Ìpamọ́ Rẹ
1. Ìpamọ́ Rẹ. Ìpamọ́ rẹ ṣe pàtàkì sí wa. Jọ̀wọ́ ka Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ Microsoft (https://go.microsoft.com/fwlink/?LinkId=521839) (the "Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀") Ìkọ̀kọ̀") bí ó ti ṣe àlàyé irú àwọn détà tí à ngbà láti ọ̀dọ̀ rẹ àti láti inú àwọn ohun èlò rẹ ("Détà"), bí a ṣe nlo Détà rẹ, àti àtìlẹ́yìn òfin tí a ní láti wọlé sí Détà rẹ. Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ tún ṣàlàyé bí Microsoft ti ń lo àkóónú rẹ, èyí tííṣe ìbánisọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn; àwọn ìfiṣọwọ́ tí o firánṣẹ́ sí Microsoft nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè náà; àti àwọn fáìlì, fọ́tò, àkọsílẹ̀, ohun àfetígbọ́, iṣẹ́ onídíjítà, ìgbàsílẹ̀ àti fídíò tí o fiṣọwọ́, tí o fipamọ́, tí o fisórí afẹ́fẹ́, tàbí ṣẹ̀da, ṣàwari, tàbí ṣàpínlò nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè, ("Àkóónú Rẹ"). Níbití ìṣètò bá dá lórí ìgbaniláàyè, àti títí dé ibi tí òfin gbà wá làáyé dé, nípa fífaramọ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, o gbà sí àkójọ̀ Microsoft, ìlò àti àfihàn Àkóónú Rẹ àti Détà bí a ti ṣàlàyé nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà. Ní ọ̀nà míràn, a ó pèsè àkíyèsí míràn a ó sì bèrè fún ìyọ̀nda rẹ bí a ti tọ́kasí nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà.
Àkóónú Rẹ
2. Àkóónú Rẹ. Púpọ̀ nínú àwọn Ìpèsè wa gbà ọ́ láàyè láti ṣẹ̀dá, fipamọ́ re, tàbí ṣàjọpín Àkóónú Rẹ tàbí gba ohun àmúlò láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwa kìí sọ pé àwa ni a ni Àkóónú Rẹ. Àkóónú Rẹ yóò má a jẹ́ tìrẹ ọwọ́ rẹ ló wà.
- a. Nígbàtí o bá pín Àkóónú Rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, ó yé ọ pé wọ́n lè, káàkiri àgbáyé, lò, ṣàfipamọ́, ṣàkọsílẹ̀, ṣàtúndá, tàn káàkiri, ta ní àtagbà, ṣàpínlò, tàbí kí wọn ṣàfihàn Àkóónú Rẹ fún ìdí tí o fi jẹ́ kí Àkóónú rẹ wà nílẹ̀ lórí Àwọn ìpèsè náà láì sanwó fún ọ. Bí o kò bá fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ní irú agbára yẹn, máṣe lo Àwọn ìpèsè náà láti ṣàjọpín Àkóónú Rẹ. O ṣèdúró, o sì fọwọ́sọ̀yà pé, níwọ̀n ìgbàtí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí yóò fi wà, ìwọ ní (ìwọ yóò sì ní) gbogbo ẹ̀tọ́ tó ṣe pàtàkì fún Àkóónú Rẹ tí a ṣàgbérù, tí a fipamọ, tàbí tí a pín lórí tàbí nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè náà àti pé àkójọpọ̀, ìlò, àti ìmúdání Àkóónú Rẹ kì yóò tàpá sí èyíkéyìí òfin tàbí ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn. Microsoft kìí ṣe oníhun, kò ṣàkóso, ṣàrídájú, sanwó fún, fọwọ́ sí tàbí gba ojúṣe yòówù fún Àkóónú Rẹ, a kò sì lè múu dáhùn fún Àkóónú Rẹ tàbí ohun àmúlò tí àwọn ẹlòmíràn gbé lọ sí ayélujára, tí wọ́n fipamọ́ tàbí ṣàjọpín nípasẹ̀ Ìpèsè náà.
- b. Títí dé ibití ó yẹ láti pèsè àwọn Ìpèsè náà fún ọ àti àwọn ẹlòmíràn, láti dáàbòbò ọ́ àti àwọn Ìpèsè náà, àtí láti mú ìlọsíwájú bá àwọn ọjà àti Ìpèsè Microsoft, o fún Microsoft ní ìwé-ẹ̀rí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ káàkiri àgbáyé, láì sí sísan owó oníhun láti lo Àkóónú Rẹ, fún àpẹẹrẹ, láti ṣe ẹ̀dà Àkóónú Rẹ tó wà lórí àwọn Ìpèsè náà, láti dìímú, gbée kiri, tún-un-tò, fihàn àti pín i kiri nípasẹ̀ àwọn irin-iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀. Bí o bá ṣàtẹ̀jáde Àkóónú Rẹ ní àwọn abala Ìpèsè náà níbití òun ti wà káàkiri ayélujára láìsí ìhámọ́, Àkóónú Rẹ lè hàn nínú àwọn àfihàn tàbí ohun àmúlò tí a fi gbé Ìpèsè náà lárugẹ. Lára àwọn Ìpèsè náà ní a ṣàtìlẹyìn fún ìpolówó ọjà. Àwọn ìṣàkóso fún bí Microsoft ṣe nfi ìpolówó ọjà ṣe ti ara ẹni wà ní https://choice.live.com. A kìí lo àwọn ohun tí o bá sọ sínú ímeèlì rẹ, ìtàkùrọ̀sọ, àwọn ìpè fidio tàbí méèlì ohùn, tàbí àwọn àkọsílẹ̀ rẹ, àwọn fọ́tò, tàbí àwọn fáìlì ara ẹni láti fi kọjú ìpolówó ọjà sí ọ. A ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn ìlànà ìpolówó ọjà wa nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀.
- c. Microsoft pèsè fún ọ agbára láti ráyès dátà tó ṣe gbéjáde nípasẹ̀ Pẹpẹ ìkọ̀kọ̀ Microsoft (https://account.microsoft.com/privacy) tàbí àbájáde ohun èlò ẹ̀rọ olùlò, nígbàtí wọ́n bá fàṣẹsí pẹ̀lú Microsoft account rẹ. Dátà tó ṣe gbé jáde ni a lè lò láti fi ṣe ìṣípòpadà sí àwọn ìpèsè olùpèsè ẹnìkẹta. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìhámọ́ dátà tó lè gbàbọ̀dè fún ààbò àwọn ìpèsè tàbí ìwé-ẹ̀rí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ Microsoft. Bí o kò bá lè ṣàgbéjáde dátà rẹ nípasẹ̀ àwọn ìṣe ẹ̀rọ wọ̀nyí, kàn sí Micosoft ní àdírẹ́sì tó wà ní Bí o ṣe lè kàn sí wa abala (https://privacy.microsoft.com/privacystatement#mainhowtocontactusmodule) tàbí nípa lílo fóòmù wẹ́ẹ̀bù wa (https://go.microsoft.com/fwlink/?linkid=2126612).
Òfin Ìṣesí
3. Òfin Ìṣesí. Àkóónú àti isesí wà lọ́wọ́ rẹ nígbàtí o bá n lo Àwọn ìpèsè náà.
- a. Nípa fífaramọ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ò n gbà pé, nígbà tí o bá n lo Àwọn Ìpèsè náà, pẹ̀lú àwọn ìpèsè AI tó ṣe ìpinu, tàbí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ṣíṣe iṣẹ́ fún ra rẹ̀ tàbí pẹ̀lú ìṣe àyípadà ọmọ ènìyàn tí ìpèlé oríṣiríṣi, o ma tẹ̀lé àwọn òfin wọ̀nyí:
- i.Máṣe ṣe nkan tí kò bofin mu, tàbí gbíyànjú láti ṣàwárí tàbí láti pín àkóónú tí kò bofin mu.
- ii. Máṣe lọ́wọ́ nínú ìṣesí yòówù tó nlo àwọn ọmọdé ní ọ̀nà àìtọ́, tó n pa wọ́n lára, tàbí tó n halẹ̀ láti pa wọ́n lára.
- iii. Má fi ọ̀rọ̀ tí a kò fẹ́ tàbí àyédèrú i-meélì ṣọwọ́, tàbí gbìyànju láti sàwárí tàbí pín nkan tó ma n ba ojú òpó jẹ́. Àkọránṣẹ́ àìbèrèfún tàbí ímeèlì púpọ̀, àfiránṣẹ́, àfihàn, àwọn olùbásọ̀rọ̀, SMS (àwọn àkọránṣẹ́), àkọránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tàbí ọ́nà ìbánisọ̀rọ̀ oníná. Ọ̀nà èrú láti gba détà n fi àwọn í-meélì ṣọwọ́ tàbí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ oníná tàbí ọ̀nà èrú àwọn olùgbà tí kò bá òfin mu láti ṣàfihàn ìwífún ti ara ẹní tàbí èyí tó ṣelẹgẹ́, bí, ọ̀rọ̀ aṣínà, déètì ọjọ́ ìbí, Àwọn nọ́mbà Ààbò, àwọn nọ́mbà, nọ́mbà Ìwé ìgbélù, ìwífún káàdì àrọ́pò, ìwífún nípa ètò ìṣúná, tàbí àwọn ìwífún tó ṣẹlẹgé, tàbí láti gba ìráyèsí àkọọ́lẹ̀ tàbí àwọn àkọsílẹ̀, àyọkúrò àwọn àkọsílẹ̀ tàbí àwọn ìwífún tó ṣelẹgẹ́, ànfànì ìsanwó àti/ tàbí ètò ìṣúná. Nkan tó ma n ba ojú òpó jẹ́ ni ìṣe tí wọ́n dásílẹ̀ láti fa ìjàmbà ìmọ̀ ẹ̀rọ, bíi gbígbé àwọn ìṣe tó parí ayédèrú, títo kíkọ̀ jálẹ̀ ìkọlù ìpèsè tàbí ìṣàkóso àṣẹ àti àwọn àpèsè ìdarí.
- iv. Máṣe ṣàfihàn ní gbangba tàbí lo Àwọn Ìpèsè náà láti ṣàwárí tàbí ṣàpínlò àkóónú tàbí àwọn ohun èlò mìíràn tí kò tọ̀nà tàbí ohun ìní (tó kan, fún àpẹrẹ, ìhòhò, bíbá ẹranko lópọ̀, àwòrán oníhòhò, èdè àìdára, àwòrán ìwà ipá, ìṣe ìjàmbá fún ra eni, tàbí iṣẹ́ ọ̀daràn) tàbí Àkóónú Rẹ tàbí ohun àmúlò tí kò faramọ́ àwọn òfin abẹ́lé tàbí àwọn ìlànà.
- v. Máṣe lọ́wọ́ nínú ìṣe tó jẹ́ jìbìtì, irọ́ pípa tabí ṣiṣi ẹnìyàn lọ́nà (àpẹrẹ, píparọ́ bèrè owó, jíjẹ́ orúkọ elòmíràn, ṣiṣe ẹ̀dà ayédèrú ìfowópamọ́sí, ṣíṣe iṣẹ́ tí kò sí, ṣíṣàwárí tàbí pínpín àkóónú 'to jẹ́ pé ẹ̀tàn ni, yiyi Ìpèsè padà lọ́nà tí kò tọ́ lati gba ọ̀pọ̀ tàbí ìpalárà ipò, ìwọ̀n, tàbí àwon ìdásí) tàbí ìrọ́ pípa tàbí ìbanilórúkọ jẹ́.
- vi. Má wá ọ̀nà kúrò nínu ewu ìdènà lórí ìráyè sí, ìlò, tàbí wíwánílẹ̀ Àwọn ìpèsè (àpẹrẹ., gbígbìyànjú láti "sá kúrò nínu ẹ̀wọ̀n" ẹ̀rọ Ọgbọ́n àpilẹ̀rọ tàbí àìfúnláṣe fífá).
- vii. Má bá wọn lọ́wọ́ nínú ìṣe tó ma fa ìjàmbá fún ọ, fún Àwọn ìpèsè, tàbí fún àwọn tókù (àpẹrẹ, títan àrún àìfojúrí ká káàkiri, ṣíṣọ ènìyàn, gbígbìyànjú láti ṣàwárí tàbí pínpín àkóónú tó dójútini, tó burú mọ́ èyàn tàbí lépa àwon tó kù, fífí àwọn apanilayà tàbí àkóónú ìjà lile, sísọ ọ̀rọ̀ ìkórira, tàbí gbígbèrò ìjà fún àwọn tókù).
- viii. Má rúfin tàbí tàpa sófin ètọ́ àwọn tókù (àpẹrẹ., pínpín ẹ̀dà àṣẹ orin àbí ohun èlò tó ti gba ẹ̀dà àṣẹ tí a kò fàṣẹsí, àtúntà tàbí àwon pínpin máàpú Bing, tàbí yíya àwòrán tàbí àwọn ìgbàsílẹ̀ fídíò/àfetígbọ́ àwọn tókù laì gba àṣẹ lọ́wọ́ wọn fún ṣíṣètò ìdámọ̀ ènìyàn nípa lílo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé èni náà/ìwífún tàbí ìdí míràn lórí lílo Àwọn ìpèsè náà).
- ix. Máṣe lọ́wọ́ nínú ohun àmúṣe tó tàpá sí ohun ìkọ̀kọ̀ tàbí àwọn ẹ̀tọ́ ààbò détà àwọn ẹlòmíràn.
- x. Máṣe ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rú àwọn òfin wọ̀nyí.
- Ìwífún díẹ̀ si nípa àwọn òfin wa, ìwọ̀ntúnwọ̀nsí àti ìṣètò ìkaní ní pá àti àwọn àdéhùn ìpèsè kan pàtó wà nílẹ̀ ní aka.ms/trustandsafety.
Lílo Àwọn Ìpèsè & Àtìlẹ́yìn
4. Lílo Àwọn Ìpèsè & Àtìlẹ́yìn.
- a. Àkọọ́lẹ̀ Microsoft. Ìwọ yóò nílò àkọọ́lẹ̀ Microsoft láti wọlé sí ọ̀pọ̀ nínú Àwọn Ìpèsè náà. Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ jẹ́ kí o wọlé sí àwọn ọjà, àyè ayélujára àti àwọn iṣẹ́ ti Microsoft àti àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ Microsoft npèsè.
- i. Ṣíṣẹ̀dá Àkọọ́lẹ̀ kan. O le ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan nípa fíforúkọ sílẹ̀ lóníforíkorí. O gbà láti máṣe lo èyíkéyìí àlàyé tó jẹ́ irọ́, àìpéye tàbí tó ṣi ni lọ́nà nígbàtí o bá n forúkọ sílẹ̀ fún àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ. Nígbà mìíràn, ẹlòmíràn, bíi olùpèsè ìpèsè Ayélujára rẹ, lè pín àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan fún ọ. Bí o bá gba àkọọ́lẹ̀ Microsoft láti ọwọ́ ẹlòmíràn, ẹlòmíràn náà lè ní àwọn àfikún ẹ̀tọ́ kan lórí àkọọ́lẹ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí agbára láti wọlé sí àti láti pa àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ rẹ́. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹwò àwọn àfikún àdéhùn yòówù tí ẹlòmíràn náà pèsè fún ọ, nítorí tí Microsoft kò ní ojúṣe kankan nípa àwọn àfikún àdéhùn wọ̀nyí. Bí o bá ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft lórúkọ ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí òwò tàbí agbanisíṣẹ́ rẹ, ìwọ jẹ́ aṣojú pé o ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti mú àwọn Adéhùn wọnyí pọn dandan fún ẹni náà. O kò le fi àwọn ìwé ẹ̀rí àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ ṣọwọ́ sí olùlò tàbí elòmíràn. Láti dáàbòbo àkọọ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí àwọn àlàyé àti ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé àkọọ́lẹ̀ rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Wàá dáhùn fún gbogbo iṣẹ́-ṣíṣe tó bá wáyé lábẹ́ àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ.
- ii. Àkọọ́lẹ̀ tí o Lò. O gbọ́dọ̀ má a lo àkọọ́lẹ̀ Microsoft láti jẹ́ kí ó lè má a ṣiṣẹ́. Èyí túmọ̀ sí wípé o gbọ́dọ̀ wọlé ó kéré jù ẹ̀kan láàrín ọdún méjì láti tọ́jú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, àti Àwọn Ìpèsè tó jọra, (àyàfi tí kò bá sọ bẹ́ẹ̀), ṣiṣẹ́, àyàfi tí wọ́n bá pèsè ìgbà pípẹ́ nínú ofin iṣẹ́-ṣíṣe Àkọọ́lẹ̀ Microsoft ní https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=2086738 tàbí nínú ìfúnni fún abala tí a sanwó fún nínú Àwọn Ìpèsè náà. Bí o kò bá wọlé ní àsìkò yìí, àwa yóò ríi bí ẹni pé àkọọ́lẹ̀ Microsoft kò ṣiṣẹ́ mọ́, a ó sì múu dópin fún ọ. Jọ̀wọ́ wo abala 4.a.iv.2 fún àtúnbọ̀tán àkọọ́lẹ̀ Microsoft tí a mú dópin. O gbọ́dọ̀ wọlé sí àpótí àgbàwọlé Outlook.com rẹ àti OneDrive rẹ (lọ́tọ̀ọ̀tọ̀), ó kéré, ní ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọdún kan, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò mú àpótí àgbàwọlé Outlook.com rẹ àti OneDrive rẹ dópin fún ọ. Tí a bá fura pé Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ wà lábẹ́ ewu lílò nípa ẹlòmíràn ní ọ̀nà jìbìtì (fún àpẹrẹ, nítorí ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ Àkọọ́lẹ̀ kan), Microsoft le dá Àkọọ́lẹ̀ rẹ dúró fún ìgbà díẹ̀ títí wàá fi le gba olóhun rẹ̀ padà. Bí a bá wo irú ìpàdánù ààbò tí èyí jẹ́, a lè nílò láti mú kí wíwọlé sí lára àwọn Àkóónú Rẹ tàbí sí gbogbo rẹ̀ má lè ṣeé ṣe mọ́. Bí o bá n ní ìṣòro láti wọlé sí àkọọ́lẹ̀ Microsoft, jọ̀wọ́ kàn sí àyè ayélujára yìí. https://go.microsoft.com/fwlink/?LinkId=238656.
- iii. Àwọn Ọmọdé àti Àwọn Àkọọ́lẹ̀. Nípa ṣíṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan tàbí lílo Àwọn ìpèsè, o gbà o sì faramọ́ Àwọn ìfẹnukò o sì gba pé yálà o ti dé ọjọ́ orí "àgbàlagbà" tàbí "ojúṣe òfin" níbí tí o gbé tàbí ibi tí àwọn òbí rẹ gbé tàbí alágbàtọ́ òfin faramọ́ àwọn Ìfẹnukò wọ̀nyí lórúkọ rẹ. Tí o kò bá mọ̀ bóyá o ti dé ọjọ́-orí ẹnití a lè pè ní "àgbàlagbà" tàbí "síṣe ojúṣe òfin" níbití o n gbé, tàbí abala yìí kò yé ọ, jọ̀wọ́ bèrè lọ́wọ́ òbí tàbí alágbàtọ́ rẹ fún ìrànwọ́. Tí o bá jẹ́ òbí tàbí alágbàtọ́ ọmọdé kan tó, ìwọ àti ọmọ rẹ gbà ẹ sì faramọ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí ẹ̀yin sì ni ó ni ojúṣe fún gbogbo ìlò àkọọ́lẹ̀ Microsoft tàbí Àwọn Ìpèsè, pẹ̀lú àwọn ìrajà, yàlá àkọọ́lẹ̀ ọmọdé náà ti wà ní ṣíṣí báyìí tàbí ìwọ yóò ṣẹ̀dá rẹ̀ tóbáyá.
- iv. Pípa Àkọọ́lẹ̀ rẹ dé.
- 1. O lè fagilé Àwọn Ìpèsè kan pàtó tàbí mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin nígbà kugbà àti fún èyíkéyìí èrèdí. Láti mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin, jọ̀wọ́ Ṣàbẹ̀wò sí https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=618278. Bí o bá ní kí a mú àkoole Microsoft rẹ dópin, o lè yàn láti fi sí ipò ìdádúró fún yálà ọjọ́ 30 tàbí 60 bóyá ó lè yí ọkàn rẹ padà. Lẹ́yìn akókò 30- tàbí 60-ọjọ́, àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ ma dópin. Jọ̀wọ́ wo abala 4.a.iv.2 nísàlẹ̀ fún àlàyé lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nígbàtí a bá mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin. Wọlé padà lákòókò ìdádúró díẹ̀ náà yóò mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ má ṣiṣẹ́ padà.
- 2. Tí a bá mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin (yálà nípasẹ̀ ìwọ tàbí àwa), àwọn nkan díẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀. Ní àkọkọ, ẹ̀tọ́ rẹ láti lo àkọọ́lẹ̀ Microsoft fún wíwọlé sí àwọn Ìpèsè náà yóò dópin lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ìkejì, a ó pa Détà tàbí Àkóónú rẹ tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ rẹ́ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ kí a fi ìpinya sáàárín ìwọ àti àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ (àyàfi tí òfin bá ní kí a tọ́jú rẹ̀, kí a dáa padà, tàbí kí a fifún ọ tàbí ẹlòmíràn tí ìwọ yàn). O gbọ́dọ̀ ní ètò àfẹ̀hìntì nígbà gbogbo nítorí tí Microsoft kì yóò lè mú Àkóónú Rẹ tàbí Détà padà lọ́gán tí a bá tí múu dópin. Ìkẹta, o le pàdánù ìráyèsí àgbéjáde tí o ti rà.
- b. Ìwọ̀ntúnọ̀nsí àti Ìkànípá. Ọpọ̀lọpọ́ Àwọn ìpèsè wa tó fàyègbà ọ́ láti takùrọ̀sọ, ṣẹ̀dá, ṣàwárí, àti láti pín àkóónú pẹ̀lú àwọn tó kù ṣe déédé nípa ààbò àwọn ẹ̀rọ láti dáàbòbò Àwọn ìpèsè wa àti àwọn olùlò tókù.
- i. Àwọn Ìlànà Ìmúlò. Òfin Ìsesí Wa ṣe ìdámọ̀ nkan tó jẹ́ èèwọ̀ nígbà tí a bá n lo Àwọn ìpèsè. A lè rí àkóónú àti àwọn ìlànà ìṣesí wa níbí (https://www.microsoft.com/DigitalSafety/policies). Àwon ìpèsè Kan Pàtó ní àfikún àwọn ìlànà àti gbèdéke agbègbè tó jẹ́ lílò fún àwọn olùlò wọn, tó wà nílẹ̀ níbí (https://aka.ms/trustandsafety).
- ii. Jíjábọ́ Ẹdùn ọkàn kan. O lè jábọ̀ àkóónú tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìṣesí tó lè rúfin Òfin Ìṣesí níbí (https://aka.ms/reportconcerns).
- iii. Àtunyẹ̀wò. Níbi tó yẹ, a lè lo àwọn ẹ̀rọ aládáṣiṣẹ́ àti àwon èniyàn láti ṣàtúnyẹ̀wò àkóónú láti dá sípáàmù tí a kófìrí mọ́, àwon kòkòrò ayélùjára, jìbìtì lórí ayélujára, ètò tó ma ṣe ìjàmbá fún ẹ̀rọ, sísá kurò lẹ́wọ̀n, tàbí àwọn àkóónú tàbí ìṣesí tó lè ṣe ni ní ìjambá t bí tí kò bá òfin mu.
- iv. Gbígbòfinró. A ní ẹ̀tó láti kọ àkóónú tó bá kọjá òpin sílẹ̀ lórí ibi ìpamọ́ tabí ìwọ̀n faìlì tí Ìpèsè náà fàyègbà. A lè dínà, ṣàyọkúrò tàbí kọ̀sílẹ̀ láti ṣàfihàn àkóónú tó bá fẹ́ rúfin Òfin Ìṣesí wa tàbí Ìlànà Ìpèsè míràn tàbí tí òfin nílò. Tí o bá rúfin àwọn ìfẹnuò wọ̀nyí tàbí Àwọn Ìlàna (https://aka.ms/trustandsafety), a lè gbé ìgbèsẹ̀ lórí àkọọ́lẹ̀ rẹ. Èyí pẹ̀lú ìkérè ìráyè sí àwọn àbùdá tàbí Àwọn ìpèsè kan pàtó, mímú àkọọ́lé Microsoft rẹ dópin lẹsẹ̀kẹsẹ̀ tàbí dídènà ìfijíṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ (bíi í-meèlì, àpínlò fáìlì tàbí ìfiránṣẹ́ kíá) sí tàbí láti Àwọn Ìpèsè. Ìpadé ìráyèsí rẹ sí Ìpèsè tàbí àkọọ́lẹ̀ lè fa ìpàdánù àwọn ìwé àṣẹ àkóónú, àkóónú tó jẹmọ, àwọn ọmọ ẹgbẹ́, àti àwọn ìyókù àkọọ́lẹ̀ Microsoft tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ náà. Nígbàtí a bá n ṣe àtúnyẹ̀wò ìtàpá sí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò àkóónú láti lè yanjú ìṣòro náà. Ṣùgbọ́n, àwa kò lè ṣàkóso gbogbo Àwọn Ìpèsè náà, a kò sí gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Fún àlàyé si nípa ìwọ̀ntúnwọ̀nsí àti ìgbófinrò ìṣètò (https://www.microsoft.com/DigitalSafety/moderation-and-enforcement), Àwọn ìfẹnukò Ìpèsè kan Pàtó, Àwọn àfikún ̀ìlànà àti ìtọ́sọ́nà (https://www.microsoft.com/DigitalSafety/policies/additional-guidelines), àti àwọn ẹ̀bẹ̀ (https://www.microsoft.com/DigitalSafety/moderation-and-enforcement/appeals), wo https://aka.ms/trustandsafety. Àlàyé nípa ìlànà wà tó jẹ́mọ gbígbà títàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ ẹni ni a lè ri ni ÀWỌN ÀKÍYÈSÍ.
- c. Àwọn Àkọọ́lẹ̀ Ilé-iṣẹ́ tàbí ti Ilé-ẹ̀kọ́. O lè wọlé sí àwọn ìpèsè Microsoft kan pẹ̀lú àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì ilé-iṣẹ́ tàbí ti ilé-ẹ̀kọ́. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o gbà wípé olóhun agbègbè ìkápá náà tó níṣe pẹ̀lú àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ ni a le sọfún nípa wíwà nílẹ̀ ti Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ àti àwọn ìṣalábàápín tí ṣepọ̀ mọ́ọ, darí kí o sì ṣàkóso Àkọọ́lẹ̀ rẹ, kí o sì ráyèsí àti láti ṣiṣẹ́ lórí Dátà rẹ, pẹ̀lú àwọn àkóónú ti ìbánisọ̀rọ̀ àti fáìlì rẹ, àti wípé Microsoft le fitó ẹni tó ni agbègbè ìkápá létí tí Àkọọ́lẹ̀ náà tàbí ti Dátà bá gbọ̀jẹ̀gẹ́. O tún gbà pé ìlò àwọn ìpèsè Microsoft rẹ le wà lábẹ́ àwọn àdéhùn tí Microsoft ní pẹ̀lú rẹ tàbí ilé-iṣẹ́ rẹ àti pé Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí ni a le má ṣàmúlò. Tí o bá ti ní àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan tẹ́lẹ̀ tí o sì n lo iṣẹ́ kan tó yàtọ̀ tàbí àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì ti ilé-ìwé láti ráyèsí Àwọn Ìpèsè tó wà lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, a le tà ọ́ lólonbó láti ṣàfikún àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ láti le tẹ̀síwájú ìráyèsí irú Àwọn Ìpèsè náà.
- d. Àfikún Irinṣẹ́/Àwọn Ètò Détà. Láti lo ọ̀pọ̀ lára àwọn Ìpèsè náà, o nílò àsopọ̀ ayélujára àti/tàbí ètò détà/ẹ̀rọ aláàgbéká. O tún lè nílò àwọn àfikún ẹ̀rọ, bíi àgbékarí, ayàwòrán tàbí gbohùngbohùn. Ìwọ ni ó ni ojúṣe fún pípèsè gbogbo ìsopọ̀, ètò, àti irinṣẹ́ tí a nílò fún lílo Àwọn Ìpèsè náà, àti láti san owó tí (àwọn) olùpèsè àwọn ìsopọ̀, ètò àti irinṣẹ́ rẹ yóò bèèrè fún. Àwọn owó náà jẹ́ àfikún sí iye owó yòówù tí o bá san fún wa fún àwọn Ìpèsè náà, àwa kì yóò sì dá irú owó bẹ́ẹ̀ padà fún ọ. Ṣàyẹ̀wò pẹ̀lú (àwọn) olùpèsè rẹ láti mọ̀ bóyá irú àwọn owó bẹ́ẹ̀ wà tó kàn ọ.
- e. Àwọn Ìwífúnni Ìpèsè. Nígbàtí a bá ní ohun kan láti sọ fún ọ nípa Ìpèsè kan tí o lò, a ó fi àwọn ìfitónilétí Ìpèsè ránṣẹ́ sí ọ. Tí o bá ti fún wa ní àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì tàbí nọ́mbà fóònù rẹ èyí tó ṣepọ̀ mọ́ Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, lẹ́yìn náà a le fi àwọn ìfitónilétí Iṣẹ́ ránṣẹ́ sí ọ nípasẹ̀ í-meèlì tàbí SMS (ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́), pẹ̀lú láti jẹ́rìísí ìdánimọ̀ rẹ kí a tó ṣàkọsílẹ̀ nọ́mbà fóònù alágbèéká rẹ kí o sì jẹ́rìísí àwọn ìrajà rẹ. A tún le fi àwọn ìfitónilétí Ìpèsè ránṣẹ́ sí ọ nípa ọ̀nà míràn (fún àpẹrẹ nípa àwọn ìfiránṣẹ́ inú-àgbéjáde). Iye owó détà tàbí ti àkọránṣẹ́ lè wà fún sísan bí o bá ngba àwọn ìfitónilétí nípasẹ̀ SMS.
- f. Àtìlẹ́yìn. Àtìlẹ́yìn fún díẹ̀ lára Àwọn Ìpèsè wà nílẹ̀ ní https://support.microsoft.com tí àwọn ìfẹnukò wọ̀nyí darí, Àwọn ìpèsè kan pàtó lè fúnni ní àfikún ìránlọ́wọ́ oníbàárà tàbí èyí tó yàtọ̀, tó wà lábẹ́ àwọn ìfẹnukò àfikún. Ó ṣeé ṣe kí àtìlẹ́yìn má wà fún àkọ́wò tàbí ẹ̀yà beta ti àwọn àbùdá tàbí Ìpèsè. Wíwánílẹ̀ Àtìlẹ́yìn lè pé oríṣiríṣi tó dá lórí ìpele ìgbésí ayé àbájáde Ìwọ níláti ní ìpéye àti (àwọn Ìpèsè Àṣe tó péye tó bá ohun tí wọ́n bèrè fún tó kéré jù fún àtìlẹ́yìn tí wọ́n ṣàpèjúwé ní Ìgbésí Ayé Microsoft (https://learn.microsoft.com/lifecycle). Àwọn Ìpèsè náà lè má wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn iṣẹ́ tí àwọn ẹlòmíràn npèsè, o ni ojúṣe láti mọ fúnra re àwọn ohun tó yẹ fún bíbáramu.
- g. Mímú Ìpèsè rẹ Dópin. Tí a bá fagilé àwọn Ìpèsè rẹ (yálà nípasẹ̀ ìwọ tàbí àwa), Ní àkọkọ ẹ̀tọ́ rẹ láti wọlé sí àwọn Ìpèsè náà yóò dópin lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìgbaniláàyè rẹ fún ẹ̀yà àìrídìmú tó níí ṣe pẹ̀lú Ìpèsè náà yóò dópin. Ìkejì, a ó pa Détà tàbí Àkóónú rẹ tó níṣe pẹ̀lú Ìpèsè rẹ rẹ́ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ kí a fi ìpinya sáàárín ìwọ àti àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ (àyàfi tí òfin bá ní kí a tọ́jú rẹ̀, kí a dáa padà, tàbí kí a fifún ọ tàbí ẹlòmíràn tí ìwọ yàn). Nítorí èyí, ó ṣeé ṣe kí ìwọ má lè wọlé sí àwọn Ìpèsè náà yòówù mọ́ (tàbí Àkóónú Rẹ tí o fipamọ́ sórí àwọn Ìpèsè wọ̀nyí). O gbọ́dọ̀ ní ètò àbọ̀ábá láti ìgbà dé ìgbà. Ìkẹta, o le pàdánù ìráyèsí àgbéjáde tí o ti rà. Bí o bá ti fagilé àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, tí o kò sì ní Microsoft mìíràn láti gbà wọlé sí àwọn Ìpèsè náà, a lè fagilé àwọn Ìpèsè rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Lílo Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnìkẹta
5. Lílo Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnìkẹta. Àwọn Ìpèsè náà le gbà ọ́ láàyè láti ráyèsí tàbí gba àwọn àgbéjáde, àwọn iṣẹ́, àwọn ojú-òpó wẹ́ẹ̀bù, àwọn ojú òpó ìsopọ̀, àkóónú, ohun ìní, àwọn ayò, ọgbọ́n-inú, àkójọpọ̀, bọ́ọ̀tì tàbí àwọn ìfilọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹta (àwọn ilé-iṣẹ́ tàbí àwọn ènìyàn tí kì í ṣe Microsoft) ("Àwọn Ìpèsè àti Ìlò-ẹ̀rọ Ẹnikẹta"). Púpọ̀ nínú àwọn Iṣẹ́ wa bákan náà máa ń jẹ́ kí o lè ṣàwárí, béèrè fún, tàbí ní àṣepọ̀ pẹ̀lú Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́, ó sì lè gbà ọ́ láàyè tàbí nílò kí o pín àwọn Àkóónú àti Dátà Rẹ pẹ̀lú irú Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Á̀wọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta bẹ́ẹ̀, o sì ní òye pé nípa lílo Àwọn Iṣẹ́ wa, ò ń darí wọn láti mu Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Á̀wọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta wà nílẹ̀ fún ọ. Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta náà lè gbà ọ́ láàyè láti Fi Àkóónú tàbí Dátà rẹ pamọ́ pẹ̀lú olùgbéjáde, olùpèsè tàbí aṣètò Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta náà. Àwọn Ìfilọ́lẹ̀ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹlòmíràn náà le fún ọ ni òfin ìpamọ́ tàbí nílò kí o gba àwọn ìfẹnukò wọn kí o tó le ṣe ìfilọ́lẹ̀ tàbí lo Àwọn Ìfilọ́lẹ̀ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta náà. Wo abala 13.b fún àwọn àfikún ìfẹnukò fún àwọn Ìlò-ẹ̀rọ tí a gbà láti inú àwọn Ibùdó Ojú-ọjà kan èyí tí Microsoft tàbí àwọn alásopọ̀ rẹ̀ ni tàbí tí wọn ń ṣàkóso (ó wà lára rẹ̀, ṣùgbọ́n kò mọ ní Ibùdó Ojú-ọjà Office, Ibùdó Ojú-ọjà Microsoft lórí Xbox àti Ibùdó Ojú-ọjà Microsoft lórí Windows nìkan. O gbọ́dọ̀ ṣàtúngbéyẹ̀wò àwọn òfin ìpamọ́ àti àwíyé ẹnìkẹta náà kí o tó gbà, ṣàmúlò, bèrè, tàbí so Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ pọ̀ mọ́ Ìfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹnìkẹta. Èyíkéyìí àwíyé ẹnìkẹta kò ṣàtúnṣe Àwọn àwíyé wọ̀nyìí. Microsoft kò fún ọ ní ìwé-ẹ̀rí fún ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ kankan gẹ́gẹ́ bí ara Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta yòówù. O gbà láti gbé gbogbo ewu àti ojúṣe tó lè wáyé nípasẹ̀ ìṣàmúlò Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ àwọn Ẹnìkẹta rẹ wọ̀nyìí, àti pé Microsoft kò ní dúró fún àwọn ìṣòro yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ ìṣàmúlò rẹ fún wọn. Microsoft kò ní dúró tàbí dáhùn fún ọ tàbí àwọn mìíràn fún àlàyé tàbí àwọn iṣẹ́ tí Àwọn Ìfilọ́lẹ̀ àtí Àwọn Iṣẹ́ Ẹnikẹta bá pèsè.
Wíwà Iṣẹ́
6. Wíwà Iṣẹ́.
- a. Àwọn Iṣẹ́ náà, àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ àwọn Ẹlòmíràn, tàbí àwọn ohun àmúlò tàbí ọjà tí a fifúnni nípasẹ̀ àwọn Iṣẹ́ náà lè máṣe wà láti ìgbà dé ìgbà, a lè lo ìdíwọ̀n ní pípèsè wọn, wọn sì lè yàtọ láti agbègbè sí agbègbè tàbí ẹ̀rọ sí ẹ̀rọ. Bí o bá yí ipò tó níí ṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ padà, o lè nílò láti ṣe àtúnrà àwọn ohun àmúlò àti ohun èlò kan tó ti wà fún ọ tẹ́lẹ̀ rí, àti tí o sanwó fún ní ibití o wà tẹ́lẹ̀. O gbà láti máṣe wọlé sí tàbí lo ohun àmúlò tàbí àwọn Iṣẹ́ tí kò bá òfin mu tàbí tí kò sí ìwé-àṣẹ fún lílò wọn ní orílẹ̀-èdè tí o tí nwọlé sí tàbí lo irú ohun àmúlò tàbi àwọn Iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, tàbí láti fi ipò tàbí ààmì ìdánimọ̀ rẹ pamọ́ tàbí kí o parọ́ nípa rẹ̀, láti lè wọlé sí tàbí lo irú ohun àmúlò tàbí àwọn Iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.
- b. Àwa ngbìyànjú láti mú kí Iṣẹ́ náà má a lọ nígbà gbogbo; ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn iṣẹ́ orí ayélujára a má a ní ìdádúró ẹ̀ẹ̀kọ̀kan, Microsoft kò sì ní ohunkóhun láti dáhùn fún ìdádúró tàbí àdánù yòówù tí o lè rí nípasẹ̀ èyí. Bí ìdádúró bá wáyé, o lè má lè mú Àkóónú tàbí Détà Rẹ tí o fipamọ́ padà mọ́. A gbà ọ́ níyànjú pé kí o má a ṣe àbọ̀ábá Àkóónú àti Détà tí o fipamọ́ sórí Àwọn Ìpèsè tàbí ibi ìpamọ́ náà láti ìgbà dé ìgbà nípa lílo Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta.
Àwọn àfikún sí Àwọn Ìpèsè tàbí Ẹ̀yà àìrídimú, àti Àwọn Àyípadà sí Ìfẹnukò Wọ̀nyí
7. Àfikún sí Àwọn Ìpèsè tàbí Ẹ̀yà Àìrídìmú, àti Àwọn Àyípadà sí Àwọn Àdéhùn Wọ̀nyí.
- a. Àwa lè yí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí padà nígbà yòówù, àwa yóò sì sọ fún ọ nígbàtí a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Lílò àwọn Iṣẹ́ náà lẹ́yìn tí àwọn àyípadà náà bá ti bẹ̀rẹ̀ túmọ̀ sí pé o faramọ́ àwọn àdéhùn titun náà. Tí o kò bá faramọ́ àwọn àdéhùn titun náà, o gbọ́dọ̀ dẹ́kun lílo Àwọn Ìpèsè náà, mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin àti, tí o bá jẹ́ òbí tàbí alágbàtọ́, ran ọmọdé rẹ lọ́wọ́ láti mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ̀ dópin.
- b. Nígbà mìíràn ìwọ yóò nílò àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú láti lè tẹ̀síwájú ní lílo àwọn Iṣẹ́ náà. A lè ṣàyẹ̀wò oríṣi ẹ̀yà àìrídìmú àti ti àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú tí o gbé wálẹ̀ láti ayélujára tàbí ti àwọn àyípadà sí ìṣètò ẹ̀rọ rẹ, láìfọwọ́yí. A tún lè ní kí o mú ẹ̀yà àìrídìmú dójú ìwọ̀n láti lè tẹ̀síwájú ní lílo àwọn Iṣẹ́ náà. Irú àwọn ìmúdójúìwọ̀n bẹ́ẹ̀ wà lábẹ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àfi bí àwọn àdéhùn míràn bá tí bá àwọn ìmúdójúìwọ̀n náà wá, nígbà náà, tí àwọn àdéhùn míìràn náà yóò ní ipa. Kìíṣe dandan fún Microsoft láti mú kí àfikún yòówù wà, kò sì sí ìdánilójú pé àwa yóò ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀yà ìlànà-ètò náà, èyítí o rà ẹ̀yà àìrídìmú, àwọn ìfilọ́lẹ̀, àkóónú tàbí àwọn àgbéjáde mìíràn náà fún, tàbí tí o gbà ìgbaniláàyè fún. Irú àwọn ìmúdójúìwọ̀n bẹ́ẹ̀ lè má wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí iṣẹ́ tí àwọn ẹlòmíràn npèsè. O lè gba fífaramọ́ rẹ fún àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú lọ́jọ́ iwájú padà nígbà yòówù nípa yíyọ ẹ̀yà àìrídìmú náà kúrò lórí ẹ̀rọ.
- c. Ní àfikún, àwọn àsìkò kan lè wà tí a nílò láti mú àwọn àfidámọ̀ inú àwọn Iṣẹ́ náà kan kúrò tàbí kí a yí wọn padà, tàbí kí a dẹ́kun pípèsè Iṣẹ́ kan tàbí wíwọlé sí àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ àwọn Ẹlòmíràn lápapo. Àfi títí dé ibití òfin tó yẹ bèèrè dé, àwa kò ní ojúṣe kankan láti pèsè àtún-gbéwálẹ̀ tàbí rírọ́pò ohun àmúlò yòówù, àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà (tí a sọ àsọyé nípa rẹ̀ ní abala 13.i), tàbí àwọn ohun èlò tí o rà tẹ́lẹ̀ rí. A lè ṣe àgbéjáde àwọn Ìpèsè náà tàbí àwọn àfidámọ̀ wọn nínú ẹ̀yà àkọ́wò tàbí beta, èyítí ó le má ṣiṣẹ́ dáradára tàbí ní ọ̀nà kan náà ti ẹ̀yà tí a gbéjáde kẹ́yìn yóò fi ṣiṣẹ́.
- d. Kí ìwọ báa lè ṣàmúlò ohun èlò tí a dáàbòbò pẹ̀lú ìṣàkóso àwọn ètẹ́ díjítà (DRM), bíí àwọn orin kan, ṣeré, fíìmù, ìwé àti púpọ̀ si, ẹ̀yà àìrídìmú DRM lè kàn sí apèsè ẹ̀tọ́ oníforíkorí tìkálárarẹ̀, sí o gba ẹ̀dà fáìlì àwọn àfikún DRM sílẹ̀, kí ó sì ṣàgbékalẹ̀ wọn.
Ìgbaniláyè Ẹ̀yà àìrídimú
8. Ìwé-Àṣẹ Ẹ̀yà Àìrídìmú. Àfi bí ó bá wá pẹ̀lú àdéhùn ìwé-àṣẹ Microsoft ọ̀tọ̀ (fún àpẹẹrẹ, bí o bá nlo ohun èlò Microsoft tó jẹ́ ara Windows, nígbà náà, àwọn Àdéhùn Ìwé-àṣẹ Ẹ̀yà àìrídìmú Microsoft fún Ètò Ìpìlẹ Kọmputa Windows ni ó ndarí irú ẹ̀yà àìrídìmú bẹ́ẹ̀), ẹ̀yà àìrídìmú yòówù tí àwa bá pèsè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ara àwọn Iṣẹ́ náà wà lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Àwọn àtòjọ ètò tí a gbà nípasẹ̀ Ìbi ìpamọ́ kan tí Microsoft ni tàbí ṣàkóso tàbí àwọn tó sopapọ̀ mọ (pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò pin sí Office Store, Microsoft Store lórí Windows àti Microsoft Store lórí Xbox) wà ní abala 13.b.i nísàlẹ̀.
- a. Bí o bá tẹ̀lé àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, a fún ọ ní ẹ̀tọ́ láti lò àti láti fi ẹ̀dà ẹ̀yà àìrídìmú náà kanṣoṣo sórí ẹ̀rọ fún ẹ̀rọ kọ̀ọ̀kan káàkiri àgbáyé fún ìmúlò ẹnìkanṣoṣo nígbà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ara ìmúlò rẹ fún Iṣẹ́ náà. Fún àwọn ohun èlò kan, irú ẹ̀yà àìrídìmú bẹ́ẹ̀ ni a lè kọ́kọ́ ṣàgbékalẹ̀ fún ìlò àdáni, àìfiṣòwò rẹ ti Àwọn Ìpèsè náà. Ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àyè ayélujára tó jẹ́ ara Iṣẹ́ náà lè ní kóòdù ẹlòmíràn nínú. Àwọn ìtọ́sọ́nà tàbí kóòdù àwọn ẹlòmíràn, èyítí ó ní àsopọ̀ pẹ̀lú tàbí tí a tọ́ka sí láti inú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àyé ayélujára náà, ni a fún ọ ní ìwé-àṣẹ fún láti ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn tó ni irú kóòdù bẹ́ẹ̀, kìí ṣe láti ọwọ́ Microsoft. Àwọn àkíyèsi, bí ó bá wà, fún kóòdù àwọn ẹlòmíràn náà ní a fi sínú rẹ fún àlàyé nìkan.
- b. A fún ọ ní ìwé-àṣẹ fún ẹ̀yà àìrídìmú náà ni, a kò tàá, Microsoft sì ni ó ni gbogbo ẹ̀tọ́ sí àwọn ẹ̀yà àìrídìmú náà, èyítí Microsoft kò fifún ni tààrà lábẹ́ àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ náà, yálà nípasẹ̀ èrò tí a mú jáde nínú ohun tí a kò fẹnusọ, nípasẹ̀ àìlè yí èrò tí a fẹ́ kí ohun tí a kò fẹnusọ mú jáde padà, tàbí lọ́nà mìíràn. Ìwé-àṣẹ yìí kò fún ọ ní ẹ̀tọ́ yòówù lati, o kò sì gbọdọ̀:
- i. yípo tàbí rékọjá àwọn ìlànà ìdáàbòbò nípasẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ tó wà nínú tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn Iṣẹ́ náà;
- ii. túká, tú palẹ̀, yọ kóòdù rẹ̀ kúrò, wọlé sínú rẹ̀ lọ́nà àìtọ́, jíi wò, lòó lọ́nà àìtọ́, tàbí tún iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tò nínú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí abala mìíràn lára àwọn Iṣẹ́ náà tó wà nínú tàbí tó ṣeé wọlé sí nípasẹ̀ àwọn Iṣẹ́ náà, àfi àti títí dé ibití òfin ẹ̀tọ́ ọjà-títà bá gba ni láàyè ní ṣiṣẹ bẹ́ẹ̀ dé;
- iii. ya àwọn àkóónú inú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn Iṣẹ́ náà sọ́tọ̀ fún ìmúlò lórí àwọn oríṣiríṣi ẹ̀rọ;
- iv. ṣe àgbéjáde, dàkọ, yá ni fún èrèdí owó, fifún ni fún ìgbà díẹ̀, tà, gbée lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, gbée wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn, pín kiri, tàbí jẹ́ kí ẹlòmíràn lo ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn Iṣẹ́ náà, àfi bí Microsoft bá fún ọ ní àṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀;
- v. fi ẹ̀yà àìrídìmú náà, ìwé-ẹrí ẹ̀yà àìrídìmú náà yòówù, tàbí ẹ̀tọ́ yòówù láti wọlé sí tàbí láti lo àwọn Iṣẹ́ náà fún ẹlòmíràn;
- vi. lo àwọn Ìṣẹ́ náà lọ́nàkọnà tí a kò fún ni ní àṣẹ láti lòó, èyí tó lè dí ìmúlò ẹlòmíràn lọ́wọ́ tàbí kí o wọlé sí iṣẹ́ yòówù, détà, àkọọ́lẹ̀, tàbí nẹ́tíwọọ̀kì, lọ́nàkọnà;
- vii. jẹ́ kò ráyèsí Àwọn ìpèsè tàbí ṣàtúnṣe èyíkèyí ohun èlò tí Microsoft fún láṣẹ (fún àpẹrẹ, Àwọn ohun èlò Xbox, Microsoft Surface, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) nípasẹ̀ àtòjọ ètò tí a kò fún láṣẹ.
Àwọn Àdéhùn Ìsanwó
9. Àwọn Àdéhùn Ìsanwó. Bí o bá ra Iṣẹ́ kan, nígbà náà, àwọn àdéhùn owó sísan wọ̀nyí kan ọjà rírà rẹ, ìwọ sì faramọ́ wọn.
- a. Owó sísan. Bí owó kan bá wà tó níí ṣe pẹ̀lú abala àwọn Iṣẹ́ náà kan; o gbà láti san owó náà pẹ̀lú irú owó tí a filélẹ̀. Iye owó tí a kọ sílẹ̀ fún àwọn Iṣẹ́ náà kò kan gbogbo àwọn owó ìlú tó yẹ fún sísan àti ìyàtọ̀ tó wà nínú pàṣípààrọ̀ owó, àfi bí a bá sọ ohun tó yàtọ̀ sí èyí. Àwọn owó-orí tó yẹ wà lára gbogbo iye owó tí a n san fún àwọn ọjà Skype tí à nsanwó fún, àfi bí a bá kọ ohun mìíràn nípa èyí. Ìwọ nìkan ni ó ni ojúṣe fún sísan irú àwọn owó ìlú bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn owó mìíràn. Skype n ṣírò owó-orí bí ó ti dá lórí àdírẹ́ẹ̀sì ibi tí o n gbé tó níṣe pẹ̀lú àlàyé ìdíyelé rẹ. Ojúṣe rẹ ni láti ṣàrídájú pé àdírẹ́ẹ̀sì yìí kójú òṣùwọ̀n ó sì péye. Àyàfi fún àwọn àgbéjáde Skype, owó-orí ni a n ṣírò bí ó ti dá lórí ibi tí o wà ní àkókò tí a ṣàkọsílẹ̀ àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ àyàfi tí òfin abẹ́lé bá ní kí a ṣírò ní ọ̀nà míràn. Podremos suspender o cancelar los Servicios si no recibimos puntualmente de usted la totalidad del pago. Ìdádúró tàbí ìfagilé Iṣẹ́ náà nítorí àìsan lè fa pípàdánù ànfàní àti wọlé sí àti láti lo àkọọ́lẹ̀ rẹ àti àkóónú inú rẹ̀. Sísopọ̀ mọ́ Íntánẹ́ẹ̀tì nípasẹ̀ alásopọ̀ àdáni tàbí tí ilé-iṣẹ́ míràn tó bo ibi tí o wà mọ́lẹ̀ le ṣokùnfà kí àwọn ìdíyelé yàtọ̀ sí àwọn tó farahàn fún ibi tí o wà gangan. Àwọn ìbánidòwòpọ̀ kan lè nílò ìṣàyípadà owó ilẹ̀ òkèèrè tàbí kí wọ́n nílò iṣẹ́ ṣíṣe síwájú síi ní orílẹ̀-èdè mìíràn, èyí sì dá lórí ipò ibití ìwọ wà. Ilé ìfowópamọ́ rẹ lè bèèrè fún àfikún owó fún àwọn iṣẹ́ náà bí o bá lo káàdì dẹ́bíìtì tàbí kírẹ́díìtì. Jọ̀wọ́ kàn sí ilé ìfowópamọ́ rẹ fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.
- b. Àkọọ́lẹ̀ Ìdíyelé Rẹ. Làti san owó fún Iṣẹ́ kan, àwa yóò ní kí o pèsè ìlànà owó sísan kan nígbàtí ìwọ nforúkọsílẹ fún Iṣẹ́ náà. Fún gbogbo Iṣẹ́ yàtọ̀ sí Skype, o le ráyèsí kí o sì yí àlàyé ìdíyelé rẹ padà àti ìlànà ìsanwó lórí Ojúlé wẹ́ẹ̀bù ìṣàkóso àkọọ́lẹ̀ Microsoft (https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=618281) àti fún ẹ̀yà àìrídìmú Skype àti àwọn àgbéjáde nípa wíwọlé sínú ààyè ìwọlé àkọọ́lẹ̀rẹ ní https://skype.com/go/myaccount. Ní àfikún, o gbà láti gba Microsoft láàyè láti lo àlàyé àkọọ́lẹ̀ yòówù tí a mú dójú ìwọ̀n, tó níí ṣe pẹ̀lú ìlànà owó sísan tí o yàn àti tí ilé-ìfowópamọ́ rẹ tàbí nẹtiwọki owó sísan tó kàn bá pèsè. O gbà láti tètè mú àkọọ́lẹ̀ rẹ àti àwọn àlàyé rẹ mìíràn dójú ìwọ̀n, èyí sì kan àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ àti àlàyé nípa ìlànà owó-sísan rẹ, kí a bá a lè parí iṣẹ́ lórí ìbánidòwòpọ̀ rẹ, kí a sì kàn sí ọ bí ó ti yẹ nípa ìbánidòwòpọ̀ rẹ. Àwọn àyípadà tí a bá ṣe sí àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ kì yóò kan iye owó tí a ó fi rànṣẹ sí àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ, kí a tó lè ṣiṣẹ lórí àwọn àyípada rẹ sí àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ.
- c. Ìdíyelé. Nípa pípèsè ìlànà ìsanwó fún Microsoft, o (i) ṣojú pé o ní àṣẹ láti lo ìlànà ìsanwó náà tí o pèsè àti pé èyíkéyìí àlàyé ìsanwó tí o pèsè jẹ́ òtítọ́ àti pé ó péye; (ii) fún Microsoft ní àṣẹ láti díyelé ọ fún Àwọn Ìpèsè tàbí àkóónú tó wà nílẹ̀ nípa lílo ìlànà ìsanwó rẹ; àti (iii) fún Microsoft ní àṣẹ láti díyelé ọ fún èyíkéyìí ẹ̀yà tí a sanwó fún lára Àwọn Ìpèsè náà tí o yàn láti forúkọ sílẹ̀ fún tàbí lò ní ìwọ̀n ìgbà tí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà lójú iṣẹ́. Àwa lè díyelé ọ (a) ṣáájú ohun tí o fẹ́ rà; (b) ní àkókò ọjà-rírà; (c) lọ́gán lẹ́yìn ọjà-rírà; (d) láti ìgbà dé ìgbà fún àwọn Iṣẹ́ tí a nṣe aláàbápín fún. Bákan náà a tún lè díyelé ọ tó iye owó tí o ti fọwọ́ sí, àwa yóò sì sọ fún ọ ṣáájú iye owó yòówù tí èyí jẹ́ fún àwọn Iṣẹ́ tí ò nṣe aláàbápín fún. Àwa lè díyelé ọ nígbà kan náà fún iye àkókò ìdíleyé ìṣáájú tó ju ọ̀kan lọ fún àwọn owó tí a kò tètè ṣiṣẹ lé lórí.
- d. Owó Sísan Láti Ìgbà Dé Ìgbà. Nígbàtí o bá ra Àwọn Ìpèsè náà lórí ìṣalábàápín (fún àpẹrẹ, oṣoṣù, ní gbogbo oṣù 3 tàbí ọdọdún), o gbà pé o n fọwọ́sí ìsanwó àsantúnsan, àti pé a ó sanwó fún Microsoft nípasẹ̀ ìlànà náà àti ìgbà àsantúnsan tí o ti faramọ́, títí a ó fi mú ìṣalábàápín fún Ìpèsè náà dópin nípasẹ̀ rẹ tàbí nípasẹ̀ Microsoft. O gbọ́dọ̀ fagilé Àwọn Iṣẹ́ rẹ ṣáájú déètì ìdíyelé tókàn láti dẹ́kun sísanwó láti tẹ̀síwájú Àwọn Iṣẹ́ rẹ. A ó pèsè àwọn ìtọ́ni fún ọ lórí bí o ti le fagilé Àwọn Iṣẹ́ rẹ. Nípa fífi ọwọ́ sí ìsanwó àṣantúnsan, o n fún Microsoft ní àṣẹ láti ṣiṣẹ́ lórí ìsanwó náà yálà bíi ìsanwó gbèsè tàbí ìfowó ránṣẹ́, tàbí sọ̀wédowó orí ẹ̀rọ láti ibi àkọọ́lẹ̀ rẹ tí o yàn (fún Automated Clearing House tàbí ìsanwó tójọra), tàbí bí ìdíyelé sí àkọọ́lẹ̀ rẹ tí o yàn (fún káàdì ìsanwó tàbí ìsanwó tójọra) (lápapọ̀, "Àwọn Ìsanwó Orí-ẹ̀rọ"). Owó ìṣalábàápín ni a máa n yọ ṣáájú ìgbà ìṣalábàápín tí o bèrè. Tí a bá dá èyíkéyìí owó padà ní àìsan tàbí ti èyíkéyìí káàdì ìsanwó ìdúnàádúrà tójọra bá padà tàbí di sísẹ́, Microsoft tàbí àwọn olùpèsè iṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ láti gba èyíkéyìí wúnrẹ̀n tí a dá padà, ìkọ̀sílẹ̀ tàbí àìtó owó sísan kí a sì ṣiṣẹ́ lórí irú ìsanwó bẹ́ẹ̀ bíi Ìsanwó Orí-ẹ̀rọ.
- e. Àwọn Àṣìṣe àti Gbólóhùn Orí Ayélujára. Fún gbogbo Iṣẹ́ yàtọ̀ sí Skype, Microsoft yóò pèsè gbólóhùn ìdíyelé orí ayélujára fún ọ lórí Ojúlé wẹ́ẹ̀bù ìṣàkóso àkọọ́lẹ̀ Microsoft (https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=618282), Ojúlé wẹ́ẹ̀bù ìṣàkóso àkọọ́lẹ̀ Microsoft, níbití o ti le wò kí o sì tẹ gbólóhùn rẹ jáde. Fún Skype, o le ráyèsí ohun àkọsílẹ̀ rẹ lóníforíkorí nípa wíwọlé sínú àkọọ́lẹ̀ rẹ ní www.skype.com (https://www.skype.com). Èyí nìkan ní àlàyé owó tí àwa npèsè. Bí a bá ṣe àṣìṣe lórí ìdíyelé rẹ, o gbọdọ sọ fún wa láàárín ọjọ́ 90 lẹ́yìn tí aṣìṣe náà kọ́kọ́ hàn lórí ìdíyelé rẹ. Àwa yóò sì ṣe ìwádìí lọ́gàn nípa ìdíyelé náà. Bí o kò bá sọ fún wa láàárín àkókò náà, o yọ wá kúrò nínú gbogbo ojúṣe àti ẹ̀sùn àdánù tó lè wáyé nípasẹ̀ àṣìṣe náà, àwa kì yóò sì ní láti ṣe àtúnṣe sí àṣìṣe náà tàbí kí a san àsanpadà, àfi bí òfin bá ní kí a ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Microsoft bá ti rí àṣìṣe ìdíyelé kan, àwa yóò ṣàtúnṣe sí àṣìṣe náà láàárín ọjọ́ 90. Ìlànà yìí kò kan ẹ̀tọ́ yòówù lábẹ́ òfin tó lè ní ipa.
- f. Òfin Owó Àsanpadà. Àfi bí òfin kò bá tàbí ìpèsè Iṣẹ́ kan pàtó ti ìfúni ìpèsè, gbogbo ọjà-rírà ohun àṣeparí, kò sì sí àsanpadà. Bí o bá gbàgbọ́ pé Microsoft ti ṣe àṣìṣe ní dídíyelé ọ, o gbọ́dọ̀ kàn sí wa láàárín ọjọ́ 90 tí ìdíyelé náà wáyé. A kì yóò san àsanpadà kankan fún ìdíyelé tó bá ti ju ọjọ́ 90 lọ, àfi bí òfin bá ní kí a ṣe bẹ́ẹ̀. À n ṣóra sí ẹ̀tọ́ láti san ìdápadà tàbí kírẹ́dítì ní ọwa ara wa àyàfi tí òfin kò bá sọ bẹ́ẹ. Bí a bá san àsanpadà tàbí gbèsè, àwa kò sí lábẹ́ ojúṣe kankan láti san irú àsanpadà bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Ìlànà àsanpadà yìí kò kan ẹ̀tọ́ yòówù lábẹ́ òfin tó lè ní ipa. Fún àlàyé síwájú síi nípa àsanpadà, jọ̀wọ́ kàn sí àkọlé ìrànlọ́wọ́ wa (https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=618283). Tí o bá gbé ní Taiwan tàbí Israel, jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí pé ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣe Ìdáàbòbò Olúbárà àti àwọn ìlànà, gbogbo ìrajà tó níṣe pẹ̀lú àkóónú dígítà tí a pèsè nípasẹ̀ ìpèsè àìfọwọ́kàn/ lóníforíkorí jẹ́ kó ṣe dápadà nígbàtí àkóónú bẹ́ẹ̀ tàbí ìpèsè bẹ́ẹ̀ bá wà lóníforíkorí. O kò ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè fún àkókò ìsinmi yòówù tàbí àsanpadà yòówù.
- g. Fífagilé Àwọn Iṣẹ́ náà. O lè fagilé Iṣẹ́ kan nígbà yòówù, pẹ̀lú tàbí láìsí ìdí. Fífagilé Àwọn Iṣẹ́ tí a sanwó fún dẹ́kun ìdíyelé ọjọ́ wájú láti tẹ̀síwájú Iṣẹ́ náà. Láti fagilé Ìpèsè kan àti láti bèèrè fún àsanpadà, bí o bá ní ẹ̀tọ́ sí ọ̀kan, kàn sí àyè ayélujára ìṣàkóso àkọọ́lẹ̀ Microsoft. Fún Skype, jọ̀wọ́ parí àwọn ohun tó wà lórí Fọ́ọ̀mù Ìyọraẹnikúrò nípa lílo àlàyé tí a pèsè níbí (https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=618286). O gbọ́dọ̀ padà sí ìfilọ̀ tó ṣàlàyé Àwọn Ìpèsè náà, nítorí (i) o lè má gba owó àsanpadà ní àkókò ìfagilé; (ii) ó lè jẹ́ ojúṣe rẹ láti san owó ìdíyelé ìfagilé; (iii) ó lè jẹ́ ojúṣe rẹ láti san gbogbo ìdíyelé tí a ṣe sínú àkọọ́lẹ̀ ìdíyelé rẹ fún Àwọn Ìpèsè náà ṣáájú ọjọ́ ìfagilé; àti (iv) o lè pàdánù ìráyèsí àti ìlò àkọọ́lẹ̀ rẹ nígbàtí o bá fagilé Àwọn ìpèsè náà; tàbí tí o bá n gbé ní ilú Taiwan tàbí Israel, (v) o lè gba owó àsanpadà tó bá iye owó tí o san fún Ìpèsè kan tí a kò lò dọ́gba, a ó sì ṣírò èyí ní àkókò ìfagilé. Tí o bá gbé ní ìlú Israel o lè fí èyíkéyí ọ̀nà tí a kọ sílẹ̀ paárẹ̀ lóri https://support.microsoft.com/help/4027815. Jọ̀wọ́ kàn sí aṣojú Microsoft nípasẹ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti gba àsanpadà tí o bá yẹ fun. Àwa yóò ṣètò Détà rẹ bí a ti ṣàlàyé lókè yìí ní abala 4. Bí o bá fagilée, wíwọlé rẹ sínú Iṣẹ́ náà yóò parí ní òpin àkókò Iṣẹ́ rẹ tó nlọ lọ́wọ́ tàbí, bí a bá má a ndíyelé àkọọ́lẹ̀ rẹ láti ìgbà dé ìgbà, ní òpin àkókò tí o ṣe ìfagilé náà. Tí o bá sọ pé o fẹ́ ìdápadà tàbí ìsanwópadà pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ rẹ fún ìsanwó Àwọn ìpèsè, a ma fẹ́ ko fagile ní déètì tí o kọ́kọ́ sanwó, o sì ma fún wa ní àṣẹ láti fagilé ìpèsè rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àti/ tàbí dá èyíkèyí àkóónú padà tí a pèsè fún ọ tí ó rópò irú ìsanwó bẹ́ẹ̀.
- h. Àwọn Ìfúnni Ìgbà Ìdánwò. Tí o bá n kópa ninú èyíkéyìí ìfúnni ìgbà ìdánwò, a le sọ fún ọ kí o fagilé (àwọn) Iṣẹ́ ìdánwò láàrín àkókò tí a sọ fún ọ nígbàtí o gba ìfúnni náà láti le dènà dídíyelé láti tẹ̀síwájú (àwọn) Iṣẹ́ náà lópin ìgbà ìdánwò náà. Fún àwọn ìfúni àkókò ìtọ́wò kan pàtó, a lè bèrè fún ìṣọdọ̀tun aládàṣe láti jẹ́ kó tàn.
- i. Àwọn Ìfúnni Ìpolówó Ọjà. Láti ìgbà dé ìgbà, Microsoft lè pèsè àwọn Iṣẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ fún àkókò ìdánwò. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti díyelé ọ fún irú Àwọn Ìpèsè bẹ́ẹ̀ (ní iye owó déédé) tí Microsoft bá pinnu (nínú èrò rẹ̀) pé o n ṣe àṣìlò àwọn àdéhùn ìfilọ̀ náà.
- j. Àwọn Àyípadà Iye-owó. A le yí owó àwọn Ìpèsè náà padà ní ìgbàkúgbà àti pé tí o bá ní ìrajà àsantúnsa, a ó sọ fún ọ nípasẹ̀ í-meèlì, tàbí ọ̀nà míràn tó mọ́gbọ́nwá, ó kéré jù ọjọ́ 15 kí iye owó náà tó yípadà. Bí o kò bá faramọ́ àyípadà iye owó náà, o gbọ́dọ̀ fagilé Iṣẹ́ náà tabí kí o dẹ́kun àti lòó kí àyípadà iye owó náà tó bẹ̀rẹ̀. Bí àkókò àti iye owó àìṣeéyípadà bá wà fún ìpèsè Iṣẹ́ rẹ, iye owó náà ní yóò má a ní ipa fún àkókò àìṣeéyípadà náà.
- k. Ìsanwó fún Ọ. Bí a bá jẹ ọ ní owó kan, o gbà láti pèsè àlàyé yòówù tí a nílò láti fún ọ ní owó náà lásìkò àti lẹkunrẹrẹ. látàrí òfin tó jẹmọ, Ìwọ ni ó ni ojúṣe fún owó ìlú yòówù àti àwọn owó tó lè wà fún sísan nípasẹ̀ owó sísan fún ọ yìí. O tún gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àwọn àgbékalẹ̀ yòówù tí a fi sórí ẹ̀tọ́ rẹ sí owó gbígbà yòówù. Bí o bá gba owó kan nípasẹ̀ àṣìṣe, a lè yíipadà tàbí kí á bèèrè fún ìdápadà owó náà. O gbà láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa nínú ìgbìyànjú wa láti ṣe èyí. A tún lè dín iye owó sísan fún ọ kù láì sọ láti lè ṣàtúnṣe sí àsanlé yòówù tó ti wáyé tẹ́lẹ̀.
- l. Àwọn Káàdì Ẹ̀bùn. Ìràpadà àti ìmúlò àwọn káàdì ẹ̀bùn (yàtọ̀ sí àwọn káàdì ẹ̀bùn Skype) ni a ndarí nípasẹ̀ Àwọn Àdéhùn àti Ìlànà Káàdì Ẹ̀bùn Microsoft (https://support.microsoft.com/help/10562/microsoft-account-gift-card-terms-and-conditions). Àlàyé nípa àwọn káàdì ẹ̀bùn Skype wà ní Ojú-ìwé Ìrànlọ́wọ́ Skype (https://go.microsoft.com/fwlink/?LinkId=615383).
- m. Ìlànà Ìsanwó Àkọọ́lẹ̀ Ilé-ìfowópamọ́. O le ṣàkọsílẹ̀ àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ tó yẹ pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ láti lòó gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ìsanwó rẹ. Àwọn àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ tó yẹ pẹ̀lú àwọn àkọọ́lẹ̀ tí a dìmú ní ilé ìṣúná owó tó lágbára láti gba àwọn ìwọlé gbèsè tààrà (fún àpẹrẹ, àwọn ilé iṣẹ́ ìṣúná owó tó wà ní Ilú Amẹrika tó sì faramọ́ automated clearing house ("ACH") àwọn ìwọlé, ilé iṣẹ́ ìṣúná owó tó wà ní Yuropu tó faramọ́ Single Euro Payments Area ("SEPA") tàbí "iDEAL" ní Netherlands). Àwọn Àdéhùn tí o faramọ́ nígbàtí o n ṣàfikún àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìsanwó nínú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ (fún àpẹrẹ, ṣíṣe "dandan" tó bá jẹ́ SEPA) tún ṣàmúlò. O ṣojú o sì fọwọ́sọ̀yà pé àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ tí o ṣàkọsílẹ̀ wà ní orúkọ rẹ tàbí a gbà ọ́ láàyè láti forúkọ sílẹ̀ kí o sì lo àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ yìí bíi ìlànà ìsanwó. Nípa ìforúkọsílẹ̀ tàbí yíyan àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ìsanwó rẹ, o fún Microsoft ní àṣẹ (tàbí àṣojú rẹ̀) láti bẹ̀rẹ̀ gbèsè kan tàbí ọ̀pọ̀ fún àpapọ̀ iye owó ọjà tí o rà tàbí ìdíyelé ìṣalábàápín rẹ (gẹ́gẹ́ bíi àdéhùn ìpèsè ìṣalábàápín rẹ) láti inú àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ (àti, tó bá ṣe pàtàkì, bẹ̀rẹ̀ kírẹ́dìtì kan tàbí ọ̀pọ̀ sínú àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ láti yanjú àwọn àṣìṣe, fúnni ní owó àsanpadà tàbí èrèdí tó jọra), àti pé o fún ilé iṣẹ́ ìṣúná tó ní àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ lọ́wọ́ ní àṣẹ láti yọ bíi gbèse tàbí gba irú kírẹ́dìtì náà. O lóye pé ìfúnláṣẹ yìí yóò wà lójú iṣẹ́ àti ìṣe títí wàá fi yọ àlayé àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ kúrò nínú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ. Kàn sí àtìlẹ́yìn oníbàárà bí a ti kọọ́ sílẹ̀ lókè ní abala 4.e ní kíákíá tí o bá gbà pé a díyelé ọ ní àṣìṣe. Àwọn òfin tí a n ṣàmúlò ní orílẹ̀-èdè rẹ tún le ṣòdíwọ̀n fún gbèsè rẹ fún èyíkéyìí ìwà gbéwiri, àwọn ìdúnàádúrà àìgbàṣẹ tàbí àṣìṣe láti inú akọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ rẹ. Nípa ìforúkọsílẹ̀ tàbí yíyan àkọọ́lẹ̀ ilé ìfowópamọ́ kan gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ìsanwó rẹ, o gbà pé o ti kà, ó sì yé ọ o sì faramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí.
Aṣàdéhùn, Irú Òfin, àti Ibùdó láti Yanjú Àáwọ̀
10. Aṣàdéhùn, Irú Òfin, àti Ibùdó láti Yanjú Àáwọ̀. Fún ìlò rẹ ti Àwọn Ìpèsè olórúkọ Skype ti ọ̀fẹ́ àti oníbàárà tí n sanwó, tí o bá n gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, o n ṣàdéhùn pẹ̀lú, gbogbo ìtọ́kasí "Microsoft" nínú Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí túmọ̀ sí, Skype Communications S.à.r.l, 23 – 29 Rives de Clausen, L-2165 Luxembourg àyàfi ti wọn kò bá sọ bẹ́ẹ̀ nísàlẹ̀. Fún Àwọn Ìpèsè olórúkọ Skype ti ọ̀fẹ́ tàbí oníbàárà tí n sanwó, tí o bá n gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, òfin Luxembourg n darí ìtúmọ̀ ti Àwọn Àdéhùn àti ìbèrè fún dídalẹ̀ kọ̀ọ̀kan, láì fi ti àwọn ìlànà òfin aáwọ̀ ṣe. Òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè ibiti iwọ n gbé ni o n darí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan gbígba ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ìpínlẹ̀ fún ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, òfin fífiga-gbága ti kò tọ́, ati nínú òfin ti n darí ìwà àìtọ́. Tí o bá n gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, ìwọ àti àwa gbà sí agbègbè àti ibi àwọn ilé-ẹjọ́ ti Luxembourg fún gbogbo aáwọ̀ tó le jáde láti tàbí tó jọmọ́ onibàárà ti Àwọn ìpèsè olórúkọ ti Skype. Fún gbogbo Ìpèsè míràn, àjọ tí o n ti ipasẹ̀ wọn ṣàdéhùn, òfin tí n darí, àti ibi láti yanjú àwọn aáwọ̀ farahàn nísàlẹ̀:
- a. Canada. Tí o bá n gbé ní (tàbí, owó kan, tàbí ibi òwò rẹ wà ní) Canada, ò n lo Àwọn ìpèsè Olórúkọ Skype tí o sanwó fún, tàbí tí o bá lo abala ọ̀fẹ́ ti Microsoft Teams, ò n bá Skype Communication US Corporation dòwò pọ̀, 2215-B Renaissance Drive, Las Vegas, NV 89119, United States. Fún gbogbo Àwọn ìpèsè oníbàárà ìsanwófún àti ọ̀fẹ́ tókù, ò n ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Àwọn òfin ìpínlẹ̀ ibití ìwọ n gbé (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, ibití olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà) ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, àti gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ mìíràn (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti n darí ìwà àìtọ́) láì ka awọn ááwọ̀ ti àwọn ìlànà òfin. Ìwọ àti àwa faramọ́ láìsí àyípadà ọkàn, pé sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Ontario ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Ìpèsè.
- b. Àríwá tàbí Gúsù America lóde United States tàbí Canada. Bí o bá n gbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Àríwá tàbí Gúsù America lóde United States tàbí Canada, ìwọ n ṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Àwọn òfin ìpínlẹ̀ Washington ni ó n darí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka àṣàyàn òfin tó rọ̀ mọ́ èyí kún. Òfin orílẹ̀-èdè ibiti à n darí Àwọn Ìpèsè rẹ sí ni o n darí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti n darí ìwà àìtọ́.
- c. Middle East, Africa tàbí Europe. Tí o bá n gbé ní (tàbí, tí ìṣòwò kan, olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Middle East, Africa tàbí ní Europe yàtọ̀ sí European Union (EU), Iceland, Lichtenstein, Norway, Switzerland, àti United Kingdom, tí o sì n lo abala ọ̀fẹ́ ti Àwọn Iṣẹ́ náà (bíi Bing àti MSN), o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A., àyàfi tí o bá n lo abala ọ̀fẹ́ ti Skype, o n ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Ireland Operations Limited, One Microsoft Place, South County Business Park, Leopardstown, Dublin 18, Ireland. Tí o bá sanwó láti lo abala kan ti Àwọn Ìpèsè, o n ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Ireland Operations Limited, One Microsoft Place, South County Business Park, Leopardstown, Dublin 18, Ireland. Fún Àwọn Ìpèsè ọ̀fẹ́ tàbí tí a nsanwó fún, òfin Ireland ni ó n darí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àti àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka awọn òfin miiran tó rọ̀ mọ́ èyí, ti wọ́n sì lè yàtọ̀ síi kún. Òfin orílẹ̀-èdè ibiti à n darí Àwọn Ìpèsè rẹ sí ni o n darí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti n darí ìwà àìtọ́. Ìwọ àti àwa faramọ́, láìsí àyípadà ọkàn, pé sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Ireland ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Ìpèsè.
- d. Asia tàbí Gúsù Pacific, àfi bí a bá dárúkọ orílẹ̀-èdè rẹ ní pàtó nísàlẹ̀ yìí. Bí o bá n gbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Asia (yàtọ̀ sí China, Japan, Republic of Korea, tàbí Taiwan) tàbí Gúsù Pacific, tí o sì nlo ẹ̀yà ọ̀fẹ́ Àwọn Ìpèsè náà (gẹ́gẹ́ bíi Bing àti MSN), ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Bí o bá sanwó láti lo abala Ìpèsè, tàbí ìwọ nlo ìpèsè Outlook.com ọ̀fẹ́ ní Singapore tàbí Hong Kong, ìwọ n ṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Regional Sales Pte Ltd., ilé-iṣẹ́ tí a dásílẹ̀ lábẹ́ àwọn òfin Singapore, pẹ̀lú àdìrẹ́sí tó fisílẹ̀ rẹ ní 182 Cecil Street, #13-01 Frasers Tower, Singapore 069547; tó bá jẹ pé, bí o bá n gbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ pé òwò, olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Australia, ìwọ n ṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Pty Ltd, 1 Denison St, North Sydney, NSW 2060, Australia, bí o bá sì n gbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ pé òwò, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) New Zealand, ìwọ n ṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft New Zealand Limited, Level 5, 22 Viaduct Harbour Avenue, PO Box 8070 Symonds Street, Auckland, 1150 New Zealand. Fún Àwọn Ìpèsè ọ̀fẹ́ àti èyítí a n sanwó fún, òfin Ìpínlẹ̀ Washington ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn àti àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn òfin miiran kún. Òfin orílẹ̀-èdè ibiti à ndarí Àwọn Ìpèsè rẹ sí ni o n darí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti n darí ìwà àìtọ́. Àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tó níṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tàbí àwọn Ìpèsè náà yàtọ̀ sí Skype, títí kan ìbéèrè yòówù tó níṣe pẹ̀lú wíwà wọn, wíwúlò, tàbí píparí iṣẹ́, ni a ó mẹ́nubà, tí a ó sì yanjú nípasẹ̀ ìlàjà ní Singapore ní ìbámu pẹ̀lú Àwọn Òfin Ìlàjà ti Singapore International Arbitration Center (SIAC), awọn òfin èyí tí a kà kún pé a kọ sínú gbólóhùn kúkúrú yìí. Àjọ àwọn adájọ́ náà yóò ní onílàjà kan nínú, èyí tí Ààrẹ SIAC yóò yàn. Èdè tí a ó lò fún ìlàjà náà yóò jẹ́ Gẹ̀ẹ́sì. Ìpinnu onílàjà náà yóò jẹ́ ìdájọ́ ìkẹyìn, èyí tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé, a ki yóò si lè jiyàn rẹ̀, a sì lè lòó gẹ́gẹ́ bíi ìlànà fún ìdájọ́ ní orilẹ̀-èdè tàbí agbègbè yòówù.
- e. Japan. Bí o bá n gbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Japan, tí o sì nlo abala ọ̀fẹ́ Àwọn Ìpèsè náà (gẹ́gẹ́ bíi Bing àti MSN), ìwọ n ṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Bí o bá sanwó láti lo ẹ̀yà ìpèsè náà kan, ìwọ n ṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Japan Co., Ltd (MSKK), Shinagawa Grand Central Tower, 2-16-3 Konan Minato-ku, Tokyo 108-0075. Fún Àwọn ìpèsè ọ̀fẹ́ tàbí tí a sanwó fún, òfin Japan ni ó n darí Àdéhùn wọ̀nyí àti àwọn ẹjọ́ yòówù tó lè wáyé láti inú wọn tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú wọn tàbi Àwọn Ìpèsè náà. Ìwọ àti àwa faramọ́, láìsí àyípadà ọkàn, pé ojúlówó sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Tokyo District ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Ìpèsè.
- f. Republic of Korea.
- i.Tí o bá gbé ní (tàbí, tí ìṣòwò kan, olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Republic of Korea, tí o sì n lo abala ọ̀fẹ́ ti Àwọn Ìpèsè náà (bíi Bing àti MSN), o ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Tí o bá sanwó láti lo abala Àwọn Ìpèsèò n ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Korea, Inc., 12th Floor, Tower A, The K-Twin Tower, Jongro-gu 1 gil 50, Seoul, Republic of Korea, 03142. Lọ́fẹ̀ẹ́ àti Àwọn Ipèsè ìsanwófún, àwọn òfin Republic of Korea jọba lórí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí àti ìṣòro tó bá wáyé nínú ìbáṣepò wọ́n tàbí Àwọn ìpèsè wọn. Ìwọ àti àwa faramọ́ ojúlówó sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Seoul Central District ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Ìpèsè.
- ii. Tí o bá gbé ní Ìlú Rebuplic of Korea, pẹ̀lú òfin, o lè ní àwọn ẹ̀tọ́ kan pàtó tí kò lè ní òpin nípasẹ̀ iṣẹ́ bí Àwọn ìfẹ́nukò wọ̀nyí. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kò fẹ ṣe ìdínà àwọn ẹ̀tọ́ yẹ tàbí dínà àwọn alásopọ̀ Microsoft tí òfin fi múlẹ̀. Láìbìkítà ohunkóhun sí ìlòdí tó wà nínú èyí, Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí ma bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ ìfàyègbà òfin. Èyíkèyí àyípadà Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí (àti àyípadà nínu iye tí o ma san fún Àwọn Ìpèsè tí ò n ṣe aláàbápín fún, tí ó bá lè lòó) o ma wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn nkan tí òfin nílò.
- g. Taiwan. Tí o bá n gbé ní (tàbí, tí ìṣòwò kan, olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Taiwan, tí o sì n lo abala ọ̀fẹ́ ti Àwọn Ìpèsè náà (bíi Bing àti MSN), o n ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Tí o bá sanwó láti lo abala kan ti Àwọn Ìpèsè, o n ṣàdéhùn pẹ̀lú Microsoft Taiwan Corp., 18F, No. 68, Sec. 5, Zhongxiao E. Rd., Xinyi District, Taipei 11065, Taiwan. Fún Àwọn Ìpèsè ọ̀fẹ́ àti ìsanwófún, àwọn òfin Taiwan ń darí Àwọn Àwíyé wọ̀nyí àti èyíkéyìí ọ̀ràn tó le jẹyọ láti tàbí tó jọmọ́ wọn tàbí Àwọn Ìpèsè. Fún àlàyé síwájú síi nípa Microsoft Taiwan Corp., jọ̀wọ́ wo àyè ayélujára tí a pèsè láti ọwọ́ Ministry of Economic Affairs R.O.C. https://gcis.nat.gov.tw/mainNew/). Ìwọ àti àwa yan, láìsí àyípadà ọkàn, Ilé-ẹjọ́ Taipei District gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹjọ́ àkọ́kọ́ tó ní ẹ̀tọ́ láti dá ẹjọ́ lórí àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Àwọn Ìpèsè, títí dé ibití òfin Taiwan gba ni láàyè dé.
Oníbàárà ìkẹyìn agbègbè rẹ lè nílò àwọn òfin agbègbè láti darí tàbí láti fún ọ ní ẹ̀tọ́ láti yanjú àríyànjiyàn ní ibòmíràn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àṣàyàn òfin àti ìpèsè ibòmíràn ní abala 10 yóò ní ipa dé ibití àwọn òfin agbègbè rẹ bá gba ni láàyè dé.
Ìfọwọ́sọ̀yà
11. Àwọn àtìlẹ́yìn ọjà.
- a. MICROSOFT, ÀTI ÀWỌN ALÁÀBÁṢIṢẸ́PỌ̀ WA, ALÁÀTÚNTÀ, OLÙPÍN ỌJÀ, ÀTI ÀWỌN ALÁGBÀTÀ, KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN ỌJÀ KANKAN, TÍ A FẸNUSỌ TÀBÍ TÍ A KÒ SỌ PÀTÓ, ÀFẸ̀HÌNTÌ TÀBÍ MÁJẸ̀MÚ NÍPA ÌMÚLÒ RẸ FÚN IṢẸ́ NÁÀ. Ó YÉ Ọ PÉ ÌMÚLÒ IṢẸ́ NÁÀ JẸ́ EWU TÌRẸ, ÀTI PÉ A PÈSÈ IṢẸ́ NÁÀ LÓRÍ ÌPÌLẸ̀ ¨BÍ Ó ṢE Rͨ ¨PẸ̀LÚ GBOGBO ÀṢÌṢE¨ ÀTI ¨BÍ Ó ṢE WÀ.¨ MICROSOFT KÒ ṢE ÌDÁNILÓJÚ KANKAN NÍPA ṢÍṢIṢẸ́ DÁRADÁRA ÀTI LÁSÌKÒ ÀWỌN ÌPÈSÈ NÁÀ. O LÈ NÍ ÀWỌN Ẹ̀TỌ́ KAN LÁBẸ́ ÀWỌN ÒFIN AGBÈGBÈ RẸ. KÒ SÍ OHUNKÓHUN NÍNÚ ÀWỌN ÀDÉHÙN WỌ̀NYÍ TÍ A GBÈRÒ PÉ KÍ Ó NÍ IPA LÓRÍ ÀWỌN Ẹ̀TỌ́ WỌ̀NYÍ, BÍ Ó BÁ KÀN WỌ́N. O GBÀ PÉ ÀWỌN Ẹ̀RỌ KỌMPUTA ÀTI TI ÌBÁRAẸNISỌ̀RỌ̀ KÒ WÀ LÁÌSÍ ÀṢÌṢE ÀTI PÉ ÀWỌN ÀKÓKÒ ÀÌṢEDÉÉDÉ KAN A MÁ A WÁYÉ LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN. ÀWA KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN PÉ IṢẸ́ NÁÀ YÓÒ JẸ́ ÈYÍ TÍ KÒ NÍ ÌDÁDÚRÓ KANKAN, TÍ YÓÒ LỌ GEERE LASIKO, PẸ̀LÚ ÀÀBÒ, LÁÌNÍ ÀṢÌṢE TÀBÍ PÉ KÌ YÓÒ SÍ ÀDÁNÙ ÀKÓÓNÚ, BẸ́Ẹ̀ SÌ NI A KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN FÚN ÀSOPỌ̀ SÍ TÀBÍ ÌFIRÁNṢẸ́ LÁTI ÀWỌN NẸTIWỌKI KỌMPUTA.
- b. TÍTÍ DÉ IBITÍ ÒFIN AGBÈGBÈ RẸ FI ÀÀYÈ GBA NI DÉ, ÀWA MÚ ÀTÌLẸ́YÌN YÒÓWÙ TÍ A KÒ DÁRÚKỌ KÚRÒ, ÈYÍ TÍ Ó KAN WÍWÚLÒ LÓRÍṢIRÍṢI Ọ̀NÀ, DÍDÁRA NÍ Ọ̀NÀ TÓ TẸ́NILỌ́RÙN, YÍYẸ FÚN ÈRÈDÍ KAN PÀTÓ, AKITIYAN BÍI ÒṢÌṢẸ́, ÀTI ÀÌTAPÁ SÍ ÀDÉHÙN.
- c. Fún àwọn aṣàmúlò tí ngbé ní Australia: Àwọn ọjà àti iṣẹ́ wa ń wá pẹ̀lú ìfọwọ́sọ̀yà tí a kò le yọkúrò lábẹ́ Òfin Oníbàá Ilẹ̀ Australian. Fún ìkùnnà gbógì pẹ̀lú iṣẹ́ náa, o ní ẹ̀tọ́:
- láti fagilé àdéhùn iṣẹ́ rẹ pẹ̀lú wa; àti
- sí ìdáwópadà fún abala tí o kò lò, tàbí sí owó gbà má bínú fún ẹ̀dínwó rẹ̀.
O tún ní ẹ̀tọ́ láti yàn tàbí ìrọ́pò fún àwọn ìkùnnà gbógì pẹ̀lú àwọn ọjà. Tí ìkùnnà kan sí ọjà tàbí iṣẹ́ kò bá tó ìkùnnà gbógì, o ní ẹ̀tọ́ sí àtúnṣe ìkùnnà náà láàrín àkókò díẹ̀. Tí a kò bá ṣe èyí o ní ẹ̀tọ́ sí owó àsanpadà fún ọjà náà kí o sì fagilé àdéhùn náà fún iṣẹ́ náà kí o sì gba owó àsanpadà fún abala tí o kò lò. O tún ní ẹ̀tọ́ fún owó gbà má bínú fún èyíkéyìí ìdíbàjẹ́ tàbí àdánù tí a le rí nítorí ìkùnnà kan nínú ọjà tàbí iṣẹ́.
- d. Fún àwọn aṣàmúlò ìkẹyìn tí ngbé ní New Zealand, o lè ní àwọn ẹ̀tọ́ kan lábẹ́ àwọn Òfin Àtìlẹ́yìn Ọjà Aṣàmúlò Ìkẹyìn New Zealand, kò sì sí ohunkóhun nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tí a gbèrò láti ní ipa lórí àwọn ẹ̀tọ́ náà.
Òpín ti Òjúṣe òfin
12. Ìdíwọ̀n Ojúṣe.
- a. Tí o bá ní ìdí kankan láti gba àsanpadà (èyítí ó kan ìtàpá sí òfin Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí), títí dé ibi tí òfin tó yẹ gbani láàyè dé, o gbà pé àtúnṣe rẹ, láìsí ohun mìíràn, ni láti gbà àsanpadà tààrà, èyítí iye owó rẹ tó iye owó Ìpèsè rẹ fún oṣù náà nínú èyítí àdánù tàbí ìtàpà sí òfin náà wáyé (tàbí iye tó tó USD$10.00 bí àwọn Ìpèsè náà bá jẹ́ ọ̀fẹ́), láti ọ̀dọ̀ Microsoft tàbí aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ yòówù, aláàtúntà, olùpín kiri, àwọn olùpèsè Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta, àti àwọn alágbàtà.
- b. Títí dé ibití òfin tí ó yẹ gba ni láàyè dé, ìwọ kó lè gba ohunkóhun padà fún (i) àwọn àdánù tàbí ìbàjẹ́ tó ti ìdí ohun kan jáde; (ii) àdánù ojúlówó èrè tàbí ti èrè tí à nretí (yálà tààrà tàbí tí kò lọ tààrà); (iii) àdánù ojúlówó owó tó nwọlé tàbí ti èyítí à nretí (yálà tààrà tàbí tí kò lọ tààrà); (iv) àdánù iṣẹ́ aláàdèhùn tàbí ti òwò tàbí àwọn àdánù tàbi ìbàjẹ́ mìíràn tó wáyé nípasẹ̀ lílò rẹ Iṣẹ́ náà ní ọ̀nà tí kìí ṣe ti ara ẹni; (v) àwọn àdánù tàbí ìbàjẹ́ pàtàkì, tí kò lọ tààrà, tó ti ìpasẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé tàbí tó wáyé nípasẹ̀ ìfìyàjẹni; àti (vi) títí dé ibití òfin fi ààyè gba ni dé, àwọn àdánù tàbí ìbàjẹ́ tó rékọjá àwọn akọsílẹ̀ tó wà ní apá 12.a lókè yìí. Àwọn ìdíwọ̀n àti ìyọkúrò wọ̀nyí yóò ní ipa bí àtúnṣe yìí kò bá san àsanpadà lẹkunrẹrẹ fún ọ fún àdánù yòówù tàbí bí ó bá kùnà láti ṣe ohun pàtàkì tí a gbèrò rẹ̀ fún tàbí bí a bá mọ̀ tàbí tó yẹ kí a mọ̀ nípa ṣíṣeéṣe àwọn àdánù náà. Títí dé òpin ibití òfin fi ààyè gba ni dé, àwọn ìdíwọ̀n àti ìyọkúrò wọ̀nyí ní ipa lórí ohunkóhun yòówù tàbí gbígbà padà yòówù tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, àwọn Iṣẹ́ náà, tàbí ẹ̀yà àìrídìmú tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Iṣẹ́ náà.
- c. Microsoft kò ní ojúṣe kankan tàbí ní ohun kankan láti dáhùn fún kíkùnà láti ṣiṣẹ́ tàbí ìdádúró ní ṣíṣe iṣẹ́ tó jẹ́ ojúṣe rẹ̀ lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí títí kan ibi tó jẹ́ pé ìkùnà tàbí ìdádúró náà wáyé nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó rékọjá agbára Microsoft (gẹ́gẹ́ bíi àríyànjiyàn àwọn òṣìṣẹ́, àwọn àmúwá Ọlọrun, ogun tàbí ìwà àwọn adánilóró. ìbàjẹ́ tí a fi ṣe ìkà fún ni, ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ tàbí ìfèsì sí òfin tí ó yẹ tàbí sí àṣẹ ìjọba). Microsoft yóò gbìyànjú láti dín ipa èyíkéèyí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kù, àti láti ṣe àwọn ojúṣe tí èyí kò kàn.
Àwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtó
13. Àwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtó. Àwọn àdéhùn tó wà ṣáájú àti lẹ́yìn apá 13 kan gbogbo àwọn Iṣẹ́ lápapọ̀. Apá yìí ní àwọn àdéhùn tó kan àwọn iṣẹ́ kan pàtó nínú, àwọn èyí tó jẹ́ àfikún sí àwọn àdéhùn gbogbogbò. Àwọn àdéhùn tó níí ṣe pẹlú ìpèsè kan pàtó wọ̀nyí ni a ó lò bí aáwọ̀ yòówù bá jẹyọ pẹ̀lú àwọn àdéhùn gbogbogbò.
Xbox
- a. Xbox.
- i. Ìlò Ara-ẹni Tí Kì í Ṣe fún Òwò. Ìpèsè orí ẹ̀rọ Xbox ("Nẹ́tíwọkì Xbox àwọn ayò Xbox Game Studios (pẹ̀lú Àwọn ayò Mojang) (https://www.xbox.com/xbox-game-studios) àwọn ìfilọ́lẹ̀, ìṣalábàápín (àpẹrẹ, ìfúni ìpèsè ìṣalábàápín Xbox Game Pass), àwọn ìpèsè (àpẹrẹ, Xbox Cloud Gaming) àkóónú tí Microsoft pèsè (lápapọ̀, "Àwọn Ìpèsè Xbox") wà fún ìlò ti ara rẹ àti ọrọ̀ ajé.
- ii. Àwọn Ìpèsè Xbox. Nígbà tí o bá forúkọsílẹ̀ láti ànfààní Àwọn Ìpèsè Xbox, àlàyé nípa ìtayò, Àwọn Ìpèsè àti ìṣàmúlò àwọn ayò àti Àwọn Ìpèsè Xbox rẹ yóò jẹ́ títọpa yóò sì jẹ́ pínpín pẹ̀lú àwọn ẹnìkẹta tí ó bá bamu, nínú èyí tí a ti rí àwọn aṣàgbékalẹ̀ ayò àti àwọn olùgbéjáde, láti mú kí Iṣẹ́ Microsoft jábọ̀ Àwọn Ìpèsè Xbox náà fún àwọn ẹnìkẹta láti tukọ̀ àwọn ayò àti àwọn ìpèsè tí kì í ṣe ti Microsoft. Ní alfikún, tí a bá ráyè sí Àwọn Ìpèsè Xbox láti orí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tàbí pẹpẹ ẹnìkẹta, àlàyé nípa ayò tí o gbá àti ìlò àwọn ayò àti Àwọn Ìpèsè Xbox lè jẹ títọpa kí ó sì jẹ́ pínpín pẹ̀lú irú àwọn ohun èlò ẹ̀rọ àwọn pẹpẹ ẹnìkẹta bẹ́ẹ̀, tí ó wà lábẹ́ àdéhùn àti àjọsọ ìkọ̀kọ̀ ẹnìkẹta. Tí o bá fàṣẹ wọlé sí pẹpẹ míràn tàbí ohun èlò ẹ̀rọ tó ní àkọọ́lẹ̀ Microsoft tàbí ṣe ìsopọ̀ àkọọ́lẹ̀ Microsoft tó ní àwọn pẹpẹ tàbí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ láti ráyèsí ìpèsè tí kìnṣe ti Microsoft (fún àpẹrẹ, olùtẹ̀jáde tí kìnṣe ti Microsoft ti Àwọn ìpèsè àti Àwọn ìfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíran), o faramọ́ ìyẹn: (a) Microsoft lè ṣe àjọpín àlàyé àkọọ́lẹ̀ níwọnba àlàyé ìlò tó jẹ mọ́ (èyí tí ó kan, láìní àhámọ́ gamertag, gamerscore, iye máàkì eré, ìtàn eré, ìlò détà àti àkójọ àwọn ọ̀rẹ́) pẹ̀lú ẹnìkẹta bí wọ́n ṣe sọ nínu Gbólóhùun Ìkọ̀kọ̀ Microsoft, àti (b) bí ètò ìkọ̀kọ̀ Xbox rẹ bá gba ni láàyè, ẹlomíràn tí kìí ṣe Microsoft náà lé ní ànfàní láti wọlé sí Àkóónú rẹ bákan náà láti inú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lórí eré tàbí àwọn èlò ẹ̀rọ tí o lò nígbàtí o bá buwọ́lù wọlé sí àkọọ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú ẹnití kìí ṣe Microsoft náà. Bákan náà, bí àwọn ààtò ìkọ̀kọ̀ Xbox rẹ bá gba ni láàyè, Microsoft lè ṣe àtẹ̀jáde orúkọ rẹ, gamertag, gamerpic, motto, avatar, gameclips àti àwọn eré rẹ tí o ti ṣe, nínú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn tí o gbà láàyè. Bí o bá ti tan àwọn ààtò Family Safety Xbox pàtó, àwọn ààtò wọ̀nyẹn jẹ́ lílò lórí àwọn pẹpẹ Xbox, Xbox Cloud Gaming, àti áàpù Xbox lórí ẹ̀rọ kòmpútà tàbí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ alágbèéká, ṣùgban ó lè fẹ̀ dé àwọn eré sítúdíò Xbox Games tàbí ìráyèsí àwọn ìpèsè tàbí múṣiṣẹ́ lórí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tókù tàbi lórí àwọn pẹpẹ. Láti ṣàrídájú ìrírí eré ìdárayá tó ní ààbò fún ẹbí rẹ, jọ̀wọ́ yẹ ààtò ìdarí òbí lórí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tókù wọ̀nyí wò àti àwọn pẹpẹ.
- iii. Àkóónú Rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ara mímú ìlọsíwájú bá àwùjọ aṣàmúlò Àwọn Ìpèsè Xbox, ìwọ fún Microsoft, àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, àti àwọn tí wọ́n pín nínú ìwé àṣẹ rẹ̀, ní ẹ̀tọ́ ọ̀fẹ káríayé, láti lò, ṣàtúnṣe sí, ṣàtúndá, pín kiri, tàn káàkiri, ṣàpínlò, àti láti ṣàfihàn Àkóónú Rẹ tàbí orúkọ rẹ, gamertag, motto, tàbí avatar tí o fihàn fún àwọn Ìpèsè Xbox yòówù.
- iv. Àwọn Olùṣàkóso Eré. Àwọn eré kan lè ma lo àwọn olùṣàkóso, àwọn aṣojú, tàbí àwọn olùgbàlejò eré. Àwọn olùṣàkóso àti àwọn olùgbàlejò eré kì í ṣe agbẹnusọ Microsoft tí a fún ní àṣẹ. Èròngbà wọn kò kúkú ṣe àfihàn èròngbà ti Microsoft.
- v. Àwọn ọmọde àti Xbox. Bí o bá jẹ́ ọmọdé tó nlo Àwọn ìpèsè Xbox, àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ rẹ lè ní ìṣàkóso lórí ọ̀pọ̀ lára abala àkọọ́lẹ̀ rẹ, wọ́n sì lè má a gba ìjábọ̀ nípa ìmúlò Àwọn ìpèsè Xbox rẹ. Àwọn àbùdá yìí jẹ́ ti Àwọn Ìpèsè Xbox nìkan ó sì má le ṣeé taari sí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tàbí pẹpẹ mìíràn.
- vi. Owó Aláyò tàbí Àwọn Ọjà Orí-ẹ̀rọ. Àwọn Ìpèsè Xbox náà lè jẹ́ owó eré orí afẹ́fẹ́ (bíi góòlù, coins tàbí àmì) tí a lè rà láti lórúkọ Microsoft nípa lílo ohun èlò owó gangan bí o bá ti dé ọjọ́-orí ¨àgbàlagbਠníbi tí ìwọ n gbé. Àwọn Ìpèsè Xbox náà tún lè jẹ́ àwọn orí-ẹ̀rọ tàbí àwọn nkan díjítà tàbí ọjà tí a lè rà láti tàbí lórúkọ Microsoft nípa lílo ohun èlò owó gangan tàbí nípa lílo owó eré. A lè má lè fi owó eré àti ọjà orí-ẹ̀rọ náà gba ohun èlò owó gangan, àwọn ọjà, tàbí àwọn nkan mìíràn tó ní owó lórí padà láti ọwọ́ Microsoft tàbí àwọn ẹlòmíràn. Yàtọ sí ìwé-àṣẹ tó ní àhámọ́, ti ara ẹni, tó ṣeé fagilé, tí kò ṣeé fifún ẹlòmíràn, tí kò sì ṣeé fún ẹlòmíràn láṣẹ láti lò, tí a fifún ni láti lè lo owó eré àti àwọn ọjà Àwọn ìpèsè Xbox níkan, ìwọ kò ní ẹ̀tọ́ kankan sí irú owó eré tàbí Àwọn ìpèsè Xbox bẹ́ẹ̀ tó nhàn lórí tàbí tó wá láti inú Àwọn Ìpèsè Xbox náà, tàbí àwọn ohun mìíràn tó lè níí ṣe pẹ̀lú ìmúlò Àwọn Ìpèsè náà tàbí tí a fi pamọ́ sínú Àwọn Ìpèsè náà. Microsoft lè bójútó, darí, ṣàtúnṣe àti/tàbí ṣe ìmúkúrò owó eré àti/tàbí àwọn ọjà orí-ẹ̀rọ tó jẹmọ́ ẹnikẹni tàbí àwọn eré Xbox tàbí àwọn ìfilọ́lẹ̀ tó bá ìṣe ti ara rẹ mu sí àwọn òfin agbègbè rẹ fọwọ́sí.
- vii. Awọn Ìmúdójúìwọ̀n Ẹ̀yà àìrídìmú. Fún ohun èlò ẹ̀rọ yòówù tó lè ní àsopọ̀ pẹ̀lú Àwọn Ìpèsè Xbox, àwa lè ṣàyẹ̀wò oríṣi ẹ̀yà àìrídìmú àtẹ ìṣàkóso Xbox rẹ tàbí ẹ̀yà àìrídìmú èlò-ẹ̀rọ Xbox rẹ láìfọwọ́yí, kí a sì gbé àwọn ìmúdójúìwọ̀n ẹ̀yà àìrídìmú tàbí àwọn àyípadà àtúntò ẹ̀rọ àtẹ ìṣàkóso Xbox tàbí ti èlò-ẹ̀rọ Xbox rẹ wálẹ̀, èyí tí ó kan àwọn èyí tó máa n dènà ìráyèsí rẹ sí Àwọn Ìpèsè Xbox náà, nípa lílo àwọn eré Xbox tàbí àwọn èlò-ẹ̀rọ Xbox tí kò ní àṣẹ, tàbí ní lílo àwọn ẹ̀rọ àsopọ̀ mọ́ ẹ̀yà àfojúrí tí a kò fún ni láṣẹ láti lò pẹ̀lú àtẹ ìṣàkóso Xbox.
- viii. Ẹ̀yà Àìrídìmú Ìrẹ́jẹ àti Ìkọwọ́bọ̀. Fún èyíkéyìí ohun èlò tó le sopọ̀ mọ́ Àwọn Ìpèsè Xbox, a le ṣàyẹ̀wò ohun èlò rẹ láìròtẹ́lẹ̀ fún ẹ̀yà àfojúrí tàbí ẹ̀yà àrídìmú tí a kò gbà láàyè, tó sì n gba ìrẹ́jẹ tàbí ìkọwọ́bọ̀ tí kò tọ́ láàyè, ní ìtàpà sí òfin Àfẹnukò Ìhùwàsí tàbí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, kí a sì gba ẹ̀dà fáìlì̀ àwọn àfikún ẹ̀yà àìrídìmú ìfilọ́lẹ̀ àti ti àyípadà àtòpọ Xbox sílẹ̀, èyí sì kan àwọn tí yóò dènà rẹ láti ráyèsí Àwọn Ìpèsè Xbox pẹ̀lú, tàbí tí kì yóò jẹ́ kí o lè lo ẹ̀yà àfojúrí tàbí ẹ̀yà àrídìmú tí n gba ìrẹ́jẹ tàbí ìkọwọ́bọ̀ tí kò tọ́ láàyè.
- ix. Àfikún Ìṣalábàápín Àwọn Àdéhùn àti Àjọṣọ. Àwọn Ìṣalábàápín Àwọn Ìpèsè Xbox ṣe pàtàkí sí àfikún àwọn àdéhù àti àjọsọ tó wà ní ìwájú Àdéhùn àti Àjọsọ Àwọn ìṣalábàápín Xbox | Xbox (https://www.xbox.com/legal/subscription-terms).
- x. Àwọn Ìṣalábàápín Àwọn Ìpèsè Xbox tí Kò Ṣiṣẹ́. Microsoft lè pa owo tó yọjú lóòrèkórè yóò sí dá owó sísan tó yọjú lóòrèkórè ní àwọn orílẹ̀ èdè tí o yàn dúró tí o kò bá lo Àwọn Ìpèsè Ìṣalábàápín Xbox fún àkókò kan. Microsoft ma pèsè ìfitónilétí fún ọ kí o tó pa owó tó yọjú lóòrèkórè. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé si, pẹ̀lú àkókò tí kò fi ṣiṣẹ́, wo FAQ Àìṣiṣẹ́ Ìṣalábàápín | Àtilẹ́yìn Xbox (https://support.xbox.com/en-GB/help/subscriptions-billing/manage-subscriptions/xbox-subscription-inactivity-policy).
- xi. Àfikún àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ olùṣàmúlò-ìgbẹ̀yìn àti òfin ìṣesí. Àwọn Ìpèsè Xbox mìíràn lè ní àwọn àdéhùn àti òfin ìṣesí tiwọn.
Ibi ìpamọ́
- b. Ibi ìpamọ́. "Ìsọ̀" túmọ̀ sí Iṣẹ́ kan tí ń gbà ọ́ láàyè láti ṣàwákiri, gbàsílẹ̀, rajà, kí o sì díwọ̀n àti àtúnyẹ̀wò àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ (ọ̀rọ̀ náa "ìṣàfilọ́lẹ̀" pẹ̀lú ìṣeré) àti àkóónú díjítà míràn. Àwọn Àwíyé wọ̀nyí kan ìlò àwọn Ìsọ̀ kan èyítí Microsoft ni tàbí darí tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ (pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò pin sí, Office Store, Microsoft Store lórí Windows àti Microsoft Store lórí Xbox). "Office Store" túmọ̀ sí Ìbi ìpamọ́ fún àwọn àbájáde Office àti àwọn ìfilọ́lẹ̀ fún Office, Microsoft 365, SharePoint, Exchange, Access and Project (ẹ̀yà 2013 tàbí tuntun), àbí èyíkèyí ìrírí tókù tó jẹ́ búrándì Office Store. “Microsoft Store on Windows” túmọ̀ sí Ìsọ̀ kan, tí Microsoft ni tó sì ń darí tàbí àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀, fún àwọn ohun èlò Windows bíi fóònù, PC àti tabulẹti, tàbí èyíkéyìí ìrírí míràn tó lórúkọ Microsoft Store tó sì wà lórí àwọn ohun èlò Windows bíi fóònù, PC, tàbí tabulẹti. "Microsoft Store lórí Xbox" túms sí pé Ibí ìpamọ́ tí jẹ́ ti Microsoft tàbí sopapọ̀ mọ́ fún àwọn ohun èlò Xbox, tàbí èyíkèyí ìrírí tí Microsoft Store ṣe tó sì jẹ́ kó wànílẹ̀ lórí ohun èlò Xbox.
- i. Àwọn Àdéhùn Ìwé-àṣẹ. Àwa yóò ṣe ìdánimọ̀ olùgbéjáde ohun èlò kọ̀ọ̀kan tó wà ní Ibi ìpamọ́ tó yẹ. Àyàfi tí a bá pèsè àwọn àwíyé ìwé-àṣẹ míràn pẹ̀lú ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, Àwọn Àwíyé Ìwé-Àṣẹ Ìṣàfilọ́lẹ̀ Gbèdéke ("SALT") ní òpin Àwọn Àwíyé wọ̀nyí jẹ́ àdéhùn láàrín ìwọ àti olùtẹ̀jáde ìṣàfilọ́lẹ̀ tí ń ṣètò àwíyé ìwé-àṣẹ tó kan ìṣàfilọ́lẹ̀ kan tí o gbàsílẹ̀ nípasẹ̀ èyíkéyìí Ìsọ̀ tí Microsoft ní tàbí darí tàbí ti àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ (àyàfi Office Store). Láti mú u yé ni síwájú síi, Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kan ìlò, àti àwọn ìpèsè tí, Àwọn Ìpèsè Microsoft nfifún ni. Apá 5 àwọn Àdéhùn wọ̀nyí náà ní ipa lórí àwọn Ohun èlò àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn yòówù tí a rà nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ kan. Àwọn ohun èlò tí o gbé wálẹ̀ nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ Office ni a kò darí nípasẹ̀ SALT náà, àwọn sì ní ìwé-àṣẹ ọ̀tọ̀ tó kàn wọ́n.
- ii. Àwọn Ìmúdójúìwọ̀n. Microsoft yóò ṣàyẹ̀wò láìfọwọ́yí fún àwọn ìmúdójúìwọ̀n, yóò sì gbé wọn wálẹ̀ sórí àwọn ohun èlò rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò buwọ́lù wọlé sí Ibi ìpamọ́ náà. O lè yí àwọn ètò Ibi ìpamọ́ tàbí ẹ̀rọ rẹ padà bí o kò bá fẹ́ má a gba àwọn ìmúdójúìwọ̀n láìfọwọ́yí sórí àwọn ohun èlò Ibi ìpamọ́. Ṣùgbọn, àwọn ohun èlò Ibi ìpamọ́ Office kan tó wà lórí ayélujára pátápátá tàbí fún ìgbà díẹ̀ ni a lè mú dójú ìwọ̀n nígbà yòówù nípasẹ̀ olùgbéjáde ohun èlò náà, wọ́n sì lè má nílò àṣẹ rẹ láti mú wọn dójú ìwọ̀n.
- iii. Ṣíṣe ìdíwọ̀n dídára àti Ṣíṣàtúnyẹ̀wò. Tí o bá díwọ̀n tàbí ṣàtúnyẹ̀wò ìfilọ́lẹ̀ kan tàbí Ọjà Onídíjítà míràn nínú Ibi ìpamọ́ náà, o le gba í-meèlì láti Microsoft tó ní àkóónú láti olùgbéjáde ìfilọ́lẹ̀ náà tàbí Ọjà Onídíjítà. Èyíkéyìí irú í-meèlì náà ń wá láti ọ̀dọ̀ Microsoft; a kò ṣàpínlò àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ pẹ̀lú àwọn olùgbéjáde àwọn ìfilọ́lẹ̀ náà tàbí Àwọn Ọjà Onídíjítà tí o gbà nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́.
- iv. ìkìlọ̀ Ààbò. Láti yàgò fún ìpalára, ìnira tàbí dídá ojú ẹni lágaara, ọ gbọ́dọ̀ ní ìsinmi láti ìgbà dé ìgbà kúrò lẹ́nu lílò àwọn eré tàbí ohun èlò mìíràn, pàápàá bí o bá nní ìrora tàbí bí ó bá nrẹ̀ ọ́, àwọn èyítí ó nwáyé nípasẹ̀ ìmúlò. Bí o bá ní ìrírí ìnira yòówù, ṣíwọ́ nínú eré. Ìnira lè jẹ́, kí èébì má a gbé ni, àìlera ìrìn-àjò, òòyì, àìmọ ibi tí ènìyàn wà, orí-fifọ́, àárẹ̀, dídá ojú ẹni lágaara, tàbí ẹyin ojú aláìlómijé. Lílò àwọn ohun èlò lè fa ìdíwọ́ ní fífọkànsí nkan, ó sì tún lè dínà mọ́ ọ ní àyíká rẹ. Yàgò fún àwọn ohun tó lè gbé ni ṣubú, àbágùnkè, àjà ilé tí kò ga sókè púpọ̀, àwọn ohun ẹlẹgẹ́ tàbí tó níyelórí, tó lè bàjẹ́. Àwọn ènìyàn méèló kan lè ní ìrírí gìrì nígbàtí wọn bá wà lábẹ́ agbára àwọn àwòrán àfojúrí bíi àwọn iná tó nṣá tàbí tó nṣẹ́jú tó lè má a hàn nínú àwọn ohun èlò náà. Àwọn ènìyàn tí kò ní ìtàn nípa gìrì pàápàá lè ní àìsàn tí a kò tíì yẹ̀wò, èyí tó lè fa àwọn gìrì wọ̀nyí. Àwọn ààmì àìsàn lè jẹ́ òòyì, àìríran dáradára, gbigbọ̀n ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀, àìmọ ibití ènìyàn wà, àìmọ ohun tí ènìyàn nṣe, dídákú, tàbi àìpérí. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ dẹ́kun lílò, kí o sì kàn sí dọ́kítà bí o bá nní èyíkéèyí nínú àwọn àmì àìsàn wọ̀nyí, tàbí kí o kàn sí dọ́kítà kí o tó lo ohun èlò náà bí o bá ti ní irú àmì àìsàn tó níí ṣe pẹ̀lú gìrì rí. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣàkóso bí àwọn ọmọ wọn ti nlo àwọn ohun èlò, kí wọ́n sì ṣàkíyèsi àwọn àmì àìsàn wọ̀nyí.
Àwọn Àbùdá Microsoft Family
- c. Àwọn Àbùdá Microsoft Family. Àwọn òbí àti àwọn ọmọ lè lo àwọn àbùdá Microsoft ebí, pẹ̀lú Microsoft family Safety, láti ní ìfọkàntán lórí òye àjọni nípa irú àwọn iṣesí, àwọn ojú-òpó wẹ́ẹ̀bù, àwọn ìlò-ẹ̀rọ, àwọn ayò, àwọn ibùdó ojútáyé, àti ìnáwó tí ó yẹ fún ebí wọn. Àwọn òbí lè ṣẹ̀dá ìdílé nípa lílọ sí https://account.microsoft.com/family (tàbí nípa títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà lórí ẹ̀rọ Windows tàbí àtẹ ìṣàkóso Xbox wọn), wọ́n sì lè pe àwọn ọmọ àti òbí mìíràn láti darapọ̀ pẹ̀lú. Oríṣìí àwọn àfidámọ̀ ló wà fún àwọn mọ̀lẹ́bí, fún ìdí èyí rọra ṣàtúnyẹ̀wò àlàyé náà tí a pèsè nígbà tí o bá gbà láti ṣẹ̀dá tàbí darapọ̀ mọ́ ẹbí kan àti nígbà tí o bá ra Àwọn Ohun Àmúlò Díjítà fún ìráyèsí ẹbí. Nípa ṣíṣẹ̀dá tàbí dídarapọ̀ mọ́ ẹbí kan, o gbà láti lo ẹbí náà gẹ́gẹ́ bí èrèdí rẹ̀, o kò sì ní lò ó ní ọ̀nà tí a kò fàṣẹ sí láti ráyè sí àlàyé ẹlòmíràn ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu. Àwọn Iṣẹ́ Microsoft nìkan ni Àwọn Ìfidámọ̀ Microsoft Family wà fún kò sì ṣeé taari sí pẹpẹ mìíràn. Fún àpẹrẹ, àwọn ààtò Family Safety Xbox pàtó jẹ́ lílò lórí àwọn pẹpẹ Xbox, Xbox Cloud Gaming, àti áàpù Xbox lórí ẹ̀rọ kòmpútà tàbí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ alágbèéká, ṣùgban ó lè fẹ̀ dé àwọn eré sítúdíò Xbox Games tàbí ìráyèsí àwọn ìpèsè tàbí múṣiṣẹ́ lórí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tókù tàbi lórí àwọn pẹpẹ. Láti ṣàrídájú ìrírí eré ìdárayá tó ní ààbò fún ẹbí rẹ, jọ̀wọ́ yẹ ààtò ìdarí òbí lórí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ wọ̀nyí àti àwọn pẹpẹ.
Kíkọ̀rọ̀ránṣẹ́ Ẹlẹ́gbẹẹgbẹ́
- d. Kíkọ̀rọ̀ránṣẹ́ Ẹlẹ́gbẹẹgbẹ́. Àwọn oríṣiríṣi iṣẹ́ Microsoft ngba ọ́ láàyè láti kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ (¨àwọn ìfiránṣẹ́¨) olóhùn tàbí SMS, wọn a sì má a gba Microsoft àti àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ tí Microsoft jẹ́ aláàkóso wọn láàyè láti fi irú ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ àti sí aṣàmúlò kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lórúkọ rẹ. NÍGBÀTÍ O BÁ FÚN MICROSOFT ÀTI ÀWỌN ALÁÀBÁṢIṢẸ́PỌ̀ TÍ MICROSOFT JẸ́ ALÁÀKÓSO WỌN NÍ ÀṢẸ LÁTI FI IRÚ ÌFIRÁNṢẸ́ BẸ́Ẹ̀ RÁNṢẸ́ SÍ Ọ TÀBÍ SÍ ÀWỌN ẸLÒMÍRÀN, ÌWỌ DÚRÓ BÍ AṢOJÚ, O SÌ FÚN WA NÍ ÌDÁNILÓJÚ PÉ ÌWỌ ÀTI Ọ̀KỌ̀Ọ̀KAN ÀWỌN ẸNITÍ O FÚN WA NÍ ÀṢẸ LÁTI RÁNṢẸ́ SÍ GBÀ LÁTI GBA IRÚ ÀWỌN ÌFIRÁNṢẸ́ BẸ́Ẹ̀ TÀBÍ ÀWỌN ÀKỌRÁNṢẸ́ ÌṢÀKÓSO MÌÍRÀN TÓ JỌ MỌ́ ÈYÍ LÁTI ỌWỌ́ MICROSOFT ÀTI ÀWỌN ALÁÀBÁṢIṢẸ́PỌ̀ TI MICROSOFT JẸ́ ALÁÀKÓSO WỌN. ¨Àwọn àkọránṣẹ́ ìṣàkóso¨ jẹ́ àwọn ìfiránṣẹ́ nípa idunadura àti ìgbà dé ìgbà láti inú iṣẹ́ Microsoft kan pàtó, èyítí ó kàn, ṣùgbọ́n tí kò parí sí ¨ìfiránṣẹ́ ìkínikáàbọ̀¨ tàbí àwọn ìtọ́sọ́nà nípa fífòpin sí gbígba ìfiránṣẹ́. Ìwọ tàbí ọmọ ẹgbẹ́ rẹ tí kò bá fẹ́ láti má a gba irú ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ lè yàn láti dẹ́kun gbígba ìfiránṣẹ́ náà síwájú síi, láti ọwọ́ Microsoft tàbí láti ọwọ́ àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ tí Microsoft jẹ́ aláàkóso wọn, nígbà yòówù, nípasẹ̀ títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí a ti pèsè. Bí o kò bá fẹ́ gba irú àwọn ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ tàbí o kò fẹ́ kópa nínú ẹgbẹ́ náà mọ́, o faramọ́ ọ pé ìwọ yóò dẹ́kun kíkópa rẹ nípasẹ̀ àwọn ìtọ́sọ́nà tí ètò tàbí iṣẹ́ tí à nsọ náà ti pèsè. Bí o bá ní ìdí láti gbàgbọ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ kan kò fẹ́ láti má a gba irú ìfiránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́, tàbí òun kò fẹ́ kópa nínú ẹgbẹ́ náà mọ́, o gbà láti yọ wọ́n kúrò nínú ẹgbẹ́ náà. Ìwọ tún dúró bí aṣojú, o sì tún fún wa ní ìdánilójú pé ìwọ àti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹnití o fún wa ní àṣẹ láti ránṣẹ́ sí ní òye pé ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ó ni ojúṣe fún sísan iye owó ìfiránṣẹ́ yòówù tí olùpèsè iṣẹ́ ẹ̀rọ aláàgbéká rẹ̀ bá bèèrè fún, èyítí ó kan iye owó ìfiránṣẹ́ sí ilú òkèèrè tí ó lè wáyé nígbàtí a bá gbé ìfiránṣẹ́ láti àwọn nọ́mbà tó jẹ́ ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Skype, Microsoft Teams, àti GroupMe
- e. Skype, Microsoft Teams, àti GroupMe.
- i. Àwọn Ìpèsè Pàjáwìrí. Àwọn ìyàtọ̀ pàtàkì wà láàárín alágbèéká tàbí oníforíkorí tó wà tẹlẹ̀ àwọn ìpèsè tẹlifóònù àti Skype, Microsoft Teams, àti GroupMe. Microsoft ní òpin ojúṣe lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè tàbí ti abẹ́lé kànkan, ìlànà tàbí òfin láti fún ọ ní ìráyèsí àwọn iṣẹ́pàjáwìrí, bíi ìpè pàjáwìrí 911 tàbí 112 ("Àwọn Ìpè pàjáwìrì") fún Skype, Microsoft Teams, àti GroupMe. Àwọn ẹ̀yà àìrídìmú tí kò pọ̀ ti Skype sí àbùdá Fóònù lè bá ìpè sí Àwọn Ìpèsè Pàjáwìrì ṣiṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí kò pọ̀, ó sì dá lórí pẹpẹ tí wọ́n lò. O lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa wíwàsílẹ̀ rẹ̀ àti bí o ṣe lè ṣàtúntò àbùdá yìí níbí: https://www.skype.com/go/emergency. Tí ìpè pàjáwìrì Skype sí Fóònù rẹ kò bá sopapọ̀, o ma níláti pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ibi tí o wà láti lè tan àwọn ìpèsè pàjáwìrì láti dá ọ lóhùn.
- ii. APIs tàbí Gbígbé sórí afẹ́fẹ́. Tí o bá fẹ́ lo àwọn àgbéjáde àti ẹ̀yà àìrídimú Skype pẹ̀lú èyíkéyìí gbígbé sórí afẹ́fẹ́ẹ́, o gbọ́dọ̀ faramọ́ "Broadcast TOS" ní https://www.skype.com/go/legal.broadcast. Tí o bá fẹ́ lo èyíkéyìí ọ̀nà ìsopọ̀ ètò ìṣàfilọ́lẹ̀ ("API") tí a ṣàfihàn tàbí jẹ́kó wà nílẹ̀ nípasẹ̀ Skype o gbọ́dọ̀ faramọ́ àwọn àwíyé ìwé-àṣẹ, tó wà nílẹ̀ ní www.skype.com/go/legal.
- iii. Àwọn Ìlànà Ìmúlò lọ́nà tó Jọjú. Àwọn òfin ìlò tó dára ni a le lò sí ìlò àgbéjáde àti ẹ̀yà àìrídìmú Skype rẹ. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹwò àwọn ìlànà wọ̀nyí tí a ṣe láti dáàbòbo ni lọ́wọ́ jìbìtì àti àṣìlò, tí ó sì lè fi àhámọ́ sí oríṣi, iye àkókò tàbí ìwọ̀n dídún ìpè tàbí àkọránṣẹ tí o lè ṣe. A fi àwọn ìlànà yìí sára àwọn Àdéhùn yìí nípasẹ ìtọ́kasi. O le rí àwọn òfin wọ̀nyí ní https://www.skype.com/go/terms.fairusage/.
- iv. Ìlò Tí araẹni/Tí kìn ṣe fún òwò. Ìlò àgbéjáde àti ẹ̀yà àìrídìmú Skype wà fún àdálò rẹ kìíṣe fún ìṣòwò. A gbà ọ́ láàyè láti lo Skype ní ibi-isẹ́ fún àwọn ìbánisọ̀rọ̀ ìṣòwò tìrẹ.
- v. Nọ́mbà Skype/Skype To Go. Tí Microsoft bá pèsè Nọ́mbà Skype tàbí nọ́mbà Skype To Go fún ọ, o gbà wípé ìwọ kọ́ ni o ni nọ́mbà náà tàbí ní ẹ̀tọ́ láti ni nọ́mbà náà títí láí. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, nọ́mbà le wà nílẹ̀ fún ọ nípasẹ̀ alájọṣiṣẹ́ Microsoft yàtọ̀ sí Microsoft, o sì le ní láti ní àdéhùn tó yàtọ̀ pẹ̀lú irú alájọṣiṣẹ́ náà. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé si lórí Nọ́mbà Skype wo https://go.skype.com/home.skype-number.
- vi. Olùṣàkóso Skype. Ìwọ ni ẹnití yóò ṣẹdá, tí yóò sì ṣe àbójútó "Àkọọ́lẹ̀ Aláàbójútó Olùṣàkóso Skype", nínú èyítí ìwọ yóò jẹ olùṣàkóso tó dádúró fún ẹgbẹ́ Aláàbójútó Skype, ṣùgbọn kìí ṣe bí okòwò tó dádúró. O le so àkọọ́lẹ̀ Microsoft ẹnìkọ̀kan rẹ pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Skype ("Àkọọ́lẹ̀ tí A Sopọ̀"). O lè yan àwọn aláàbójútó mìíràn sí ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Skype rẹ bí wọ́n bá faramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Bí o bá fún Àkọọ́lẹ̀ Aláàsopọ̀ kan ní àwọn Nọmba Skype, ìwọ ni ó ni ojúṣe fún títẹ̀lé àwọn òfin tí ó yẹ tó níí ṣe pẹ̀lú ibití àwọn aṣàmúlò Àkọọ́lẹ̀ Aláàsopọ̀ rẹ bá ngbe tàbí tí wọ́n wà. Tí o bá yàn láti yọ Àkọọ́lẹ̀ Tí A Sopọ̀ kúrò láti ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Skype, èyíkéyìí àwọn ìṣalábàápín tí a yàn, Skype Credit tàbí Nọ́mbà Skype ni a kò ni le gbà padà àti pé Àkóónú Rẹ tàbí ohun ìní tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ tí a yọkúrò ni o kò ni le ráyèsí mọ́. O gbà pé kí a lo àlàyé ara ẹni yòówù tó jẹ́ ti àwọn aṣàmúlò Àkọọ́lẹ̀ Aláàsopọ̀ rẹ ní ọ̀nà tó bá àwọn òfin ààbò détà tó yẹ mu. Olùṣàkóso Skype rẹ lè gbà ìdádúró ránpẹ́ bí àwọn ọmọ ikọ̀ bá kùnà láti ṣe ti Òfin Ìṣesí tó wà nínu MSA yìí.
- vii. Owó sísan lórí Skype. Àwọn owó-orí tó yẹ wà lára gbogbo iye owó tí a nsan fún àwọn ọjà Skype tí à n sanwó fún, àfi bí a bá kọ ohun mìíràn nípa èyí. Àwọn iye owó tó yẹ kí a san fún pípè, yàtọ̀ sí àsantẹ́lẹ̀, ni owó àsopọ̀ (tí a ngbà lẹ́ẹ̀kan lórí ìpè kọ̀ọ̀kan) àti iye owó ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan bí a ti ṣe àlàyé nínú www.skype.com/go/allrates. Àwọn owó ìpè ni a ó yọkúrò nínú ìyókù owó Kírẹ́dìtì Skype rẹ. Microsoft le yí iye ìpè rẹ padà nígbàkugbà nípa fífi irú àyípadà náà ṣọwọ́ sí www.skype.com/go/allrates. Iye owó titun náà yóò ní ipa lórí ipè rẹ tó wáyé lẹ́yìn àgbéjáde iye owó titun náà. Jọ̀wọ́ wo àwọn iye owó ìpè titun kí o tó ṣe ìpè rẹ. Àwọn àkókò ìpè tí kò tó odindi ìṣẹjú kan àti iye owó ìpè tí kò tó odindi kan ni a ó kà bí odindi kan. Ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, àwọn àgbéjáde àlòsanwó ti Skype ni alájọṣiṣẹ́ abẹ́lé Microsoft n pèsè àti wípé àwíyé ìlò irú alájọṣiṣẹ́ náà ni a ó lò fún irú ìdúnàádúrà náà. Láìwo èyí tó lọ lọ́wọ́, o lè ní ẹ̀tọ́ si, lábẹ́ òfin tó dè, láti ṣe ìdápadà, èyí tí o bèrè, ti èyíkèyí ìyókù owó ìṣalábàápín àsantẹ́lẹ̀ nígbà tí o ṣe pàṣípàrọ̀ Nọ́mbà Skype rẹ sí olùpèsè míràn.
- viii. Kírẹ́díitì Skype. Microsoft kò fọwọ́sọ̀yà wípé wàá le lo iyókù Skype Credit láti ra gbogbo àgbéjáde Skype, nítorí àlòsanwó lè yípadà láti gbà dé gbà. Tí o kò bá lo Skype Credit rẹ fún ọjọ́ 180, Microsoft yóò fi Skype Credit rẹ sípò àìṣiṣẹ́. O lè tún mú Skype Credit rẹ ṣíṣẹ́ nípa títẹ̀lé àtọ́ka àsopọ̀ fún mímú ṣiṣẹ́ padà ní https://www.skype.com/go/store.reactivate.credit. Tí o bá wà ní Japan o sì ra Skype Credit láti ojúlé wẹ́ẹ̀bù Skype, àwọn gbólóhùn méjì tókàn wọ̀nyí kò kàn ọ́ àti pé Skype Credit rẹ yóò dópin láàrín ọjọ́ 180 lẹ́yìn ọjọ́ ìrajà. Kété tí kírẹ́dìtì rẹ bá dópin, a kò ní le sọ ọ́ dọ̀tun tàbí lòó mọ́. Tí a bá mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin, fún èyíkéyìí èrèdí, èyíkéyìí Skype Credit tí a kò lò tó níṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft ni yóò sọnù a kò sì le gbàá padà. Àwọn kírẹ́dítì Skype lè má lè ṣàgbélọ sí àwọn tókù.
- ix. Páàdì Títẹ Skype. Páàdì Títẹ Skype tó ní ìṣalabàápín tó n ṣiṣẹ́ tàbí Kírẹ́dítì Skype lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì àtẹ iṣẹ́ Skype àti àtòjọ ètò alágbèéká. Páàdì Títẹ̀ Skype jẹ́ àbájáde Skype tí o lè ráyèsí láti inú Microsoft Teams tàbí lórí wẹ́ẹ̀bù.
- x. Iye Owó Àtẹ̀jáde sí Ìlú Òkèèrè. GroupMe a má lo àwọn nọ́mbà tó wà ní Amẹ́ríkà ní báyìí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ikọ̀ tí a bá ṣẹ̀dá. Gbogbo àkọránṣẹ́ tí a firánṣẹ́ sí tàbí tí a bá gbà láti nọ́mbà GroupMe kan ni a ó kà sí àkọránṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè tí a firánṣẹ́ sí tàbí tí a gbà láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Tó dá lórí ibi tí o wà, Microsoft Teams lè ma lo nómbà fóònù tó lè jé àtèjísé eléyo òrò òkè òkun. Jọ̀wọ́ bèèrè lọ́wọ́ olùpèsè rẹ nípa iye owó sísan tó yẹ fún ilẹ̀ òkèèrè.
- xi. Microsoft Teams SMS. Microsoft Teams lè lo àwọn nọ́mbà ti Australia tí Belgacom International Carrier Services SA. pèsè pẹ̀lú ibi ìṣòwò wọn gangan ní Boulevard du Roi Albert II, 27 1030, Bruxelles Belgium ("BICS"), fún àtẹ̀jíṣẹ́ tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí àwọn olùgbà tó ní nọ́mbà Australia. Microsoft àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ kò ní nkan ṣe pẹ̀lú BICS.
Bing àti MSN
- f. Bing àti MSN.
- i. Àwọn Ohun Àmúlò Bing àti MSN. Àwọn átíkù, ọ̀rọ̀, fọ́tò, àwòrán ayé, fídíò, àwọn olùmúṣiṣẹ́ fídíò àti ohun ìní ẹnikẹta tó wà nílẹ̀ lórí Bing àti MSN, pẹ̀lú nípasẹ̀ àwọn bọ́ọ̀tì Microsoft, ìfilọ́lẹ̀ àti ètò, wà fún ìlò àdáni, àìfiṣòwò rẹ nìkan. Àwọn ìlò míràn, pẹ̀lú gbígba ẹ̀dà fáìlì sílẹ̀, ṣíṣẹ̀dà tàbí títún àwọn ohun ìní wọ̀nyí pín kiri, tàbí lílo àwọn ohun ìní wọ̀nyí tàbí àgbéjáde láti kọ àwọn àgbéjáde tìrẹ, ni a gbà láàyè nìkan dé ibi tí Microsoft yọ̀nda tàbí àwọn olóhun ẹ̀tọ́, tàbí èyítí òfin ìmúlò gbà láàyè. Microsoft tàbí àwọn mìíràn tó ní ẹ̀tọ́ ni ó ni gbogbo ẹ̀tọ́ sí àwọn ohun àmúlò náà, èyítí Microsoft kò fifún ni tààrà lábẹ́ àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ náà, yálà nípasẹ̀ èrò tí a mú jáde nínú ohun tí a kò fẹnusọ, nípasẹ̀ àìlè yí èrò tí a fẹ́ kí ohun tí a kò fẹnusọ mú jáde padà, tàbí lọ́nà mìíràn.
- ii. Àwọn Máàpù Bing. O lè ma lo ohun tí a n pè ní Àwòrán ojú ẹyẹ tí United States, Canada, Mexico, New Zealand, Australia tàbí Japan fún ìmúlò ìjọba láì gba àṣẹ ọ̀tọ̀ tí a kọ sílẹ láti ọwọ́ wa.
- iii. Bing Places. Nígbàtí o bá pèsè Détà tàbí Àkóónú Rẹ fún Bing Places o fún Microsoft ní ìwé-àṣẹ káàkiri àgbáyé, àṣẹ́ ìtọ́jú oníbàárà ọ̀fẹ́ láti lò, ṣàtúndá, fipamọ́, ṣàyípadà, ṣàkójọpọ̀, gbé lárugẹ, ṣàfihàn, àti ṣàjọpín Détà àti Àkóónú Rẹ, (pẹ̀lu ẹ̀tọ́ dúkíà ọlọ́gbọ́n nínu Détà àti nínu Àkóónú Rẹ), àti piń ìwé àṣẹ̀ re èyíkèyí tàbí gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ tó n lọ sí àwọn ẹnìkẹtà sí kekèké.
Cortana
- g. Cortana.
- i. Ìmúlò Ara ẹni Tí Kìí Ṣe fún Òwò. Cortana jẹ́ Iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ ara ẹni ti Microsoft. Àwọn ẹ̀yà, iṣẹ́ àti àkóónú tí Cortana ń pèsè (lápapọ̀ "Àwọn Iṣẹ́ Cortana") wà fún àdálò rẹ nìkan kìíṣe fún ìṣòwò.
- ii. Ìṣiṣẹ́ àti Àkóónú. Cortana ń pèsè àwọn oríṣiríṣi àfidámọ̀, lára èyítí ó jẹ́ aládàáni. Àwọn Iṣẹ́ Cortana le gbà ọ́ láàyè láti ráyèsí àwọn iṣẹ́, àlàyé tàbí ìṣiṣẹ́ èyítí Àwọn Iṣẹ́ Microsoft ń pèsè tàbí Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn àti Àwọn Iṣẹ́. Àwọn àdéhùn tó níṣe pẹ̀lú ìpèsè pàtó ní abala 13 tún kan ìlò rẹ fún àwọn Ìpèsè Microsoft tó yẹ, àwọn èyítí a nráyèsí nípasẹ̀ àwọn Ìpèsè Cortana. Cortana a má a pèsè àlàyé fún èrèdí ìṣètò rẹ nìkan, ìwọ sì gbọ́dọ̀ lo òye òmìnira tìrẹ nígbàtí o bá nṣàgbéyẹ̀wò àlàyé wọ̀nyí, tí o sì ngbáralé wọn. Microsoft kò ṣe ìmúdánilójú kankan nípa ṣíṣeé gbáralé, wíwà tàbí ṣíṣiṣẹ́ lásìkò àwọn ìrírí ara ẹni tí Cortana ń pèsè. Microsoft kì yóò dáhùn tí ẹ̀yà Cortana bá pẹ́ tàbí dènà rẹ láti gbà, ṣàtúnyẹ̀wò tàbí fi ìbánisọ̀rọ̀ kan tàbí ìfitónilétí ránṣẹ́, tàbí gbígba iṣẹ́ kan.
- iii. Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta. Bí ara fífi Àwọn Iṣẹ́ Cortana jíṣẹ́, Cortana le dábàá kó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bá Àwọn Ìṣàfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹlòmíràn ṣepọ̀ (ọgbọ́n ẹlòmíràn tàbí àwọn iṣẹ́ tó sopọ̀). Tí o bá yàn, Cortana le pàrọ̀ àlàyé pẹ̀lú Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn, bíi kóòdù ìfìwéránṣẹ́ rẹ àti ìbéèrè àti ìdáhùn tí Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn dápadà, láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gba àwọn iṣẹ́ tí o bèrè fún. Cortana le mú ọ ṣiṣẹ́ láti rajà nípasẹ̀ Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn nípa lílo àwọn ètò àti irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ tí o ti fìdímúlẹ̀ tààrà pẹ̀lú Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn náà. O le ṣèpínyà Iṣẹ́ Cortana rẹ láti Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn nígbàkugbà. Ìlò Àwọn Iṣẹ́ Cortana rẹ láti sopọ̀ mọ́ Àwọn Iṣẹ́ àti Ìṣàfilọ́lẹ̀ Ẹlòmíràn wà lábẹ́ abala 5 ti àwọn Àwíyé wọ̀nyí. Àwọn olùgbéjáde Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta le ṣe àyípadà tàbí fòpin sí iṣẹ́-ṣíṣe tàbí àfidámọ̀ àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnikẹta tàbí ìbáṣiṣẹ́pọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn Ìpèsè Cortana. Microsoft kò ní dáhùn tàbí jẹ gbèsè fún àwọn ẹ̀yà àìrídìmú tàbí fámúwià àwọn olùgbéjáde.
- iv. Àwọn Ohun Èlò Ìmúṣiṣẹ́ Cortana. Àwọn ohun èlò ìmúṣiṣẹ́ Cortana jẹ́ àwọn àgbéjáde tàbí ohun èlò tí a fún lágbára láti ráyèsí àwọn Ìpèsè Cortana, tàbí àwọn àgbéjáde tàbí ohun èlò tó lè bá àwọn Ìpèsè Cortana ṣiṣẹ́. Àwọn ohun èlò ìmúṣiṣẹ́ Cortana pẹ̀lú àwọn ohun èlò ẹnikẹta tàbí àwọn àgbéjáde èyítí Microsoft kò ni, ṣe, tàbí múdàgbà. Microsoft kò ní dáhùn tàbí jẹ gbèsè fún àwọn ohun èlò tàbí àwọn àgbéjáde ẹnikẹta wọ̀nyí.
- v. Àwọn Àfikún Ẹ̀yà Àìrídìmú. A le ṣàyẹ̀wò ẹ̀yà àìrídìmú ti Iṣẹ́ Cortana rẹ ní aládàáṣe kí o sì gba àfikún ẹ̀yà àìrídimú sílẹ̀ tàbí ṣàtòpọ̀ àyípadà tàbí bèrè èyíkéyìí olùṣẹ̀dá ohun èlò ti Cortana múṣiṣẹ́ láti jẹ́ kí ẹ̀yà àirídìmú Iṣẹ́ Cortana rẹ kójú òṣùwọ̀n.
Àwọn ìpèsè àti Àwọn ìfilọ́lẹ̀ Microsoft 365
- h. Àwọn Ìpèsè àti Àwọn ìfilọ́lẹ̀ Microsoft 365.
- i. Lo Àwọn Àdéhùn. MMicrosoft 365 Family, Microsoft 365 Personal, Office Online, Sway, OneNote.com àti èyíkèyí ìfilọ́lẹ̀ tàbí Ìpèsè Microsoft 365 tàbí Àwọn ìpèsè búrándì Office wàfún ìlò àdání rẹ, ìlò tí kìíṣe fún ìṣòwò, àyàfi tí o bá ní ẹ̀tọ́ ìlò ìṣòwò lábẹ́ àdéhùn tó yàtọ̀ pẹ̀lú Microsoft. Lilo awọn ìfilọ́lẹ̀ bii Word, Excel, PowerPoint, Outlook, OneDrive, Access, àti Publisher ni Microsoft 365 Family, Microsoft 365 Personal, àti èyíkéyí ìfilọ́lẹ̀ tàbí ìpèsè alábàápín ti Microsoft 365 miiran ni a ṣakoso nipasẹ awọn ofin iwe-aṣẹ afikun ti o wa ni https://aka.ms/useterms papọ pẹlu Awọn Àdéhùn wọnyi.
- ii. Àfikún Àwon Àdéhùn Outlook. Outlook pẹ̀lú àwọn ìlò Máàpù Bing. Èyíkèyí àkóónú tí a pèsè nípasẹ̀ Àwọn Máàpù Bing, pẹ̀lú geocodes, ni a lè lò láàrín àbájáde náà nípasẹ̀ èyí tí a fi pèsè àkóónú. Ìlò Máàpú Bing ní ni àwọn Ìfẹnukò Ìlò àwọn olùlò Máàpù Bing ṣàkóso èyí tó wà nílẹ̀ ní go.microsoft.com/?linkid=9710837 àti gbólóhùn Ìpamọ̀ Microsoft tó wà nílẹ̀ ní go.microsoft.com/fwlink/?LinkID=248686.
Àwọn Ọjà Onídíjítà
- i. Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà. Nípasẹ̀ Microsoft Groove, Àwọn Fíìmù àti TV Microsoft, Store, Àwọn ìpèsè Xbox àti èyíkèyí ìpèsè tó jẹmọ àti ọjọ́ ìwájú, Microsoft lè gbà, gbọ́ sétí, wò, ṣeré tàbí kà (gẹ́gẹ́ bí o ti lè jẹ́) orin, àwọn àwòrán, fídíò, àyọkà, àwọn ìwé tàbí àwọn ohun èlò tókù ("Àwọn ọjà dígítà") tí o lè gbà ní fóòmù dígítà. Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà wà fún ìmúlò ti ara rẹ nìkan, láì fi ṣòwò, àti fún ìdálárayá rẹ. O gbà láti máṣe tún wọn pín kiri, tàn wọ́n káàkiri, lò wọ́n ní ìta gbangba tàbí kí o fi wọ́n hàn ní ìta gbangba tàbí kí o gbé ẹ̀dà àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà yòówù láti ọwọ́ dọ́wọ́. Àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà lè jẹ́ ti Microsoft tàbí ti àwọn ẹlòmíràn. Ní gbogbo ìgbà, ó yé ọ, o sì gbà pé àwọn ẹ̀tọ́ rẹ nípa àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà ní àhámọ́ nípasẹ̀ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, àwọn òfin ẹ̀tọ́ ọjà-títà, àti, òfin ẹ̀dà ẹ̀tọ́, àti Ìlò Ìlànà tó wà ní https://go.microsoft.com/fwlink/p/?LinkId=723143. O gbà pé ìwọ kì yóò gbìyànjú láti ṣàtúnṣe sí àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà yòówù tí o gbà nípasẹ̀ àwọn Iṣẹ́ náà yòówù fún ìdí yòówù, lára èyí tí ó jẹ́ fún èròngbà àti pa àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà lára dà tàbí láti yí oníhun tàbí orísun wọn padà. Microsoft tàbí àwọn oníhun àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà lè, láti ìgbà dé ìgbà, yọ àwọn Ọjà Oní-nọ́mbà náà kúrò lára àwọn Iṣẹ́ náà láì sọ fún ni.
Ibi ìpamọ́ Microsoft
- j. Ibi ìpamọ́ Microsoft.
- i. Fífúnni ní Ibi ìpamọ́ Onedrive. Bí o bá ní àwọn àkóónú púpọ̀ nínú àkọọ́lẹ̀ OneDrive rẹ, èyí tó ju iye tí a fún ọ lábẹ́ àwọn àdéhùn iṣẹ́ aláàbápín ọ̀fẹ́ tàbí èyítí ó nsanwó fún Ibi ìpamọ́ Microsoft, tí o kò sì fèsì sí ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ Microsoft tó ní kí o ṣàtúnṣe sí àkọọ́lẹ̀ rẹ nípa yíyọ àkóónú tó bá ti pọ̀ jù kúrò tàbí ṣíṣe ètò aláàbápín titun mìíràn tó ní ibi ìpamọ́ tó pọ̀ síi nínú, àwa ní ẹ̀tọ́ láti ti àkọọ́lẹ̀ rẹ pa, kí a sì pa Àkóónú Rẹ lórí OneDrive rẹ́, tàbí kí a mú kí wíwọlé rẹ sí wọn má ṣiṣẹ́ mọ́. Ka díẹ̀ si nipa àwọn ìpín ibi ìpamọ́ Microsoft níbí (https://prod.support.services.microsoft.com/office/how-does-microsoft-storage-work-2a261b34-421c-4a47-9901-74ef5bd0c426).
- ii. Ìṣesí Iṣẹ́ OneDrive. Èyí sì dá lórí àwọn ohun kan bíi àwọn irinṣẹ́ rẹ, àsopọ̀ rẹ lórí ayélujára àti akitiyan Microsoft ní rírí sí ìṣesí àti ìdúróṣinṣin àwọn ìpèsè rẹ̀, Ìwọ lè ní àwọn ìrírí ìdádúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní ṣíṣàgbérù àkóónú tàbí mímú wọn dógbà lórí OneDrive.
- iii. Fífúnni ní Ibi ìpamọ́ Outloo.com. Tí o bá kojá ìpín ìbi ìpamọ́ Outlook.com tàbí ìpín ibi ìpamọ́ Micrsoft tí a pèsè fún ọ lábẹ́ ìṣalábàápín ọ̀fẹ́ tàbí ìsanwófún, o kò ní lè gbà àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí fi àtẹ̀jíṣe ṣọwọ́ títí dìgbà tí o bá yo àpọ̀jù àkóónú tàbí lọ sí ìṣalábàápín tuntun tó ní ibi ìpamọ́ tó pọ̀. Tí o bá kùnà láti yọ àpọ̀jù àkóónú kúrò tàbí gba àfikún ibi ìpamọ́ tó pọ̀ lẹ́yìn tí o gba ìfitónilétí láti Microsoft, a ní ẹ̀rọ́ lati pa ìráyè sí Àkóónú Rẹ rẹ́ tàbí kí a paá. Ka díẹ̀ si nipa àwọn ìpín ibi ìpamọ́ Microsoft níbí (https://prod.support.services.microsoft.com/office/how-does-microsoft-storage-work-2a261b34-421c-4a47-9901-74ef5bd0c426).
Ìsanwópadà Microsoft
- k. Ìsanwópadà Microsoft. Ètò Ìsawópadà Microsoft ("Cashback") máa ń fi ààyè gba àwọn oníbàárà Microsoft láti gba owó padà nígbà tí wọ́n bá rajà lọ́wọ́ àwọn òǹtajà tí ó ń kópa nípa lílo àwọn ọjà àti àwọn iṣẹ́ Microsoft kan bíi Bing.com àti Microsoft Edge. Nípa fíforúkọsílẹ̀ fún Ìsanwópadà tàbí mímú ìfilọ̀ Ìsanwópadà ṣiṣẹ́, o gbà, o sì fara mọ́ Àwọn Àdéhùn àti Àjọsọ Ìsanwópadà (https://www.microsoft.com/bing/rebates-terms). Àwọn àmúyẹ kan pàtó, ààlà, àti àwọn gbèdéke mìíràn wà fún ìkópa rẹ nínú Ìsawópadà; fún àlàyé síwájú síi, wo FAQ Ìsawópadà (https://www.bing.com/rebates/faq).
Microsoft Rewards
- i. Microsoft Rewards.
- i. Àlàyé gbogbogbò. Microsoft Rewards ("Ètò Èrènáà") jẹ́ ọ̀fẹ́ láti darapọ̀, o sì gbà ọ́ láàyè láti gba àmì ("Àmì") fún àwon ìṣe kan pàtó àti fún ìlò ara-ẹni àwọn àbájáde àti iṣẹ́ Microsoft kan. Tí o bá ní àkọọ́lẹ̀ Microsoft tí ó sì wà ní agbègbè tó n kópa (tí a ṣètumọ̀ nísàlẹ̀ yìí), a ti forúkọ rẹ sílẹ̀ sí Ètò Àwọn èrè ó sì le bẹ̀rẹ̀ sí ní gba kókó àmì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. O lè fagi lé ìkópa ẹ nínú Ètò Èrè náà nígbàkugbà nípa títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ̀nà ó wà nísàlẹ̀ yìí.
- ii. O lè ṣe ìyámìpadà àwọn Àmì rẹ pẹ̀lú oríṣiríṣìí àwọn ọ̀nà ("Àwọn Ọ̀nà Ìyámìpadà"), wà pẹ̀lú rẹ̀ fún àwon àbájáde àti àwọn ìpèsè kàn pàtó tí a kò sílẹ̀ lórí Ojú ìwé Ìyámìpadà ní https://aka.ms/redeemrewards ("Àwọn Èrè"). Láti lè jẹ́ èni tó ye láti lè ṣe ìyámìpadà àwọn Àmì rẹ fún Àwọn Ọ̀nà Ìgbàpadà, o ní láti kọ́kọ́ tan àkoọ́lẹ̀ Ètò Èré rẹ ("Àkoọ́lẹ̀ Ètò Èré") lórí Pẹpẹ Àwọn Eré ní https://rewards.microsoft.com/ àbí lórí àwọn ojú òpó wẹ́ẹ̀bù Microsoft àti àwọn ojú ìwé kan pàtó. Kòsí iye owó láti tan Àkọọ́lẹ̀ Àwọn Èrè rẹ.
- iii. Àwọn ìdènà àti gbèdéke kan ní ó jẹ́ lílo láti gbà, yílámìpadà, àti àwọn ìlò tókù ti Àwon Kókó nínu Ètò Àwọn èrè. Fún àlàyé síwájú síi wo abala Àwọn Èrè ní https://support.microsoft.com ("FAQ").
- iv. Àwọn Àmúyẹ. O nílò àkọọ́lẹ̀ Microsoft tó fẹsẹ̀múlẹ̀ o sì ní láti ma gbé ní ìkan lára àwọn agbègbè tí wọn kọ sínú Ìbéèrè Lemọ́lemọ́ FAQ ("Àwọn Àgbègbè") láti mú Àkọọ́lẹ̀ Àwọn èrè rẹ ṣiṣẹ́ àti láti ma gba owó, yílámìpadà, tàbí ki o lo Àwọn kókó. O lè ṣí kí o sì lo Àkọọ́lẹ̀ Àwọn Èrè kan ṣoṣo, kódà tí o bá ní ọpọ̀lọpọ̀ àdírẹ́sì í-meélì. Ìdílé kọ̀ọ̀kan kò ní ju Àkọọ́lẹ̀ Èrè mẹ́fà lọ. Ìlò ara-ẹni àti àìfiṣòwò nìkan ni Ètò Èrè náà wà fún. Ìlò àtagbà aládani orí-ẹ̀rọ (VPN) tàbí ìmọ̀ ẹ̀rọ mìíràn tàbí ìpèsè tó kù tí a lè lò láti bojú tàbí kò jẹ́ kí agbègbè rẹ lè yọrí sí fagilé Àkọọ́lẹ̀ Èrè rẹ kí o sì padànù Àwọn Àmì tí o ti kójọ.
- v. Gbígba Àwọn Àmì. A lè fún ọ ní àwon àǹfàní láti gba Àwọn Àmì fún àwọn ìṣe àmúyẹ kan ("Àwọn Ìfilọ̀ni") bíi Wíwákiri, Àwọn ohun tí o rà, ìlò àwọn àbájáde àti àwọn Iṣẹ́ Microsoft kan pàtó, àti àwọn ànfàní tó kù láti orí Microsoft. O ní Àkọọ́lẹ̀ Àwọn èrè tó n ṣisẹ́ láti gbà àǹfàní irú Àwọn Ìfilọni bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí o bá ti parí àwọn àmúyẹ fún àwọn Ìfilọni kan, ó lè nílò kí o gba Àwọn Àmì orí Pẹpẹ Èrè náà kí o tó lè gba Àwọn Àmì náà kí a sì tó fi kún Àkọọ́lẹ̀ Èrè rẹ. Àìgba Àwọn Èrè náà láàrin àsìkò tí Microsoft là kalẹ̀ lè yọrí sí pípàdánù Àwọn Àmì. Àwọn Ìfilọni tó kójú òsùnwọ̀n lè yàtọ̀ nípasẹ̀ Agbègbè ó sì lè jẹ́ iye àwọn àkókò kan nìkan ni yóò fi wà nílẹ̀ tàbí kí ó wà lábẹ́ àwọn gbèdéke mìíràn. O ní látì tẹ̀lé gbogbo àwọn àdéhùn àti àjọsọ Ìfilọni kan pàtó láti gba Àmì tó ma bá Ìfilọni náà wá. A lè fún ọ ní àwọn Ìfilọni tààrà lórí Pẹpe Èrè tàbí nígbà tí o bá lo àwọn àbájáde tàbí àwọn iṣẹ́ Microsoft kan pàtó. Ní àkókò dé àkókò, Microsoft lè fi lọ̀ oh tàbí kí wọn ó fún ọ ní àwọn àfikún Àmì fúnra lára wọn pẹ̀lú ìfitónilétí ṣaájú tàbí láìfitónilétí ṣaájú, pẹ̀lú àwọn ohun tí Microsoft kà sí Ìwákiri inú ire àti àwọn ìbáṣepọ̀ mìíràn pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Microsoft.
- vi. Fún èrèdí Ètò Èrè, "Ìṣàwákiri" jẹ́ ìṣe olùlò olóríjorí láti fọwọ́ tẹ àyọkà wọlé pẹ̀lú èròngbà rere àti lè gba àwọn àbájáde ìṣàwákiri Bing fún èrèdí ìwádìí irú olùlò bẹ́ẹ̀; "Ìṣàwákiri" kò ní àwọn ìwé ìbéèrè nínú tí wọn kò ní lọ́kàn tàbí tí wọn kò lò fún èròńgbà rere èrèdí ìwádìí ara-ẹni tàbí ìbéèrè tí ẹ̀rọ bèbí tẹ̀wọlé, ẹ̀rọ kékeré, tàbí àwọn ọ̀nà àìfọwọ́yí tàbí ìlujìbìtì mìíràn. Fún èrèdí Ètò Èrè, “Gbígba Nkan” jẹ́ ìgbésẹ̀ ríra àwọn ọjà tàbí ìgbàsílẹ̀ àti gbígba ìwé-àṣẹ kan fún àwọn àkóónú díjítà tààrà láti orí Microsoft, yálà ọ̀fẹ́ tàbí a sanwó fún un. A kì í fúnni ní Àmì fún gbogbo ohun tí a bá rà láti ọwọ́ Microsoft, àwọn gbèdéke kan sì máa jẹ́ lílò.
- vii. Àwọn ìdènà àti Àwọn gbèdéke lórí Àmì. Microsoft ló n fún ní ní Àmì sí Àwọn àkọọ́lẹ̀ Àwọn Èrè olúkúlùkù, a kò sì lè taari rẹ̀ sí ẹlòmíràn tàbí nkan. Láìwo èyí tó lọ, Microsoft lè ti ìgbà dé gbà pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ fi ààyè gbà ọ́ (i) láti pín Àmì láàrín ìdílé rẹ (gbèdéke lè wà), (ii) láti dá Àmì rẹ jọ láti ṣatìlẹ́yìn fún àjọ aṣọ̀fẹ́ tó wà lórí Ojú-ewé Ìyámìpadà rẹ, tàbí (iii) tó dá lórí Agbègbè rẹ tàbí tí ó wà lábẹ́ àdéhùn àti àjọsọ miíràn, láti gba gbogbo rẹ tàbi díẹ̀ lára Àmì nínú àwọn ètò èrè kan mìíràn tàbí ìfifúni, pẹ̀lú àwọn etò tí Microsoft darí tàbí ẹnìkẹta tí wọn fún láṣẹ. Àwọn àmì jẹ́ dukìá Microsoft, yóò sì wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kò sì ní jẹ́ dúkìá ti ara rẹ; wọn kò ní iye owó lórí, o sì lè má gba owó tàbí gba owó dípò wọn. Gẹ́gẹ́ bí ohun ìgbọ́jàlárugẹ nìkan ni a fi ń fún ọ ní Àmì. Ìwọ kò lè ra Àmì. Microsoft lè ní gbèdéke fun iye Àmì tàbí Èrè tí o lè gbà tàbí yílámìpadà gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, fún ìdílẹ́ kànkan, tàbí ní àkókò tí a ṣètò (àpẹrẹ ọjọ́ kan) tó bá jẹ́ pé o ní ànfàní ìgbàgbọ́; jọ̀wọ́ lo sí ìbéèrè lémọ́lemọ́ FAQ fún àwọn gbèdéke tó jẹ́ lílò tó lọ lọ́wọ́. Àyàfi tí Ẹyàn Ìfúni tàbí Ìranipadà kò bá sọ ọ́ kedere, Àwọn Àmì tí o bá gbà nínú Ètò náà kò wúlò, o kò sì lè lò wọ́n pọ̀ mọ́ ètò mìíràn tí Microsoft tàbí tí àwọn ẹnìkẹta bá filọni. Ọjọ́ yóò lọ lórí Àwọn Àmì tí a kò ní ìranipadà tó so mọ́ Àkọọ́lẹ̀ Èrè rẹ tí o kò bá gbà tàbí ìràpadà èyíkéyìí nínú àwọn Àmì inú Àkọọ́lẹ̀ Eré re fún oṣù 12 tẹ̀lérawọn.
- viii. Ìràpadà. Àwọn ẹ̀yán Ìràpadà yóò wà nilẹ̀ fún ọ lórí Ojú ìwé Ìràpadà àti lorí àwọn ojú-òpó wẹ́ẹ̀bù kan Microsoft pàtó àti àwọn ojú ìwé. O ní láti gba owó kí o sì ní gbogbo Àkọọ́lẹ̀ Àwọn Èrè gbogbo Àmì tí o nílò fún Ọ̀nà Ìràpadà kí o tó lè yí Àmì rẹ padà fún Ọ̀nà Ìràpadà yẹn. Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé iye kékeré ni ó wà nílẹ̀ fún Èrè kan pàtó, a ó sì fi Èrè wọ̀nyẹn jíṣẹ́ pẹ̀lú òṣùwọn bí a bá ṣe tètè dé sí. A lè bèrè pé kí o pèsè àfikún àlàyé, gẹ́gẹ́ bí àdírẹ́ẹ̀sì ìfìwéránṣẹ́ rẹ àti nọ́mbà fóònù rẹ (yàtọ̀ sí VOIP tàbí nọ́mbà tí a fi n pè lọ́fẹ̀ẹ́), a sì tún lè bèrè pé kí o tẹ kóòdù adènà jìbìtì tàbí kí o fọwọ́sí àfikún ìwé lábẹ́ òfin láti ṣe ìràpadà fún ọ̀nà Ìràpadà kan pàtó. Lọ́gán tí o bá ti gba Àwọn Àmì rẹ padà, ìwọ kò lè fagilé e mọ́ o kò sì lè dá Àwọn ẹ̀yàn Ìràpadà láti fi gba Àmì padà mọ́, àfi ní àwọn ìgbà tí àgbéjáde kan bá ní àlébù tàbí bí òfin bá ṣe ní kí a ṣeé. Bí o bá yan Ọ̀nà Ìràpadà kan tí kò sí tàbí tí kò sí nílẹ̀ fún àwọn ìdí mìíràn, a lè fi Ọ̀nà Ìràpadà tó jẹ́ iye kan náà tàbí dá Àmì re padà láyè ara rẹ.
- ix. Microsoft lè ṣe ìmúdójúìwọ̀n tàbí ṣe ìdádúró fífúní ní Àwọn Ọ̀nà Ìràpadà kan pàtọ́ nígbàkúùgba fún ìdí yìówù. Àwọn Ọ̀nà Ìràpadà lè ní ọjọ́ orí tàbí àwọn àmúyẹ Agbègbè tó yẹ, tàbí àwọn àdéhùn tàbí àjọsọ lórí ìràpadà tàbí ìlò wọn. Irú àmúyẹ bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn ipò yóò jẹ́ mímú wọlé sínú ìfìlọ̀ ìràpadà tó ṣe pàtàkì. Ìwọ ni o ma dáhùn fún gbogbo àwọn owó-orí ìjọba àpapọ̀, ti ìpínlẹ̀ àti ti ìbílẹ̀, àti fún owó mìíràn yòówù fún gbígbà àti lílo Àwọn ẹ̀yán ìràpadà. A ó fi àwọn èrè ránṣẹ́ sí àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì tó so mọ́ àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, fún ìdí èyí jẹ́ kí àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ kójú pé. À kò ní tún Àwọn Èrè tí a kò rí fi jíṣẹ́ fún ni, nítorí náà a ó gbẹ́sẹ̀ lé wọn. A kò lè tún àwọn èrè tà. Ìwọ kò lè gbà ju Àwọn Àmì 550,000 lọ ní ọdún orí kàlẹ́ndà kan nínú Ètò Èrè náà.
- x. Fífagilé Àkọọ́lẹ̀ Èrè Rẹ. Bí o kò bá fẹ́ láti kópa nínú Ètò Èrè náà mọ́, tẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó wà lórí ojú-ewé ìjádekúrò (https://rewards.microsoft.com/optout) láti fagilé Àkọọ́lẹ̀ Èrè rẹ. Tí o bá fagilé Àkọọ́lẹ̀ Àwọn Èrè rẹ, o máa pàdánù gbogbo Àwọn Àmì tí o ti gbà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ o sì máá sọ ipa láti gba Àwọn Àmì tuntun ní ọjọ́ ìwájú nù. Láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba Àwọn Àmì padà, o gbọdọ̀ ṣí Àkọọ́lẹ̀ Àwọn Èrè tuntun kan (ṣùgbọ́n Microsoft kò ní dá Àwọn Àmì tí o ti pàdánù tẹ́lẹ̀ padà). Àkọọ́lé Àwọn èrè Rẹ lè jẹ́ fífagilé (kí o sì pàdánù Àwọn Àmì rẹ) bí o kò bá wọlé sínu àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ fún oṣù 12 tẹ̀léra wọn.
- xi. Àyípadà Ètò tàbí Ìdádúró. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti ṣàyípadà, ṣàtúnṣe, dádúró, tàbí fagilé Ètò Àwọn Èrè náà tàbí èyíkèyí ara rẹ̀ nígbàkugbà, ní ayè ara rẹ, láìgbà ìfitónilétí ṣaájú. Bákan náà, bí Ètò Èrè bá jẹ́ fífagilé tàbí jẹ́ dídádúró, a máa ṣàkitiyan tó yẹ láti fi tó ọ létí nípasẹ̀ í-meélì àti lórí Pẹpẹ Èrè àti láti fún ọ ní ó kéré tán ọjọ́ 90 láti ṣèyámìpadà Àwọn Àmì tí o ti kójọ, àyààfi tí a bá pinu pé irú ìfagilé bẹ́ẹ̀ ní láti bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ fún àwọn ìdí òfin àti ààbò.
- xii. Àwọn Àdéhùn Tókù. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti fagilé Àkọọ́lẹ̀ Àwọn Èrè rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, yọ ọ́ kúrò nínú ìkópa fún Ètò Èrè ní ọjọ́ ìwájú, gbésẹ̀lé gbogbo Àwọn Àmì tí o ti gbà, àti ìfagilé tàbí ìdádúró Ọ̀nà Ìràpadà tí o ti gba nípasẹ̀ Ètò Èrè tí Microsoft bá gbàgbọ́ pé o ti kọwọ́bọ̀, ṣàṣìlò, tàbí ṣe jìbìtì ara Ètò Àwọn Èrè yìówù tàbí rúfin àwon àdéhùn wọ̀nyìí. Microsoft tún ní ẹ̀tọ́ láti fagilé tàbí dá èyíkèyí Ọ̀nà Ìràpadà dúró díẹ̀ tí o bá gba tàbí gbìyànjú láti gbà á nípasẹ̀ Ètò Àwọn Èrè bí Microsoft bá pinu pé o kò yẹ láti gba Ọ̀nà Ìràpadà fún àwọn ìdí òfin (bíi àwọn òfin àgbéjáde). Pẹ̀lú bí Microsoft ṣe n sapá láti rí i dájú pé ìgúnrégé wà, àṣìṣe kò sì wọ́pọ̀. Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti ṣàtúnṣe irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ nígbàkugbà, kódà tí ó bá nípa lórí àwọn Ìfúni tuntun tàbí tí wọ́n dádúró, èyí tí o gbà, tàbí Àwọn Àmí èrè tàbí Àwọn èrè. Nínú àìṣedéédé tàbí tí àṣìṣe bá wà nínú àwọn àdéhùn Ètò Èrè wọ̀nyìí tàbí àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó ní ohun tí ó jọ mọ́ ọn tàbí ìpolówó-ọjà, àwọn ìfẹnukò wọ̀nyìí ni wọn yóò dúró, jọbà, àwọn ni wọn yóò sì ṣèdarí.
Azure
- m. Azure. Ìlò Azure rẹ ni àwọn àwíyé àti ipò ti àdéhùn míràn ń darí lábẹ́ èyítí p ti gba àwọn iṣẹ́, bí a ti ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ojú ìwé ìwífún Ofin Microsoft Azure ní https://aka.ms/AA7z67v.
Microsoft Soundscape
- n. Microsoft Soundscape. O gbà pè Microsoft Soundscape (1) a kò dásílẹ̀, pọndádán, tàbí wà fún ohún èlò ìṣègùn, ati (2) a kò dásílẹ̀, pọndádán láti jé arópo fún ìmọ̀ràn ìṣègùn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ wíwá àìsàn, ìtọ́jú, tàbí ìdájọ́ ka sì ma lòó láti rópò tàbí lòó fún ìmọ̀ràn ìṣègùn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, wíwá àìsàn, ìtọ́jú, tàbí ìdájọ́.
Pẹpẹ Agbára
- o. Pẹpẹ Agbára. Ìlò ìpèsè Pẹpẹ Agbára rẹ ni àwọn àwìyẹ àti ipò darí tó jé àdéhùn tó yàtọ̀ lábẹ́ èyítí bí a ti ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ojú ìwé ìwífún Ofin Pẹpẹ Agbára ní Pẹpẹ Agbára Microsoft (https://www.microsoft.com/en-us/power-platform/business-applications/legal).
Dynamics 365
- p. Dynamics 365. Ìlò ìpèsè Dynamics 365 rẹ ni àwọn àdehùn àti ipò darí ti àdéhùn tó yàtọ̀ lábẹ́ èyítí o gba àwọn ìpèsè, ti ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ojú ìwé ìwífún Ofin Dynamics 365 ní Microsoft Dynamics 365 (https://www.microsoft.com/en-us/dynamics-365/business-applications/legal).
Àwọn Ìrírí Copilot AI
- q. Àwọn Ìrírí Copilot AI. Ìlò Àwọn Ìrírí Copilot AI rẹ (àyààfi Copilot pẹ̀lú ààbò détà oko-òwò) wà lábẹ́ àṣẹ àwọn àfikún àdéhùn àti àjọṣọ tí ó rọ̀ mọ́ àwọn iṣẹ́ tí o sanwó fún náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ ṣe wà ní Copilot - Àwọn àdéhùn ìlò (bing.com) (https://www.bing.com/new/termsofuse#content-policy) pẹ̀lú àwọn àdéhùn wọ̀nyìí. Bí o bá jẹ́ Copilot Microsoft pẹ̀lú olùlò ààbò dátà oko-òwò, jọ̀wọ́ ṣàbẹ̀wò sí ojú-ewé yìí láti ṣàtúnyẹ̀wò àdéhùn ìlò tí ó kàn ọ́, pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyìí: https://aka.ms/BCETermsOfUse.
Àwọn Ìpèsè AI
- r. Àwọn Ìpèsè AI. "Àwọn ìpèsè AI" jẹ́ àwọn ìpèsè tàbí àwọn àbùdá tó lo àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ Ọgbọ́n Àpilẹ́rọ (AI), pẹ̀lú àwọn ìpèsè AI àtọwọ́dá.
- i. Kò sí Àmọ̀ràn Àkọ́ṣẹ́mọṣẹ́. A kò ṣètò àwọn ìpèsè AI, pẹ̀lú èròngbà, tàbí láti lò wọ́n dípo àmọ̀ràn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.
- ii. Ìdápadà sẹ́yìn Ìmọ̀ ẹ̀rọ. O lè má lo àwọn ìpèsè AI láti ṣàwárí àwọn nkan ìpìlẹ̀ yìówù ti àwọn àwòṣe náà, àwọn ọ́gírídíìmù, àti àwọn ẹ̀rọ. Fún àpẹẹrẹ, o lè má gbìyànjú láti pinnu tàbí láti yọ ìwọ̀n àwòṣe tàbí yọ ẹ̀yà àwọn ìpèsè AI yìówù kúrò nínú ohun èlò ẹ̀rọ rẹ.
- iii. Fífa Détà jáde. Àyàfi tí ó bá gba àṣẹ tó hàn kedere, o lè má lo fífá wẹ́ẹ̀bù, kíkó èrè wẹ́ẹ̀bù, tàbí àwon ìlànà fífa détà wẹ́ẹ̀bù jáde láti fa détà jáde nínu àwon ìpèsè AI.
- iv. Gbèdéke lórí ìlò détà láti Àwọn Ìpèsè AI. O lè má lo Àwọn ìpèsè AI, tàbí détà láti inú àwọn ìpèsè AI láti ṣẹ̀dá, kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, tàbí ṣègbélárugẹ (tààrà tàbí àìlọtààrà) èyíkèyí ìmọ̀ ẹ̀rọ AI.
- v. Ìlò Àkóónú Rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ara pípèsè àwọn ìpèsè AI, Microsoft máa ṣètò, yóò sì fi àwọn ohun tí o mú wọlé sí ìpèsè náà àti àwọn àbájáde ìpèsèẹ́ náà pamọ́, fún àmójútó àti láti dèènà èébú tàbí àwọn ìlò to lè ṣeni ní ìjàmbá tàbí àwọn àbájáde ìpèsè náà.
- vi. Ìjónínkan Àkóónú. Microsoft kò ní fira rẹ̀ pe onínkan àwọn àkóónú yìówù kí o pèsè, fi sóde, mú wọlé, tà dá sílẹ̀ fún, tàbí tí o gbà láti inú, àwọn ìpèsè AI (pẹ̀lú àwọn ààbọ̀ àti àwọn àbá). O ó nílò láti mú ìpinnu tìrẹ nípa àwọn ẹ̀tọ dúkìá ọpọlọ tí o ní nínú àwọn àkóónú àbájáde àti ìlò rẹ̀, kíyèsí, nínú àwọn nkan mìíràn, (àwọn) àpẹẹrẹ ìlò rẹ àti àwọn òfin àwọn ṣàkáá́ní tí ó ṣe pàtàkì. O fara mọ́ o sì jẹ́ asọjú pé ìwọ ni o ni ín tàní ìwọ ni ò n tarí gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ àkòónú rẹ gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú àwọn Àdéhùn tí ó so mọ́ ọn, láìsí gbèdéke, gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ tí ó ṣe pàtàkì fún ọ láti pèsè, ṣàgbéjáde, ṣàgbésókè, ṣàmúwọlé, tàbí fa àkóónú náà kalẹ̀.
- vii. Àwọn àlàyé àkóónú. Nígbàtí o bá lo àwọn ìpèsè AI láti ṣàgbéjáde àkóónú, Microsoft lè fi àlàyé nípa àkóónú náà pamọ́ yóò sì kó àlàyé yìí àti àkóónú pẹ́ pẹ̀lú àwọn ìwé ẹ̀rí àkóónú. O lè má lo àwọn ìpèsè AI yìí tàbí ṣèdásílẹ̀ àkóónú pẹ̀lú ìdí yíyọkúrò, ṣíṣàtúnṣe, ìdílọ́wọ́, tàbí fífi àwọn àláyè àkóónú pamọ́ tàbí ìlànà ẹ̀rí, àmì, tàbí ìṣàmì bíbẹ́kọ́ọ̀ lo àwọn ìpèsè AI láti ṣàgbéjáde àkóónú fún ìdí ìṣinilọ́kàn àwọn tókù nípa bóyà wọ́n ṣàgbéjáde àkóónú nípa lílo àwọn ìpesè AI.
- viii. Gbígba ẹ̀tọ́ Ẹnìkẹta. Ọwọ́ rẹ nìkan ni dídáhùn sí àwọn gbígba ẹ̀tọ́ ẹnìketà nípa ìlò Rẹ ti àwọn ìpesè AI Rẹ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin tó yẹ wà (pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò pin sí, ìtàpá sófin àṣẹ-ẹ̀dà tàbí àwọn ẹ̀tọ́ tókù tó jẹ mọ́ àbájáde àkóónú lásìkò ìlò àwọn ìpèsè AI rẹ).
- ix. Àwọn ìdènà Ìlò. Láfikún fún fífaramọ́ "Òfin Ìṣesí" lókè, o gbà pé o kò ní lo àwọn ìpèsè AI, pẹ̀lú àwọn tó ṣe ìpinu, tàbí ṣe iṣẹ́ fún ra wọn tàbí ìpele orísi ìdásí ọmọ ènìyàn.
- 1. Láti ṣe ìpinu tàbí gbé ìgbésè láìsí ènìyàn tó yẹ nibẹ̀ láti ṣọ tó lè ní ìpalára àtubọ̀tán lórí ipò òfin ẹnikẹni, ipò ìṣúná, àwọn ànfàní ayé, àwọn ànfàní iṣẹ́, tàbí ẹ̀tọ ọmọnìyàn, tàbí tó lè fa ìjàmbá ara tàbí ọpọlọ sí ẹnìkan tàbí ìkọ̀ àwọn ènìyàn;
- 2. Láti tàn ènìyàn jẹ tàbí kí o mọ̀ọ́mọ̀ sọ ọ̀rọ̀ tí kpo rí bẹ́ẹ̀ (àpẹrẹ., ìpolówó irọ́), tàbí lílo àwọn ipa tí wọn kò mọ́ (àpẹrẹ, àfojúrí, àfetígbọ́, tàbí àwọn ìṣàmì tókù tó kọjá òyè ènìyàn) pẹ̀lú èrò láti yí ọkàn ènìyàn padà tàbí da ìwá ènìyàn rú ní ọ̀nà tó fa ìjàmbá;
- 3. Láti lo ipò ìwálẹ̀ ènìkan látàrí ọjọ́ orí, abárapá, tàbí ipò àwùjọ tàbí ọ̀rọ̀ ajé kan pàtó, pẹ̀lú èròngbà, tàbí ipa, ìwà tó jẹ́ pé ohun kan ló jẹ́ kí ẹni náà ṣe ìpinu tí kò yẹ kò ṣe tàbí èni tó wà nínu ikọ̀ yẹn ní ọ̀nà tó lè fà tàbí tó ṣeéṣe láti fa kí ènìyàn bẹ́ẹ̀ wà ní ipò yẹn tàbí ìjàmbá tí èlómíràn ṣe fun;
- 4. Fún àmì ayò àwùjọ tàbí mímọ ènìyàn tó lè fà ìyàsọ̀tọ̀, ìṣesí ìjàmbá tí kò dára, ẹlẹ̀yà, tó fa ewu, tí kò gbe ni, tí àwọn ènìyàn kan pàtó tàbí ìkọ̀ àwọn ènìyàn;
- 5. Fún àyẹ̀wò ewu ọ̀daràn ti àwọn ènìyàn tó dá lórí bí àwọn ènìyàn ṣe ri ènìyàn náà sí tàbí àyẹ̀wò ìhùwàsí àti ìwà wọn. Èwọ̀ yìí kò ní jẹ́ lílò sí àwọn ìpèsè AI tí à n lò láti ṣàtìlẹ́yìn bí ènìyàn ṣe rí àti ipa tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ìṣe ọ̀daràn, eléyì tó dá lórí àwọn ẹ̀rí tí a ṣàrídájú tó sopọ̀ mọ́ ìṣe ọ̀daràn tààrà;
- 6. Látàrí dátà ẹ́kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ara wọn, láti pín àwọn ènìyàn sí ìsọ̀rí tàbí mọ̀ tàbí ní òye nípa ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá, òṣèlú, ọmọ ẹgbẹ́ káràkátà, ẹ̀sìn tàbí ìgbàgbọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ayé, tàbí ìbálòpọ̀ tàbí ìmọ̀ nípa ìbálòpọ̀, àyàfi dátà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ẹni tí wọ́n kò kọsílẹ̀ tó bófinmú, bíi àwọn àwòrán, tó dá lórí dátà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ara ẹni tàbí ìsọ̀rí dátà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ẹni ní ibi ìgbófinró.
- 7. Láti ṣèdásílẹ̀ tàbí fẹ dátà ìdámọ̀ ojú nípasẹ̀ fífa ibikíbi ní àwọn àwòrán ojú láti orí íntánẹ́ẹ̀tì tàbí fídíò CCTV;
- 8. Fún ìmọ̀ ẹ̀rọ ìdánimọ̀ ojú lórí afẹ́fẹ́ lórí àwọn ayàwòrán alágbèéká tí èyíkèyí agbófinró lágbàáyé lò láti gbìyànjú láti dá olúkúlùkù mọ̀ ní àìdarí, ní agbègbè "aginjù", pẹ̀lú (láìsí ìdíwọ́) àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n rìn kiri tí wọ́n wọ ayàwòrán sí inú ara wọn tàbí àwọn ayàwòrá tó wà ní ìwájú ọkọ́ wọn nípa lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìdámọ̀ ojú láti gbìyànjú láti dá àwọn ènìyàn tó wà nínu dátà àkọsílẹ̀ àwọn afurasí tàbí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ti tú sílẹ̀; tàbí
- 9. Láti gbìyànjú láti mọ ipò ọkàn àwọn ènìyàn nínu àwọn ìwà bí ìwa ara , ọpọlọ (àpẹrẹ bí wọ́n ṣeṣe ojú, bí wọ́n ṣe yí ojú, tàbí bí wọ́n ṣe n sọ̀rọ̀) pẹ̀lú mímọ àwọn ipò ọkàn bíi ìbínú, ìkórira, ìdùnú, ìbànújẹ́, ìyàlẹ́nu, ìbẹ̀rù, tàbí àwọn ìfẹnukò tókù tí wọ́n ma n lò láti ṣàpèjúwé ipò ọkà ènìyàn.
Àwọn Ìpèsè Ìbánisọ̀rọ̀
- s. Àwọn Ìpèsè Ìbánisọ̀rọ̀. Àwọn ìpèsè jẹ́ kí ìbánisọ̀rọ̀ wà láàrín olúkúlùkù, tó wà nínu rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò pín sí Skype, Teams, Outlook, àti GroupMe, ni ìfẹnukò ìlò àfikún darí tó wà ní https://aka.ms/useterms lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn Ìfẹnukò wọ̀nyí.
Ǹkan pẹ́pẹ̀pẹ́
14. Oníruru. Abala yìí, àti abala 1, 9 (fún iye owó tó yẹ fún sísan ṣáájú òpin àwọn Àdéhùn wọ̀nyí), 10, 11, 12, 15, 17 àti àwọn tó jẹ́ pé nípasẹ̀ àdéhùn wọn, wọn yóò ní ipa lẹ́yìn tí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí bá ti parí, yóò rékọjá ìfòpinsí tàbí fífagilé yòówù fún àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Títí dé ibití òfin tó yẹ gba ni láàyè dé, a lè pín àwọn Àdéhùn wọ̀nyí fún ni, gbé ojúṣe wa fún ẹlòmíràn lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, tàbí kí a fún àwọn ẹlòmíràn ní ìwé-àṣẹ fún àwọn ẹ̀tọ́ wa lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, nígbà yòówù láì sọ fún ọ. O kò gbọdọ̀ pín àwọn Àdéhùn wọ̀nyí fún ni tàbí kí o fi ẹ̀tọ́ yòówù láti lo àwọn Iṣẹ́ náà fún ẹlòmíràn. Èyí ni gbogbo àdéhùn láàárín ìwọ àti Microsoft fún ìmúlò rẹ fún àwọn Iṣẹ́ náà. O rékọjà àdéhùn ìṣáájú yòówù láàárín ìwọ àti Microsoft nípa ìmúlò rẹ fún àwọn Iṣẹ́ náà. Ní fífaramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ìwọ kò gbáralé gbólóhùn yòówù, ìṣojú fún ni, àtìlẹ́yìn, òye, ìlérí tàbí ìfinilọ́kànbalẹ ju bí a ti sọ nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí lọ. Gbogbo abala àwọn Àdéhùn wọ̀nyí yóò ní ipa títí dé ibití òfin tó yẹ gba ni láàyè dé. Bí ilé-ẹjọ́ kan tàbí onílàjà bá ṣe ìdájọ́ pé a kò lè lo abala kan lára àwọn Àdehùn wọ̀nyí bí a ti kọ ọ́, a lè fi àwọn àdéhùn tó jọ́ èyí rọ́pò àwọn irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ títí dé ibití wọ́n ti ṣeé lò dé lábẹ́ òfin tó yẹ, ṣùgbọ́n àwọn tó kù lára àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kì yóò yípadà. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà fún ànfàní ìwọ àtí àwa nìkan. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kò sí fún ànfàní ẹlòmíràn, àfi fún àwọn tí yóò jogún Microsoft àti àwọn tí Microsoft bá yàn. Àkórí-ọ̀rọ̀ àwọn abala wà fún ìtọ́kasí nìkan, wọn kò sì ní ipa kankan lábẹ́ òfin.
15. A Gbọ́dọ̀ Mú Ẹ̀sún Wá Láàárín Ọdún Kan. Ẹ̀sùn yòówù tó bá níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tàbí àwọn Iṣẹ náà ni a gbọ́dọ̀ mú wá sí ilé-ẹjọ́ (tàbí sọ́dọ̀ onílàjà bí abala 10.d bá ní ipa) láàárín ọdún kan sí ọjọ́ tí ó lè kọ́kọ́ mú ẹ̀sùn náà wá, àfi bí òfin agbègbè rẹ bá nílò àkókò tó ju èyí lọ láti mú ẹ̀sùn wá. Bí o kò bá múu wá láàárín àkókò náà, ó ti di ohun tí a dínà mọ́ láíláí.
16. Àwọn Òfin Ọjà Gbígbé Lọ Sí Òkèèrè. O gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún gbogbo òfin àti ìlànà gbígbé ọjà lọ si ilẹ òkèèrè fún títà ti ìlú ẹni àti ti ilẹ òkèèrè ti o kan software àti/tàbí Iṣẹ́ náà, èyí tí ó kan ìhámọ́ ní ibití a ngbé ọjà lọ, awọn aṣàmúlò ìkẹyìn, àti ìmúlò ìkẹyìn. Fún àlàyé síwájú síi nípa àwọn ìhámọ́ lórí ilẹ̀ àti ti gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà, lọ sí https://www.microsoft.com/exporting.
17. Ìtọ́jú Ẹ̀tọ́ àti Ìjábọ̀. Àyàfi bí a ti pèsè lábẹ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, Microsoft kò fún ọ ní ìwé àṣẹ tàbí èyíkéyìí ẹ̀tọ́ míràn bó ti wù kó rí lábẹ́ àṣẹ kankan, bí o ti le ṣeé, ẹ̀tọ́ ìtajà, àṣírí ìṣòwò, àmì òwò tàbí ohun ìní àkọsílẹ̀ míràn tí a ni tàbí tí Microsoft ń darí tàbí èyíkéyìí ilé-iṣẹ́ tójọra, pẹ̀lú ṣùgbọ́n kò pín sí orúkọ kankan, ìmúra òwò, àmì ìdánimọ̀ tàbí ohun míràn tójọra. Tí o bá fun Microsoft ní ọgbọ́n-inú kankan, ìwé àgbéyẹ̀wò, àbà tàbí ìjábọ̀, pẹ̀lú ọgbọ́n-inú àìlópin fún àgbéjáde titun, ìmọ̀-ẹ̀rọ́, ìpolówó ọjà, orúkọ àgbéjáde, ìjábọ̀ àgbéjáde àti ìmúgbòrò àgbéjáde (""Ìjábọ̀""), tí o fún Microsoft, láì díyelé, owó àjẹmọ́nù tàbí ojúṣe míràn fún ọ, ẹ̀tọ́ láti ṣe, tí o ti ṣe, ṣẹ̀dá àwọn iṣẹ́ àwárí, lò, ṣàpínlò kí o sì ṣòwò Ìjábọ̀ rẹ ní ọ̀nàkọnà àti fún èrèdí kankan. O kò ní fún ní Ìjábọ̀ tó wà lábẹ́ ìwé àṣẹ tó nílò kí Microsoft fún ẹ̀yà àìrídìmú, ìmọ̀-ẹ̀rọ tàbí ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ìwé-àṣẹ sí ẹnikẹta kankan nítorí Microsoft ṣàfikún Ìjábọ̀ rẹ nínú wọn.
ÀKÍYÈSÍ
Àwọn àkíyèsi àti ìlànà fún mímú ẹ̀sùn wá fún títàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ ẹni. Microsoft nbọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ àwọn ẹlòmíràn. Bí o bá fẹ́ fi àkíyèsi nípa ìtàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ rẹ ránṣẹ́, èyí tí ó kan ẹ̀sùn fún ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa, jọ̀wọ́ lo ìlànà tó wa fún fífi ránṣẹ́ Àwọn Àkíyèsi Ìtàpásí (https://www.microsoft.com/en-us/legal/intellectualproperty/infringement) àwọn ètò wo lo kò ara Àwọn àdéhùn yìí jọ. ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ ṢE PÀTÀKÌ SÍ ÌLÀNÀ YÌÍ NÌKAN NI A Ó FÈSÌ.
Microsoft a má a lo àwọn ìlànà tí a gbékalẹ̀ ni Àkórí 17, Kóòdù United States, Abala 512, àti, ibi tó yẹ, Chapter III of Regulation (EU) 2022/2065, láti fèsì sí àwọn àkíyèsi nípa ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa. Ní àwọn ìgbà tó yẹ, Microsoft lè mú àkọọ́lẹ̀ àwọn aṣàmúlò àwọn iṣẹ́ Microsoft tó jẹ́ olùtàpá sí ẹ̀tọ́ nígbà gbogbo má ṣiṣẹ́ tàbí kí ó múu dópin. Fún ìlọsíwájú si, ní àwọn ipò to yẹ, Microsoft lè dá àwon ìfitónilétì ìṣètò dúrò díẹ̀ nípasẹ̀ àwọn olúkúlùkù tàbí àwọn ǹkan tó má ń fa àwọn ìfitónilétì kalẹ̀ lemọ́lemọ́. Àlàyé síwájú si ti àwọn ètò tó níṣe fún Ìpèsè, pẹ̀lú àtúnṣe fún àwọn ìpinu tí Microsoft ṣe gẹ́gẹ́ bí ara àwọn ètò wọ̀nyí, ní a le rí ní Àwọn àkíyèsí Ìtàpasófin (https://www.microsoft.com/legal/intellectualproperty/infringement).
Àwọn àkíyèsi àti ìlànà nípa ohun tó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ nínú ìpolówó ọjà. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹ̀wò Àwọn Ìtọ́sọ́nà nípa Ohun-ìní Iṣẹ́ Ọpọlọ (https://go.microsoft.com/fwlink/?LinkId=243207) nípa àwọn ohun tó níí ṣe pẹ̀lú ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ nínú nẹtiwọki ìpolówó ọjà.
Àwọn àkíyèsi nípa ẹ̀tọ́ ọjà-títà àti ààmì ọjà-títà. Àwọn Ìpèsè náà jẹ́ ẹ̀dà àṣẹ © Microsoft Corporation àti/tàbí àwọn olùpèsè rẹ, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ní ìpamọ́. Àwọn Àwíyé náà ṣàmúlò Microsoft Trademark & Brand Guidelines (https://www.microsoft.com/en-us/legal/intellectualproperty/trademarks) (bí a ti ń ṣàtúnṣe láti ìgbàdégbà). Microsoft àti àwọn orúkọ, àmì ìdánimọ̀, àti àwọn àwòrán ti gbogbo àgbéjáde Microsoft, ẹ̀yà àìrídìmú, àti àwọn iṣẹ́ le jẹ́ yálà àìforúkọsílẹ̀ tàbí àmì òwò tí a kọsílẹ̀ ti ilé iṣẹ́ àpapọ̀ Microsoft ní Amerika àti/tàbí àwọn agbègbè míràn. Ìwọ̀nyí ni àkójọ̀ àmì ìṣòwò Microsoft tí a kọsílẹ̀ ṣùgbọ́n tó jù bẹ́ẹ̀ lọ ní https://cdn-dynmedia-1.microsoft.com/is/content/microsoftcorp/microsoft/mscle/documents/presentations/TrademarksListFY25Q3.pdf. Àwọn orúkọ àwọn ilé-iṣẹ́ àti ọjà gidi lè jẹ́ ààmì ọjà-títà àwọn oníhun wọn. Àwọn ẹ̀tọ́ yòówù tí a kò fífún ni nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà ní ìpamọ́. Àwọn ẹ̀yà àìrídìmú tí a lò ní àwọn olùpín àyè ayélujára Microsoft kan dá lórí iṣẹ́ òmìnira Ẹgbẹ́ JPEG. Copyright © 1991-1996 Thomas G. Lane. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́. ẹ̀yà àìrídìmú "gnuplot" tí a ń lò nínú àwọn apèsè ojúlé wẹ́ẹ̀bù Microsoft kan jẹ́ tí àṣẹ ìtajà © 1986‑1993 Thomas Williams, Colin Kelley. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́.
Àkíyèsi Ìtọ́jú Ìlera. Microsoft kìí pèsè ìtọ́jú ìlera tàbí ìmọràn ìtọ́jú ìlera, ìwádìí àti àyẹwò àìsàn tàbí ìtọ́jú yòówù. Má a wá ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ dọkítà rẹ tàbí àwọn àkọṣẹmọṣẹ olùpèsè iṣẹ ìlera mìíràn nípa ìbéèrè yòówù tí o lè ní nípa ipò ìlera kan, oúnjẹ, tàbi ètò wíwà ní àlàáfíà. Máṣe fojú fo ìmọ̀ràn ìtọ́jú ìlera tàbí kí o sọ àsìkò nù ní wíwá a rí nítorí àlàyé tí o wọlé sí lórí tàbí nípasẹ àwọn Iṣẹ́ náà.
Àwọn àlàyé iye owó tó wà lórí ilé-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan àti détà rẹ (èyí tó kan iye ìtọ́kasí). Ìwífún ìṣòwò tí o pèsè nípasẹ̀ Àwọn ìpèsè náà wà fún ìlò ti ara rẹ, èyí tí kìn ṣe ọrọ̀ ajé. O kò gbọ́dọ̀ lo èyíkèyí lára àwọn détà ìṣúná tàbí àwọn ààmì èyíkèyí àṣẹ ẹlòmíràn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú onígbọ̀wọ́, títajà, ṣíṣòwò, tàbí mímú ìlọsíwájú bá àwọn irin-iṣẹ́ ìṣúná owó tàbí àwọn ọjà ìfọwóṣòwò yóòwù (fún àpẹrẹ ọjà tí a ṣe ní àkànṣe, àwọn owó ìfiṣòwò, àwọn owó pàṣípàrọ̀ òwò, àwọn ètò ìfowóṣòwò, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, níbití iye owó, ìdápadà tàbí ìṣesí irin-iṣẹ́ tàbí ọjà ìfiṣòwò náà dá lórí, tàbí níí ṣe pẹ̀lú, tàbí gbèrò láti tọpasẹ èyíkèyí fún èyíkèyí pẹ̀lú détà ìṣúnà) láì gba ìfọwọ́sí pẹ̀lú àṣẹ ẹnikẹta.
Àkíyèsi Ìṣúná Owó. Microsoft kìí ṣe adíìnádúrà/alágbàtà tàbí olùdámọràn ìfowóṣòwò tó ní àṣẹ lábẹ òfin ààbò ìjọba àpapọ United States ní àwọn ipò ìdájọ́ mìíràn, òun kìí sì fún ni ní ìmọràn nípa fífowóṣòwò, rírà, tàbí títa àwọn ọjà tó ní ààbò tàbí àwọn ọjà tàbí iṣẹ ìṣòwò mìíràn. Kò sí ohunkóhun nínú àwọn Iṣẹ yìí tó jẹ ìfilọ tàbi ẹ̀bẹ̀ láti ra tàbí ta ọjà tó ní ààbò yòówù. Yálà Microsoft tàbí àwọn tó nfún ni ní ìwé-àṣẹ lábẹ rẹ fún àlàyé iye owó tó wà lórí ilé-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tàbí détà ìtọkasí ní ó fọwọsi tàbí dámọràn ọjà tàbí iṣẹ ìṣúná owó kan pàtó. Kò sí ohun kankan nínú Àwọn Ìpèsè náà ti a ṣe láti jẹ́ ìmọ̀ràn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, pẹ̀lú àìní òdíwọ̀n, ìdókòwò tàbí ìmọ̀ràn owó-orí.
Àkíyèsi nípa gègé ìdíwọ̀n Fidio H.264/AVC àti VC-1. Lára ẹ̀yà àìrídìmú náà lè jẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ H.264/AVC àti/tàbí VC-1 tí MPEG LA, L.L.C fún ní ìwé-àṣe. Iṣẹ́ ìmọ ẹ̀rọ yìí jẹ ìlànà àfúnpọ détà fún àlàyé fidio. MPEG LA, L.L.C. nílò àkíyèsi yìí:
A FÚN NI NÍ ÌWWÉ-ÀṢẸ FÚN ỌJÀ YÌÍ LABẸ ÌWÉ-ÀṢẸ H.264/AVC, ÀTI VC-1 FÚN ÌMÚLÒ ARA ẸNI LÁÌFIṢÒWÒ FÚN AṢÀMÚLÒ ÌKẸYÌN LÁTI (A) FI KÓÒDÙ SÍ FIDIO NÍ ÌBÁMU PẸLU GÈGÉ ÌDÍWỌN (¨ÀWỌN GÈGÉ ÌDÍWỌN´) ÀTI/TÀBÍ (B) YỌ KÓÒDÙ KÚRÒ LÁRA FIDIO H.264/AVC, ÀFOJÚRÍ MPEG-4, ÀTI VC-1 TÍ A FI KÓÒDÙ SÍ NÍPASẸ AṢÀMÚLÒ ÌKẸYÌN TÍ NṢE OHUN ÀMÚṢE TI ARA ẸNI LÁÌFIṢÒWÒ, ÀTI/TÀBÍ TÍ A GBÀ LÁTI ỌWỌ OLÙPÈSÈ FIDIO TÓ NÍ ÌWÉ-ÀṢẸ LÁTI PÈSÈ IRÚ FIDIO BẸẸ. A KÒ FÚN NI NÍ ÌWÉ-ÀṢẸ TÀBÍ A KÓ GBÈRÒ RẸ FÚN ÌMÚLÒ MÌÍRÀN. ÀFIKÚN ÀLÀYÉ NI A LÈ GBÀ LÁTI ỌWỌ MPEG LA, L.L.C. WO MPEG LA WEBSITE (https://www.mpegla.com).
Fún èrèdí ìmúdánilójú nìkan, àkíyèsi yìí kò fi àlà sí tàbí dènà ìmúlò ẹya àìrídìmú tí a pèsè labẹ àwọn Àdéhùn wọnyi fún ìmúlò ìṣòwò tó jẹ ti ara ẹni tí kò kan (i) àtúnpín kiri ẹya àìrídìmú náà fún àwọn ẹlomiran, tàbí (ii) ṣiṣẹda ohun àmúlò pẹlu GÈGÉ IDIWỌN FIDIO tó bá iṣẹ imọ ẹrọ fún pípín kiri fún àwọn ẹlomiran mu.
Àkíyèsi nípa gègé ìdíwọ̀n Fidio H.265/HEVC. Ẹyà àìrídìmú lẹ pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ H.265/HEVC. Ìlọsíwájú Ìráyèsí LLC LA, L.L.C. nílò àkíyèsi yìí:
TÍ Ó BÁ PẸLÚ, ÌMÒ ẸRỌ H.265/HEVC NÍNÚ ẸYÀ ÀÌRÍDÌMÚ YÌÍ NI Ó JẸ BÍBÒ NÍPASẸ ÌKAN TÀBÍ PÚPỌ ÀWỌN ÈTÓ TI ÀTÒKỌ ÌTÓSÍ NÍ: PATENTLIST.ACCESSADVANCE.COM. TÓ DÁ LÓRÍ BÍ O ṢE GBA ÈYÀ ÀÌRÍDÌMÚ NÁÀ, ÀBÁJÁDE YÌÍ LÈ NÍ ÌWÉ ÀṢẸ LÁBÉ ÈKA ÌTÓSÍ ÌLÓSÍWÁJÚ HEVC.
Tí ẹ̀yà àìrídìmú yìí bá ṣàfilọ́lẹ̀ lórí ohun èlò Microsoft, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé àfikún ìwé àṣẹ ní a lè rí ní: aka.ms/HEVCVirtualPatentMarking.
ÀWỌN ÌFẸNUKÒ ÀṢẸ GBÈDÉKE ÀTÒJỌ ÈTÒ
ÀWỌN ÀDÉHÙN ÌWÉ-ÀṢẸ OHUN ÈLÒ DÉÉDÉ
MICROSOFT STORE, MICROSOFT STORE LÓRÍ WINDOWS, ÀTI MICROSOFT STORE LÓRÍ XBOX
Àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ wọ̀nyí jẹ́ ìfohùnṣọ̀kàn láàárín ìwọ àti olùgbéjáde ohun èlò náà. Jọ̀wọ́ kà wọ́n. Èyí kan àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ ẹ̀yà àìrídìmú tí o gbà sílẹ̀ láti Ìtajà Oníforíkorí Microsoft, Microsoft Store on Windows tàbí Microsoft Store on Xbox (ìkọ̀ọ̀kan èyí tí a ń pè ní "Ìtajà Oníforíkorí" nínú àdéhùn ìgbaniláyè wọ̀nyí), pẹ̀lú èyíkéyìí àfikún tàbí àfikún ìmúdára fún ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, àyàfi tí ìṣàfilọ́lẹ̀ náà bá wá pẹ̀lú àdéhùn ọ̀tọ̀tọ̀, nínú èyítí a ń ṣàmúlò àdéhùn wọ̀nyí.
NÍPA GBÍGBÉWÁLẸ̀ TÀBÍ LÍLO OHUN ÈLÒ NÁÀ, TÀBÍ GBÍGBÌYÀNJÚ LÁTI ṢE ÈYÍKÉÈYÍ NÍNÚ ÀWỌN WỌ̀NYÍ, ÌWỌ FARAMỌ́ ÀWỌN ÀDÉHÙN WỌ̀NYÍ. BÍ O KÒ BÁ FARAMỌ́ WỌN, ÌWỌ KÒ NÍ Ẹ̀TỌ́ LÁTI, O KÒ SÌ GBỌDỌ̀ GBÉ OHUN ÈLÒ NÁÀ WÁLẸ̀ TÀBÍ KÍ O LÒÓ.
Olùtẹ̀jáde ìṣàfilọ́lẹ̀ náà túmọ̀ sí ẹni tí ń fún ọ ní ìgbaniláyè sí ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, bí a ti dáamọ̀ nínú Ìtajà Oníforíkorí náà.
Bí o bá mú àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ wọ̀nyí ṣe, ìwọ ní àwọn ẹ̀tọ́ tí a kọ sí ìsàlẹ̀ wọ̀nyí.
- 1. AWỌN ẸTỌ NIPA FÍFI SORI ẸRỌ ATI LÍLÒ; PÍPARÍ IṢẸ́. O le ṣàgbékalẹ̀ kí o sì lo ìfilọ́lẹ̀ náà lórí àwọn ohun èlò Windows tàbí àwọn kọ́nsòlù Xbox bí a ti júwe nínú Òfin Ìlò Microsoft (https://go.microsoft.com/fwlink/p/?LinkId=723143). Microsoft ni ó ni ẹ̀tọ́ láti ṣàtúnṣe sí Òfin Ìlò Microsoft (https://go.microsoft.com/fwlink/p/?LinkId=723143) nígbà yòówù.
- 2. ÀWỌN IṢẸ́ TÍ À NṢE LÓRÍ AYÉLUJÁRA.
- a. Ìfaramọ́ fún Àwọn iṣẹ́ tí à nṣe lórí Ayélujára. Bí ohun èlò náà bá nso pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀rọ kọmputa lórí Ayélujára, èyí tí ó lè kan nípasẹ̀ nẹtiwọki aláìlowáyà, lílo ohun èlò náà nṣiṣẹ́ bíi ìfaramọ́ rẹ fún gbígbé àwọn àlàyé ẹ̀rọ káàkiri (èyí tí ó kàn, ṣùgbọ́n tí kò parí sí àlàyé iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ nípa ẹ̀rọ àti ẹ̀yà àìrídìmú ohun èlò rẹ, àti àwọn àsopọ̀mọ́ ẹ̀rọ) fún àwọn iṣẹ́ tí à nṣe lórí ayélujára tàbí àwọn iṣẹ́ aláìlowáyà. Bí a bá pèsè àwọn àdéhùn mìíràn pẹ̀lú ìmúlò rẹ fún àwọn iṣẹ́ tí à nwọlé sí nípasẹ̀ ohun èlò náà, àwọn àdéhùn náà tún ní ipa.
- b. Àṣìlò Awọn iṣẹ ti a nṣe lori Ayelujara. O kò gbọ́dọ̀ lo iṣẹ́ yòówù tí à nṣe lórí Ayélujára ni ọ̀nà yòówù tí ó lè mú ìpalára bá a tàbí lọ́nà tí yoo dí bí àwọn ẹlomiiran ṣe nlò ó tàbí nẹtiwọki aláìlowáyà náà lọ́wọ́. O kò gbọ́dọ̀ lo iṣẹ́ náà lati gbìyànjú lati wọlé, láì ní àṣẹ, sí iṣẹ́ yòówù, détà, àkọọ́lẹ̀, tàbí nẹ́tíwọọ̀kì, lọ́nàkọnà.
- 3. ÌDÍWỌ̀N AGBÁRA ÌWÉ-ÀṢẸ. A gba ìwé-àṣẹ fun ohun èlò naa ni, a ko tà á. Ìfohùnṣọ̀kan yìí fún ọ ní àwọn ẹ̀tọ́ kan nìkan lati lo ohun èlò náà. Bí Microsoft bá mú kí agbára àti lo àwọn ohun èlò náà má ṣiṣẹ́ lórí àwọn ẹ̀rọ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìfohùnṣọkan rẹ pẹ̀lú Microsoft, àwọn ẹ̀tọ́ ìwé-ẹ̀rí yòówú tó níí ṣe pẹ̀lú rẹ̀ yóò dópin. Olùgbéjáde ohun èlò náà ni ó ní gbogbo ẹ̀tọ́ mìíràn yòókù. Àfi bí òfin tí ó yẹ bá fún ọ ni ẹ̀tọ́ síwájú síi láì ka ìhámọ́ yi si, o lè lo ohun èlò naa gẹ́gẹ́ bí a ti gbà ọ́ láàyè ninu ìfohùnṣọ̀kan yìí nìkan. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìhámọ́ yòówù nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ohun èlò náà, èyítí ó fún ọ ni ànfàní láti lòó ní àwọn ọ̀nà kan nìkan. Ìwọ kò gbọdọ̀:
- a. Dá ọgbọ́n sí ìhámọ́ yòówù nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ohun èlò náà;
- b. Tún iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tò, tú ohun èlò náà palẹ̀, àfi dé ibiti òfin ti o yẹ bá fún ọ ní ẹ̀tọ́ dé, láì ka ìhámọ́ yìí sí;
- c. Ṣe ẹ̀dà ohun èlò náà síwájú síi ju bí a ti sọ nínú ìfohùnṣọ̀kan yìí tàbí bí òfin tó yẹ ti gba ni láàyè, láì ka ìhámọ́ yìí sí;
- d. Ṣe àgbéjáde tàbí mú kí ohun èlò náà wà fún àwọn ẹlòmíràn láti ṣe ẹ̀dà rẹ̀.
- e. Yá ẹlòmíràn ní ẹ̀yà àìrídìmú náà ní ìrètí àti gba owó tàbí ní ìrètí pé wọn yóò dá a padà lẹ́yìn ìgbà díẹ̀;
- f. Fi ìfilọ́lẹ̀ tàbí àdéhùn yìí fún ẹnìkẹta yòówù.
- 4. ṢÍṢE ÀKỌSÍLẸ̀. Bí a bá pèsè àkọsílẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò náà, o lè da àkọsílẹ̀ inú rẹ̀ kọ, o sì lè lòó fún ànfàní ìwádìí ti ara rẹ.
- 5. ÀWỌN ÌHÁMỌ́ NÍPA IṢẸ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÀTI TI GBÍGBÉ ỌJÀ LỌ SÍ ILẸ̀ OKÈÈRÈ FÚN TÍTÀ. Ohùn èlò yìí wà lábẹ́ òfin àti ìlànà orílẹ̀-èdè Amẹrika fún gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà. O gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún gbogbo òfin àti ìlànà gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà ti ìlú ẹni àti ti ilẹ̀ òkèèrè tó kan ìmọ̀ ẹ̀rọ tí a lò tàbí tí ohun èlò náà ṣe àtìlẹ́yìn fún. Lára àwọn òfin wọ̀nyí ní ìhámọ́ nípa ibití à ngbé ọjà náà lọ, àwọn aṣàmúlò ìkẹyìn ati ìmúlò ìkẹyìn. Fún àlàyé nípa àwọn ọjà tó ní ààmì Microsoft lára, lọ sí àyè ayélujára Microsoft fún gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà (https://go.microsoft.com/fwlink/?linkid=868967).
- 6. AWỌN IṢẸ́ ÀTÌLẸ́YÌN. Kàn sí olùgbéjáde ohun èlò náà láti mọ àwọn iṣẹ́ àtìlẹ́yìn tó wà. Microsoft, olùpèsè ẹ̀yà àfojúrí rẹ àti ilé-iṣẹ́ tí npèsè ìbáraẹnisọ̀rọ̀ rẹ (àfi bí ọ̀kan nínú wọn bá jẹ́ olùgbéjáde ohun èlò náà) kò ní ojúṣe fún pípèsè iṣẹ́ àtìlẹ́yìn fún ohun èlò náà.
- 7. ÀKÓPỌ̀ GBOGBO ÌFOHÙNṢỌ̀KAN. Ìfohùnṣọ̀kan yìí, àti òfin ìkọ̀kọ̀ tó yẹ yòówù, àfikún àdéhùn yòówù tó lè bá ohun èlò náà wá, àti àwọn àdéhùn fún àwọn àfikún àti ìmúdójúìwọ̀n, jẹ́ ìfohùnṣọ̀kan ìwé-ẹ̀rí lápapọ̀ láàárín ìwọ àti olùgbéjáde ohun èlò fún ohun èlò náà.
- 8. ÒFIN TÓ NṢIṢẸ́.
- a. United States àti Canada. Bí o bá ra ohun èlò náà ní United States tàbí Canada, àwọn òfin ìpínlẹ̀ tàbí agbègbè ibití ìwọ ngbé (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, ibití olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà) ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn ìfohùnṣọ̀kan yìí, ó sì kan ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá síi, àti gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ mìíràn (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́) láì ka awọn òfin miiran tó rọ̀ mọ́ èyí, ti wọ́n si le yàtọ̀ síi kún.
- b. Lóde United States àti Canada. Bí o bá ra ohun èlò náà ní orílẹ̀-èdè miiran, òfin orílẹ̀-èdè náà ni a ó lò.
- 9. IPA TI ÒFIN NÍ. Ìfohùnṣọ̀kan yìí ṣe àpèjúwe àwọn ẹ̀tọ́ ẹni kan lábẹ́ òfin. Ìwọ lè ni àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn lábẹ́ àwọn òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè rẹ. Ìfohùnṣọ̀kan yìí kò yí àwọn ẹ̀tọ́ rẹ lábẹ́ àwọn òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè rẹ padà bí àwọn òfin ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè rẹ kò bá gbà á láàyè lati ṣe bẹ́ẹ̀.
- 10. ÌKỌ̀SÍLẸ̀ ÀTÌLẸ́YÌN. látàrí òfin tó dè, àtòjọ ètò náà gba àṣẹ "bí ó ṣe rí", pẹ̀lú gbogbo àṣìṣe¨ àti bí ó ṣe wà. Ìwọ ni ó ni gbogbo ewu tó wà nínú lílò ó. Olùgbéjáde ohun èlò náà, lórúkọ ara rẹ̀, Microsoft (bí Microsoft kìí bá ṣe olùgbéjáde rẹ̀), àwọn tí npèsè iṣẹ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ aláìlowáyà, lórí nẹtiwọki àwọn ẹnití a ti pèsè ohun èlò náà, àti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ wa, alágbàtà, aṣojú àti olùpèsè (¨Àwọn Ẹni Tó Wà Lábẹ́ Rẹ̀¨), kò ṣe àtìlẹ́yìn tààrà, àfẹ̀hìntì, tàbí májẹ̀mú nípa ohun èlò náà. Gbogbo ewu tó wà nípa dídára, níní ààbò, rírọrùn, àti iṣẹ́-ṣíṣe ohun èlò náà jẹ́ tìrẹ. Bí ohun èlò náà bá ní àbàwọ́n, o faramọ́ gbogbo iye owó àbójútó àti àtúnṣe. Ìwọ lè ni àwọn àfikún ẹ̀tọ́ aṣàmúlò ìkẹyìn tàbi àwọn àtìlẹ́yìn ìṣedéédé miiran lábẹ́ àwọn òfin agbègbè rẹ, àwọn èyí tí ìfohùnṣọ̀kan yìí kò lè yípadà. Títí dé ibití òfin agbègbè rẹ fi ààyè gba ni dé, Àwọn Ẹni Tó Wà Lábẹ́ Rẹ̀ mú àwọn àtìlẹ́yìn ìdápadà tàbí májẹ̀mú tí a kò mẹ́nubà tààrà nípa ṣíṣeétà, yíyẹ fún lílò kan pàtó, níní ààbò, rírọrùn ati àìgbọdọ̀ tàpá sí ẹ̀tọ́ ẹlomiiran, kúrò.
- 11. ÌHÁMỌ́ ATI ÌYỌKÚRÒ LÓRÍ IYE OWÓ ÀTÚNṢE ATI ÀSANPADÀ FÚN ÌBÀJẸ́. Títí dé ibití òfin kò ti ṣe ìdènà dé, bí o bá ní ìdí kankan fún gbígba àsanpada, o lè gbà awọn àsanpadà tààrà láti ọwọ́ olùgbéjáde ohun elò ní iye tó tó iye owó tí o san fún ohun èlò náà tàbí USD$1.00, èyíkéèyí tó bá pọ̀ jù nínú méjèèjì. látàrí òfin tó dè, iwọ kii yoo, ati gba eyikeyi ẹtọ si, wa lati gba eyikeyi awọn ibajẹ miiran pada, pẹlu iyọrisi, awọn ere ti o sọnù, pataki, aiṣe-taara tabi awọn ibajẹ iṣẹlẹ lati akede ohun elo. Ti awọn ofin agbegbe rẹ ba ṣe àtìlẹyìn ọja, iṣeduro tabi ipo botilẹjẹpe awọn ofin wọnyi ko ba ṣe, labẹ ofin ti o wulo, iye akoko rẹ ti ni opin si 90-ọjọ lati igba ti o ṣe igbasilẹ ohun elo naa.
Ìhámọ́ naa tun kan:
- Ohun yòówù tó níí ṣe pẹ̀lú ohun èlò tàbí àwọn iṣẹ́ náà tó wà nípasẹ̀ ohun èlò náà; àti
- Àwọn gbígba ẹ̀tọ́ fún rírú òfin àdéhùn, rírú òfin àtìlẹ́yìn, tàbí ìlànà, dídáhùn fún ni tó pọn dandan, àìbìkítà, tàbí àwọn òfin ti ndarí ìwà àìtọ́ titi dé ibiti òfin fi ààyè gba ni dé.
O tún ṣì ní ipa bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé:
- Àtúnṣe yìí ko ṣe àsanpadà fún ọ lẹkunrẹrẹ fún àwọn àdánù yòówù; tàbí
- Olùgbéjáde ohun èlò náà mọ̀ tàbí ó yẹ kí ó mọ̀ nípa wíwáyé irú àwọn ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀.
Àwọn Iṣẹ́ Tó Kàn
Àwọn ọjà, ohun èlò àti iṣẹ wọnyi ni Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft kàn, ṣugbọn wọn lè má wà ní ọjà rẹ.
- Account.microsoft.com
- Aṣèrànwọ́ Àtìlẹyìn àti Ìràpadà Microsoft fún Office 365
- Bing Apps
- Bing Dictionary
- Bing Image and News (iOS)
- Bing Search APIs/SDKs
- Bing Search app
- Bing Translator
- Bing Webmaster
- Bing.com
- Bingplaces.com
- Clipchamp
- Cortana skills by Microsoft
- Cortana
- Default Homepage and New Tab Page on Microsoft Edge
- Dev Center App
- Device Health App
- Dictate
- education.minecraft.net
- Face Swap
- Feedback Intake Tool for Azure Maps (aka “Azure Maps Feedback”)
- Forms.microsoft.com
- forzamotorsport.net
- Groove Music Pass
- Groove
- GroupMe
- Image Creator from Microsoft Designer
- LineBack
- Link to Windows
- Maps App
- Microsoft 365 Business Standard, Microsoft 365 Business Basic, Microsoft 365 Apps, Microsoft 365 app, Microsoft 365 Copilot, Microsoft 365 Copilot app, and Microsoft 365 Copilot Chat*
- *Until a commercial domain is established for use of these services, at which time separate Microsoft commercial terms will govern instead.
- Microsoft 365 Consumer
- Microsoft 365 Family
- Microsoft 365 fún ayélujára
- Microsoft 365 Personal
- Microsoft Academic
- Microsoft Add-Ins for Skype
- Microsoft Bots
- Microsoft Copilot
- Microsoft Defender fún olúkálùkú
- Microsoft Educator Community
- Microsoft Family
- Microsoft Health
- Microsoft Launcher
- Microsoft Loop
- Microsoft Pay
- Microsoft Pix
- Microsoft Reading Coach
- Microsoft Research Interactive Science
- Microsoft Research Open Data
- Microsoft Rewards
- Microsoft Soundscape
- Microsoft Sway
- Microsoft Teams
- Microsoft Translator
- Microsoft Wallpaper
- Minecraft Realms Plus and Minecraft Realms
- Mixer
- MSN (tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí Microsoft Start)
- MSN Dial Up
- MSN Explorer
- MSN Food & Drink
- MSN Health & Fitness
- MSN Money
- MSN News
- MSN Premium
- MSN Sports
- MSN Travel
- MSN Weather
- MSN.com
- Next Lock Screen
- Office Store
- Olùyanjú Ìṣirò Microsoft
- Olùṣàkóso Skype
- OneDrive.com
- OneDrive
- OneNote.com
- Outlook.com
- Paint 3D
- Phone Link
- Presentation Translator
- rise4fun
- Seeing AI
- Send
- Skype in the Classroom
- Skype.com
- Skype
- Smart Search
- Snip Insights
- Spreadsheet Keyboard
- Sway.com
- to-do.microsoft.com
- Translator for Microsoft Edge
- Translator Live
- Universal Human Relevance System (UHRS)
- UrWeather
- ux.microsoft.com
- Video Breakdown
- Visio Online
- Web Translator
- whiteboard.office.com
- Windows Live Mail
- Windows Live Writer
- Windows Movie Maker
- Windows Photo Gallery
- Xbox Game Pass
- Xbox Live Gold
- Xbox Live
- Xbox Music
- Xbox Store
- Àkọọ́lẹ̀ Microsoft
- Àtìlẹ́yín Microsoft (Aṣàmúlò Ìkẹyìn)
- Àwọn Fíìmù àti TV Microsoft
- Àwọn Ojú-ìwé Bing
- Àwọn eré Minecraft
- Àwọn eré Xbox àti Windows, Àwọn ìfilọ́lẹ̀ àti ojúlé wẹ́ẹ̀bù tí Microsoft ṣe àgbéjáde wọn
- Àwọn eré, ìfilọ́lẹ̀ àti ojúlé wẹ́ẹ̀bù Windows tí Microsoft ṣàgbéjáde wọn
- Àwọn eré, ìfilọ́lẹ̀ àti ojúlé wẹ́ẹ̀bù Xbox Game Studios
- Àwọn Àkójọpọ̀ Microsoft
- Àwọn Àkójọpọ̀
- Àwọn Àwòrán Ayé Bing
- Àwọn Ìdínwókù Bing
- Àwọn ìfilọ́lẹ̀ àti ìpèsè tó wà lára Microsoft 365 Àdáni
- Àwọn ìfilọ́lẹ̀ àti ìpèsè tó wà lára Microsoft 365 Ìpìlẹ̀
- Àwọn ìfilọ́lẹ̀ àti ìpèsè tó wà lára ṣíṣe-alábàápín aṣàmúlò Microsoft 365
- Àwọn ìfilọ́lẹ̀ àti ìpèsè tó wà lára Ẹbí Microsoft 365
- Àwọn ìrírí Microsoft 365 aláṣàyàn ti a so pọ̀
- Ìfilọ́lẹ̀ Aṣètò SMS
- Ìtajà oníforíkorí Windows
- Ìtajà oníforíkorí
- Ìṣàwárí Microsoft nínú Bing
- Ẹ̀yà ọ̀fẹ́ Microsoft 365