Àlàyé ní ṣókí nípa àwọn Àyípadà sí Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft – Ọjọ́ 30, Oṣù Kẹsàn-án, Ọdún 2026
Àwa nmú Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft dójú ìwọ̀n, èyí tí ó kan bí o ti nlo àwọn àgbéjáde tàbí ìpèsè Microsoft lórí ayélujára fún aṣàmúlò ìkẹyìn. Ojú-ìwé yìí n pèsè àlàyé ní ṣókí nípa àwọn àyípadà pàtàkì sí Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft.
Láti lè rí gbogbo àwọn àyípadà náà, jọ̀wọ́ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft níbí.
- Nínú àkòrí, a ti sún ọjọ́ tí àwa yóò ṣe àgbéjáde sí ọjọ́ 30, Oṣù Keje, Ọdún 2026, àti ọjọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sí ọjọ́ 30, Oṣù Kẹsàn-án, Ọdún 2026.
- Ní abala ojú-ìwé nípa ìsọdimímọ̀, a ti fi ọ̀rọ̀ tó pọ̀ síi kún un láti fi àwọn àgbéjáde aṣàmúlò ìkẹyìn, àwọn ààyè ayélujára àti àwọn ìpèsè tó tọ́ka sí Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft kún un lábẹ́ ¨Àwọn Ìpèsè¨ tó wà lábẹ́ òfin àwọn Àdéhùn náà.
- Ní abala ¨Wíwà Iṣẹ́¨, a ti fi ọ̀rọ̀ tó pọ̀ síi kún un ní pàtó, àwọn èyí tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà aṣàmúlò ìkẹyìn àwọn ará Brazil.
- Ní abala ¨Ẹnití nbá ni dá Májẹmù, Àṣàyàn Òfin, & Ibití a ó ti Parí Àríyàjiyàn¨, a ti mú ẹnití nbá ni dá májẹmù fún àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Àríwá Amẹrika, Gúsù Amẹrika àti Gúsù Pacific dójú ìwọ̀n.
- Ní abala ¨Ìfọwọ́sọ̀yà¨, a ti fi ọ̀rọ̀ tó pọ̀ síi kún un ní pàtó, àwọn èyí tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà aṣàmúlò ìkẹyìn ní Brazil.
- Ní abala ¨Àwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtó¨, a ṣe àwọn àfikún àti àyípadà wọ̀nyí:
- Ní abala ¨Ibi ìpamọ́¨, a mú àwọn ọ̀rọ̀ nípa àwọn ìmúdójúìwọ̀n láìfọwọ́yí dójú ìwọ̀n, láti gba àwọn aṣàmúlò láàyè láti dá ìmúdójúìwọ̀n dúró fún ìgbà ránpẹ́, a sì ṣàlàyé àwọn ipa tí èyí yóò ní bí a kò bá mú àwọn ìfilọ́lẹ̀ kan dójú ìwọ̀n.
- Lábẹ́ abala ¨Cortana¨, a ṣàlàyé pé Microsoft kò ṣe àtìlẹ́yìn mọ́ fún Cortana láti 2024, a sì yọ àwọn abala tó níí ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ Cortana tí wọn kò ṣeé lò mọ́ kúrò.
- Ní abala ¨Àwọn Ìpèsè àti Àwọn ìfilọ́lẹ̀ Microsoft 365¨, a mú ìsọlórúkọ àwọn orúkọ àpapọ̀ àgbéjáde Microsoft 365 dójú ìwọ̀n, a sì sọ àsọyé pé ìlò àwọn ìfilọ́lẹ̀ àti ìpèsè tí a tọ́ka sí náà wà lábẹ́ òfin àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ náà.
- Ní abala ¨Àwọn Ọjà Onídíjítà¨, a pa ìtọ́kasí Microsoft Groove rẹ́, èyí tó jẹ́ ohun tí kò sí mọ́.
- Ní abala ¨Microsoft Rewards¨, a mú àwọn atọ́ka àsopọ̀ sí àwọn ojú-ìwé tó yẹ dójú ìwọ̀n, a sì mú iye àwọn máàkì tí a lè gbà padà lọ́dọọdún dójú ìwọ̀n láti lè ṣàfihàn àwọn ààlà onípele méjì.
- A fún abala ¨Copilot¨ ní orúkọ mìíràn, àwọn ẹ̀yà Copilot tí èyí kàn náà, tí wọ́n wà lábẹ́ òfin Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft ni a sì jẹ́ kí ó yé ni.
- Jálẹ̀ àwọn Àdéhùn náà, a ṣe àwọn àyípadà láti lè mú ohun gbogbo yé ni síi, àti láti lè ṣe àtúnṣe sí àwọn gírámà, àṣìtẹ̀ ọ̀rọ̀ àti irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mìíràn. A tún ti mú ìsọlórúkọ àti àwọn ọ̀rọ̀ atọ́ka-ọ̀nà dójú ìwọ̀n.