Àlàyé ní ṣókí nípa àwọn Àyipadà si Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft – Ọjọ́ 30, Oṣù Kẹsàn-án, Ọdún 2025
Àwa nmú Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft dójú ìwọ̀n, èyí tí ó kan bí o ti nlo àwọn àgbéjáde tàbí ìpèsè Microsoft lórí ayélujára fún aṣàmúlò ìkẹyìn. Ojú-ìwé yìí n pèsè àlàyé ní ṣókí nípa àwọn àyípadà pàtàkì sí Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft.
Láti lè rí gbogbo àwọn àyípadà náà, jọ̀wọ́ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft níbí.
- Nínú àkòrí, a ti sún ọjọ́ tí àwa yóò ṣe àgbéjáde sí ọjọ́ 30, Oṣù Keje, Ọdún 2025, àti ọjọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sí ọjọ́ 30, Oṣù Kẹsàn-án, Ọdún 2025.
- Ní abala “Àkóónú Rẹ”, a fi abala tuntun "c." kún un, èyí tó nsọ nípa détà tó ṣeé gbé lọ láti ibìkan sí òmíràn.
- Ní abala “Àtìlẹ́yìn’, laarin abala “Lílo Àwọn Iṣẹ́ & Àtìlẹ́yìn“, a ṣe àwọn àtúnkọ kan tó yọ àwọn ọ̀rọ̀ atọ́ka-ọ̀nà tí kò tọ́ kúrò, tó sì ṣàlàyé pé àwọn Ìpèsè kan lè má a pèsè àtìlẹ́yìn ọ̀tọ̀ tàbí àfikún, àti pé àwọn àtílẹ́yìn bẹ́ẹ̀ lè wà lábẹ́ àwọn àdéhùn tí kò sí lára Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft.
- A yọ abala “Fún àwọn aṣàmúlò tí ngbé ní Australia” kúrò lábẹ́ abala “Àtìlẹ́yìn” nítorí àwọn àyípadà sí àwọn òfin agbègbè náà.
- Lábẹ́ abala “Asia tàbí Gúsù Pacific, àfi bí a bá dárúkọ orílẹ̀-èdè rẹ ní pàtó nísàlẹ̀ yìí”, nínú “Àjọ Tí Ń Ṣàdéhùn, Ẹ̀yàn Òfin, àti Ibití A Ti le Parí Aáwọ̀”, a ti yọ àwọn àdéhùn fún àwọn tó ngbé ní Australia kúrò nítorí àyípadà sí àwọn òfin agbègbè náà.
- Ní abala “Àwọn Ìfúnni Ìgbà Ìdánwò”, nínú abala “Àwọn Àwíyé Ìsanwó”, a ti fi ọ̀rọ̀ tó pọ̀ síi kún un láti sọ àsọyé nípa pé àwọn ìfúnni ìgbà ìdánwò kan lè nílò pé kí a tan ìsọdọ̀tun-àfúnraẹniṣe.
- Ní abala “Àwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtó“, a ṣe àwọn àfikún àti àyípadà wọ̀nyí:
- Ní abala “Àwọn Ìpèsè Xbox”, nínú abala “Xbox”, a sọ àsọyé síwájú síi pé wíwọlé sí ẹ̀rọ tàbí pẹpẹ-iṣẹ́ kan pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ, tàbí síso àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ pọ̀ mọ́ irú ẹ̀rọ tàbí pẹpẹ-iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ láti ráàyèsí ìpèsè tí kìí ṣe ti Microsoft fi ọ́ sábẹ́ àwọn ẹ̀tọ́ ìṣàmúlò Microsoft tí a ṣàlàyé ní abala náà. Ní àfikún, a sọ àsọyé síwájú síi pé ó ṣeé ṣe kí a má mú àwọn ètò Ààbò Ẹbí tó jẹ́ mọ́ Xbox nìkan ṣiṣẹ́ nígbàtí a bá nráàyè sínú àwọn eré tàbí ìpèsè Xbox Game Studios nípasẹ̀ ẹ̀rọ tàbí pẹpẹ-iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn.
- Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àyípadà tí a ṣe nínú abala “Àwọn Ìpèsè Xbox”, a ti fi ọ̀rọ̀ tó pọ̀ síi kún abala “Àwọn Àfidámọ̀ Microsoft Family”, lábẹ́ abala “Xbox”, nípa pé ó ṣeé ṣe kí a má mú àwọn ètò Ààbò Ẹbí tó jẹ́ mọ́ Xbox nìkan ṣiṣẹ́ nígbàtí a bá nráàyè sínú àwọn eré tàbí ìpèsè Xbox Game Studios nípasẹ̀ ẹ̀rọ tàbí pẹpẹ-iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn.
- A ṣe àwọn àtúnṣe sí abala “Skype, Microsoft Teams, àti GroupMe” láti lè pèsè àlàyé fún dídá iṣẹ́ Skype dúró.
- A ṣe àtúnṣe sí abala “Àwọn ìdènà àti Àwọn gbèdéke lórí Àmì”, lábẹ́ abala “Microsoft Rewards” láti lè ṣàlàyé pé àwọn ààmì tí a kò bá ràpadà kì yóò ṣiṣẹ́ mọ́ tí a kò bá gba ààmì yòówù tàbí kí a rà wọ́n padà fún oṣù 12 léraléra.
- A ṣe àtúnṣe sí abala “Fífagilé Àkọọ́lẹ̀ Èrè Rẹ”, lábẹ́ abala “Microsoft Rewards” láti ṣàlàyé pé ó ṣeé ṣe láti fagilé àkọọ́lẹ̀ Rewards bí a kò bá wọlé síi fún oṣù 12 léraléra.
- A fi abala tuntun nípa àwọn ìdènà ìmúlò kún abala “Àwọn Iṣẹ́ AI”.
- A ti fi abala tuntun “Àwọn Ìpèsè Ìbáraẹnisọ̀rọ̀” kún un, èyí tó ń sọ pé àwọn ìpèsè tó ń mú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ laarin àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, gẹ́gẹ́ bíi Skype, Teams, àti Outlook, wà lábẹ́ àwọn àfikún àdéhùn ìṣàmúlò. Àwọn àdéhùn wọ̀nyí ni a mẹ́nubà, tí a sì fi ọ̀nà-àsopọ̀ wọn sínú abala yìí.
- Jálẹ̀ àwọn Àdéhùn náà, a ti ṣe àwọn àyípadà kan láti lè mú ohun gbogbo yé ni síi, àti láti lè ṣe àtúnṣe sí àwọn gírámà, àṣìtẹ̀ ọ̀rọ̀ àti irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mìíràn. A tún ti mú ìsọlórúkọ àti àwọn ọ̀rọ̀ atọ́ka-ọ̀nà dóju ìwọ̀n.