlò lè fa ìdíwọ́ ní fífọkànsí nkan, ó sì tún lè dínà mọ́ ọ ní àyíká rẹ. Yàgò fún àwọn ohun tó lè gbé ni ṣubú, àbágùnkè, àjà ilé tí kò ga sókè púpọ̀, àwọn ohun ẹlẹgẹ́ tàbí tó níyelórí, tó lè bàjẹ́. Àwọn ènìyàn méèló kan lè ní ìrírí gìrì nígbàtí wọn bá wà lábẹ́ agbára àwọn àwòrán àfojúrí bíi àwọn iná tó nṣá tàbí tó nṣẹ́jú tó lè má a hàn nínú àwọn ohun èlò náà. Àwọn ènìyàn tí kò ní ìtàn nípa gìrì pàápàá lè ní àìsàn tí a kò tíì yẹ̀wò, èyí tó lè fa àwọn gìrì wọ̀nyí. Àwọn ààmì àìsàn lè jẹ́ òòyì, àìríran dáradára, gbigbọ̀n ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀, àìmọ ibití ènìyàn wà, àìmọ ohun tí ènìyàn nṣe, dídákú, tàbi àìpérí. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ dẹ́kun lílò, kí o sì kàn sí dọ́kítà bí o bá nní èyíkéèyí nínú àwọn àmì àìsàn wọ̀nyí, tàbí kí o kàn sí dọ́kítà kí o tó lo ohun èlò náà bí o bá ti ní irú àmì àìsàn tó níí ṣe pẹ̀lú gìrì rí. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣàkóso bí àwọn ọmọ wọn ti nlo àwọn ohun èlò, kí wọ́n sì ṣàkíyèsi àwọn àmì àìsàn wọ̀nyí.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Àfidámọ̀ Microsoft FamilyÀwọn Àfidámọ̀ Microsoft Family14c_MicrosoftFamily
Ní ṣókí
 • c. Àwọn Àfidámọ̀ Microsoft Family. Àwọn òbí àti àwọn ọmọ wọn lè lo àwọn àfidámọ̀ Microsoft Family láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé wá nípasẹ̀ òye irú ìwà, ààyè ayélujára, ohun èlò, eré, ipò, àti owó níná tó yẹ fún ìdílé wọn. Àwọn òbí lè ṣẹ̀dá ìdílé nípa lílọ sí https://account.microsoft.com/family (tàbí nípa títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà lórí ẹ̀rọ Windows tàbí àtẹ ìṣàkóso Xbox wọn), wọ́n sì lè pe àwọn ọmọ àti òbí mìíràn láti darapọ̀ pẹ̀lú. Oríṣìí àwọn àmúyẹ ló wà fún àwọn mọ̀lẹ́bí, fún ìdí èyí rọra ṣàtúnyẹ̀wò àlàyé náà tí a pèsè nígbàtí o bá gbà láti ṣẹ̀dá tàbí darapọ̀ mọ́ ẹbí kan àti nígbà tí o bá ra Àwọn Ohun Àmúlò Díjítà fún ìráyèsí ẹbí. Nípa ṣíṣẹ̀dá tàbí dídarapọ̀ mọ́ ẹbí kan, o gbà láti lo ẹbí náà gẹ́gẹ́ bí èrèdí rẹ̀ o kò sì ní lòó ní ọ̀nà tí a kò fún láṣẹ́ láti ráyèsí àlàyé ẹlòmíràn ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Kíkọ̀rọ̀ránṣẹ́ Ẹlẹ́gbẹẹgbẹ́Kíkọ̀rọ̀ránṣẹ́ Ẹlẹ́gbẹẹgbẹ́14d_GroupMessaging
Ní ṣókí
 • d. Kíkọ̀rọ̀ránṣẹ́ Ẹlẹ́gbẹẹgbẹ́. Àwọn oríṣiríṣi iṣẹ́ Microsoft ngba ọ́ láàyè láti kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ (¨àwọn ìfiránṣẹ́¨) olóhùn tàbí SMS, wọn a sì má a gba Microsoft àti àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ tí Microsoft jẹ́ aláàkóso wọn láàyè láti fi irú ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ àti sí aṣàmúlò kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lórúkọ rẹ. NÍGBÀTÍ O BÁ FÚN MICROSOFT ÀTI ÀWỌN ALÁÀBÁṢIṢẸ́PỌ̀ TÍ MICROSOFT JẸ́ ALÁÀKÓSO WỌN NÍ ÀṢẸ LÁTI FI IRÚ ÌFIRÁNṢẸ́ BẸ́Ẹ̀ RÁNṢẸ́ SÍ Ọ TÀBÍ SÍ ÀWỌN ẸLÒMÍRÀN, ÌWỌ DÚRÓ BÍ AṢOJÚ, O SÌ FÚN WA NÍ ÌDÁNILÓJÚ PÉ ÌWỌ ÀTI Ọ̀KỌ̀Ọ̀KAN ÀWỌN ẸNITÍ O FÚN WA NÍ ÀṢẸ LÁTI RÁNṢẸ́ SÍ GBÀ LÁTI GBA IRÚ ÀWỌN ÌFIRÁNṢẸ́ BẸ́Ẹ̀ TÀBÍ ÀWỌN ÀKỌRÁNṢẸ́ ÌṢÀKÓSO MÌÍRÀN TÓ JỌ MỌ́ ÈYÍ LÁTI ỌWỌ́ MICROSOFT ÀTI ÀWỌN ALÁÀBÁṢIṢẸ́PỌ̀ TI MICROSOFT JẸ́ ALÁÀKÓSO WỌN. ¨Àwọn àkọránṣẹ́ ìṣàkóso¨ jẹ́ àwọn ìfiránṣẹ́ nípa idunadura àti ìgbà dé ìgbà láti inú iṣẹ́ Microsoft kan pàtó, èyítí ó kàn, ṣùgbọ́n tí kò parí sí ¨ìfiránṣẹ́ ìkínikáàbọ̀¨ tàbí àwọn ìtọ́sọ́nà nípa fífòpin sí gbígba ìfiránṣẹ́. Ìwọ tàbí ọmọ ẹgbẹ́ rẹ tí kò bá fẹ́ láti má a gba irú ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ lè yàn láti dẹ́kun gbígba ìfiránṣẹ́ náà síwájú síi, láti ọwọ́ Microsoft tàbí láti ọwọ́ àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ tí Microsoft jẹ́ aláàkóso wọn, nígbà yòówù, nípasẹ̀ títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí a ti pèsè. Bí o kò bá fẹ́ gba irú àwọn ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ tàbí o kò fẹ́ kópa nínú ẹgbẹ́ náà mọ́, o faramọ́ ọ pé ìwọ yóò dẹ́kun kíkópa rẹ nípasẹ̀ àwọn ìtọ́sọ́nà tí ètò tàbí iṣẹ́ tí à nsọ náà ti pèsè. Bí o bá ní ìdí láti gbàgbọ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ kan kò fẹ́ láti má a gba irú ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́, tàbí òun kò fẹ́ kópa nínú ẹgbẹ́ náà mọ́, o gbà láti yọ wọ́n kúrò nínú ẹgbẹ́ náà. Ìwọ tún dúró bí aṣojú, o sì tún fún wa ní ìdánilójú pé ìwọ àti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹnití o fún wa ní àṣẹ láti ránṣẹ́ sí ní òye pé ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ó ni ojúṣe fún sísan iye owó ìfiránṣẹ́ yòówù tí olùpèsè iṣẹ́ ẹ̀rọ aláàgbéká rẹ̀ bá bèèrè fún, èyítí ó kan iye owó ìfiránṣẹ́ sí ilú òkèèrè tí ó lè wáyé nígbàtí a bá gbé ìfiránṣẹ́ láti àwọn nọ́mbà tó jẹ́ ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Skype àti GroupMeSkype àti GroupMe14e_Skype
Ní ṣókí
 • e. Skype àti GroupMe.
  • i. Kò sí Ànfàní àti Wọlé sí Àwọn Iṣẹ́ Pàjáwìrì. Àwọn ìyàtọ̀ pàtàkì wà láàárín àwọn iṣẹ́ tẹlifóònù tó ti wà tẹ́lẹ̀ àti Skype. A kò nílò Microsoft láti fún ọ ní ìráyèsí Àwọn Iṣẹ́ Pàjáwìrì lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè tàbí ti abẹ́lé kankan, ìlànà tàbí òfin. A kò ṣe ẹ̀yà àìrídìmú àti àgbéjáde Skype láti ṣàtìlẹ́yìn tàbí pe àwọn ìpè pàjáwìrì sí èyíkéyìí ilé-ìwòsàn, aṣojú agbófinró, ibi ìtọ́jú ìlera tàbí èyíkéyìí iṣẹ́ tó so aṣàmúlò kan pọ̀ mọ́ òṣìṣẹ́ iṣẹ́ pàjáwìrì tàbí àwọn ibi ìdáhùn ààbò gbogbogbò ("Àwọn Iṣẹ́ Pàjáwìrì"). Usted reconoce y acepta que: (i) ó jẹ́ ojúṣe rẹ láti ra àwọn iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ orí tábìlì tàbí (alágbèéká) aláìlowáyà tí ń fúnni ní ìráyèsí Àwọn Iṣẹ́ Pàjáwìrì, àti Ẹ̀yà àìrídìmú àti (ii) àgbéjáde Skype kìíṣe ìrọ́pò fún iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ rẹ.
  • ii. APIs or Títànkáàkiri. Tí o bá fẹ́ lo àwọn àgbéjáde àti ẹ̀yà àìrídimú Skype pẹ̀lú èyíkéyìí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, o gbọ́dọ̀ faramọ́ "Broadcast TOS" ní https://www.skype.com/go/legal.broadcast. Tí o bá fẹ́ lo èyíkéyìí ọ̀nà ìsopọ̀ ètò ìṣàfilọ́lẹ̀ ("API") tí a ṣàfihàn tàbí jẹ́kó wà nílẹ̀ nípasẹ̀ Skype o gbọ́dọ̀ faramọ́ àwọn àwíyé ìwé-àṣẹ, tó wà nílẹ̀ ní www.skype.com/go/legal.
  • iii. Àwọn Ìlànà Ìmúlò lọ́nà tó Jọjú. Àwọn òfin ìlò tó dára ni a le lò sí ìlò àgbéjáde àti ẹ̀yà àìrídìmú Skype rẹ. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹwò àwọn ìlànà wọ̀nyí tí a ṣe láti dáàbòbo ni lọ́wọ́ jìbìtì àti àṣìlò, tí ó sì lè fi àhámọ́ sí oríṣi, iye àkókò tàbí ìwọ̀n dídún ìpè tàbí àkọránṣẹ tí o lè ṣe. A fi àwọn ìlànà yìí sára àwọn Àdéhùn yìí nípasẹ ìtọ́kasi. O le rí àwọn òfin wọ̀nyí ní https://www.skype.com/go/terms.fairusage/.
  • iv. Lílo Àwòrán Ayé. Àgbéjáde àti ẹ̀yà àìrídìmú Skype ní àwọn ẹ̀yà tí ń gbà ọ́ láàyè láti fa àlàyé kalẹ̀ sí, tàbí fi ara rẹ sórí àwòrán àgbáye nípa lílo, iṣẹ́ wíwà lórí àwòrán àgbáyé. Nípa lílo àwọn àfidámọ̀ wọ̀nyí, o faramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àti àwọn àdéhùn Google Maps tó wà ní https://www.google.com/intl/en_ALL/help/terms_maps.html tàbí irú àwọn àdéhùn Google Maps bẹ́ẹ̀ tó wà ní orílẹ̀-èdè rẹ.
  • v. Àwọn Aṣàmúlò ti Ìjọba. Tí o bá fẹ́ láti lo àkọọ́lẹ̀ ìṣòwo kan tàbí Olùṣàkóso Skype lórúkọ Ìjọba U.S. Tàbí aṣojú Ìjọba U.S., àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kò nípa lórí rẹ̀. Fún àwọn àdéhùn tó yẹ tàbí àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí usgovusers@skype.net.
  • vi. Ìmúlò Ara ẹni/Tí Kìí Ṣe fún Òwò. Ìlò àgbéjáde àti ẹ̀yà àìrídìmú Skype wà fún àdálò rẹ kìíṣe fún ìṣòwò. A gbà ọ́ láàyè láti lo Skype ní ibi-isẹ́ fún àwọn ìbánisọ̀rọ̀ ìṣòwò tìrẹ.
  • vii. Skype Number/Skype To Go. Tí Microsoft bá pèsè Nọ́mbà Skype tàbí nọ́mbà Skype To Go fún ọ, o gbà wípé ìwọ kọ́ ni o ni nọ́mbà náà tàbí ní ẹ̀tọ́ láti ni nọ́mbà náà títí láí. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, nọ́mbà le wà nílẹ̀ fún ọ nípasẹ̀ alájọṣiṣẹ́ Microsoft yàtọ̀ sí Microsoft, o sì le ní láti ní àdéhùn tó yàtọ̀ pẹ̀lú irú alájọṣiṣẹ́ náà.
  • viii. Olùṣàkóso Skype. Ìwọ ni ẹnití yóò ṣẹdá, tí yóò sì ṣe àbójútó "Àkọọ́lẹ̀ Aláàbójútó Olùṣàkóso Skype", nínú èyítí ìwọ yóò jẹ olùṣàkóso tó dádúró fún ẹgbẹ́ Aláàbójútó Skype, ṣùgbọn kìí ṣe bí okòwò tó dádúró. O le so àkọọ́lẹ̀ Microsoft ẹnìkọ̀kan rẹ pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Skype ("Àkọọ́lẹ̀ tí A Sopọ̀"). O lè yan àwọn aláàbójútó mìíràn sí ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Skype rẹ bí wọ́n bá faramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Bí o bá fún Àkọọ́lẹ̀ Aláàsopọ̀ kan ní àwọn Nọmba Skype, ìwọ ni ó ni ojúṣe fún títẹ̀lé àwọn òfin tí ó yẹ tó níí ṣe pẹ̀lú ibití àwọn aṣàmúlò Àkọọ́lẹ̀ Aláàsopọ̀ rẹ bá ngbe tàbí tí wọ́n wà. Tí o bá yàn láti yọ Àkọọ́lẹ̀ Tí A Sopọ̀ kúrò láti ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Skype, èyíkéyìí àwọn ìṣalábàápín tí a yàn, Kírẹ́dìtì Skype tàbí Nọ́mbà Skype ni a kò ni le gbà padà àti pé Àkóónú Rẹ tàbí ohun ìní tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ tí a yọkúrò ni o kò ni le ráyèsí mọ́. O gbà pé kí a lo àlàyé ara ẹni yòówù tó jẹ́ ti àwọn aṣàmúlò Àkọọ́lẹ̀ Aláàsopọ̀ rẹ ní ọ̀nà tó bá àwọn òfin ààbò détà tó yẹ mu.
  • ix. Owó sísan lórí Skype. Àwọn owó-ìlú tó yẹ wà lára gbogbo iye owó tí a nsan fún àwọn ọjà Skype tí à nsanwó fún, àfi bí a bá kọ ohun mìíràn nípa èyí. Àwọn iye owó tó yẹ kí a san fún pípè, yàtọ̀ sí àsantẹ́lẹ̀, ni owó àsopọ̀ (tí a ngbà lẹ́ẹ̀kan lórí ìpè kọ̀ọ̀kan) àti iye owó ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan bí a ti ṣe àlàyé nínú www.skype.com/go/allrates. Àwọn owó ìpè ni a ó yọkúrò nínú ìyókù owó Kírẹ́dìtì Skype rẹ. Microsoft le yí iye ìpè rẹ padà nígbàkugbà nípa fífi irú àyípadà náà ṣọwọ́ sí www.skype.com/go/allrates. Iye owó titun náà yóò ní ipa lórí ipè rẹ tó wáyé lẹ́yìn àgbéjáde iye owó titun náà. Jọ̀wọ́ wo àwọn iye owó ìpè titun jùlọ kí o tó ṣe ìpè rẹ. Àwọn àkókò ìpè tí kò tó odindi ìṣẹjú kan àti iye owó ìpè tí kò tó odindi kan ni a ó kà bí odindi kan. Ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, àwọn àgbéjáde àlòsanwó ti Skype ni alájọṣiṣẹ́ abẹ́lé Microsoft ń pèsè àti wípé àwíyé ìlò irú alájọṣiṣẹ́ náà ni a ó lò fún irú ìdúnàádúrà náà.
  • x. Kírẹ́díitì Skype. Microsoft kò fọwọ́sọ̀yà wípé wàá le lo iyókù Skype Credit láti ra gbogbo àgbéjáde Skype. Tí o kò bá lo Skype Credit rẹ fún ọjọ́ 180, Microsoft yóò fi Skype Credit rẹ sípò àìṣiṣẹ́. O lè tún mú Kírẹ́díìtì Skype rẹ ṣíṣẹ́ nípa títẹ̀lé àtọ́ka àsopọ̀ fún mímú ṣiṣẹ́ padà ní https://www.skype.com/go/store.reactivate.credit. Tí o bá wà ní Japan o sì ra Kírẹ́dìtì Skype láti ojúlé wẹ́ẹ̀bù Skype, àwọn gbólóhùn méjì tókàn wọ̀nyí kò kàn ọ́ àti pé Kírẹ́dìtì Skype rẹ yóò dópin láàrín ọjọ́ 180 lẹ́yìn ọjọ́ ìrajà. Kété tí kírẹ́dìtì rẹ bá dópin, a kò ní le sọ ọ́ dọ̀tun tàbí lòó mọ́. O lè mú àfidámọ̀ Àtúngbà Àìfọwọ́yí ṣiṣẹ́ nígbàtí o bá ra Kírẹ́díìtì Skype nípa fífi àmì sí àpótí tó yẹ. Tí a bá múu ṣiṣẹ́, ìyókù Kírẹ́dìtì Skype rẹ ni a ó ṣe àtúnrọkún rẹ pẹ̀lú iye owó kan náà, àti nípasẹ ìlànà ìsanwó tí o yàn, nígbà gbogbo tí ìyókù owó inú Skype rẹ bá lọ sílẹ̀ ju iye kan pàtó tí Skype nṣètò láti ìgbà dé ìgbà lọ. Bí o bá ra ètò àsantẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìlànà owó-sísan tó yàtọ̀ sí káàdì ìyáwó, PayPal tàbí Moneybookers (Skrill), tí o sì ti mú Àtúngbà Àìfọwọ́yí ṣiṣẹ́, a ó fi iye owó tó yẹ láti ra àsantẹ́lẹ̀ rẹ tí nbọ̀ kún iye owó tó kù nínú Kírẹ́díìtì Skype rẹ. O lè sọ Ìṣàrọkún-Aládàáṣe di aláìṣiṣẹ́ nígbàyòówù nípa ríráyèsí àti ṣíṣe àyípadà àwọn ètò rẹ ní àyè àkọọ́lẹ̀ rẹ lórí Skype.
  • xi. Iye Owó Ìfiránṣẹ́ sí Ìlú Òkèèrè. GroupMe a má lo àwọn nọ́mbà tó wà ní Amẹ́ríkà ní báyìí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹgbẹ́ tí a bá ṣẹ̀dá. Gbogbo àkọránṣẹ́ tí a firánṣẹ́ sí, tàbí tí a bá gbà láti nọ́mbà GroupMe kan ni a ó kà sí àkọránṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè tí a firánṣẹ́ sí, tàbí tí a gbà láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Jọ̀wọ́ bèèrè lọ́wọ́ olùpèsè rẹ nípa iye owó sísan tó yẹ fún ilẹ̀ òkèèrè.
  • xii. Firánṣẹ́ kí o sì gba owó. Nípa lílo ẹ̀yà fíránṣẹ́ kí o sì gba owó (tó bá wà nílẹ̀), o gbà wípé Microsoft ń lo àwọn ẹlòmíràn láti pèsè àwọn iṣẹ́ ìsanwó kó sì ṣe ìfiránṣẹ́. Microsoft kò pèsè àwọn iṣẹ́ ìsanwó tàbí fi nkan ránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ni kìíṣe ìṣòwò iṣẹ́ owó. Fífiránṣẹ́ àti gbígba owó lórí Skype le wà nílẹ̀ nìkan fún àwọn aṣàmúlò tí jẹ́ ọmọ-ọdún 18 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ (tàbí bí bẹ́ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bíi àwọn àwíyé ẹnikẹta) àti ẹni tó forúkọ sílẹ̀ tí a sì fọwọ́sí fún àkọọ́lẹ̀ kan pẹ̀lú olùpèsè ẹnikẹta. Láti lo ẹ̀yà firánṣẹ́ kí o sì gba owó, o le ní láti forúkọ sílẹ̀ sí àwọn àdéhùn àti ipo ẹnikẹta àti láti pèsè ìyọ̀nda láti ṣàpínlò dátà pẹ̀lú ẹnikẹta wọ̀nyí fún àwọn èrèdí pípèsè àkọọ́lẹ̀ náà. Tí Microsoft bá gba àkíyèsí wípé ìlò rẹ ti ẹ̀yà ìfowóránṣẹ́ tako àwíyé àti ipò ẹlòmíràn, Microsoft le ní láti gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí àkọọ́lẹ̀ rẹ, bíi fífagilé tàbí ídádúró àkọọ́lẹ̀ rẹ. Microsoft kò ní dáhùn fún àwọn iṣẹ́ ìsanwó èyítí ẹlòmíràn ń pèsè tàbí èyíkéyìí ìgbésẹ̀ tí a gbé lábẹ́ àwíyé àti ipò ẹlòmíràn. Microsoft kò fọwọ́sọ̀yà, ìṣojú tàbí ìdánilójú pé ẹ̀yà firánṣẹ́ tàbí gba owó yóò wà nílẹ̀ tàbí yóò máa wà nílẹ̀.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Bing àti MSNBing àti MSN14f_BingandMSN
Ní ṣókí
 • f. Bing àti MSN.
  • i. Àwọn Ohun Àmúlò Bing àti MSN. Àwọn átíkù, ọ̀rọ̀, fọ́tò, àwòrán ayé, fídíò, àwọn olùmúṣiṣẹ́ fídíò àti ohun ìní ẹnikẹta tó wà nílẹ̀ lórí Bing àti MSN, pẹ̀lú nípasẹ̀ àwọn bọ́ọ̀tì Microsoft, ìfilọ́lẹ̀ àti ètò, wà fún ìlò àdáni, àìfiṣòwò rẹ nìkan. Àwọn ìlò míràn, pẹ̀lú gbígba ẹ̀dà fáìlì sílẹ̀, ṣíṣẹ̀dà tàbí títún àwọn ohun ìní wọ̀nyí pín kiri, tàbí lílo àwọn ohun ìní wọ̀nyí tàbí àgbéjáde láti kọ àwọn àgbéjáde tìrẹ, ni a gbà láàyè nìkan dé ibi tí Microsoft yọ̀nda tàbí àwọn olóhun ẹ̀tọ́, tàbí èyítí òfin ìmúlò gbà láàyè. Microsoft tàbí àwọn mìíràn tó ní ẹ̀tọ́ ni ó ni gbogbo ẹ̀tọ́ sí àwọn ohun àmúlò náà, èyítí Microsoft kò fifún ni tààrà lábẹ́ àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ náà, yálà nípasẹ̀ èrò tí a mú jáde nínú ohun tí a kò fẹnusọ, nípasẹ̀ àìlè yí èrò tí a fẹ́ kí ohun tí a kò fẹnusọ mú jáde padà, tàbí lọ́nà mìíràn.
  • ii. Àwọn Àwòrán Ayé Bing. Ìwọ kò gbọdọ̀ lo ohun tí a npè ní Àwòrán ojú ẹyẹ tí United States, Canada, Mexico, New Zealand, Australia tàbí Japan fún ìmúlò ìjọba láì gba àṣẹ ọ̀tọ̀ tí a kọ sílẹ láti ọwọ́ wa.
  • iii. Bing Places àti Bing Manufacturer Center. Nígbàtí o bá pèsè Détà tàbí Àkóónú Rẹ fún Bing Places tàbí Bing Manufacturer Center, o fún Microsoft ní ìwé-àṣẹ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ káàkiri àgbáyé, láì sí sísan owó oníhun, láti lò, ṣàtúndá, fipamọ́, ṣàyípadà, ṣàkójọpọ̀, gbé lárugẹ, gbé kiri, ṣàfihàn tàbí ṣàjọpín, gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ kan, àti láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìwé-àṣẹ sí àwọn ẹ̀tọ́ náà.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
CortanaCortana14g_Cortana
Ní ṣókí
 • g. Cortana.
  • i. Ìmúlò Ara ẹni Tí Kìí Ṣe fún Òwò. Cortana jẹ́ Iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ ara ẹni ti Microsoft. Àwọn ẹ̀yà, iṣẹ́ àti àkóónú tí Cortana ń pèsè (lápapọ̀ "Àwọn Iṣẹ́ Cortana") wà fún àdálò rẹ nìkan kìíṣe fún ìṣòwò.
  • ii. Ìṣiṣẹ́ àti Àkóónú. Cortana ń pèsè àwọn oríṣiríṣi àfidámọ̀, lára èyítí ó jẹ́ aládàáni. Àwọn Iṣẹ́ Cortana le gbà ọ́ láàyè láti ráyèsí àwọn iṣẹ́, àlàyé tàbí ìṣiṣẹ́ èyítí Àwọn Iṣẹ́ Microsoft ń pèsè tàbí Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn àti Àwọn Iṣẹ́. Àwọn àdéhùn tó níṣe pẹ̀lú ìpèsè pàtó ní abala 13 tún kan ìlò rẹ fún àwọn Ìpèsè Microsoft tó yẹ, àwọn èyítí a nráyèsí nípasẹ̀ àwọn Ìpèsè Cortana. Cortana a má a pèsè àlàyé fún èrèdí ìṣètò rẹ nìkan, ìwọ sì gbọ́dọ̀ lo òye òmìnira tìrẹ nígbàtí o bá nṣàgbéyẹ̀wò àlàyé wọ̀nyí, tí o sì ngbáralé wọn. Microsoft kò ṣe ìmúdánilójú kankan nípa ṣíṣeé gbáralé, wíwà tàbí ṣíṣiṣẹ́ lásìkò àwọn ìrírí ara ẹni tí Cortana ń pèsè. Microsoft kì yóò dáhùn tí ẹ̀yà Cortana bá pẹ́ tàbí dènà rẹ láti gbà, ṣàtúnyẹ̀wò tàbí fi ìbánisọ̀rọ̀ kan tàbí ìfitónilétí ránṣẹ́, tàbí gbígba iṣẹ́ kan.
  • iii. Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta. Bí ara fífi Àwọn Iṣẹ́ Cortana jíṣẹ́, Cortana le dábàá kó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bá Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn ṣepọ̀ (ọgbọ́n ẹlòmíràn tàbí àwọn iṣẹ́ tó sopọ̀). Tí o bá yàn, Cortana le pàrọ̀ àlàyé pẹ̀lú Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn, bíi kóòdù ìfìwéránṣẹ́ rẹ àti ìbéèrè àti ìdáhùn tí Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn dápadà, láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gba àwọn iṣẹ́ tí o bèrè fún. Cortana le mú ọ ṣiṣẹ́ láti rajà nípasẹ̀ Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn nípa lílo àwọn ètò àti irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ tí o ti fìdímúlẹ̀ tààrà pẹ̀lú Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn náà. O le ṣèpínyà Iṣẹ́ Cortana rẹ láti Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn nígbàkugbà. Ìlò Àwọn Iṣẹ́ Cortana rẹ láti sopọ̀ mọ́ Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn wà lábẹ́ abala 5 ti àwọn Àwíyé wọ̀nyí. Àwọn olùgbéjáde Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta le ṣe àyípadà tàbí fòpin sí iṣẹ́-ṣíṣe tàbí àfidámọ̀ àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta tàbí ìbáṣiṣẹ́pọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn Ìpèsè Cortana. Microsoft kò ní dáhùn tàbí jẹ gbèsè fún àwọn ẹ̀yà àìrídìmú tàbí fámúwià àwọn olùgbéjáde.
  • iv. Àwọn Ohun Èlò Ìmúṣiṣẹ́ Cortana. Àwọn ohun èlò ìmúṣiṣẹ́ Cortana jẹ́ àwọn àgbéjáde tàbí ohun èlò tí a fún lágbára láti ráyèsí àwọn Ìpèsè Cortana, tàbí àwọn àgbéjáde tàbí ohun èlò tó lè bá àwọn Ìpèsè Cortana ṣiṣẹ́. Àwọn ohun èlò ìmúṣiṣẹ́ Cortana pẹ̀lú àwọn ohun èlò ẹnikẹta tàbí àwọn àgbéjáde èyítí Microsoft kò ni, ṣe, tàbí múdàgbà. Microsoft kò ní dáhùn tàbí jẹ gbèsè fún àwọn ohun èlò tàbí àwọn àgbéjáde ẹnikẹta wọ̀nyí.
  • v. Àwọn Àfikún Ẹ̀yà Àìrídìmú. A le ṣàyẹ̀wò ẹ̀yà àìrídìmú ti Iṣẹ́ Cortana rẹ ní aládàáṣe kí o sì gba àfikún ẹ̀yà àìrídimú sílẹ̀ tàbí ṣàtòpọ̀ àyípadà tàbí bèrè èyíkéyìí olùṣẹ̀dá ohun èlò ti Cortana múṣiṣẹ́ láti jẹ́ kí ẹ̀yà àirídìmú Iṣẹ́ Cortana rẹ kójú òṣùwọ̀n.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Outlook.comOutlook.com14h_Outlook_com
Ní ṣókí
 • h. Outlook.com. Àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì Outlook.com (tàbí @msn, @hotmail, tàbí @live) tí o lò láti ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ yóò jẹ́ tìrẹ nìkan níwọ̀n ìgbà tí àpótí àgbàwọlé Outlook.com tàbí àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ bá ṣì nṣiṣẹ́. Bí ó bá wáyé pé ìwọ tàbí Microsoft mú àpótí àgbàwọlé Outlook.com tàbí àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin ní ìbámu pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, a lè mú àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì náà padà sínú ẹ̀rọ wa, a sì lè fifún aṣàmúlò mìíràn.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Ìpèsè OfficeÀwọn Ìpèsè Office14i_officeBasedServices
Ní ṣókí
 • i. Àwọn Ìpèsè Office. Office 365 Home, Office 365 Personal, Office 365 University, Office Online, Sway, OneNote.com àti ìṣalábàápín Office 365 mìíràn yòówù tàbí àwọn Ìpèsè tí a sààmì Office sí wà fún ìlò àdání rẹ, ìlò tí kìíṣe fún ìṣòwò, àyàfi tí o bá ní ẹ̀tọ́ ìlò ìṣòwò lábẹ́ àdéhùn tó yàtọ̀ pẹ̀lú Microsoft.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Ìṣẹ́ Ìlera MicrosoftÀwọn Ìṣẹ́ Ìlera Microsoft14j_MicrosoftHealthServices
Ní ṣókí
 • j. Àwọn Ìṣẹ́ Ìlera Microsoft.
  • i. HealthVault. Èròngbà HealthVault ni láti pé kí o lè fi àwọn àlàyé ara ẹni rẹ tó níí ṣe pẹ̀lú ìlera àti àlàyé nípa àwọn ẹlòmíràn (bíi ẹbí rẹ) pamọ́, pẹ̀lú ìyọ̀nda wọn. Àkọọ́lẹ̀ HealthVault kò sí fún ìmúlò àwọn olùpèsè ìtọ́jú ìlera tàbí fún èrèdí ìṣòwò, tí kìí ṣe ti ara ẹni. Àlàyé tó wà nínú àkọọ́lẹ̀ rẹ lè má jẹ́ pípé tàbí èyí tó bá ìgbà mú nígbà gbogbo, olùpèsè ìtọ́jú ìlera yòówù sì gbọ́dọ̀ ríi bí àlàyé lásán. Iṣẹ́ HealthVault kò ní àkọsílẹ̀ fún àwọn olùpèsè ìtọ́jú ìlera tàbí fún èrèdí ìtọ́jú ìlera tàbí ìṣàkóso aláìsàn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn àkọsílẹ̀ HealthVault kìí ṣe ètò àkọsílẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ bí a ti ṣàlàyé nínú òfin U.S. Bí olùpèsè ìtọ́jú ilera kan bá yàn láti fi détà yòówù tí ó wà láti inú HealthVault kún àkọsílẹ̀ tirẹ̀, òun gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dà kan pamọ́ sórí ẹ̀rọ ti ara rẹ̀. Bí ẹnìkan bá wà tó ní àkọsílẹ̀ inú àkọọ́lẹ̀ rẹ lọ́wọ́ (nítorí tí ọ̀kan lára yín pe ẹnìkejì wá), o faramọ́ ọ pé ẹni náà ní ìṣàkóso lẹkunrẹrẹ lórí àkọsílẹ̀ náà, òun sì lè fagilé wíwọlé rẹ sínú àkọsílẹ̀ náà, ó lè ṣàkóso wíwọlé àwọn ẹlòmíràn sínú àkọsílẹ̀ náà, ó sì tún lè wo détà àkọsílẹ̀ náà, èyí tí ó kan bí wọ́n ti lo àkọsílẹ̀ náà àti ìgbà tí wọ́n lòó. Microsoft kò ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn àlàyé ara ẹni tí kìí ṣe ti Microsoft (gẹ́gẹ́ bíi Facebook àti OpenID), nítorí náà àtìlẹ́yìn oníbàárà HealthVault kì yóò lè ran ni lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ìṣòro bíbuwọ́lù wọlé fún àwọn wọ̀nyí. Bí o bá sọ àwọn àlàyé ìbuwọ́lù wọlé rẹ nù, tàbí bí a bá mú àkọọ́lẹ̀ náà, níbití ìwọ ti gba àwọn àlàyé náà dópin, ìwọ kì yóò lè mú àwọn détà rẹ tí o fipamọ́ padà mọ́. Láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má a lè wọlé nígbà gbogbo, a dámọ̀ràn pé kí o má a lo àlàyé ìbuwọ́lù wọlé tó ju ọ̀kan lọ pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ HealthVault rẹ. Microsoft kò fọ́wọ́ sí tàbí ṣàkóso, òun kò sì ní ojúṣe fún, iṣẹ́-ṣíṣe, àtìlẹ́yìn, tàbí ààbò àwọn àlàyé ara ẹni tí kìí ṣe ti Microsoft, tí ìwọ lè má a lò.
  • ii. Microsoft Band. Ìfilọ́lẹ̀ àti ohun èlò Microsoft Band kìíṣe àwọn ohun èlò ìlera a sì ṣeé fún èrèdí ìdápé àti ara líle nìkan. A kò ṣe wọ̀n tàbí rò láti lò wọ́n fún ìlò nínú àyẹ̀wò àrùn tàbí àwọn ipò míràn, tàbí nínú ìwòsàn, ìgbóguntì, títọ́jú, tàbí ìdènà àrùn àti àwọn ipò míràn. Microsoft kò ní ohunkóhun láti dáhùn fún ìpinnu yòówù tí o bá ṣe nípasẹ̀ àlàyé tí o gbà láti ọwọ́ Microsoft Band.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbàÀwọn Ọjà Oní-nọ́mbà14k_DigitalGoods
Ní ṣókí
 • k. Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà. Nípasẹ̀ Microsoft Groove, Microsoft Movies & TV, Store àti àwọn iṣẹ́ mìíràn tó níí ṣe pẹ̀lú wọn àti àwọn iṣẹ́ ọjọ́ iwájú, Microsoft lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbà, láti tẹ́tísí, láti wò, láti tan ẹ̀rọ tàbí láti ka (èyíkéèyí tó bá báamu) orin, àwòrán, fídíò, àkọránṣẹ́, ìwé, eré tàbí ohun èlò mìíràn ("Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà") tí o lè gbà gẹ́gẹ́ bíi díjítàlì. Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà wà fún ìmúlò ti ara rẹ nìkan, láì fi ṣòwò, àti fún ìdálárayá rẹ. O gbà láti máṣe tún wọn pín kiri, tàn wọ́n káàkiri, lò wọ́n ní ìta gbangba tàbí kí o fi wọ́n hàn ní ìta gbangba tàbí kí o gbé ẹ̀dà àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà yòówù láti ọwọ́ dọ́wọ́. Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà lè jẹ́ ti Microsoft tàbí ti àwọn ẹlòmíràn. Ní gbogbo ìgbà, ó yé ọ, o sì gbà pé àwọn ẹ̀tọ́ rẹ nípa àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà ní àhámọ́ nípasẹ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, àwọn òfin ẹ̀tọ́ ọjà-títà, àti àwọn òfin ìmúlò tó wà ní https://go.microsoft.com/fwlink/p/?LinkId=723143. O gbà pé ìwọ kì yóò gbìyànjú láti ṣàtúnṣe sí àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà yòówù tí o gbà nípasẹ̀ àwọn Iṣẹ́ náà yòówù fún ìdí yòówù, lára èyí tí ó jẹ́ fún èròngbà àti pa àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà lára dà tàbí láti yí oníhun tàbí orísun wọn padà. Microsoft tàbí àwọn oníhun àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà lè, láti ìgbà dé ìgbà, yọ àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà kúrò lára àwọn Iṣẹ́ náà láì sọ fún ni.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
OneDriveOneDrive14l_OneDrive
Ní ṣókí
 • l. OneDrive.
  • i. Fífúnni ní Ibi ìpamọ́. Bí o bá ní àwọn àkóónú púpọ̀ nínú àkọọ́lẹ̀ OneDrive rẹ, èyí tó ju iye tí a fún ọ lábẹ́ àwọn àdéhùn iṣẹ́ aláàbápín ọ̀fẹ́ tàbí èyítí ó nsanwó fún fún OneDrive lọ, tí o kò sì fèsì sí ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ Microsoft tó ní kí o ṣàtúnṣe sí àkọọ́lẹ̀ rẹ nípa yíyọ àkóónú tó bá ti pọ̀ jù kúrò tàbí ṣíṣe ètò aláàbápín titun mìíràn tó ní ibi ìpamọ́ tó pọ̀ síi nínú, àwa ní ẹ̀tọ́ láti ti àkọọ́lẹ̀ rẹ pa, kí a sì pa Àkóónú Rẹ lórí OneDrive rẹ́, tàbí kí a mú kí wíwọlé rẹ sí wọn má ṣiṣẹ́ mọ́.
  • ii. Ìṣesí Iṣẹ́. Ìwọ lè ní àwọn ìrírí ìdádúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní fífi àkóónú ṣọwọ́ lórí ayélujára tàbí ní mímú wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ lórí OneDrive, èyí sì dá lórí àwọn ohun kan bíi àwọn ẹ̀rọ rẹ, àsopọ̀ rẹ lórí ayélujára àti akitiyan Microsoft ní rírí sí ìṣesí àti ìdúróṣinṣin àwọn iṣẹ́ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Èrè MicrosoftÀwọn Èrè Microsoft14m_MicrosoftRewards
Ní ṣókí
 • m. Àwọn Èrè Microsoft.
  • i. Àwọn Èrè Microsoft ( "Program") ń gbà ọ́ láàyè láti gba àwọn kókó tí o le ràpadà fún àwọn ìṣiṣẹ́ bíi ìṣàwárí tó fẹsẹ̀múlẹ̀, ohun gbígbà, àti àwọn ìfúnni míràn láti ọ̀dọ̀ Microsoft. Àwọn ìfilọ̀ ẹ̀bùn lè yàtọ̀ láti ọjà dé ọjà. Wíwákiri jẹ́ ìṣesí aṣàmúlò kan ní titẹ ọ̀rọ̀ wọlé fún èrèdí tó ti ọkàn mímọ́ wá láti ṣàwárí èsì ìwákiri lórí Bing fún àwọn èrèdí ìṣèwádìí ti aṣàmúlò náà, kò sì kan ìbéèrè yòówù tí bọ́ọ̀tì, macro, tàbí ìlànà àìfọwọ́yí inú ẹ̀rọ tàbí ìlànà àìṣòtítọ yòówù bá tẹ̀ síi ("Wíwákiri"). Ohun tí o gbà/rà jẹ́ ìgbésẹ̀ ríra/gbígba ọjà tàbí gbígbé wálẹ̀ àti rírà/gbígba ìwé-àṣẹ ìgbaniláàyè fún àkóónú oní-díjítàlì láti ọwọ́ Microsoft, bóyá lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí nípasẹ̀ owó-sísan ("Ohun tí o rà/gbà"). A kìí fún ni ní máàkì èrè fún gbogbo ohun tí a bá rà láti ọwọ́ Microsoft. Microsoft lè pèsè àfikún ànfàní láti gba máàkì láti ìgbà dé ìgbà, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìfilọ̀ máàkì-gbígbà wọ̀nyí kì yóò sì wà títí láí. Àwọn máàkì tí o gbà ṣeé lò láti fi gba àwọn nnkan ("Àwọn èrè") ní ojú-ewé ìràpadà. Fún àlàyé síwájú síi wo abala Àwọn Èrè ní support.microsoft.com ("FAQ").
   • 1. Àmúyẹ fún Ètò. O nílò ojúlówó àkọọ́lẹ̀ Microsoft, ẹ̀rọ rẹ sì gbọ́dọ̀ kún ojú òṣùwọ̀n àwọn àmúyẹ tó kéré jùlọ tí ẹ̀rọ gbọ́dọ̀ ní. Ètò náà ṣí sílẹ̀ fún àwọn aṣàmúlò tí ngbé ní àwọn agbègbè ìpèsè ọjà tí a kọ sílẹ̀ ní FAQ. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kò gbọdọ̀ ní ju àkọọ́lẹ̀ Ètò kan lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì, ìdílé kọ̀ọ̀kan kò sì lè ní ju àkọọ́lẹ̀ mẹ́fà lọ. Ètò náà wà fún ìlò àdáni àti àìfiṣòwò rẹ nìkan.
   • 2. Àwọn máàkì. Àyàfi fún àpínlò àwọn kókó láàrín ẹbí Microsoft (a le ṣàmúlò òdíwọ̀n) tàbí dídá àwọn kókó rẹ fún àjọ tí kò sí fún èrè tí a kójọ ní ibi ìràdàpadà, o kò le fi àwọn kókó náà ṣọwọ́. Àwọn máàkì kìí ṣe ohun-ìní ti ara rẹ, ìwọ kò sì gbọdọ̀ gba owó yòówù bíi pàṣípààrọ̀ fún wọn. A nfún ọ ní máàkì gẹ́gẹ́ bí ohun ìgbọ́jàlárugẹ. Ìwọ kò lè ra máàkì. Microsoft le dín ìwọ̀n kókó náà kù tàbí Àwọn Èrè fún ẹnìkan, mọ̀lẹ́bí, tàbí lórí àkókò kan tí a pinnu (fún àpẹrẹ ọjọ́ kan) tó bá jẹ́ wípé a le fọkàn tán ọ. Ìwọ kò lè gbà ju máàkì 550,000 lọ ní ọdún orí kàlẹ́ndà kan nínú Ètò náà. Àwọn máàkì tí o bá gbà nínú Ètò náà kò wúlò, o kò sì lè lò wọ́n pọ̀ mọ́ ètò mìíràn yòówù tí Microsoft tàbí àwọn ẹnìkẹta npèsè. Máàkì tí o kò bá rà padà kì yóò wúlò mọ́ bí o kò bá gbà tàbí ṣe ìràpadà máàkì kankan fún oṣù 18.
   • 3. Àwọn èrè. O le ra kókó rẹ padà nípa ìṣàbẹ̀wò sí ojú-ewé ìràpadà tàbí o le dá kókó sí àjọ tí kò sí fún èrè tí a ṣàkójọ. Oríṣi Èrè kan pàtó lè má pọ̀ púpọ̀ nílẹ̀, a ó sì fúnni ní irú àwọn Èrè bẹ́ẹ̀ bí a bá ṣe tètè kópa sí. A lè bèrè pé kí o pèsè àfikún àlàyé, gẹ́gẹ́ bí àdírẹ́ẹ̀sì ìfìwéránṣẹ́ rẹ àti nọ́mbà fóònù rẹ (yàtọ̀ sí VOIP tàbí nọ́mbà tí a fi npè lọ́fẹ̀ẹ́), a sì tún lè bèrè pé kí o tẹ kóòdù adènà jìbìtì tàbí kí o fọwọ́sí àfikún ìwé lábẹ́ òfin láti fi àwọn máàkì rẹ gba Èrè. Lọ́gán tí o bá ti bèrè fún Èrè, ìwọ kò lè fagilé e mọ́, o kò sì lè dá a padà láti fi gba máàkì padà mọ́, àfi ní àwọn ìgbà tí àgbéjáde kan bá ní àlébù tàbí bí òfin bá ṣe ní kí a ṣeé. Tí o bá bèrè fún Èrè tí kò sí nílẹ̀ tàbí tí a kò ní lọ́wọ́ fún ìdí míràan, a le rọ́pò Èrè kan ti iye tó dọ́gba tàbí dá kókó rẹ padà. Microsoft le ṣàfikún Èrè tí a fúnni lórí ojú-ewé ìràpadà tàbí ṣe àìtẹ̀síwájú fífúni ní Èrè pàtó kan. Àwọn Èrè kan lè ní àmúyẹ tiwọn tó níí ṣe pẹ̀lú ọjọ́ orí. Irú àmúyẹ bẹ́ẹ̀ ni a ó ti mẹ́nubà nínú ìfìlọ̀ nípa èrè náà. Ìwọ ni ó ni ojúṣe fún gbogbo àwọn owó-orí ìjọba àpapọ̀, ti ìpínlẹ̀ àti ti ìbílẹ̀, àti fún owó mìíràn yòówù fún gbígbà àti lílo Èrè náà. Àwọn Èrè ni a í firánṣẹ́ sí àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, fún ìdí èyí jẹ́ kí àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ kójú òṣùwọ̀n. Àwọn Èrè tí a kò bá lè fi jíṣẹ́ fún àwọn tó ni wọ́n ní a kì yóò fifúnni mọ́, wọ́n sì ti di ohun tí a gbẹ́sẹ̀lé. Àwọn Èrè kò sí fún àtúntà.
   • 4. Fífagilé Kíkópa Rẹ Nínú Ètò Èrè náà. A le fagilé àkọọ́lẹ̀ Ètò rẹ tí o kò bá wọlé ó kéré jù ẹ̀ẹ̀kan láàrín oṣù 18. Ní àfikún, Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti fagilé àkọọ́lẹ̀ Ètò náà tí aṣàmúlò pàtó fún ìkọlù, àṣìlò, jíja Ètò ní olè, tàbí ìdẹ́jàá àwọn àwíyé wọ̀nyí. Bí Ètò bá di èyítí a fagilé, (láti ọwọ́ ìwọ tàbí àwa) tàbí bí a bá mú Ètò náà dópin fún iye àsìkò kan, ìwọ yóò ní ọjọ́ 90 láti fi máàkì rẹ gba èrè; bí bẹ́ẹ̀kọ́, a ó gbẹ́sẹ̀lé àwọn máàkì náà. Ní ìgbàtí a bá ti fagilé e, ẹ̀tọ́ rẹ láti lo Ètò náà fún gbígba máàkì ní ọjọ́ iwájú ti dópin.
   • 5. Àwọn Àwíyé mìíràn. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti fagilé àmúyẹ rẹ; mú wíwọlé rẹ sórí Ètò tabí àkọọ́lẹ̀ Èrè náà dópin; àti/tàbí kọ̀ láti fúnni ní máàkì, Èrè àti láti gba ni láàyè láti fi èrè ẹni ṣe ẹlòmíràn láàánú, bí Microsoft bá gbàgbọ́ pé ìwọ nṣe màdàrú pẹ̀lú tàbí nṣe àṣìlò abala yòówù lára Ètò náà tàbí ìwọ nṣe àwọn ohun to tàpá sí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
AzureAzure14n_Azure
Ní ṣókí
 • n. Azure. Ìlò Azure rẹ ni àwọn àwíyé àti ipò ti àdéhùn míràn ń darí lábẹ́ èyítí p ti gba àwọn iṣẹ́, bí a ti ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní https://go.microsoft.com/fwLink/?LinkID=522330.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
OníruruOníruru16_17_18_miscellaneous
Ní ṣókí

14. Oníruru. Abala yìí, àti abala 1, 9 (fún iye owó tó yẹ fún sísan ṣáájú òpin àwọn Àdéhùn wọ̀nyí), 10, 11, 12, 15, 17 àti àwọn tó jẹ́ pé nípasẹ̀ àdéhùn wọn, wọn yóò ní ipa lẹ́yìn tí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí bá ti parí, yóò rékọjá ìfòpinsí tàbí fífagilé yòówù fún àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Títí dé ibití òfin tó yẹ gba ni láàyè dé, a lè pín àwọn Àdéhùn wọ̀nyí fún ni, gbé ojúṣe wa fún ẹlòmíràn lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, tàbí kí a fún àwọn ẹlòmíràn ní ìwé-àṣẹ fún àwọn ẹ̀tọ́ wa lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, nígbà yòówù láì sọ fún ọ. O kò gbọdọ̀ pín àwọn Àdéhùn wọ̀nyí fún ni tàbí kí o fi ẹ̀tọ́ yòówù láti lo àwọn Iṣẹ́ náà fún ẹlòmíràn. Èyí ni gbogbo àdéhùn láàárín ìwọ àti Microsoft fún ìmúlò rẹ fún àwọn Iṣẹ́ náà. O rékọjà àdéhùn ìṣáájú yòówù láàárín ìwọ àti Microsoft nípa ìmúlò rẹ fún àwọn Iṣẹ́ náà. Ní fífaramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ìwọ kò gbáralé gbólóhùn yòówù, ìṣojú fún ni, àtìlẹ́yìn, òye, ìlérí tàbí ìfinilọ́kànbalẹ ju bí a ti sọ nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí lọ. Gbogbo abala àwọn Àdéhùn wọ̀nyí yóò ní ipa títí dé ibití òfin tó yẹ gba ni láàyè dé. Bí ilé-ẹjọ́ kan tàbí onílàjà bá ṣe ìdájọ́ pé a kò lè lo abala kan lára àwọn Àdehùn wọ̀nyí bí a ti kọ ọ́, a lè fi àwọn àdéhùn tó jọ́ èyí rọ́pò àwọn irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ títí dé ibití wọ́n ti ṣeé lò dé lábẹ́ òfin tó yẹ, ṣùgbọ́n àwọn tó kù lára àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kì yóò yípadà. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà fún ànfàní ìwọ àtí àwa nìkan. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kò sí fún ànfàní ẹlòmíràn, àfi fún àwọn tí yóò jogún Microsoft àti àwọn tí Microsoft bá yàn. Àkórí-ọ̀rọ̀ àwọn abala wà fún ìtọ́kasí nìkan, wọn kò sì ní ipa kankan lábẹ́ òfin.

15. A Gbọ́dọ̀ Mú Ẹ̀sún Wá Láàárín Ọdún Kan. Ẹ̀sùn yòówù tó bá níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tàbí àwọn Iṣẹ náà ni a gbọ́dọ̀ mú wá sí ilé-ẹjọ́ (tàbí sọ́dọ̀ onílàjà bí abala 10(d) bá ní ipa) láàárín ọdún kan sí ọjọ́ tí ó lè kọ́kọ́ mú ẹ̀sùn náà wá, àfi bí òfin agbègbè rẹ bá nílò àkókò tó ju èyí lọ láti mú ẹ̀sùn wá. Bí o kò bá múu wá láàárín àkókò náà, ó ti di ohun tí a dínà mọ́ láíláí.

16. Àwọn Òfin Ọjà Gbígbé Lọ Sí Òkèèrè. O gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún gbogbo òfin àti ìlànà gbígbé ọjà lọ si ilẹ òkèèrè fún títà ti ìlú ẹni àti ti ilẹ òkèèrè ti o kan software àti/tàbí Iṣẹ́ náà, èyí tí ó kan ìhámọ́ ní ibití a ngbé ọjà lọ, awọn aṣàmúlò ìkẹyìn, àti ìmúlò ìkẹyìn. Fún àlàyé síwájú síi nípa àwọn ìhámọ́ lórí ilẹ̀ àti ti gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà, lọ sí https://go.microsoft.com/fwlink/?linkid=868968 àti https://www.microsoft.com/exporting.

17. Ìtọ́jú Ẹ̀tọ́ àti Ìjábọ̀. Àyàfi bí a ti pèsè lábẹ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, Microsoft kò fún ọ ní ìwé àṣẹ tàbí èyíkéyìí ẹ̀tọ́ míràn bó ti wù kó rí lábẹ́ àṣẹ kankan, bí o ti le ṣeé, ẹ̀tọ́ ìtajà, àṣírí ìṣòwò, àmì òwò tàbí ohun ìní àkọsílẹ̀ míràn tí a ni tàbí tí Microsoft ń darí tàbí èyíkéyìí ilé-iṣẹ́ tójọra, pẹ̀lú ṣùgbọ́n kò pín sí orúkọ kankan, ìmúra òwò, àmì ìdánimọ̀ tàbí ohun míràn tójọra. Tí o bá fun Microsoft ní ọgbọ́n-inú kankan, ìwé àgbéyẹ̀wò, àbà tàbí ìjábọ̀, pẹ̀lú ọgbọ́n-inú àìlópin fún àgbéjáde titun, ìmọ̀-ẹ̀rọ́, ìpolówó ọjà, orúkọ àgbéjáde, ìjábọ̀ àgbéjáde àti ìmúgbòrò àgbéjáde (""Ìjábọ̀""), tí o fún Microsoft, láì díyelé, owó àjẹmọ́nù tàbí ojúṣe míràn fún ọ, ẹ̀tọ́ láti ṣe, tí o ti ṣe, ṣẹ̀dá àwọn iṣẹ́ àwárí, lò, ṣàpínlò kí o sì ṣòwò Ìjábọ̀ rẹ ní ọ̀nàkọnà àti fún èrèdí kankan. O kò ní fún ní Ìjábọ̀ tó wà lábẹ́ ìwé àṣẹ tó nílò kí Microsoft fún ẹ̀yà àìrídìmú, ìmọ̀-ẹ̀rọ tàbí ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ìwé-àṣẹ sí ẹnikẹta kankan nítorí Microsoft ṣàfikún Ìjábọ̀ rẹ nínú wọn.

Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
ÀWỌN ÀKÍYÈSÍÀWỌN ÀKÍYÈSÍNOTICES
Ní ṣókí

Àwọn àkíyèsi àti ìlànà fún mímú ẹ̀sùn wá fún títàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ ẹni. Microsoft nbọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ àwọn ẹlòmíràn. Bí o bá fẹ́ fi àkíyèsi nípa ìtàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ rẹ ránṣẹ́, èyí tí ó kan ẹ̀sùn fún ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa, jọ̀wọ́ lo ìlànà wa fún fífi ránṣẹ́ Àwọn Àkíyèsi Ìtàpásí. ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ ṢE PÀTÀKÌ SÍ ÌLÀNÀ YÌÍ NÌKAN NI A Ó FÈSÌ.

Microsoft a má a lo àwọn ìlànà tí a gbékalẹ̀ ni Àkórí 17, Kóòdù United States, Abala 512 láti fèsì sí àwọn àkíyèsi nípa ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa. Ní àwọn ìgbà tó yẹ, Microsoft lè mú àkọọ́lẹ̀ àwọn aṣàmúlò àwọn iṣẹ́ Microsoft tó jẹ́ olùtàpá sí ẹ̀tọ́ nígbà gbogbo má ṣiṣẹ́ tàbí kí ó múu dópin.

Àwọn àkíyèsi àti ìlànà nípa ohun tó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ nínú ìpolówó ọjà. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹ̀wò Àwọn Ìtọ́sọ́nà nípa Ohun-ìní Iṣẹ́ Ọpọlọ nípa àwọn ohun tó níí ṣe pẹ̀lú ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ nínú nẹtiwọki ìpolówó ọjà.

Àwọn àkíyèsi nípa ẹ̀tọ́ ọjà-títà àti ààmì ọjà-títà. Gbogbo àwọn Iṣẹ́ náà jẹ́ ẹ̀tọ́ ọjà-títà © 2018 Microsoft Corporation àti/tàbí àwọn olùpèsè rẹ, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ní ìpamọ́. Àwọn Àwíyé náà ṣàmúlòMicrosoft Trademark & Brand Guidelines (bí a ti ń ṣàtúnṣe láti ìgbàdégbà). Microsoft àti àwọn orúkọ, àmì ìdánimọ̀, àti àwọn àwòrán ti gbogbo àgbéjáde Microsoft, ẹ̀yà àìrídìmú, àti àwọn iṣẹ́ le jẹ́ yálà àìforúkọsílẹ̀ tàbí àmì òwò tí a kọsílẹ̀ ti Microsoft ní Amerika àti/tàbí àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Ìwọ̀nyí ni àkójọ̀ àmì ìṣòwò Microsoft tí a kọsílẹ̀ ṣùgbọ́n tó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn orúkọ àwọn ilé-iṣẹ́ àti ọjà gidi lè jẹ́ ààmì ọjà-títà àwọn oníhun wọn. Àwọn ẹ̀tọ́ yòówù tí a kò fífún ni nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà ní ìpamọ́. Àwọn ẹ̀yà àìrídìmú tí a lò ní àwọn olùpín àyè ayélujára Microsoft kan dá lórí iṣẹ́ òmìnira Ẹgbẹ́ JPEG. Copyright © 1991-1996 Thomas G. Lane. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́. ẹ̀yà àìrídìmú "gnuplot" tí a ń lò nínú àwọn apèsè ojúlé wẹ́ẹ̀bù Microsoft kan jẹ́ tí àṣẹ ìtajà © 1986‑1993 Thomas Williams, Colin Kelley. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́.

Àkíyèsi Ìtọ́jú Ìlera. Microsoft kìí pèsè ìtọ́jú ìlera tàbí ìmọràn ìtọ́jú ìlera, ìwádìí àti àyẹwò àìsàn tàbí ìtọ́jú yòówù. Má a wá ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ dọkítà rẹ tàbí àwọn àkọṣẹmọṣẹ olùpèsè iṣẹ ìlera mìíràn nípa ìbéèrè yòówù tí o lè ní nípa ipò ìlera kan, oúnjẹ, tàbi ètò wíwà ní àlàáfíà. Máṣe fojú fo ìmọ̀ràn ìtọ́jú ìlera tàbí kí o sọ àsìkò nù ní wíwá a rí nítorí àlàyé tí o wọlé sí lórí tàbí nípasẹ àwọn Iṣẹ́ náà.

Àwọn àlàyé iye owó tó wà lórí ilé-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan àti détà rẹ (èyí tó kan iye ìtọ́kasí). © 2013 Morningstar, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́. Àlàyé tó wà níbí: (1) jẹ ohun-ìní Morningstar àti/tàbí àwọn olùpèsè àkóónú rẹ; (2) a kò gbọdọ dàákọ tàbí pín i kiri; àti (3) a kò ṣe àtìlẹyìn pé ó jẹ pípé, ẹkúnrẹrẹ tàbí lásìkò. Yálà Morningstar tàbí àwọn olùpèsè àkóónú rẹ kò ní ojúṣe fún ìbàjẹ́ tàbí àdánù yòówù tó wáyé nípasẹ ìmúlò àlàyé yìí. Ìṣesí àtijọ́ kìí ṣe ìdánilójú fún àgbéjáde ọjọ́ iwájú.

O kò gbọdọ lo èyíkèéyì lára awọn Ìtọ́kasíSM, détà ìtọ́kasí, tàbí àwọn ààmì Dow Jones pẹlú fífifúnni, ṣíṣẹda, ṣíṣe onigbọwọ, títajà, ṣíṣòwò, tàbí mímú ìlọsíwájú bá àwọn ìrin-iṣẹ ìṣúná owó tàbí àwọn ọjà ìfowóṣòwò yòówù (fún àpẹẹrẹ abajáde, ọjà tí a ṣe ní àkànṣe, àwọn owó ìfiṣòwò, àwọn owó pàṣípààrọ òwò, àwọn ètò ìfowóṣòwò, àti bẹẹ bẹẹ lọ, níbití iye owó, ìdápadà tàbí ìṣesí irin-iṣẹ tàbí ọjà ìfiṣòwò náà dá lórí, tàbí níí ṣe pẹlú, tàbí gbèrò láti tọpasẹ èyíkéèyí nínú Ìtọkasi tàbí onigbọwọ fún èyíkéèyí nínú àwọn Ìtọkasi náà) láì gba ìfọwọ́sí Dow Jones tí a kọ sílẹ.ọ́

Àkíyèsi Ìṣúná Owó. Microsoft kìí ṣe adíìnádúrà/alágbàtà tàbí olùdámọràn ìfowóṣòwò tó ní àṣẹ lábẹ òfin ààbò ìjọba àpapọ United States ní àwọn ipò ìdájọ́ mìíràn, òun kìí sì fún ni ní ìmọràn nípa fífowóṣòwò, rírà, tàbí títa àwọn ọjà tó ní ààbò tàbí àwọn ọjà tàbí iṣẹ ìṣòwò mìíràn. Kò sí ohunkóhun nínú àwọn Iṣẹ yìí tó jẹ ìfilọ tàbi ẹ̀bẹ̀ láti ra tàbí ta ọjà tó ní ààbò yòówù. Yálà Microsoft tàbí àwọn tó nfún ni ní ìwé-àṣẹ lábẹ rẹ fún àlàyé iye owó tó wà lórí ilé-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tàbí détà ìtọkasí ní ó fọwọsi tàbí dámọràn ọjà tàbí iṣẹ ìṣúná owó kan pàtó. Kò sí ohun kankan nínú Àwọn Ìpèsè náà ti a ṣe láti jẹ́ ìmọ̀ràn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, pẹ̀lú àìní òdíwọ̀n, ìdókòwò tàbí ìmọ̀ràn owó-orí.

Àkíyèsi nípa gègé ìdíwọ̀n Fidio H.264/AVC, MPEG-4 Visual, àti VC-1. Lára ẹ̀yà àìrídìmú náà lè jẹ́ iṣẹ́ ìmọ ẹ̀rọ H.264/AVC, MPEG-4 Visual àti/tàbí VC-1 tí MPEG LA, L.L.C lè fún ni ìwé-àṣẹ. Iṣẹ́ ìmọ ẹ̀rọ yìí jẹ ìlànà àfúnpọ détà fún àlàyé fidio. MPEG LA, L.L.C. nílò àkíyèsi yìí:

A FÚN NI NÍ ÌWWÉ-ÀṢẸ FÚN ỌJÀ YÌÍ LABẸ ÌWÉ-ÀṢẸ H.264/AVC, ÀFOJÚRÍ MPEG-4, ÀTI VC-1 FÚN ÌMÚLÒ ARA ẸNI LÁÌFIṢÒWÒ FÚN AṢÀMÚLÒ ÌKẸYÌN LÁTI (A) FI KÓÒDÙ SÍ FIDIO NÍ ÌBÁMU PẸLU GÈGÉ ÌDÍWỌN (¨ÀWỌN GÈGÉ ÌDÍWỌN´) ÀTI/TÀBÍ (B) YỌ KÓÒDÙ KÚRÒ LÁRA FIDIO H.264/AVC, ÀFOJÚRÍ MPEG-4, ÀTI VC-1 TÍ A FI KÓÒDÙ SÍ NÍPASẸ AṢÀMÚLÒ ÌKẸYÌN TÍ NṢE OHUN ÀMÚṢE TI ARA ẸNI LÁÌFIṢÒWÒ, ÀTI/TÀBÍ TÍ A GBÀ LÁTI ỌWỌ OLÙPÈSÈ FIDIO TÓ NÍ ÌWÉ-ÀṢẸ LÁTI PÈSÈ IRÚ FIDIO BẸẸ. KÒ SÍ ÈYÍKÉÈYÍ LÁRA ÌWÉ-ÀṢẸ NÁÀ TÓ KAN ỌJÀ MÌÍRÀN LÁÌ KA PÉ BÓYÁ IRÚ ỌJÀ BẸẸ WÀ LÁRA ẸYA ÀÌRÍDÌMÚ YÌÍ NÍNÚ OHUN KANṢOṢO. A KÒ FÚN NI NÍ ÌWÉ-ÀṢẸ TÀBÍ A KÓ GBÈRÒ RẸ FÚN ÌMÚLÒ MÌÍRÀN. ÀFIKÚN ÀLÀYÉ NI A LÈ GBÀ LÁTI ỌWỌ MPEG LA, L.L.C. WO MPEG LA WEBSITE.

Fún èrèdí ìmúdánilójú nìkan, àkíyèsi yìí kò fi àlà sí tàbí dènà ìmúlò ẹya àìrídìmú tí a pèsè labẹ àwọn Àdéhùn wọnyi fún ìmúlò ìṣòwò tó jẹ ti ara ẹni tí kò kan (i) àtúnpín kiri ẹya àìrídìmú náà fún àwọn ẹlomiran, tàbí (ii) ṣiṣẹda ohun àmúlò pẹlu GÈGÉ IDIWỌN FIDIO tó bá iṣẹ imọ ẹrọ fún pípín kiri fún àwọn ẹlomiran mu.

Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
ÀWỌN ÀDÉHÙN ÌWÉ-ÀṢẸ OHUN ÈLÒ DÉÉDÉÀWỌN ÀDÉHÙN ÌWÉ-ÀṢẸ OHUN ÈLÒ DÉÉDÉSTANDARDAPPLICATIONLICENSETERMS
Ní ṣókí

ÀWỌN ÀDÉHÙN ÌWÉ-ÀṢẸ OHUN ÈLÒ DÉÉDÉ

ÌTAJÀ ONÍFORÍKORÍ MICROSOFT, ÌTAJÀ ONÍFORÍKORÍ WINDOWS, ÀTI ÌTAJÀ ONÍFORÍKORÍ XBOX

Àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ wọ̀nyí jẹ́ ìfohùnṣọ̀kàn láàárín ìwọ àti olùgbéjáde ohun èlò náà. Jọ̀wọ́ kà wọ́n. Èyí kan àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ ẹ̀yà àìrídìmú tí o gbà sílẹ̀ láti Ìtajà Oníforíkorí Microsoft, Ìtajà Oníforíkorí Windows tàbí Ìtajà Oníforíkorí Xbox (ìkọ̀ọ̀kan èyí tí a ń pè ní "Ìtajà Oníforíkorí" nínú àdéhùn ìgbaniláyè wọ̀nyí), pẹ̀lú èyíkéyìí àfikún tàbí àfikún ìmúdára fún ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, àyàfi tí ìṣàfilọ́lẹ̀ náà bá wá pẹ̀lú àdéhùn ọ̀tọ̀tọ̀, nínú èyítí a ń ṣàmúlò àdéhùn wọ̀nyí.

NÍPA GBÍGBÉWÁLẸ̀ TÀBÍ LÍLO OHUN ÈLÒ NÁÀ, TÀBÍ GBÍGBÌYÀNJÚ LÁTI ṢE ÈYÍKÉÈYÍ NÍNÚ ÀWỌN WỌ̀NYÍ, ÌWỌ FARAMỌ́ ÀWỌN ÀDÉHÙN WỌ̀NYÍ. BÍ O KÒ BÁ FARAMỌ́ WỌN, ÌWỌ KÒ NÍ Ẹ̀TỌ́ LÁTI, O KÒ SÌ GBỌDỌ̀ GBÉ OHUN ÈLÒ NÁÀ WÁLẸ̀ TÀBÍ KÍ O LÒÓ.

Olùtẹ̀jáde ìṣàfilọ́lẹ̀ náà túmọ̀ sí ẹni tí ń fún ọ ní ìgbaniláyè sí ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, bí a ti dáamọ̀ nínú Ìtajà Oníforíkorí náà.

Bí o bá mú àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ wọ̀nyí ṣe, ìwọ ní àwọn ẹ̀tọ́ tí a kọ sí ìsàlẹ̀ wọ̀nyí.

 • 1. AWỌN ẸTỌ NIPA FÍFI SORI ẸRỌ ATI LÍLÒ; PÍPARÍ IṢẸ́. O le ṣàgbékalẹ̀ kí o sì lo ìfilọ́lẹ̀ náà lórí àwọn ohun èlò Windows tàbí àwọn kọ́nsòlù Xbox bí a ti júwe nínú Òfin Ìlò Microsoft. Microsoft ni ó ni ẹ̀tọ́ láti ṣàtúnṣe sí Òfin Ìlò Microsoft nígbà yòówù.
 • 2. ÀWỌN IṢẸ́ TÍ À NṢE LÓRÍ AYÉLUJÁRA.
  • a. Ìfaramọ́ fún Àwọn iṣẹ́ tí à nṣe lórí Ayélujára. Bí ohun èlò náà bá nso pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀rọ kọmputa lórí Ayélujára, èyí tí ó lè kan nípasẹ̀ nẹtiwọki aláìlowáyà, lílo ohun èlò náà nṣiṣẹ́ bíi ìfaramọ́ rẹ fún gbígbé àwọn àlàyé ẹ̀rọ káàkiri (èyí tí ó kàn, ṣùgbọ́n tí kò parí sí àlàyé iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ nípa ẹ̀rọ àti ẹ̀yà àìrídìmú ohun èlò rẹ, àti àwọn àsopọ̀mọ́ ẹ̀rọ) fún àwọn iṣẹ́ tí à nṣe lórí ayélujára tàbí àwọn iṣẹ́ aláìlowáyà. Bí a bá pèsè àwọn àdéhùn mìíràn pẹ̀lú ìmúlò rẹ fún àwọn iṣẹ́ tí à nwọlé sí nípasẹ̀ ohun èlò náà, àwọn àdéhùn náà tún ní ipa.
  • b. Àṣìlò Awọn iṣẹ ti a nṣe lori Ayelujara. O kò gbọ́dọ̀ lo iṣẹ́ yòówù tí à nṣe lórí Ayélujára ni ọ̀nà yòówù tí ó lè mú ìpalára bá a tàbí lọ́nà tí yoo dí bí àwọn ẹlomiiran ṣe nlò ó tàbí nẹtiwọki aláìlowáyà náà lọ́wọ́. O kò gbọ́dọ̀ lo iṣẹ́ náà lati gbìyànjú lati wọlé, láì ní àṣẹ, sí iṣẹ́ yòówù, détà, àkọọ́lẹ̀, tàbí nẹ́tíwọọ̀kì, lọ́nàkọnà.
 • 3. ÌDÍWỌ̀N AGBÁRA ÌWÉ-ÀṢẸ. A gba ìwé-àṣẹ fun ohun èlò naa ni, a ko tà á. Ìfohùnṣọ̀kan yìí fún ọ ní àwọn ẹ̀tọ́ kan nìkan lati lo ohun èlò náà. Bí Microsoft bá mú kí agbára àti lo àwọn ohun èlò náà má ṣiṣẹ́ lórí àwọn ẹ̀rọ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìfohùnṣọkan rẹ pẹ̀lú Microsoft, àwọn ẹ̀tọ́ ìwé-ẹ̀rí yòówú tó níí ṣe pẹ̀lú rẹ̀ yóò dópin. Olùgbéjáde ohun èlò náà ni ó ní gbogbo ẹ̀tọ́ mìíràn yòókù. Àfi bí òfin tí ó yẹ bá fún ọ ni ẹ̀tọ́ síwájú síi láì ka ìhámọ́ yi si, o lè lo ohun èlò naa gẹ́gẹ́ bí a ti gbà ọ́ láàyè ninu ìfohùnṣọ̀kan yìí nìkan. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìhámọ́ yòówù nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ohun èlò náà, èyítí ó fún ọ ni ànfàní láti lòó ní àwọn ọ̀nà kan nìkan. Ìwọ kò gbọdọ̀:
  • a. Dá ọgbọ́n sí ìhámọ́ yòówù nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ohun èlò náà;
  • b. Tún iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tò, tú ohun èlò náà palẹ̀, àfi dé ibiti òfin ti o yẹ bá fún ọ ní ẹ̀tọ́ dé, láì ka ìhámọ́ yìí sí;
  • c. Ṣe ẹ̀dà ohun èlò náà síwájú síi ju bí a ti sọ nínú ìfohùnṣọ̀kan yìí tàbí bí òfin tó yẹ ti gba ni láàyè, láì ka ìhámọ́ yìí sí;
  • d. Ṣe àgbéjáde tàbí mú kí ohun èlò náà wà fún àwọn ẹlòmíràn láti ṣe ẹ̀dà rẹ̀;
  • e. Yá ẹlòmíràn ní ẹ̀yà àìrídìmú náà ní ìrètí àti gba owó tàbí ní ìrètí pé wọn yóò dá a padà lẹ́yìn ìgbà díẹ̀;
  • f. Fi ìfilọ́lẹ̀ tàbí àdéhùn yìí fún ẹnìkẹta yòówù;
 • 4. ṢÍṢE ÀKỌSÍLẸ̀. Bí a bá pèsè àkọsílẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò náà, o lè da àkọsílẹ̀ inú rẹ̀ kọ, o sì lè lòó fún ànfàní ìwádìí ti ara rẹ.
 • 5. ÀWỌN ÌHÁMỌ́ NÍPA IṢẸ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÀTI TI GBÍGBÉ ỌJÀ LỌ SÍ ILẸ̀ OKÈÈRÈ FÚN TÍTÀ. Ohùn èlò yìí wà lábẹ́ òfin àti ìlànà orílẹ̀-èdè Amẹrika fún gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà. O gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún gbogbo òfin àti ìlànà gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà ti ìlú ẹni àti ti ilẹ̀ òkèèrè tó kan ìmọ̀ ẹ̀rọ tí a lò tàbí tí ohun èlò náà ṣe àtìlẹ́yìn fún. Lára àwọn òfin wọ̀nyí ní ìhámọ́ nípa ibití à ngbé ọjà náà lọ, àwọn aṣàmúlò ìkẹyìn ati ìmúlò ìkẹyìn. Fún àlàyé nípa àwọn ọjà tó ní ààmì Microsoft lára, lọ sí àyè ayélujára Microsoft fún gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà.
 • 6. AWỌN IṢẸ́ ÀTÌLẸ́YÌN. Kàn sí olùgbéjáde ohun èlò náà láti mọ àwọn iṣẹ́ àtìlẹ́yìn tó wà. Microsoft, olùpèsè ẹ̀yà àfojúrí rẹ àti ilé-iṣẹ́ tí npèsè ìbáraẹnisọ̀rọ̀ rẹ (àfi bí ọ̀kan nínú wọn bá jẹ́ olùgbéjáde ohun èlò náà) kò ní ojúṣe fún pípèsè iṣẹ́ àtìlẹ́yìn fún ohun èlò náà.
 • 7. ÀKÓPỌ̀ GBOGBO ÌFOHÙNṢỌ̀KAN. Ìfohùnṣọ̀kan yìí, àti òfin ìkọ̀kọ̀ tó yẹ yòówù, àfikún àdéhùn yòówù tó lè bá ohun èlò náà wá, àti àwọn àdéhùn fún àwọn àfikún àti ìmúdójúìwọ̀n, jẹ́ ìfohùnṣọ̀kan ìwé-ẹ̀rí lápapọ̀ láàárín ìwọ àti olùgbéjáde ohun èlò fún ohun èlò náà.
 • 8. ÒFIN TÓ NṢIṢẸ́.
  • a. United States àti Canada. Bí o bá ra ìfilọ́lẹ̀ náà ní United States tàbí Canada, àwọn òfin ìpínlẹ tàbí agbègbè ibití ìwọ ngbé (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, ibití olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà) ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn àdéhùn wọnyí, wọn sì kan àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá síi, àti gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà mìíràn (títí kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́) láì ka àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn òfin miiran kún.
  • b. Lóde United States àti Canada. Bí o bá ra ohun èlò náà ní orílẹ̀-èdè miiran, òfin orílẹ̀-èdè náà ni a ó lò.
 • 9. IPA TI ÒFIN NÍ. Ìfohùnṣọ̀kan yìí ṣe àpèjúwe àwọn ẹ̀tọ́ ẹni kan lábẹ́ òfin. Ìwọ lè ni àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn lábẹ́ àwọn òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè rẹ. Ìfohùnṣọ̀kan yìí kò yí àwọn ẹ̀tọ́ rẹ lábẹ́ àwọn òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè rẹ padà bí àwọn òfin ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè rẹ kò bá gbà á láàyè lati ṣe bẹ́ẹ̀.
 • 10. ÌKỌ̀SÍLẸ̀ ÀTÌLẸ́YÌN. A fún ọ ní ìwé-àṣẹ fún ohun èlò yìí “bí ó ṣe rí”, ¨pẹ̀lú gbogbo àṣìṣe¨ àti bí ó ṣe wà¨. Ìwọ ni ó ni gbogbo ewu tó wà nínú lílò ó. Olùgbéjáde ohun èlò náà, lórúkọ ara rẹ̀, Microsoft (bí Microsoft kìí bá ṣe olùgbéjáde rẹ̀), àwọn tí npèsè iṣẹ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ aláìlowáyà, lórí nẹtiwọki àwọn ẹnití a ti pèsè ohun èlò náà, àti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ wa, alágbàtà, aṣojú àti olùpèsè (¨Àwọn Ẹni Tó Wà Lábẹ́ Rẹ̀¨), kò ṣe àtìlẹ́yìn tààrà, àfẹ̀hìntì, tàbí májẹ̀mú nípa ohun èlò náà. Gbogbo ewu tó wà nípa dídára, níní ààbò, rírọrùn, àti iṣẹ́-ṣíṣe ohun èlò náà jẹ́ tìrẹ. Bí ohun èlò náà bá ní àbàwọ́n, o faramọ́ gbogbo iye owó àbójútó àti àtúnṣe. Ìwọ lè ni àwọn àfikún ẹ̀tọ́ aṣàmúlò ìkẹyìn tàbi àwọn àtìlẹ́yìn ìṣedéédé miiran lábẹ́ àwọn òfin agbègbè rẹ, àwọn èyí tí ìfohùnṣọ̀kan yìí kò lè yípadà. Títí dé ibití òfin agbègbè rẹ fi ààyè gba ni dé, Àwọn Ẹni Tó Wà Lábẹ́ Rẹ̀ mú àwọn àtìlẹ́yìn ìdápadà tàbí májẹ̀mú tí a kò mẹ́nubà tààrà nípa ṣíṣeétà, yíyẹ fún lílò kan pàtó, níní ààbò, rírọrùn ati àìgbọdọ̀ tàpá sí ẹ̀tọ́ ẹlomiiran, kúrò.
 • 11. ÌHÁMỌ́ ATI ÌYỌKÚRÒ LÓRÍ IYE OWÓ ÀTÚNṢE ATI ÀSANPADÀ FÚN ÌBÀJẸ́. Títí dé ibití òfin kò ti ṣe ìdènà dé, ‎bí o bá ní ìdí kankan fún gbígba àsanpada, o lè gbà awọn àsanpadà tààrà láti ọwọ́ olùgbéjáde ohun elò ní iye tó tó iye owó tí o san fún ohun èlò náà tàbí USD$1.00, èyíkéèyí tó bá pọ̀ jù nínú méjèèjì. Ìwọ kì yóò, o sì fojú fo ẹ̀tọ́ yòówù láti, gbìyànjú láti gba àsanpadà miiran yòówù, èyí tí ó kan àwọn àsanpadà tí ó ti ìdí ohun kan jáde, ti àwọn èrè tí a pàdánù, àkànṣe, àwọn èyí tí kò lọ tààrà, tàbí àwọn èyí tí ó ti ipasẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé láti ọwọ́ olùgbéjáde ohun èlò náà. Bí àwọn òfin agbègbè rẹ bá fi ipá gbé òfin àtìlẹ́yìn àsanpadà, àfẹ̀hìntì tàbí májẹ̀mú kan sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdéhùn wọnyí kò ṣe bẹ́ẹ̀, iye àkókò rẹ̀ kò kọjá ọjọ́ 90 láti ọjọ́ tí o gbé ohun èlò náà wálẹ̀.

Ìhámọ́ naa tun kan:

 • Ohun yòówù tó níí ṣe pẹ̀lú ohun èlò tàbí àwọn iṣẹ́ náà tó wà nípasẹ̀ ohun èlò náà; àti
 • Àwọn gbígba ẹ̀tọ́ fún rírú òfin àdéhùn, rírú òfin àtìlẹ́yìn, tàbí ìlànà, dídáhùn fún ni tó pọn dandan, àìbìkítà, tàbí àwọn òfin ti ndarí ìwà àìtọ́ titi dé ibiti òfin fi ààyè gba ni dé.

O tún ṣì ní ipa bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé:

 • Àtúnṣe yìí ko ṣe àsanpadà fún ọ lẹkunrẹrẹ fún àwọn àdánù yòówù; tàbí
 • Olùgbéjáde ohun èlò náà mọ̀ tàbí ó yẹ kí ó mọ̀ nípa wíwáyé irú àwọn ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Àwọn Iṣẹ́ Tó KànÀwọn Iṣẹ́ Tó Kànserviceslist
Ní ṣókí

Àwọn ọjà, ohun èlò àti iṣẹ wọnyi ni Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft kàn, ṣugbọn wọn lè má wà ní ọjà rẹ.

 • Account.microsoft.com
 • Advertising.microsoft.com
 • Aṣèrànwọ́ Àtìlẹyìn àti Ìràpadà Microsoft fún Office 365
 • Bing App for Android
 • Bing Apps
 • Bing Bots
 • Bing Business Bot
 • Bing Desktop
 • Bing Dictionary
 • Bing for Business
 • Bing Image and News (iOS)
 • Bing in the Classroom
 • Bing Search APIs/SDKs
 • Bing Search app
 • Bing Sportscaster
 • Bing Toolbar
 • Bing Translator
 • Bing Webmaster
 • Bing Wikipedia Browser
 • Bing.com
 • Bing
 • Bingplaces.com
 • Citizen Next
 • Cortana skills by Microsoft
 • Cortana
 • Default Homepage and New Tab Page on Microsoft Edge
 • Dev Center App
 • Device Health App
 • Dictate
 • Docs.com
 • education.minecraft.net
 • Face Swap
 • Feedback Intake Tool for Azure Maps (aka “Azure Maps Feedback”)
 • Forms.microsoft.com
 • forzamotorsport.net
 • Groove Music Pass
 • Groove
 • GroupMe
 • HealthVault
 • LineBack
 • Maps App
 • Microsoft Academic
 • Microsoft Add-Ins for Skype
 • Microsoft Bots
 • Microsoft Educator Community
 • Microsoft Family
 • Microsoft Health
 • Microsoft Pay
 • Microsoft Research Interactive Science
 • Microsoft Research Open Data
 • Microsoft Soundscape
 • Microsoft Translator
 • Microsoft Wallpaper
 • Microsoft XiaoIce
 • Mixer
 • MSN Dial Up
 • MSN Explorer
 • MSN Food & Drink
 • MSN Health & Fitness
 • MSN Money
 • MSN News
 • MSN Premium
 • MSN Sports
 • MSN Travel
 • MSN Weather
 • MSN.com
 • Next Lock Screen
 • Office 365 Consumer
 • Office 365 Home
 • Office 365 Personal
 • Office 365 Pro Plus optional connected experiences
 • Office 365 University
 • Office fún wẹ́ẹ̀bù (tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí Office Online)
 • Office Store
 • Office Sway
 • Office.com
 • Olùṣàkóso Skype
 • OneDrive.com
 • OneDrive
 • OneNote.com
 • Outlook.com
 • Paint 3D
 • Picturesque Lock Screen
 • Presentation Translator
 • Remix 3D
 • Rinna
 • rise4fun
 • Ruuh
 • Seeing AI
 • Send
 • Skype in the Classroom
 • Skype Interviews
 • Skype Qik
 • Skype.com
 • Skype
 • Smart Search
 • Snip Insights
 • Spreadsheet Keyboard
 • Sprinkles
 • Sway.com
 • to-do.microsoft.com
 • Translator for Microsoft Edge
 • Translator Live
 • UrWeather
 • Video Breakdown
 • Visio Online
 • Web Translator
 • Who’s In
 • Windows Live Mail
 • Windows Live Writer
 • Windows Movie Maker
 • Windows Photo Gallery
 • Xbox Game Pass
 • Xbox Live Gold
 • Xbox Live
 • Xbox Music
 • Xbox Store
 • Àkọọ́lẹ̀ Microsoft
 • Àwọn eré Xbox àti Windows, Àwọn ìfilọ́lẹ̀ àti ojúlé wẹ́ẹ̀bù tí Microsoft ṣe àgbéjáde wọn
 • Àwọn eré, ìfilọ́lẹ̀ àti ojúlé wẹ́ẹ̀bù Windows tí Microsoft ṣàgbéjáde wọn
 • Àwọn eré, ìfilọ́lẹ̀ àti ojúlé wẹ́ẹ̀bù Xbox Game Studios
 • Àwọn Fíìmù àti TV Microsoft
 • Àwọn Àwòrán Ayé Bing
 • Ìtajà oníforíkorí Windows
 • Ìtajà oníforíkorí
Ọ̀rọ̀ lẹkunrẹrẹ
Ọjọ́ 1, Oṣù Keje, Ọdún 20190